ORIN 17
“Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọmọ Ọlọ́run wá sáyé
Láti fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa.
Ó fi ọ̀run sílẹ̀
Ká lè rígbàlà,
Ó fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.
Aláàánú ni Jésù Kristi,
Ó fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀.
Ẹ̀rí fi hàn pé onínúure ni
Nígbà tó sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”
2. Àǹfààní ńlá lèyí fún wa
Pá a lè tẹ̀ lápẹẹrẹ Jésù;
Ká jẹ́ onínúure,
Ká máa fìfẹ́ hàn,
Ní ojoojúmọ́ ayé wa.
Táwọn opó bá wá bá ọ
Tàbí àwọn tó sorí kọ́,
Fẹ̀rí hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn dénú;
Kíwọ náà sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”
(Tún wo Jòh. 18:37; Éfé. 3:19; Fílí. 2:7.)