Mọ Bí Ó Ṣe Yẹ Kí O Dáhùn
BÍ Ẹ̀DẸ làwọn ìbéèrè kan ṣe rí. Ńṣe ni wọ́n máa ń lóyún ọ̀rọ̀ sínú. Ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àwọn ìbéèrè yẹn gan-an ló sábà máa ń ṣe pàtàkì.
Àní bí ẹni tó béèrè ọ̀rọ̀ bá tiẹ̀ ń hára gàgà láti gbọ́ ìdáhùn, ó yẹ kó o mọ bí ó ṣe yẹ kí o dáhùn, ìyẹn sì wé mọ́ fífi òye mọ ìwọ̀n ọ̀rọ̀ tó yẹ láti sọ àti ìhà tó yẹ kó o ti gbé ọ̀rọ̀ náà. (Jòh. 16:12) Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe fi hàn, ìgbà mìíràn wà tí ẹnì kan lè máa béèrè ìsọfúnni kan tí kò tọ́ sí i láti mọ̀ tàbí èyí tí kò ní ṣe é láǹfààní.—Ìṣe 1:6, 7.
Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ ni pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kól. 4:6) Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé ká mọ ohun tá ó fi dáhùn ìbéèrè, a ní láti tún mọ ọ̀nà tó yẹ ká gbà sọ ọ́, kó tó di pé à ń dáhùn.
Fòye Mọ Èrò Ọkàn Ẹni Tó Béèrè Ọ̀rọ̀
Àwọn Sadusí gbìyànjú láti kẹ́dẹ mú Jésù nípa bíbi í ní ìbéèrè kan nípa àjíǹde obìnrin kan tó ti fẹ́ ọ̀pọ̀ ọkọ rí. Ṣùgbọ́n, Jésù mọ̀ pé wọn ò kúkú gba àjíǹde gbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nígbà tí Jésù máa dáhùn ìbéèrè wọn, ńṣe ló kúkú fọ́ èrò òdì tó mú kí wọ́n tiẹ̀ bi í ní ìbéèrè yẹn yángá. Àlàyé tó jíire àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n mọ̀ ni Jésù lò láti fi tọ́ka ohun kan tí wọn kò ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ jáde, ìyẹn, ẹ̀rí tó fi hàn kedere pé Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde lóòótọ́. Ìdáhùn rẹ̀ ya àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu débi pé ẹ̀rù tiẹ̀ ń bà wọ́n láti tún bi í ní ìbéèrè mìíràn.—Lúùkù 20:27-40.
Láti mọ bí ó ṣe yẹ kí o dáhùn, o ní láti fòye mọ èrò ọkàn àwọn tó ń bi ọ́ ní ìbéèrè àti ohun tó jẹ wọ́n lógún. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tẹ́ ẹ jọ wà nílé ẹ̀kọ́ tàbí tẹ́ ẹ jọ wà níbi iṣẹ́ lè béèrè ìdí tí o kò fi ń ṣe Kérésìmesì. Kí ló fa ìbéèrè yẹn ná? Ṣé ìdí yẹn gan-an ló fẹ́ mọ̀ ni àbí ó kàn fẹ́ mọ̀ bóyá àyè tiẹ̀ wà fún ọ láti ṣe fàájì bó o bá fẹ́? Láti mọ ìdí tó fi béèrè, ó lè gba pé kó o bi í ní ohun tó mú kó béèrè bẹ́ẹ̀. Kí o sì wá fi ìyẹn dáhùn ìbéèrè rẹ̀. O tún lè lo àǹfààní yẹn láti fi jẹ́ kó rí bí títẹ̀lé ìtọ́ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ àwọn àṣà kan nínú àjọ̀dún yẹn tó ń kó àwọn èèyàn sí ìdààmú àti wàhálà.
Ká ní wọ́n pè ọ́ láti wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àwùjọ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan. Tó o bá sọ̀rọ̀ tán, wọ́n lè béèrè àwọn ìbéèrè. Bó bá jẹ́ òótọ́ inú ló sún wọn láti bi ọ́ ní àwọn ìbéèrè yẹn, tí kò sì lọ́jú pọ̀, ó lè jẹ́ ìdáhùn tó rọrùn tó sì sojú abẹ níkòó ló máa dáa jù. Bí ẹ̀tanú táwọn èèyàn ń ní ládùúgbò ibẹ̀ bá hàn nínú àwọn ìbéèrè yẹn, kí o tó dáhùn ìbéèrè wọ̀nyẹn ó lè túbọ̀ ṣàǹfààní tó o bá kọ́kọ́ ṣe àwọn àlàyé ráńpẹ́ nípa ohun tó sábà máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn ní irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn àti ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi yàn láti jẹ́ kí Bíbélì ṣamọ̀nà àwọn láti mọ ìhà tí ó yẹ kí àwọn wà nínú nǹkan wọ̀nyẹn. Ó sábà máa ń dára kí á ka irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ sí ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn, ká má ṣe kà á sí àtakò, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ gbé wọn kalẹ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Kí o wá lo ìdáhùn rẹ wàyí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti fi la àwọn olùgbọ́ rẹ lóye, láti fi fún wọn ní ìsọfúnni tó péye, àti láti fi ṣàlàyé bí Ìwé Mímọ́ ṣe ti àwọn ohun tá a gbà gbọ́ lẹ́yìn.
Kí lo lè ṣe bí ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ kò bá fẹ́ fún ọ láyè láti lọ sí àpéjọ? Lákọ̀ọ́kọ́, ro tiẹ̀ mọ́ tìẹ ná. Ṣé tó o bá yọ̀ǹda láti padà wá lo àkókò tìrẹ láti fi ṣiṣẹ́ nígbà mìíràn, ọ̀ràn yẹn á yanjú? Ǹjẹ́ tó o bá ṣàlàyé fún un pé ìtọ́ni tí a ń rí gbà nígbà àpéjọ wa máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ òṣìṣẹ́ tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ìyẹn lè mú kó yíhùn padà? Bí o bá fi hàn pé o ro tiẹ̀ mọ́ tìẹ, bóyá òun náà yóò gbà láti fún ọ láyè láti lọ ṣe ohun tí ó rí pé ó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ yìí. Ká wá ní nǹkan àbòsí kan ló fẹ́ kó o ṣe ńkọ́? Tó o bá sọ ọ́ dájú ṣáká pé o kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì fi ọ̀rọ̀ látinú Ìwé Mímọ́ tì í lẹ́yìn, yóò mọ ìhà tó o wà. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ kò ní dára jù tó o bá kọ́kọ́ ṣàlàyé fún un pé ẹni tó bá lè torí tiẹ̀ purọ́ tàbí jalè lè padà wá purọ́ fún òun alára tàbí kó jà á lólè pẹ̀lú?
Ẹ̀wẹ̀, bóyá o jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí kò fẹ́ kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nílé ẹ̀kọ́. Rántí pé olùkọ́ rẹ lè má fara mọ́ èrò ọkàn rẹ, iṣẹ́ rẹ̀ sì ni láti rí i pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tẹrí ba. Àwọn ìpèníjà tó dojú kọ ọ́ ni (1) láti gba ti ohun tó jẹ ẹ́ lógún rò, (2) láti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìhà tó o wà, àti (3) láti má yẹhùn lórí ohun tó o mọ̀ pé yóò mú inú Jèhófà dùn. Tó o bá fẹ́ kí ọ̀ràn náà yanjú lọ́nà tó dára jù lọ, ó lè gbà ju pé kí o kàn sọ̀rọ̀ ṣókí tó sojú abẹ níkòó nípa ohun tó o gbà gbọ́. (Òwe 15:28) Tí o bá ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọdé, ó dájú pé bàbá tàbí ìyá rẹ yóò bá ọ múra ohun tí o máa sọ.
Ní àwọn ìgbà mìíràn, ó lè jẹ́ pé o ní láti já àwọn ẹ̀sùn kan tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ fi kàn ọ́ ní koro. Ọlọ́pàá, aṣojú ìjọba, tàbí adájọ́ kan lè ní kí o wá dáhùn àwọn ìbéèrè lórí pípa òfin kan mọ́, tàbí ìhà tó o wà nínú ọ̀ràn àìdásí-tọ̀túntòsì gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, tàbí ìhà tó o kọ sí àwọn ayẹyẹ tó jẹ́ ti ìfọkànsin orílẹ̀-èdè ẹni. Báwo ló ṣe yẹ kó o fèsì? Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé kí a máa fèsì “pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Bákan náà, bi ara rẹ léèrè nípa ìdí tí nǹkan wọ̀nyẹn fi jẹ wọ́n lógún, kí o sì wá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fi hàn pé o gbà pé ó jẹ wọ́n lógún. Lẹ́yìn náà wá ńkọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lábẹ́ òfin Róòmù, nípa bẹ́ẹ̀ ìwọ náà lè tọ́ka sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lábẹ́ òfin tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ tìrẹ. (Ìṣe 22:25-29) Bóyá tó o bá ṣàlàyé ìhà tí àwọn Kristẹni ìjímìjí tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lóde òní kọ sí ọ̀rọ̀ yẹn yóò túbọ̀ la aṣojú ìjọba yẹn lóye sí i. Tàbí o tiẹ̀ lé sọ bí ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run ṣe máa ń súnni láti túbọ̀ fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin èèyàn tó tọ̀nà mọ́. (Róòmù 13:1-14) Lẹ́yìn ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún fara mọ́ àlàyé rẹ nípa àwọn ìdí tó tinú Ìwé Mímọ́ wá tó jẹ́ kó o ṣe ohun tó o ṣe.
Ohun Tí Ẹni Tó Béèrè Ọ̀rọ̀ Rò Nípa Ìwé Mímọ́
Nígbà tó o bá ń wo ọ̀nà tí o máa gbé ìdáhùn rẹ gbà, ó lè gba pé kí o ronú nípa ohun tí ẹni tó béèrè ọ̀rọ̀ rò nípa Ìwé Mímọ́. Jésù ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè àwọn Sadusí nípa àjíǹde. Jésù mọ̀ pé kìkì àwọn ìwé Mósè ni wọ́n tẹ́wọ́ gbà, ìyẹn ló fi lo àkọsílẹ̀ kan tó wà nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì láti fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wá kọ́kọ́ fi gbólóhùn kan bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹ̀, ó ní: “Ṣùgbọ́n pé a gbé àwọn òkú dìde ni Mósè pàápàá sọ di mímọ̀.” (Lúùkù 20:37) Ìwọ náà lè rí i pé ó dáa tó o bá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn apá ibi tí ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ gbà gbọ́ tí ó sì mọ̀ dáadáa nínú Bíbélì.
Bí ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ kò bá wá gbà pé ohun tí Bíbélì bá sọ ni abẹ gé ńkọ́? Ṣàkíyèsí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó ń sọ̀rọ̀ láàárín Áréópágù, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣe 17:22-31. Ó sọ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ fún wọn láìjẹ́ pé ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì ní tààràtà. O lè ṣe ohun kan náà níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀. Láwọn ibì kan, ó lè gba pé kó o ti bá ẹnì kan jíròrò lọ́pọ̀ ìgbà kó o tó lè máa wá tọ́ka sí Bíbélì ní tààràtà. Nígbà tó o bá sì tiẹ̀ wá sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ó lè bọ́gbọ́n mu pé kí o kàn kọ́kọ́ sọ àwọn ìdí díẹ̀ tí ó fi yẹ láti gbé e yẹ̀ wò dípò tí wàá fi sọ ọ́ ní ṣàkó pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, kí ohun tó wà lọ́kàn rẹ jẹ́ láti jẹ́rìí nípa ète Ọlọ́run, tó bá sì yá kí o wá jẹ́ kí olùgbọ́ rẹ fúnra rẹ̀ rí ohun tí Bíbélì wí. Bíbélì lè yíni lérò padà ju ohunkóhun mìíràn tí a lè fúnra wa sọ lọ.—Héb. 4:12.
Kí Ó “Máa Fìgbà Gbogbo Jẹ́ Pẹ̀lú Oore Ọ̀fẹ́”
Ó mà bá a mu gan-an o, pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ olóore ọ̀fẹ́, la ní kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn “máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́ tí a fi iyọ̀ dùn”! (Kól. 4:6; Ẹ́kís. 34:6) Ìyẹn túmọ̀ sí pé a ní láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, àní tó bá tiẹ̀ jọ pé ọ̀rọ̀ onítọ̀hún ò fẹ́ gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu wa ní láti dára, kó má ṣe jẹ́ kòbákùngbé ọ̀rọ̀.
Pákáǹleke ńláǹlà lọ́pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń bá yí, èébú lomi ọbẹ̀ tí wọ́n ń gbọ́n mu lójoojúmọ́ ayé. Bí a bá wá tọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n lè fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wa. Báwo ló ṣe yẹ ká fèsì? Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” Irú ìdáhùn bẹ́ẹ̀ lè mú inú ẹni tó ń kanra yẹn rọ̀ pẹ̀lú. (Òwe 15:1; 25:15) Ìwà àti ohùn pẹ̀lẹ́ máa ń fa àwọn èèyàn tó jẹ́ pé àárín àwọn oníjàgídíjàgan ni wọ́n ń gbé mọ́ra débi pé wọ́n á fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tá a mú wá.
A kò nífẹ̀ẹ́ sí bíbá àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún òtítọ́ jiyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé fún àwọn èèyàn tó bá gbà wá láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ipòkípò yòówù ká bá pàdé, a ń fi í sọ́kàn pé ìdáhùn pẹ̀lẹ́ ló yẹ ká máa fúnni, pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn ìlérí iyebíye tí Ọlọ́run ṣe ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.—1 Tẹs. 1:5.
Àwọn Ìpinnu Ti Ara Ẹni àti Ọ̀ràn Ẹ̀rí Ọkàn
Tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tàbí onígbàgbọ́ bíi tìrẹ bá bi ọ́ nípa ohun tó yẹ kí òun ṣe nínú irú ipò kan, báwo ló ṣe yẹ kí o dáhùn? O lè mọ ohun tí ìwọ fúnra rẹ lè ṣe. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò gbé ẹrù ìpinnu tó bá ṣe ní ìgbésí ayé. (Gál. 6:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé òun gba àwọn tí òun wàásù fún níyànjú láti máa ṣe ‘ìgbọràn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.’ (Róòmù 16:26) Àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé. Ẹni tó bá ń torí pé òun fẹ́ tẹ́ ẹni tó ń bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí èèyàn mìíràn lọ́rùn ṣe àwọn ìpinnu, èèyàn lonítọ̀hún ń sìn, kò gbé nípa ìgbàgbọ́. (Gál. 1:10) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìdáhùn ṣókí, tó ṣe tààrà lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣe ẹni tó ń ṣèwádìí yìí lóore.
Ọ̀nà wo ni wàá wá gbà dáhùn lọ́nà tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu? O lè pe àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ìlànà àti àpẹẹrẹ tó yẹ nínú Bíbélì. Nígbà mìíràn, o lè fi hàn án bí ó ṣe lè fúnra rẹ̀ ṣèwádìí láti rí àwọn ìlànà àti àpẹẹrẹ yẹn. O tiẹ̀ lè ṣàlàyé àwọn ìlànà yìí àti ìlò àwọn àpẹẹrẹ yẹn ṣùgbọ́n kó o má sọ bí wọ́n ṣe yanjú ohun tí onítọ̀hún bá wá ní tààràtà. Wá bi onítọ̀hún bóyá ó rí ohun tó lè lò níbẹ̀ láti fi ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Gbà á níyànjú pé kó lo àwọn ìlànà àti àpẹẹrẹ wọ̀nyí láti fi yan ọ̀nà tí yóò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Ńṣe ni o ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti ‘kọ́ agbára ìwòye rẹ̀ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’—Héb. 5:14.
Dídáhùn ní Àwọn Ìpàdé Ìjọ
Àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni sábà máa ń jẹ́ ká láǹfààní láti polongo ìgbàgbọ́ wa ní gbangba. Ọ̀nà kan tí a máa ń gbà ṣe ìyẹn ni nípa nínawọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè nípàdé. Báwo lo ṣe yẹ kí ìdáhùn wa rí? Ó yẹ kó jẹ́ èyí tí ń fi ìbùkún fún Jèhófà, tàbí èyí tí ń sọ̀rọ̀ oore rẹ̀. Ohun tí onísáàmù náà Dáfídì ṣe nìyẹn nígbà tó wà ní “inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.” (Sm. 26:12) A sì tún ní láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa níṣìírí, tí yóò ru wọ́n sókè “sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà,” bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe rọni láti ṣe. (Héb. 10:23-25) Tí a bá ń ka apá ibi tí a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀, a ó lè dáhùn lọ́nà bẹ́ẹ̀.
Tí a bá wá pè ọ́ láti dáhùn, sọ ojú ọ̀rọ̀, kó yéni yékéyéké kó sì ṣe ṣókí. Má ṣe kárí ìpínrọ̀ yẹn látòkè délẹ̀; kókó kan péré ni kó o sọ̀rọ̀ lé lórí. Bí o bá sọ apá kan lára ìdáhùn yẹn, àwọn yòókù á lè láǹfààní láti ṣàlàyé nípa rẹ̀ síwájú sí i. Ní pàtàkì, ó ṣàǹfààní láti ṣàlàyé nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a bá yàn sínú ẹ̀kọ́ yẹn. Nígbà tó o bá ń ṣàlàyé yìí, gbìyànjú láti pe àfiyèsí sí apá tó kan kókó tí ẹ ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Fi kọ́ra láti máa ṣàlàyé lọ́rọ̀ ara rẹ dípò kíka ọ̀rọ̀ inú ìpínrọ̀ yẹn jáde ní tààràtà. Má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọ bí àlàyé rẹ kò bá bọ́ sójú ọ̀nà tó. Gbogbo ẹni tó bá ti ń dáhùn ìbéèrè nìyẹn máa ń ṣẹlẹ̀ sí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ó dájú pé mímọ bó ṣe yẹ ká dáhùn kò mọ sórí kéèyàn ṣáà ti mọ ohun tí yóò fi dáhùn ìbéèrè ọ̀hún gan-an. Ó gba kéèyàn lo òye. Àmọ́, ó máa ń dùn mọ́ni gan-an bí a bá dáhùn látọkànwá tí ìdáhùn yẹn sì wọ àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn ṣinṣin!—Òwe 15:23.