Orin 94
Àwọn Ẹ̀bùn Rere Ọlọ́run Tẹ́ Wa Lọ́rùn
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run lókè
Làwọn ẹ̀bùn rere,
Ọrẹ pípé táa nífẹ̀ẹ́ sí,
Táa sì nílò, ti ńwá.
Kò sí àyídáyidà kan
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀.
Jèhófà lọba Olùpèsè
Ìyè òun ìmọ́lẹ̀.
2. Kò sídìí láti ṣàníyàn
Àtijẹ àtimu;
Òun tó ńbọ́ ẹyẹ tó ńfò ni
Yóò máa bójú tó wa.
A kìí lépa ohun asán,
A kórìíra asọ̀.
Ìpèsè Ọlọ́run tó fún wa,
O’un díẹ̀ ńtẹ́ wa lọ́rùn.
3. Ohun tó ńjọ ayé lójú
Asán ni lójú Jáà.
Ká máa fọjọ́ ayé wa yìí
Ṣohun táá ṣàǹfààní.
Ká lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run
Báa kú kò ní ṣègbé.
A nítẹ̀ẹ́lọ́rùn baba ìwà,
Ojú wa ńmọ́nà kan.
(Tún wo Jer. 45:5; Mát. 6:25-34; 1 Tím. 6:8; Héb. 13:5.