Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì
“Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì. . . . Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—MÁT. 6:24.
1-3. (a) Báwo lọ̀rọ̀ ìṣúnná owó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí? Kí làwọn kan ń ṣe láti yanjú ìṣòro náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ìṣòro wo làwọn kan máa ń ní nípa bí wọ́n á ṣe tọ́jú àwọn ọmọ wọn?
OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Marilyna sọ nípa ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ James pé: “Ojoojúmọ́ ló máa ń rẹ ọkọ mi tẹnutẹnu nígbà tó bá fi máa dé láti ibiṣẹ́, gbogbo owó tó sì ń mú wálé kò kọjá ohun tá a lè ná tán lóòjọ́. Mò ń wá bí màá ṣe mú kí ẹrù rẹ̀ fúyẹ́, kí n sì tún lè máa ra àwọn nǹkan ìṣeré ọmọdé fún Jimmy ọmọ wa, irú èyí tó máa ń rí lọ́wọ́ àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀.” Ó tún wu Marilyn pé kó ran àwọn ìbátan wọn lọ́wọ́ kó sì fi owó díẹ̀ pa mọ́ torí ọjọ́ ìdágìrì. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ti gba àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ kí wọ́n lè rí towó ṣe. Àmọ́ nígbà tó ń ronú bóyá kóun lọ tàbí kóun má lọ, kò mọ èyí tí ì bá ṣe. Kí nìdí?
2 Ìdí ni pé Marilyn kò fẹ́ fi ìdílé rẹ̀ ọ̀wọ́n sílẹ̀ kò sì fẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí tí wọ́n jọ máa ń ṣe dúró. Síbẹ̀, ó ronú pé àwọn kan ti lọ sókè òkun rí tó sì dà bíi pé ìyẹn ò pa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lára. Àmọ́, ó wá ń ronú nípa bó ṣe máa tọ́ Jimmy dàgbà látòkè òkun. Ó ronú pé, ṣé òun á sì lè tọ́ ọmọ náà dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Éfé. 6:4.
3 Marilyn fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wu ọkọ rẹ̀ pé kó lọ, síbẹ̀ ó sọ pé òun ò ní dá a dúró. Àwọn alàgbà àtàwọn míì nínú ìjọ gbà á níyànjú pé kó má lọ, àmọ́ àwọn arábìnrin mélòó kan rọ̀ ọ́ pé kó lọ sókè òkun. Wọ́n sọ fún un pé: “Tó o bá nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ, wàá lọ. Ìyẹn ò sì ní kó o má sin Jèhófà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Marilyn kò balẹ̀, ó fẹnu ko ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, ó sì gba òkè òkun lọ. Ó wá ṣèlérí fún wọn pé: “Mi ò ní pẹ́ rárá tí màá fi pa dà.”
OJÚṢE ÌDÍLÉ ÀTI ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ
4. Kí nìdí tí àwọn kan fi ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè? Àwọn wo ni wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọmọ wọn tì?
4 Kò wu Jèhófà pé kí òṣì máa ta àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ọjọ́ sì ti pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń lọ sílẹ̀ òkèèrè kí wọ́n lè gbọn ìṣẹ́ dà nù. (Sm. 37:25; Òwe 30:8) Kí ebi má bàa pa ìdílé Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá ìgbàanì kú, ó rán àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílẹ̀ Íjíbítì pé kí wọ́n lọ ra oúnjẹ.b (Jẹ́n. 42:1, 2) Kì í sábà jẹ́ torí ebi ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń gba ilẹ̀ òkèèrè lọ lóde òní. Àmọ́ ó lè jẹ́ torí pé wọ́n ti tọrùn bọ gbèsè ńlá. Ohun táwọn míì sì ń wá ò ju bí wọ́n ṣe lè mú kí nǹkan gbé pẹ́ẹ́lí sí i nínú ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì jẹ́ pé wọn ò fẹ́ kí ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ febi pa ìdílé wọn, torí náà wọ́n pinnu pé ó máa dára káwọn wá àtijẹ àtimu lọ sí apá ibòmíì ní orílẹ̀-èdè wọn tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fi àwọn ọmọ wọn tí kò tíì tójú bọ́ sílẹ̀ fún ọkọ tàbí aya wọn. Ó sì lè jẹ́ èyí tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọ náà ní wọ́n á ní kó máa tọ́jú àwọn yòókù, tàbí kí wọ́n kó wọn ti òbí wọn àgbà, ìbátan wọn míì, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú bọ̀rọ̀ kọ́ ni àwọn tó ń kó lọ sílẹ̀ míì fi ń fi aya tàbí ọkọ àtàwọn ọmọ wọn sílẹ̀, síbẹ̀ wọ́n gbà pé kò sí ọgbọ́n míì táwọn lè dá sí i.
5, 6. (a) Kí ni Jésù sọ nípa béèyàn ṣe lè rí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀? (b) Àwọn nǹkan tara wo ni Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà fún? (d) Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún wa?
5 Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, tí nǹkan ò sì ṣẹnuure fún, wọ́n sì lè máa ronú pé ó dìgbà táwọn bá lówó lọ́wọ́ kí àwọn tó láyọ̀ kí ọkàn àwọn sì balẹ̀. (Máàkù 14:7) Àmọ́, ibòmíì ni Jésù fẹ́ kí àwọn èèyàn fojú sí. Ó fẹ́ kí wọ́n gbára lé Jèhófà, tó jẹ́ Orísun ọrọ̀ tí kì í tán. Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó ṣàlàyé pé èèyàn ò lè rí ojúlówó ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ látinú àwọn nǹkan tara tàbí ìsapá ara ẹni, bí kò ṣe látinú àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba wa ọ̀run.
6 Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ wa, kò sọ pé ká máa gbàdúrà fún owó. Ohun tá a nílò lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní ká béèrè, ìyẹn “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” Ó sọ ní ṣàkó fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” (Mát. 6:9, 11, 19, 20) Kò sídìí fún wa láti ṣiyè méjì pé Jèhófà máa bù kún wa bó ti ṣèlérí. Ìbùkún tí Ọlọ́run máa fún wa kọjá o káre láé, ńṣe ló máa dìídì fún wa ní ohun tá a nílò ní ti gidi. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀nà kan ṣoṣo tá a fi lè ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ dípò tá ó fi máa gbẹ́kẹ̀ lé owó.—Ka Mátíù 6:24, 25, 31-34.
7. (a) Ta ni Jèhófà fa iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ lé lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí méjèèjì pawọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn?
7 Lára ọ̀nà téèyàn lè gbà máa ‘wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́’ ni pé kéèyàn máa ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé bí Jèhófà ṣe fẹ́. Ìlànà tó kan àwa Kristẹni yìí náà wà nínú Òfin Mósè. Ó yẹ kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Diutarónómì 6:6, 7.) Àwọn òbí ni Ọlọ́run fa iṣẹ́ yìí lé lọ́wọ́, kì í ṣe àwọn òbí wọn àgbà tàbí àwọn míì. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ni pé kí òbí méjèèjì pawọ́ pọ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà kí wọ́n sì jọ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 31:10, 27, 28) Ọ̀dọ̀ òbí làwọn ọmọ ti máa ń kọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n mọ̀. Ní pàtàkì, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run látinú ohun táwọn òbí ń sọ nípa Jèhófà lójoojúmọ́ àti bí wọ́n ṣe ń kíyè sí àpẹẹrẹ tí wọ́n ń fi lélẹ̀.
ÀWỌN ÀBÁJÁDE ÀÌRÒTẸ́LẸ̀
8, 9. (a) Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tí òbí kan ò bá gbé pẹ̀lú àwọn yòókù nínú ìdílé? (b) Báwo ni jíjìnnà sí ìdílé ẹni ṣe lè fa ẹ̀dùn ọkàn kó sì mú kéèyàn hùwà tí kò tọ́?
8 Àwọn tó máa ń lọ sílẹ̀ òkèèrè máa ń ro ohun tó máa ná wọn àti ewu tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kó tó di pé wọ́n lọ. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló máa ń ro ibi tó máa já sí tí wọ́n bá fi ìdílé wọn sílẹ̀. (Òwe 22:3)c Kò pẹ́ tí Marilyn fi ilé sílẹ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàárò ọkọ àti ọmọ rẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ sì ń gbọgbẹ́. Ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ náà sì ń ṣàárò rẹ̀. Ńṣe ni Jimmy ọmọ rẹ̀ kékeré yìí máa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tẹ́ ẹ fi mi sílẹ̀?” Ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ ni Marilyn dágbére pé òun máa lò lẹ́yìn odi, ló bá di pé ọdún ń gorí ọdún. Ó wá kíyè sí i pé nǹkan ti ń yí pa dà nínú ìdílé òun. Ó kíyè sí i pé Jimmy kì í fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí òun mọ́, ọkàn rẹ̀ kò sì fà sí òun mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni obìnrin yìí fi sọ pé, “Mo wa di àjèjì sí ọmọ mi gbáà.”
9 Tí àwọn òbí àtàwọn ọmọ kò bá gbé pọ̀, ó lè fa ẹ̀dùn ọkàn, ó sì lè mú kí wọ́n hùwà tí kò tọ́.d Bí àwọn ọmọ bá ṣe kéré tó lọ́jọ́ orí nígbà táwọn òbí já wọn jù sílẹ̀, bí wọ́n bá sì ṣe pẹ́ tó tí wọ́n fi wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìpalára tó máa ṣé á ṣe pọ̀ tó. Marilyn ṣàlàyé fún Jimmy pé torí rẹ̀ lòun ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe. Àmọ́ lójú Jimmy, ńṣe ló dà bíi pé màmá rẹ̀ pa á tì. Inú Jimmy kì í dùn nígbà tí màmá rẹ̀ kọ́kọ́ fi ilé sílẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn yẹn, tí màmá rẹ̀ bá wá bẹ ilé wò, kì í wù ú láti rí i sójú. Bó ṣe sábà máa ń rí lára irú àwọn ọmọ tí wọ́n pa tì bẹ́ẹ̀, Jimmy gbà pé màmá òun ò yẹ lẹ́ni tóun ń ṣègbọràn sí, ọkàn òun ò sì fà sí i mọ́.—Ka Òwe 29:15.
10. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí òbí bá ń fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ dípò kó wà pẹ̀lú wọn? (b) Àwọn nǹkan wo ni kò ṣeé ṣe tí òbí kan bá ń tọ ọmọ rẹ̀ láti ọ̀nà jíjìn?
10 Marilyn máa ń fi owó àtàwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ọmọ rẹ̀ láti fi rọ́pò bí kó ṣe sí pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, ó wá rí i pé ńṣe lòun túbọ̀ ń sọ ara òun di àjèjì sí ọmọ òun, àti pé láìfura òun tún ń kọ́ ọ pé àwọn nǹkan tara ló ṣe pàtàkì ju àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìdílé. (Òwe 22:6) Jimmy tiẹ̀ máa ń sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ dúró sí ọ̀hún, ẹ ṣá ti máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́.” Marilyn wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé òun ò lè máa tọ́ ọmọ òun láti ọ̀nà jíjìn nípasẹ̀ lẹ́tà, bíbá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí nípasẹ̀ fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé: “O kò lè gbá ọmọ rẹ mọ́ra tàbí kó o fi ẹnu kò ó lẹ́nu pé ó dàárọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”
11. (a) Bí tọkọtaya bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ torí iṣẹ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó wọn? (b) Báwo ni arábìnrin kan ṣe wá rí i pé ó máa dára kí òun pa dà sọ́dọ̀ ìdílé òun?
11 Nígbà tó yá, àárín Marilyn àti Jèhófà kò gún mọ́, bọ́rọ̀ sì ṣe rí nípa òun àti ọkọ rẹ̀ James náà nìyẹn. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ló kù tó ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí tàbí kó má tiẹ̀ lọ nígbà míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ní láti já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀ tó fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe. Torí pé Marilyn àti James ò ní ẹni tí wọ́n lè fi ṣe agbọ̀ràndùn, ó di pé kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ wọn lọ ẹlòmíì, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bá àwọn yẹn ṣe ìṣekúṣe. Marilyn wá rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àti ọkọ òun ò bá àwọn míì ṣe panṣágà, bí àwọn ṣe ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ mú kó nira fáwọn láti fi ìtọ́ni Bíbélì sílò pé káwọn máa gba ti ara àwọn rò, káwọn má sì máa fi ìbálòpọ̀ du ara àwọn. Bí wọ́n ṣe jìnnà síra wọn kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan téèyàn máa ń dédé ṣe, bíi kí wọ́n jọ ronú, kí wọ́n jọ dínjú síra wọn, kí wọ́n jọ rẹ́rìn-ín músẹ́, kí wọ́n fọwọ́ kanra, kí wọ́n dì mọ́ra, kí wọ́n ‘fìfẹ́ hàn’ síra wọn, tàbí kí wọ́n jọ gbádùn “ẹ̀tọ́” ìgbéyàwó. (Orin Sól. 1:2; 1 Kọ́r. 7:3, 5) Bẹ́ẹ̀ ni kò sí bí wọ́n ṣe lè jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọ wọn. Marilyn wá sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè pé ká tó lè la ọjọ́ ńlá Jèhófà já, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé, ó yé mi pé ilé tóó lọ. Mo rí i pé ó pọn dandan kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sí àjọṣe àárín èmi àti ìdílé mi àti àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà.”
ÌMỌ̀RÀN RERE NI WÀÁ TẸ̀ LÉ NI ÀBÍ BÚBURÚ?
12. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo la lè fún àwọn tó ń gbé níbi tó jìn sí ìdílé wọn?
12 Ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn fi wo ìpinnu tí Marilyn ṣe pé òun máa pa dà sílé. Àwọn alàgbà ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́ lókè òkun yìn ín torí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó fi hàn. Àmọ́, ńṣe làwọn míì tó fi ilẹ̀ òkèèrè ṣe ilé tí wọ́n sì fi àwọn ìdílé wọn sẹ́yìn bẹnu àtẹ́ lù ú. Dípò tí wọ́n á fi tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀, ṣe ni wọ́n ń rọ̀ ọ́ pé kó ṣì dúró. Wọ́n sọ fún un pé: “O máa tó pa dà wá. Báwo ni wàá ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ tó o bá pa dà sílé?” Dípò tí Kristẹni kan á fi máa sọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ńṣe ló yẹ kó “pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ . . . òṣìṣẹ́ ní ilé,” ìyẹn ní ilé tiwọn, “kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Ka Títù 2:3-5.
13, 14. Kí nìdí tó fi gba ìgbàgbọ́ kéèyàn tó fi ìfẹ́ Jèhófà ṣáájú ti ìdílé? Sọ àpẹẹrẹ kan.
13 Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn ló mú kí wọ́n lọ máa gbé nílẹ̀ òkèèrè. Ìdí sì ni pé, àṣà ilẹ̀ wọn, ojúṣe wọn nínú ìdílé, ní pàtàkì ojúṣe wọn sí àwọn òbí ni wọ́n kà sí pàtàkì jù. Dájúdájú, ó gba ìgbàgbọ́ fún Kristẹni kan láti sọ pé ìfẹ́ Jèhófà lòun máa ṣe dípò kóun máa tẹ̀ lé àṣà tó gbòde tàbí ohun tí ìdílé òun fẹ́.
14 Ẹ gbọ́ ohun tí Carin sọ: “Òkè òkun lèmi àti ọkọ mi ń gbé nígbà tí mo bí ọmọ wa ọkùnrin tó ń jẹ́ Don, kò sì tíì pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo àwọn ará ilé wa retí pé kí n fi ọmọ mi ránṣẹ́ kí àwọn òbí mi lè bá mi tọ́jú rẹ̀ títí tí nǹkan á fi ṣẹnuure fún wa.” Nígbà tí Carin kọ̀ jálẹ̀ pé òun lòun máa tọ́jú ọmọ òun, ńṣe làwọn ẹbí rẹ̀, títí kan ọkọ rẹ̀ ń fi í ṣẹlẹ́yà, wọ́n sọ pé alápá-má-ṣiṣẹ́ ni. Òun alára sọ pé: “Ká sòótọ́, nígbà yẹn, mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí ohun tó burú nínú kí n gbé Don ti àwọn òbí mi fún ìwọ̀nba ọdún díẹ̀. Àmọ́, mo mọ̀ pé àwa tá a jẹ́ òbí Don ni Jèhófà gbé iṣẹ́ títọ́ ọmọ wa lé lọ́wọ́.” Nígbà tí Carin lóyún ẹlẹ́ẹ̀kejì, ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ pé kó ṣẹ́ oyún náà. Ìpinnu rere tí Carin ṣe nígbà tó bí àkọ́bí rẹ̀ mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó tún wá pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà lòun máa ṣe. Ní báyìí, inú gbogbo wọn dùn pé àwọn jọ ń gbé pa pọ̀. Nǹkan míì là bá máa sọ báyìí ká ní Carin ti fi àwọn ọmọ rẹ̀ ránṣẹ́ sílé fún àwọn míì láti bá a tọ́ wọn dàgbà.
15, 16. (a) Sọ ìrírí arábìnrin kan tí àwọn òbí rẹ̀ já sílẹ̀ ní kékeré. (b) Kí nìdí tó fi pinnu pé òun ò ní já ọmọ òun sílẹ̀ fún ẹlòmíì?
15 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Vicky sọ pé: “Mo gbé lọ́dọ̀ ìyá mi àgbà fún ọdún mélòó kan, ṣùgbọ́n àbúrò mi obìnrin wà lọ́dọ̀ àwọn òbí wa. Nígbà tí mo fi máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi, wọ́n ti dà bí àjèjì sí mi. Ará máa ń yá àbúrò mi láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wọn, ó máa ń dì mọ́ wọn, wọ́n sì sún mọ́ra gan-an. Ara tèmi ò fi bẹ́ẹ̀ yá mọ́ wọn títí tí mo fi dàgbà, mi kì í sì í finú hàn wọ́n. Èmi àti àbúrò mi fi dá àwọn òbí wa lójú pé a máa tọ́jú wọn lọ́jọ́ ogbó wọn. Torí pé ó jẹ́ ojúṣe mi ni mo ṣe máa ṣe é, àmọ́ àbúrò mi á ṣe é torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn.
16 Vicky sọ pé: “Ní báyìí, màámi sọ pé kí n mú ọmọbìnrin mi wá káwọn tọ́jú rẹ̀, bí wọ́n ṣe fi èmi náà sọ́dọ̀ màmá wọn. Mo yáa dọ́gbọ́n sọ fún wọn pé rárá. Èmi àti ọkọ mi fẹ́ láti tọ́ ọmọ tá a bí dàgbà ní ọ̀nà Jèhófà. Mi ò sì fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe èmi àti ọmọ mi jẹ́ lọ́jọ́ iwájú.” Vicky wá rí i pé ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà ṣàṣeyọrí ni pé kéèyàn fi ìfẹ́ Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ ṣáájú lílépa owó àtàwọn ohun tí ìdílé fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣe kedere pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì,” fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.—Mát. 6:24; Ẹ́kís. 23:2.
JÈHÓFÀ Ń MÚ KÍ ÌSAPÁ WA “YỌRÍ SÍ RERE”
17, 18. (a) Kí ló fi hàn pé ìgbà gbogbo làwa Kristẹni lè ṣe yíyàn tó tọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Jèhófà, Baba wa ti gbà pé òun á rí i dájú pé ọwọ́ wa tẹ àwọn ohun tá a nílò lóòótọ́ tí a bá fi Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. (Mát. 6:33) Látàrí èyí, ìgbà gbogbo làwa Kristẹni tòótọ́ lè yan ohun tó tọ́. Jèhófà ṣèlérí pé, ìṣòro yòówù kó lè dé, òun máa ṣe “ọ̀nà àbájáde” tí kò ní mu wa tẹ àwọn ìlànà Bíbélì lójú. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Tá a bá ‘fi ìyánhànhàn dúró de’ Jèhófà, tá a “gbójú lé e” nípa gbígbàdúrà pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti ìtọ́sọ́nà, tá a sì ń pa àwọn àṣẹ àti ìlànà rẹ̀ mọ́, ó dájú pé ‘yóò gbé ìgbésẹ̀’ nítorí wa. (Sm. 37:5, 7) Ó máa dìídì bù kún wa bá a ṣe ń sapá tọkàntọkàn láti máa sìn ín, tá a sì gbà pé òun nìkan ṣoṣo ni Ọ̀gá wa tòótọ́. Tá a bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́, ó máa mú kí ayé wa “yọrí sí rere.”—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 39:3.
18 Bí ọkọ àti ìyàwó bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìyẹn sì ti fa ìpalára èyíkéyìí, kí ni wọ́n lè ṣe sí irú ìpalára bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe ká lè máa bójú tó ìdílé wa láìsí pé à ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀? Báwo la sì ṣe lè rọ àwọn míì láti ṣe ìpinnu tó tọ́ lórí kókó yìí? A máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
b Láwọn ìgbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì, ó ṣeé ṣe kó tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí wọn ò fi sí pẹ̀lú ìdílé wọn. Àmọ́ nígbà tí Jékọ́bù àtàwọn ọmọ rẹ̀ wá kó lọ sí Íjíbítì, taya tọmọ ni wọ́n jọ lọ.—Jẹ́n. 46:6, 7.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Fún Àwọn Tó Fẹ́ Ṣí Lọ sí Ìlú Míì” nínú Jí! March–April 2013.
d Ìròyìn tó ń wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fi hàn pé lára ohun tó máa ń fa àwọn ìṣòro tó díjú nínú ìdílé ni kí ọkọ tàbí aya fi ilé sílẹ̀ kó lè lọ máa ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèèrè. Lára àwọn ìṣòro náà ni pé kí ọkọ tàbí aya lójú síta, kí wọ́n máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn ṣèṣekúṣe tàbí kí wọ́n máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìbátan. Ní ti àwọn ọmọ, wọ́n lè di ìpáǹle tàbí kí wọ́n má ṣe dáadáa mọ́ nílé ìwé, wọ́n lè máa fín àwọn míì níràn, kí wọ́n máa ṣàníyàn, kí wọ́n sorí kọ́, tàbí kí wọ́n máa gbìyànjú láti pa ara wọn.