ORÍ KỌKÀNLÁ
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?
Ọ̀ràn pàtàkì wo ló jẹ yọ nínú ọgbà Édẹ́nì?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ohun tí ìyà tó ń jẹ aráyé ti fà kúrò?
1, 2. Irú ìyà wo ló ń jẹ aráyé lónìí, ìbéèrè wo lèyí sì mú káwọn èèyàn máa béèrè?
LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ kan tí wọ́n ti ja ogun àjàkú akátá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tógun pa, ni wọ́n sin pọ̀ sínú kòtò gìrìwò kan. Wọ́n ri àwọn àmì kan yí kòtò gìrìwò náà ká, ohun tí wọ́n sì kọ sára àwọn àmì náà ni: “Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀?” Ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nìyẹn tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bá ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn máa ń béèrè ìbéèrè yẹn nígbà tí ogun, àjálù, àrùn tàbí ìwà ọ̀daràn bá gbẹ̀mí àwọn èèyàn wọn, tàbí tó ba ilé wọn jẹ́, tàbí tó fìyà tó pọ̀ jẹ wọ́n láwọn ọ̀nà mìíràn. Wọ́n máa ń fẹ́ mọ ìdí tírú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi bẹ́ẹ̀ fi ṣẹlẹ̀ sí wọn.
2 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé? Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ alágbára, tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tó jẹ́ ọlọgbọ́n tó sì ń ṣe ohun tó tọ́, kí nìdí tí ìkórìíra àti ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ tó báyìí láyé? Ǹjẹ́ o ti ronú bẹ́ẹ̀ rí?
3, 4. (a) Kí ló fi hàn pé kò burú téèyàn bá béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ́ èèyàn? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìwà ibi àti ìyà tó ń jẹ aráyé?
3 Ǹjẹ́ ó burú kéèyàn béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ́ èèyàn? Àwọn kan rò pé táwọn bá béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, àwọn ò nígbàgbọ́ nìyẹn tàbí pé àwọn ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Àmọ́, tó o bá ka Bíbélì, wàá rí i pé àwọn èèyàn olóòótọ́ tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ti béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí rí. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù bi Jèhófà pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?”—Hábákúkù 1:3.
4 Ǹjẹ́ Jèhófà sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí Hábákúkù nítorí pé ó béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí Hábákúkù sọ di ara àkọsílẹ̀ Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí. Ọlọ́run tún ran Hábákúkù lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ ìdí tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ṣẹlẹ̀ ó sì ràn án lọ́wọ́ kó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún ìwọ náà nìyẹn. Rántí pé Bíbélì fi kọ́ni pé “Ó bìkítà fún [ọ].” (1 Pétérù 5:7) Ọlọ́run kórìíra ìwà ibi àti ìyà tí ìwà ibi máa ń fà fún aráyé ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. (Aísáyà 55:8, 9) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
KÍ LÓ DÉ TÍ ÌYÀ FI PỌ̀ TÓ BẸ́Ẹ̀?
5. Nígbà mìíràn, kí làwọn ohun táwọn èèyàn máa ń sọ pé ó jẹ́ ìdí téèyàn fi ń jìyà, ṣùgbọ́n ki ni Bíbélì fi kọ́ni?
5 Àwọn èèyàn nínú onírúurú ẹ̀sìn ló máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn àtàwọn tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nípa ìdí tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ìdáhùn tí wọ́n sì sábà máa ń fún wọn ni pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni ìyà tó ń jẹ̀ẹ̀yàn. Wọ́n sọ pé tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà. Wọ́n ń sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn pé àdììtú làwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe. Wọ́n ní òun ló ń fikú pa èèyàn. Kódà wọ́n sọ pé òun ló ń pa àwọn ọmọdé kí wọ́n lè lọ bá a lọ́run. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run kì í mú kí ohun búburú ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: ‘Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, bẹ́ẹ̀ sì ni Olódùmarè kò ní hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!’—Jóòbù 34:10.
6. Kí nìdí táwọn kan fi ń fi àṣìṣe dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?
6 Ǹjẹ́ o mọ ìdí táwọn èèyàn fi máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló fa gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé láìmọ̀ pé àṣìṣe ńlá làwọn ń ṣe? Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń dá Ọlọ́run Olódùmarè lẹ́bi ni pé wọ́n rò pé òun gan-an lẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí. Wọn ò lóye ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tí Bíbélì fi kọ́ni. O kọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀hún ní Orí Kẹta ìwé yìí. Ẹ̀kọ́ náà ni pé Sátánì Èṣù gan-an lẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí.
7, 8. (a) Báwo layé ṣe ń hu irú ìwà tí ẹni tó ń ṣàkóso rẹ̀ ń hù? (b) Báwo ni àìpé ẹ̀dá èèyàn àti “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ṣe dá kún ìyà tó ń jẹ aráyé?
7 Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Tó o bá ro ọ̀rọ̀ yẹn dáadáa, wàá rí i pé bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ìwà tí ẹ̀dá ẹ̀mí tá ò lè rí yìí ń hù, layé ń hù, nítorí pé òun ló ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Akórìíra ẹni ni Sátánì, ẹlẹ̀tàn ni, ó sì ya ìkà. Nítorí náà, ìkórìíra, ẹ̀tàn àti ìwà ìkà ló kún inú ayé tí Èṣù ń ṣàkóso. Ìdí kan nìyẹn tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
8 Ìdí kejì tí ìyà tó ń jẹ́ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tún wà lára ohun tá a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí Kẹta ìwé yìí. Ìdí náà ni pé látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì laráyé ti di aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Ohun táwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ń wá ni bí wọ́n á ṣe máa jẹ gàba lórí àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn sì máa ń fa ogun, ìninilára àti ìpọ́njú. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Ìdí kẹta tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Ka Oníwàásù 9:11) Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ni alákòóso ayé yìí, nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni nígbàkigbà nítorí pé ó ṣe kòńgẹ́ rẹ̀.
9. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ìdí rere kan ní láti wà tí Jèhófà fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé pé kó ṣì máa bá a nìṣó?
9 Ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Òun kọ́ ló ń fa ogun, ìwà ọ̀daràn, ìnilára tàbí àwọn ìjábá tó máa ń fa ìyà fún èèyàn. Síbẹ̀, ó ṣì yẹ ká mọ̀ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni Olódùmarè, ó ní agbára láti fòpin sí i. Kí ló wá dé tí kò fi lo agbára rẹ̀ kó sì fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé? Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ìdí rere kan gbọ́dọ̀ wà tí kò fi tíì fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé.—1 Jòhánù 4:8.
Ọ̀RÀN PÀTÀKÌ KAN JẸ YỌ
10. Kí ni Sátánì jiyàn lé lórí, báwo ló sì ṣe ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Ká tó lè mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé, a ní láti ronú nípa ìgbà tí ìyà náà bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí Sátánì tan Ádámù àti Éfà jẹ tí wọ́n fi ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ọ̀ràn pàtàkì kan jẹ yọ. Kì í ṣe pé Sátánì ń jiyàn pé Jèhófà lágbára tàbí pé kò ní, ó sáà mọ̀ pé agbára Jèhófà ò láàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń jiyàn lé lórí ni ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso. Nígbà tí Sátánì pe Ọlọ́run ní òpùrọ́ tó sì sọ pé Ọlọ́run ń fi ohun tó dára du àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé alákòóso burúkú ni Jèhófà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:2-5) Sátánì sọ pé á sàn fọ́mọ aráyé tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn. Ẹ̀sùn rèé o. Sátánì ta ko ipò tí Jèhófà wà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ìyẹn ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso.
11. Kí nìdí tí Jèhófà ò kàn fi lu àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pa ní Édẹ́nì?
11 Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Bí wọ́n sì ṣe ṣọ̀tẹ̀ yẹn, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: “A ò fẹ́ kí Jèhófà jẹ́ Alákòóso wa. A lè fúnra wa mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.” Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà yanjú ọ̀ràn yìí? Ọ̀nà wo ló lè gbà fi yé gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè pé ohun táwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn sọ ò tọ̀nà àti pé ọ̀nà tóun ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ? Ẹnì kan lè sọ pé ì bá dára ká ní Ọlọ́run ti lu àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn pa kó sì tún ètò mìíràn ṣe lákọ̀tun. Àmọ́ Jèhófà ti sọ ohun tó ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé, ìyẹn ni pé kí àwọn irú ọmọ Ádámù àti Éfà kún ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa gbé nínú Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Gbogbo ohun tí Jèhófà bá sì ti pinnu pé kó ṣẹ ló máa ń ṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) Yàtọ̀ síyẹn, lílu àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pa ní Édẹ́nì kì bá má yanjú awuyewuye tí Sátánì ń bá Jèhófà ṣe nípa ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso.
12, 13. Ṣàpèjúwe ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì láti di alákòóso ayé àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn èèyàn kí wọ́n máa ṣàkóso ara wọn.
12 Jẹ́ ká gbé àpèjúwe kan yẹ̀ wò. Fojú inú wò ó pé olùkọ́ kan ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìṣirò kan tó le gan-an. Ni akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ní làákàyè, àmọ́ tó yàyàkuyà, bá sọ pé bó ṣe yẹ kí olùkọ́ náà ṣe ìṣirò náà kọ́ ló ń ṣe é. Láti fi hàn pé olùkọ́ náà kò kúnjú ìwọ̀n, ọlọ̀tẹ̀ yìí ta kú pé òun mọ ọ̀nà tó dára láti ṣe ìṣirò náà ju ọ̀nà tí olùkọ́ náà gbà ń ṣe é lọ. Nígbà tó yá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan rò pé òótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ yẹn ń sọ, àwọn náà bá gùn lé ìwà rẹ̀. Kí ló yẹ kí olùkọ́ yìí ṣe? Tó bá lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ olórí kunkun yìí kúrò ní kíláàsì, èrò wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù máa ní? Ṣé wọn ò ní máa rò pé òótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ̀sùn kan olùkọ́ náà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí wọ́n gbè sẹ́yìn rẹ̀ ń sọ? Olùkọ́ náà lè tẹ́ lójú gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tó kù ní kíláàsì náà, nítorí wọ́n á máa rò pé ó ti mọ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ yẹn máa táṣìírí òun ló fi lé e jáde. Ohun tó dára ni pé kí olùkọ́ náà fàyè gba akẹ́kọ̀ọ́ tó yàyàkuyà náà pé kó fi bó ṣe lóun máa ṣe ìṣirò náà han kíláàsì kí wọ́n lè rí i.
13 Ohun tí Jèhófà ṣe jọ èyí. Rántí pé àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì nìkan kọ́ ló mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì ló ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. (Jóòbù 38:7; Dáníẹ́lì 7:10) Ọ̀nà tí Jèhófà bá gbà yanjú ọ̀tẹ̀ náà yóò sọ nǹkan kan fún gbogbo àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyẹn, yóò sì tún sọ nǹkan kan fún gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nítorí náà, kí ni Jèhófà ṣe? Ó fàyè gba Sátánì pé kó fi bó ṣe lóun máa ṣàkóso aráyé hàn. Ọlọ́run tún fàyè gba àwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣàkóso ara wọn lábẹ́ Sátánì.
14. Àǹfààní wo ló máa wà nínú bí Jèhófà ṣe pinnu láti fàyè gba àwọn èèyàn kí wọ́n ṣàkóso ara wọn?
14 Olùkọ́ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpèjúwe tá a ṣe lẹ́ẹ̀kan mọ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ tó yàyàkuyà yẹn àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fara mọ́ ọn kò tọ̀nà. Ṣùgbọ́n ó tún mọ̀ pé yóò ṣe kíláàsì náà láǹfààní tóun bá fàyè gba àwọn tó ń gbó òun lẹ́nu náà kí wọ́n wá gbìyànjú láti fi hàn níwájú kíláàsì pé ohun táwọn sọ tọ́. Ìgbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń gbó olùkọ́ yìí lẹ́nu bá kùnà ló máa wá hàn kedere sí gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rere pé olùkọ́ àwọn nìkan ló kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ àwọn. Tí olùkọ́ náà bá wá lé àwọn ìpáǹle akẹ́kọ̀ọ́ náà kúrò ní kíláàsì lẹ́yìn náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù á rí ìdí tí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe mọ̀ pé gbogbo èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn áńgẹ́lì ni yóò jàǹfààní tí wọ́n bá rí i pé Sátánì àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ò kẹ́sẹ járí, tí wọ́n sì rí i pé àwọn èèyàn ò lè ṣàkóso ara wọn. Bíi ti Jeremáyà ayé ọjọ́un, wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ pàtàkì yìí, pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI FÀYÈ GBA ÌYÀ PẸ́ TÓ BẸ́Ẹ̀?
15, 16. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé láti wà pẹ́ tó bẹ́ẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà kò fi ṣe é kí ìwà búburú, irú bí ìwà ọ̀daràn tó burú jáì, má ṣẹlẹ̀?
15 Àmọ́, kí ló dé tí Jèhófà fi jẹ́ kí ìyà tó ń jẹ aráyé wà pẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Kí sì nìdí tó fi ń jẹ́ kí àwọn nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀? Ó dára, ronú nípa nǹkan méjì tí olùkọ́ inú àpèjúwe ẹ̀ẹ̀kan kò ṣe. Àkọ́kọ́, kò dá akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣọ̀tẹ̀ náà dúró pé kó má fi bó ṣe lóun fẹ́ ṣe ìṣirò náà hàn. Èkejì, olùkọ́ náà kò ran ọlọ̀tẹ̀ náà lọ́wọ́ nígbà tó ń ṣe ìṣirò náà. Bákan náà, wo ohun méjì tí Jèhófà pinnu pé òun kò ní ṣe. Àkọ́kọ́, kò dá Sátánì àtàwọn tó kún un lọ́wọ́ dúró pé kí wọ́n má gbìyànjú láti fi hàn pé ẹjọ́ àwọn tọ́. Nítorí náà, ó pọn dandan kó fún wọn lákòókò tó gùn tó. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni èèyàn ti fi dán onírúurú ìjọba wò. Èèyàn ti tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti láwọn ọ̀nà mìíràn, ṣùgbọ́n ńṣe ni ìwà ìrẹ́jẹ, ìṣẹ́, ìwà ọ̀daràn àti ogun ń pọ̀ sí i. Ó ti wá hàn báyìí pé ìṣàkóso èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí.
16 Èkejì, Jèhófà kò ran Sátánì lọ́wọ́ láti ṣàkóso ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, tí Jèhófà bá ṣe é pé kí ìwà ọ̀daràn tó burú jáì má ṣẹlẹ̀, ṣe kò ní jẹ́ pé ńṣe ló ń sọ pé ohun táwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe tọ̀nà? Ṣé Ọlọ́run ò ní mú káwọn èèyàn máa rò pé àwọn èèyàn lè ṣàkóso ara wọn, tí wàhálà kankan ò sì ní ṣẹlẹ̀? Bí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé òun náà ti di òpùrọ́ bíi ti ọlọ̀tẹ̀ náà nìyẹn. Àmọ́, “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.”—Hébérù 6:18.
17, 18. Kí ni Jèhófà yóò ṣe sí gbogbo aburú tí ìṣàkóso èèyàn àti ìṣàkóso Sátánì ti fà?
17 Gbogbo aburú tó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ńkọ́? Ó yẹ ká rántí pé nítorí pé Jèhófà ni Olódùmarè, ó lè mú gbogbo àbájáde ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn kúrò, yóò sì mú un kúrò. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti kẹ́kọ̀ọ́ kọjá, Jèhófà yóò fòpin sí bí àwọn èèyàn ṣe ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́ yóò sì sọ ọ́ dí Párádísè. Jèhófà yóò mú ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà kúrò nítorí ìgbàgbọ́ táwọn olódodo ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Jèhófà yóò tún mú ohun tí ikú ti fà kúrò nípa jíjí àwọn òkú dìde. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò lo Jésù “láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́ ni Jèhófà yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí. A dúpẹ́ pé kò tètè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé sùúrù tó ní la fi láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ká sì sìn ín. (Ka 2 Pétérù 3:9, 10) Ní báyìí ná, lójú méjèèjì ni Jèhófà ń wá àwọn tó fẹ́ fi òótọ́ sìn ín, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da ìyà èyíkéyìí tó bá ń jẹ wọ́n nínú ayé oníwàhálà yìí.—Jòhánù 4:23; 1 Kọ́ríńtì 10:13.
18 Àwọn kan lè máa rò ó pé, Ká ní Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tí wọn kò fi ní lè ṣọ̀tẹ̀ ni, bóyá gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé yìí kì bá tí jẹ wá. Kó o tó lè mọ̀, o ní láti rántí ẹ̀bùn iyebíye kan tí Jèhófà fún ọ.
BÁWO NI WÀÁ ṢE LO Ẹ̀BÙN TÍ ỌLỌ́RUN FÚN Ọ?
19. Ẹ̀bùn iyebíye wo ni Jèhófà fún wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká mọyì rẹ̀?
19 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí Karùn-ún, nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó fún un ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀bùn iyebíye lẹ̀bùn yẹn? Àìlóǹkà ẹranko ni Ọlọ́run dá, gbogbo ohun tí wọ́n sì ń ṣe ni Ọlọ́run ti dá mọ́ wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. (Òwe 30:24) Àwọn èèyàn ti ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tí kò lè ronú tó jẹ pé ohunkóhun tí wọ́n bá sáà ti ní kó ṣe ló máa ń ṣe. Ṣé inú wa yóò dún tó bá jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn? Rárá, inú wa ò lè dùn, nítorí pé a máa ń fẹ́ òmìnira láti yan ohun tó wù wá nípa irú èèyàn tá a fẹ́ dà, irú ìgbé ayé tá a fẹ́ gbé, irú àwọn èèyàn tá a fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A fẹ́ lómìnira, Ọlọ́run sì fẹ́ ká ní in.
20, 21. Báwo la ṣe lè lo ẹ̀bùn òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti yan ohun tó wù wá lọ́nà tó dára, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
20 Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn téèyàn ń ṣe tipátipá. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Wo àpèjúwe yìí ná: Nínú kí ọmọ fúnra rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ òbí rẹ̀ nígbà tí òbí rẹ̀ bá fún un ní nǹkan, tàbí kó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá kọ́ ọ ló tó mọ bá a ṣe ń dúpẹ́, èwo lo rò pé yóò dùn mọ́ òbí nínú jù? Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì kó o ronú lórí ìbéèrè tó sọ pé, báwo ni wàá ṣe lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ọ? Sátánì, Ádámù àti Éfà lo òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ohun tó wù wọ́n lọ́nà tó burú jáì. Wọ́n kọ Jèhófà Ọlọ́run sílẹ̀. Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ lo ẹ̀bùn yẹn ní tìẹ?
21 O láǹfààní láti lo ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún ọ, ìyẹn òmìnira láti yan ohun tó bá wù ọ́, lọ́nà tó dára. O lè dara pọ̀ mọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí wọ́n ti wà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà. Wọ́n ń mú inú Jèhófà dùn nítorí pé wọ́n ń kópa ribiribi láti fi Èṣù hàn pé ó jẹ́ òpùrọ́ àti alákòóso tí kò dára. (Òwe 27:11) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá yan ọ̀nà to tọ́ nígbèésí ayé. Èyí la óò gbé yẹ̀ wò ní orí tó kàn.