Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìdárò
WÒLÍÌ Jeremáyà fojú ara rẹ̀ rí ìmúṣẹ ìdájọ́ tó ti ń kéde fún ogójì ọdún. Báwo ló ṣe rí lára wòlíì yìí nígbà tó rí i tí ìlú rẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an pa run? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi nasẹ̀ ìwé Ìdárò nínú Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì sọ pé, “Jeremáyà jókòó ó ń sunkún ó sì dárò pẹ̀lú ìdárò yìí lórí Jerúsálẹ́mù.” Ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wòlíì Jeremáyà kọ ìwé náà. Nígbà yẹn, ó ṣì rántí dáadáa bí wọ́n ṣe fi ogun yí ìlú Jerúsálẹ́mù ká fún ọdún kan àtààbọ̀ tí wọ́n sì dáná sún un lẹ́yìn náà. Ìwé ìdárò jẹ́ ká mọ bí ọkàn Jeremáyà ṣe gbọgbẹ́ tó. (Jeremáyà 52:3-5, 12-14) Kò tíì sí ìlú mìíràn nínú ìtàn tí wọ́n dárò rẹ̀ lọ́nà tó ṣeni láàánú tó sì bani nínú jẹ́ tó báyìí rí.
Ìwé Ìdárò jẹ́ àpapọ̀ ewì márùn-ún. Mẹ́rin àkọ́kọ́ jẹ́ ìdárò tàbí orin arò, ìkarùn-ún sì jẹ́ ẹ̀bẹ̀ tàbí àdúrà. Orin mẹ́rin àkọ́kọ́ yìí yàtọ̀ sí orin karùn-ún, nítorí pé álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ló bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ kọ̀ọ̀kan wọn, àpapọ̀ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì náà sì jẹ́ méjìlélógún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ méjìlélógún ni orin kárùn-ún ní, èyí tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iye lẹ́tà tó wà nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù, wọn ò lo àwọn álífábẹ́ẹ̀tì náà láti to àwọn ẹsẹ inú orin kárùn-ún.
‘OJÚ MI TI WÁ SÍ ÒPIN RẸ̀ NÍNÚ OMIJÉ’
“Wo bí ó ti jókòó ní òun nìkan, ìlú ńlá tí ó kún fún ọ̀pọ̀ yanturu ènìyàn! Wo bí ó ti dà bí opó, òun tí ó jẹ́ elénìyàn púpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè! Wo bí òun tí ó jẹ́ ọmọ aládé obìnrin láàárín àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ ṣe wá wà fún òpò àfipámúniṣe!” Ọ̀nà yìí ni wòlíì Jeremáyà gbà bẹ̀rẹ̀ ìdárò rẹ̀ lórí ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wòlíì yìí ń sọ ìdí tí àjálù yìí fi ṣẹlẹ̀, ó ní: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti mú ẹ̀dùn-ọkàn wá bá a ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu ìrélànàkọjá rẹ̀.”—Ìdárò 1:1, 5.
Bíbélì ṣàpèjúwe ìlú Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí opó tó pàdánù ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀, tó wá ń béèrè pé: “Ìrora kankan ha wà tí ó dà bí ìrora mi?” Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọ̀tá rẹ̀ pé: “Kí gbogbo ìwà búburú wọn wá síwájú rẹ, kí o sì bá wọn lò lọ́nà mímúná, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti bá mi lò lọ́nà mímúná ní tìtorí gbogbo ìrélànàkọjá mi. Nítorí ìmí ẹ̀dùn mi pọ̀, ọkàn-àyà mi sì ń ṣàmódi.”—Ìdárò 1:12, 22.
Inú Jeremáyà bà jẹ́ gan-an tó fi sọ pé: “Nínú ìgbóná ìbínú [Jèhófà] ti ké gbogbo ìwo Ísírẹ́lì lulẹ̀. Ó ti yí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ padà níwájú ọ̀tá; àti ní Jékọ́bù, ó ń jó bí iná tí ń jó fòfò, èyí tí ó ti jẹ gbogbo àyíká run.” Nígbà tí wòlíì yìí ń ṣàlàyé bí ìbànújẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tó, ó dárò pé: “Ojú mi ti wá sí òpin rẹ̀ nínú kìkìdá omijé. Ìfun mi ń hó. A ti tú ẹ̀dọ̀ mi jáde sí ilẹ̀yílẹ̀.” Kódà ẹnu ya àwọn tó ń kọjá níbẹ̀, wọ́n ní: “Ṣe ìlú ńlá náà nìyí tí wọ́n máa ń sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Òun ni ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra, ayọ̀ ńláǹlà fún gbogbo ilẹ̀ ayé’?”—Ìdárò 2:3, 11, 15.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:15—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “tẹ ìfúntí wáìnì tí ó jẹ́ ti wúńdíá ọmọbìnrin Júdà?” Nígbà táwọn ará Bábílónì ń pa ìlú tí Bíbélì pè ní wúńdíá yìí run, wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń tẹ èso àjàrà nínú ìfúntí wáìnì. Jèhófà ti sàsọtẹ́lẹ̀ èyí, ó sì jẹ́ kó ṣẹlẹ̀, nípa báyìí, a lè sọ pé ó “tẹ ìfúntí wáìnì.”
2:1—Báwo la ṣe “ju ẹwà Ísírẹ́lì láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé”? Níwọ̀n bí “ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé,” rírẹ ohun tó wà nípò gíga sílẹ̀ ni ‘jíjù nǹkan láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé’ máa ń dúró fún nígbà míì. Ìgbà táwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì sọ ilẹ̀ Júdà dahoro ni Ọlọ́run ju “ẹwà Ísírẹ́lì” sílẹ̀. Ẹwà yìí túmọ̀ sí ògo àti agbára tó ní nígbà tí ìbùkún Jèhófà ṣì wà lórí rẹ̀.—Aísáyà 55:9.
2:1, 6—Kí ni “àpótí ìtìsẹ̀” Jèhófà àti “àtíbàbà” rẹ̀? Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù kọrin pé: “Ẹ jẹ́ kí a wá sínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀ títóbi lọ́lá; ẹ jẹ́ kí a tẹrí ba níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.” (Sáàmù 132:7) Nítorí náà, ilé ìjọsìn Jèhófà tàbí tẹ́ńpìlì rẹ̀ ni “àpótí ìtìsẹ̀” inú Ìdárò 2:1 ń tọ́ka sí. Àwọn ará Bábílónì “fi iná sun ilé Jèhófà” bíi pé àtíbàbà, tàbí ahéré kan lásán tó wà nínú ọgbà ni.—Jeremáyà 52:12, 13.
2:16, 17—Ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹsẹ kẹrìndínlógún bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà Hébérù náà, áyínì, kí ẹsẹ kẹtàdínlógún sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà náà, péè, kí wọ́n bàa lè bá bí álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ṣe tò tẹ̀ léra mu? Nígbà táwọn òǹkọ̀wé tí Ọlọ́run mí sí bá ń kọ ewì ní ọ̀nà yìí, wọ́n sábà máa ń tẹ̀ lé bí álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ṣe tò tẹ̀ léra. Àmọ́ ṣá o, wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ bí èyí kò bá ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dún dáadáa. Wọ́n gbà pé ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ ní ṣe pàtàkì ju títẹ̀lé ọ̀nà ìgbàto ọ̀rọ̀ lásán, èyí táá kàn jẹ́ kéèyàn rántí ọ̀rọ̀. Wọ́n tún yí àwọn lẹ́tà méjì yìí kan náà padà nínú orin kẹta àti orin kẹrin ìwé Ìdárò.—Ìdárò 3:46, 49; 4:16, 17.
2:17—“Àsọjáde” wo ní pàtàkì ni Jèhófà mú ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù? Kò sí àní-àní pé ohun tó wà nínú Léfítíkù 26:17 ni ẹsẹ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tó sọ pé: “Èmi yóò sì dojú kọ yín, a ó sì ṣẹ́gun yín dájúdájú níwájú àwọn ọ̀tá yín; àwọn tí ó kórìíra yín yóò sì wulẹ̀ tẹ̀ yín mọ́lẹ̀, ẹ ó sì sá lọ ní ti tòótọ́ nígbà tí ẹnì kankan kò lépa yín.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:1-9. Jerúsálẹ́mù sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ ní òru, omijé rẹ̀ sì wà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ni a sọ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń mí ìmí ẹ̀dùn. Ìbànújẹ́ ńlá ti bá àwọn wúńdíá rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì ní ìbànújẹ́ kíkorò. Kí nìdí? Nítorí pé Jerúsálẹ́mù dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni. Ẹ̀gbin rẹ̀ wà lára ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀. Àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ kì í mú ayọ̀ wá; ẹkún, òṣé, ẹ̀dùn ọkàn, àti ìbànújẹ́ ló máa ń yọrí sí.
1:18. Bí Jèhófà ṣe fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fi hàn pé ó jẹ́ olódodo nígbà gbogbo.
2:20. Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ pé bí wọn kò bá fetí sí ohùn òun, ègún yóò wá sórí wọn. Lára rẹ̀ ni pé wọ́n á jẹ ‘ẹran ara àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn.’ (Diutarónómì 28:15, 45, 53) Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run!
“MÁ FI ETÍ RẸ PA MỌ́ FÚN ÌTURA MI”
Nínú Ìdárò orí kẹta, a pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní “abarapá ọkùnrin.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin yìí wà nínú ìdààmú, ó kọrin pé: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí ọkàn tí ń wá a.” Nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run tòótọ́, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Gbọ́ ohùn mi. Má fi etí rẹ pa mọ́ fún ìtura mi, fún igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.” Nígbà tó ń bẹ Jèhófà pé kó kíyè sí ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá, ó sọ pé: “Ìwọ yóò fi ìbálò kan bá wọn lò padà, Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”—Ìdárò 3:1, 25, 56, 64.
Jeremáyà sọ bínú rẹ̀ ṣe bà jẹ́ tó nítorí ohun búburú jáì tó jẹ́ àbájáde dídó táwọn ọ̀tá dó ti Jerúsálẹ́mù fún ọdún kan àtààbọ̀, ó wá dárò pé: “Ìyà ìṣìnà ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi wá pọ̀ ju ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Sódómù lọ, èyí tí a bì ṣubú bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan, èyí tí ọwọ́ kankan kò sì wá ràn lọ́wọ́.” Jeremáyà ń bá ìdárò rẹ̀ lọ, ó ní: “Ó sàn fún àwọn tí a fi idà pa jù fún àwọn tí a fi ìyàn pa, nítorí pé àwọn wọ̀nyí ń joro dànù, a gún wọn ní àgúnyọ nítorí àìsí àmújáde inú pápá gbalasa.”—Ìdárò 4:6, 9.
Ewì karùn-ún ṣàpèjúwe àwọn èèyàn ìlú Jerúsálẹ́mù bíi pé wọ́n ń sọ̀rọ̀. Wọ́n ní: “Rántí, Jèhófà, ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa. Wò, kí o sì rí ẹ̀gàn wa.” Bí wọ́n ti ń sọ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé: “Jèhófà, fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ìwọ yóò jókòó. Ìtẹ́ rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran. Mú wa padà, Jèhófà, sọ́dọ̀ ara rẹ, wéréwéré ni àwa yóò sì padà wá. Mú ọjọ́ tuntun wá fún wa bí ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.”—Ìdárò 5:1, 19, 21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
3:16—Kí ni gbólóhùn náà, ‘Ó fi taàrá ká eyín mi’ túmọ̀ sí? Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Nígbà táwọn Júù ń lọ sígbèkùn, wọn ò rọ́gbọ́n dá ju pé kí wọ́n yan búrẹ́dì wọn nínú àwọn kòtò tí wọ́n gbẹ́ sínú ilẹ̀, èyí sì mú kí òkúta wẹ́wẹ́ wà nínú búrẹ́dì wọn.” Jíjẹ irú búrẹ́dì bẹ́ẹ̀ lè kán èèyàn léyín.
4:3, 10—Kí nìdí tí Jeremáyà fi fi “ọmọbìnrin àwọn ènìyàn [rẹ̀]” wé “ògòǹgò ní aginjù”? Jóòbù 39:16 sọ pé ògòǹgò máa “ń ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ ṣúkaṣùka, bí ẹni pé kì í ṣe tirẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, bí ẹyẹ náà bá pamọ tán, ńṣe ló máa bá àwọn ẹyẹ mìíràn lọ tí akọ á sì máa bójú tó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ náà. Kí ló sì máa ń ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá rí ewu? Àti akọ àti abo ẹyẹ náà á sá kúrò nínú ìtẹ́, wọ́n á sì fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀. Nígbà táwọn ará Bábílónì wá dó ti Jerúsálẹ́mù, ìyàn inú ìlú náà lágbára débi pé, àwọn ìyá tí wọ́n máa ń láàánú ká ní ohunkóhun kò ṣẹlẹ̀ wá ya ìkà sáwọn ọmọ tiwọn fúnra wọn, bíi ti ẹyẹ ògòǹgò inú aginjù. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí báwọn akátá ṣe máa ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ wọn.
5:7—Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń mú káwọn èèyàn jìyà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn baba ńlá wọn ṣẹ̀? Rárá o, Jèhófà kì í fìyà jẹ àwọn èèyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Àmọ́ o, àwọn ohun tó ń tìdí ẹ̀ṣẹ̀ yọ lè máà tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀, káwọn ìran tó ń bọ̀ sì máa jìyà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nítorí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un yà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n lọ ń bọ̀rìṣà, èyí mú kó ṣòro fáwọn tó tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ lẹ́yìn ìgbà náà láti rọ̀ mọ́ ọ̀nà òdodo.—Ẹ́kísódù 20:5.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
3:8, 43, 44. Nígbà àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí ìlú Jerúsálẹ́mù, Jèhófà kọ̀ láti tẹ́tí sí igbe àwọn èèyàn ìlú náà bí wọ́n ti ń ké pè é pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Kí nìdí? Nítorí pé àwọn èèyàn náà jẹ́ aláìgbọràn ni, wọ́n sì kọ̀ láti ronú pìwà dà. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dáhùn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i.—Òwe 28:9.
3:20. Jèhófà, tó jẹ́ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,” ga débi pé ó ní láti rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ “láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18; 113:6) Síbẹ̀ Jeremáyà mọ̀ pé Olódùmarè ṣe tán láti rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ kó bàa lè fún àwọn èèyàn náà níṣìírí. Ẹ ò rí i pé ó yẹ kínú wa máa dùn gan-an pé kì í ṣe pé Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ alágbára gbogbo àti ọlọ́gbọ́n gbogbo nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀!
3:21-26, 28-33. Báwo la ṣe lè fara da ìnira tó tiẹ̀ gàgaàrá? Jeremáyà sọ fún wa. A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé Jèhófà pọ̀ ní ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti pé ọ̀pọ̀ ni àánú rẹ̀. Ó tún yẹ ká máa rántí pé wíwà tá a tiẹ̀ wà láàyè tó fún wa láti má ṣe sọ̀rètínù, àti pé ó yẹ ká ní sùúrù ká sì dúró de Jèhófà fún ìgbàlà, ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti láìráhùn. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún yẹ ká “fi ẹnu [wa] sínú ekuru,” ìyẹn ni pé tí ìdààmú bá dé, ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, ní mímọ̀ pé bí Ọlọ́run bá fàyè gba ohun kan láti ṣẹlẹ̀, fún ìdí rere kan ni.
3:27. Kíkojú àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò nígbà tá a wà lọ́dọ̀ọ́ lè gba pé ká fara da ìnira àti ìfiṣẹ̀sín. Àmọ́, ó “dára kí abarapá ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.” Kí nìdí? Nítorí pé kíkọ́ láti fara da ìnira nígbà téèyàn wà lọ́dọ̀ọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn wà ní ìmúrasílẹ̀ láti lè kojú ìṣòro nígbà tó bá dàgbà.
3:39-42. ‘Ká máa ráhùn ṣáá’ nígbà tá a bá ń kórè ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá kò bọ́gbọ́n mu. Dípò ká máa ṣàròyé nítorí pé à ń kórè ìwà àìtọ́ tá a hù, ẹ “jẹ́ kí a wá ọ̀nà wa kàn, kí a sì yẹ̀ ẹ́ wò, kí a sì padà tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà.” Tá a bá ronú pìwà dà tá a sì tún ọ̀nà wa ṣe, ọlọ́gbọ́n la jẹ́.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Ìwé Ìdárò nínú Bibeli jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà nípa Jerúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Júdà lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì fi iná sun ìlú náà tí wọ́n sì sọ ilẹ̀ náà dahoro. Àwọn gbólóhùn tó wà nínú ìwé yìí, tó fi hàn pé lóòótọ́ làwọn èèyàn náà ṣẹ̀, jẹ́ ká rí i kedere pé lójú Jèhófà, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn náà ló jẹ́ kí wọ́n rí ìyọnu. Àwọn orin tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé yìí tún ní àwọn ọ̀rọ̀ tó fi ìrètí hàn nínú Jèhófà, àti báwọn kan ṣe fẹ́ láti yí padà kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ọjọ́ Jeremáyà ni kò ní ìrú èrò yìí lọ́kàn, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé ohun tí Jeremáyà àtàwọn àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà ní lọ́kàn nìyẹn.
Ẹ̀kọ́ méjì pàtàkì ni ojú tí Jèhófà fi wo ipò tí Jerúsálẹ́mù wà kọ́ wa, gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú ìwé Ìdárò. Ẹ̀kọ́ kìíní, ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù àti sísọ tí wọ́n sọ ilẹ̀ Júdà dahoro fún wa níṣìírí láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì tún jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe kọ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ẹ̀kọ́ kejì ni ohun tá a rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jeremáyà fúnra rẹ̀. (Róòmù 15:4) Kódà nígbà tí wòlíì tínú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an yìí wà nínú ipò kan tó dà bíi pé kò sí ìrètí rárá, ó yíjú sí Jèhófà fún ìgbàlà. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fọkàn tán Jèhófà pátápátá àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé wa!—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Wòlíì Jeremáyà fojú ara rẹ̀ rí ìmúṣẹ ìdájọ́ tó kéde rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ẹlẹ́rìí ara Kòríà wọ̀nyí rí ìdánwò ìgbàgbọ́ nítorí pé wọn ò lọ́wọ́ sógun