Orin 36
“Ohun Tí Ọlọ́rùn Ti So Pọ̀”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Okùn fọ́nrán mẹ́ta
So pọ̀ tiyì tẹ̀yẹ.
A gbọ́ ẹ̀jẹ́ mímọ́ náà,
Lójú Jáà àtèèyàn.
Ọkọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fáya pé,
Màá fẹ́ọ tọkàntọkàn.
(ÈGBÈ)
‘Ohun t’Ọ́lọ́run so pọ̀
Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’
2. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Láti ṣe ìfẹ́ Jáà,
Wọ́n wá ńgbàdúrà kí wọ́n
Lè mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ.
Aya jẹ́jẹ̀ẹ́ fọ́kọ pé,
Màá fẹ́ọ tọkàntọkàn.
(ÈGBÈ)
‘Ohun t’Ọ́lọ́run so pọ̀
Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’
(Tún wo Jẹ́n. 2:24; Oníw. 4:12; Éfé. 5:22-33.)