Iye Ènìyàn Tí Ó Ń Pa Bá Ti Ogun Dọ́gba
NÍGBÀ tí Marilyn, ọmọ ọdún 23, rù, tí ó sì rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu, ó ronú pé ó lè jẹ́ oyún tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ló fà á. Ó tún ń wúkọ́ tí kò lọ, ó sì sọ fún dókítà rẹ̀. Dókítà sọ pé ó ní àrùn àkóràn kan ní apá òkè ọ̀nà èémí rẹ̀, ó sì kọ oògùn agbógunti kòkòrò àrùn fún un. Nígbà tó yá tí Marilyn bẹ̀rẹ̀ sí í làágùn lákọlákọ lóru, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú gidigidi. Ó pa dà lọ sọ́dọ̀ dókítà rẹ̀, ìyẹn sì ṣètò pé kí wọ́n ya fọ́tò X ray àyà rẹ̀.
Òjìji tí ó hàn lórí fọ́tò X ray náà pé nǹkan ń ṣe é mú kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀, àmọ́ wọn kò lè kàn sí Marilyn lórí tẹlifóònù. Marilyn sọ pé: “Dókítà kàn sí mọ́mì mi, ó sì wí fún un pé ohun kan ń ṣe mí ní ti gidi. Mọ́mì mi wá mi wá, ó sì wí pé kí n rí [dókítà] lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dókítà ní kí n lọ sí ilé ìwòsàn, wọ́n ya fọ́tò X ray míràn fún mi, wọ́n sì dá mi dúró síbẹ̀.”
Ẹ̀rù ba Marilyn láti gbọ́ pé òun ní ìkọ́ ẹ̀gbẹ (TB). Ó rò pé òun yóò kú, àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lo àwọn oògùn agbógunti ikọ́ ẹ̀gbẹ fún un, ara rẹ̀ yá láìpẹ́.
Ìyàlẹ́nu tí Marilyn ní nígbà tí ikọ́ ẹ̀gbẹ mú un ṣeé lóyé. Títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ ìlera dunjú pàápàá gbà gbọ́ pé a ti ṣẹ́gun ikọ́ ẹ̀gbẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà. Igbákejì olùtọ́jú aláìsàn kan ní ibùdó ìṣètọ́jú kan ní London sọ pé: “Mo rò pé ó ti lọ tipẹ́tipẹ́ ni. Àmọ́, nígbà tí mo wá ṣiṣẹ́ níhìn-ín, mo rí i pé ó ṣì wà, ó sì ń gbalẹ̀ kan ní àárín gbùngbùn ìlú ńlá ọlọ́pọ̀ èrò.”
Ikọ́ ẹ̀gbẹ tún ti pa dà wá sí àwọn ibi tí ó ti kúrò pátápátá tẹ́lẹ̀ rí; ó sì ti burú bàlùmọ̀ ní àwọn ibi tí kò tí ì kúrò tẹ́lẹ̀. Dípò kí a ṣẹ́gun ikọ́ ẹ̀gbẹ, ó jẹ́ panipani tí iye tí ó ń pa bá ti ogun àti ìyàn dọ́gba. Ronú nípa èyí wò:
◼ Lójú ohun ribiribi tí ìmọ̀ ìṣègùn òde òní ń ṣe, ikọ́ ẹ̀gbẹ ti pa nǹkan bí 200 mílíọ̀nù ènìyàn láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá.
◼ Ó tó bílíọ̀nù méjì ènìyàn—ìdá mẹ́ta gbogbo ènìyàn ayé—tí wọ́n ti kó àkóràn bacillus ikọ́ ẹ̀gbẹ, irú bakitéríà kan. Ní àfikún, láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan ni ẹnì kan ń kó ikọ́ ẹ̀gbẹ!
◼ Ní 1995, iye ènìyàn tí ó ní ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ó ti pẹ́ lára jẹ́ mílíọ̀nù 22. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta tó kú, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.
Pẹ̀lú àwọn ègbòogi gbígbéṣẹ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà, kí ló dé tí àrùn yí kò yé pọ́n aráyé lójú? A óò ha ṣẹ́gun rẹ̀ láé bí? Ọ̀nà kankan ha wà tí o lè gbà dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ rẹ̀ bí? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
New Jersey Medical School—National Tuberculosis Center