ORIN 28
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 15)
1. Ta lọ̀rẹ́ rẹ, Baba,
Táá máa gbé ilé rẹ;
Ẹni tí Ìwọ gbẹ̀rí rẹ̀ jẹ́,
Tó sì mọ̀ ọ́ dunjú?
Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ,
Tí wọ́n sì nígbàgbọ́;
Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin,
Tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.
2. Ta ni yóò dọ̀rẹ́ rẹ,
Tó sì lè sún mọ́ ọ;
Táá mú kó o láyọ̀, kínú rẹ dùn,
Tíwọ sì mọ̀ dunjú?
Àwọn olódodo
Tó ń gbórúkọ rẹ ga;
Àwọn tó máa ń ṣègbọràn sí ọ,
Tó máa ń sọ òtítọ́.
3. Gbogbo àníyàn wa
La gbé síwájú rẹ.
Ojoojúmọ́ lò ń fà wá mọ́ra;
Ò ń fìfẹ́ ṣìkẹ́ wa.
A fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ
Títí ayérayé.
Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì tó dáa jù ọ́ lọ;
Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì bíi rẹ.
(Tún wo Sm. 139:1; 1 Pét. 5:6, 7.)