ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
Ta ni Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Láti ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ti ń ṣàlàyé pé Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù lorúkọ tí Sátánì Èṣù ń jẹ́ látìgbà tí wọ́n ti lé e kúrò lọ́run. Èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé Ìṣípayá sọ nípa Sátánì Èṣù pé òun ni òléwájú nínú ìjà tí wọ́n máa gbé ko àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé. (Ìṣí. 12:1-17) Ìdí nìyẹn tá a fi rò pé Gọ́ọ̀gù ní láti jẹ́ orúkọ míì tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Sátánì á máa jẹ́.
Àmọ́, àlàyé yìí mú kí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ. Kí nìdí? Rò ó wò ná: Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí wọ́n máa ṣẹ́gun Gọ́ọ̀gù, ó sọ nípa rẹ̀ pé: “Dájúdájú, àwọn ẹyẹ aṣọdẹ, àwọn ẹyẹ tí ó ní onírúurú ìyẹ́ apá, àti àwọn ẹranko inú pápá ni èmi yóò fi ọ́ ṣe oúnjẹ fún.” (Ìsík. 39:4) Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò fi ibì kan níbẹ̀ fún Gọ́ọ̀gù, ibi ìsìnkú ní Ísírẹ́lì . . . Ibẹ̀ ni wọn yóò sì sin Gọ́ọ̀gù àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ sí.” (Ìsík. 39:11) Àmọ́, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ‘àwọn ẹyẹ aṣọdẹ àti àwọn ẹranko inú pápá’ jẹ ẹ̀dá ẹ̀mí? Ǹjẹ́ wọ́n sì lè ‘sin òkú’ Sátánì sórí ilẹ̀ ayé? Bíbélì fi hàn kedere pé ṣe ni wọ́n máa ju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún, kì í ṣe pé ẹyẹ máa jẹ ẹ́ tàbí pé wọ́n máa sin ín.—Ìṣí. 20:1, 2.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ní òpin ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà, a máa ṣí Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, “yóò sì jáde lọ láti ṣi orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọpọ̀ fún ogun.” (Ìṣí. 20:8) Tó bá jẹ́ pé Sátánì fúnra rẹ̀ ni Gọ́ọ̀gù, ǹjẹ́ ó máa tún lè ṣi Gọ́ọ̀gù lọ́nà? Torí náà, “Gọ́ọ̀gù” tí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti ìwé Ìṣípayá mẹ́nu bà kì í ṣe Sátánì.
Ta wá ni Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ó yẹ ká wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ká lè mọ ẹni tó ń gbéjà ko áwọn èèyàn Ọlọ́run. Kì í ṣe Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù nìkan ni Bíbélì sọ pé ó máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó tún sọ pé “ọba àríwá” máa gbéjà kò wọ́n, ó sì sọ pé “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” máa gbéjà kò wọ́n. (Ìsík. 38:2, 10-13; Dán. 11:40, 44, 45; Ìṣí. 17:14; 19:19) Ṣé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa gbéjà kò wọ́n ni? Kò dájú. Ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé àtakò kan náà ni àwọn orúkọ tí Bíbélì lò yìí ń tọ́ka sí. Kí nìdí tá a fi gbà bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ló máa gbógun àjàkẹ́yìn yìí ja àwọn èèyàn Ọlọ́run tó sì máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣí. 16:14, 16.
Nígbà tá a fi gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa bí wọ́n ṣe máa gbógun àjàkẹ́yìn yìí ja àwọn èèyàn Ọlọ́run wéra, ó wá ṣe kedere pé kì í ṣe Sátánì ni Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bí kò ṣe àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣé ẹni tó dúró fún “ọba àríwá” ló máa ṣáájú àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè yìí? A ò tíì lè fi gbogbo ẹnu sọ. Àmọ́ èrò yìí fẹ́ fara jọ ohun tí Jèhófà sọ nípa Gọ́ọ̀gù, ó ní: “Ìwọ yóò sì wá láti àyè rẹ, láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn gun ẹṣin, ìjọ ńlá, àní ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ níye.”—Ìsík. 38:6, 15.
Bákan náà, nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì, tóun àti Ìsíkíẹ́lì jọ gbé láyé sọ̀rọ̀ nípa ọba àríwá, ó ní: “Ìròyìn kan yóò wà tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu, láti yíyọ oòrùn àti láti àríwá, dájúdájú yóò jáde lọ nínú ìhónú ńláǹlà láti pani rẹ́ ráúráú àti láti ya ọ̀pọ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun. Yóò sì pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin sáàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge; ó sì dájú pé yóò wá ní tààrà sí òpin rẹ̀, kì yóò sì sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún un.” (Dán. 11:44, 45) Kedere lọ̀rọ̀ yìí fara jọ ohun tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Gọ́ọ̀gù.—Ìsík. 38:8-12, 16.
Kí ni ogun àjàkẹ́yìn yìí máa yọrí sí? Dáníẹ́lì sọ pé: “Ní àkókò yẹn, Máíkẹ́lì [Jésù Kristi] yóò dìde dúró [ní Amágẹ́dọ́nì], ọmọ aládé ńlá tí ó dúró [látọdún 1914] nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ. Dájúdájú, àkókò wàhálà [ìpọ́njú ńlá] yóò wáyé irú èyí tí a kò tíì mú kí ó wáyé rí láti ìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn. Àti ní àkókò yẹn, àwọn ènìyàn rẹ yóò sá àsálà, olúkúlùkù ẹni tí a rí tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé náà.” (Dán. 12:1) Ohun tí Jésù tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run máa ṣe yìí tún wà nínú Ìṣípayá 19:11-21.
Àmọ́, ta ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù” nínú Ìṣípayá 20:8? Nígbà ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé lópin ẹgbẹ̀rún [1000] ọdún náà, àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà máa ṣe bíi ti ‘Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,’ ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè tó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run lápá ìparí ìpọ́njú ńlá. Ibì kan náà lọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì sì máa yọrí sí, ìyẹn ìparun ayérayé! (Ìṣí. 19:20, 21; 20:9) Abájọ tó fi bá a mu bí Bíbélì ṣe pe gbogbo àwọn tó máa ya ọlọ̀tẹ̀ níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà ní “Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù.”
Bá a ṣe ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń fojú sọ́nà láti mọ ẹni tó máa jẹ́ “ọba àríwá” lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́. Ẹni yòówù kó ṣáájú àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ohun méjì yìí dá wa lójú: (1) Jésù máa ṣẹ́gun Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, yóò sì pa wọ́n run; àti (2) Jésù Kristi, Ọba wa tó ń ṣàkóso, máa gba àwọn èèyàn Ọlọ́run là, yóò sì ṣamọ̀nà wọn wọnú ayé tuntun tí àlàáfià àti ààbò tó péye máa wà.—Ìṣí. 7:14-17.