Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
APRIL 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 7-9
Ẹ̀bùn Ni Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya
Lo Ẹ̀bùn Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
3 Ẹni tí kò ṣègbéyàwó sábà máa ń ní àkókò tó pọ̀ ju ti àwọn lọ́kọláya, ó sì tún máa ń ní òmìnira jù wọ́n lọ. (1 Kọ́r. 7:32-35) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́, torí pé ó máa jẹ́ kó lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kó máa fìfẹ́ hàn sí àwọn míì, kó sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti wá mọyì àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwà láìṣègbéyàwó, wọ́n sì ti pinnu láti “wá àyè fún un,” bó tiẹ̀ jẹ́ fún àkókò díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan fẹ́ láti ṣègbéyàwó, àmọ́ nígbà tí wọn kò rí ọkọ tàbí aya tàbí tí wọn kò ní ọkọ tàbí aya mọ́, wọ́n tún ipò ara wọn gbé yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, wọ́n sì wá rí i pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àwọn lè wà láìní ọkọ tàbí aya. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n fara mọ́ ipò tí wọ́n bá ara wọn, wọ́n sì ń bá a lọ láìní ọkọ tàbí aya.—1 Kọ́r. 7:37, 38.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kọ́ríńtì Kìíní àti Ìkejì
7:33, 34—Kí ni “àwọn ohun ti ayé,” tí ọkùnrin tàbí obìnrin tó ti ṣègbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Àwọn nǹkan tara tó yẹ káwọn Kristẹni tó bá ti ṣègbéyàwó máa ṣàníyàn nípa rẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí. Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni oúnjẹ, aṣọ àti ilé, àmọ́ kì í ṣàwọn ohun búburú ayé yìí táwọn Kristẹni ní láti sá fún ló ń sọ o.—1 Jòhánù 2:15-17.
Wíwà Lápọ̀n-ọ́n—Ilẹ̀kùn Sí Ìgbòkègbodò Àpọkànpọ̀ṣe
14 Kristẹni àpọ́n kan tí ń lo ipò àìgbéyàwó rẹ̀ láti lépa góńgó onímọtara-ẹni-nìkan kò ṣe “dáadáa” ju àwọn Kristẹni tí ó gbéyàwó lọ. Ó wà lápọ̀n-ọ́n, kì í ṣe ‘ní tìtorí ìjọba náà,’ ṣùgbọ́n nítorí ohun ti ara rẹ̀. (Mátíù 19:12) Ọkùnrin tí kò gbéyàwó tàbí obìnrin tí kò lọ́kọ ní láti “ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa,” ó ní láti ṣàníyàn láti “jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà Olúwa,” kí ó sì máa ‘ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.’ Èyí túmọ̀ sí yíya àfiyèsí tí a kò pín níyà sọ́tọ̀ pátápátá fún ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà àti Kristi Jésù. Kìkì nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ni àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọn kò ní alábàáṣègbéyàwó fi lè ṣe “dáadáa” ju àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó lọ.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
lv àfikún 219 ¶2-221 ¶3
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà
Jèhófà ò fẹ́ káwọn tó gbéra wọn níyàwó dalẹ̀ ara wọn. Nígbà tí Jèhófà ń so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀, ó wí pé: “Ọkùnrin . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” Nígbà tó ṣe, Jésù Kristi sọ gbólóhùn yìí kan náà, ó sì fi kún un pé: “Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:3-6) Nítorí èyí, Jèhófà àti Jésù ń wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ètò táá máa wà títí lọ, àyàfi bí ọkọ tàbí aya bá kú. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló fìdí ìgbéyàwó múlẹ̀, ìkọ̀sílẹ̀ kúrò lóun téèyàn á fọwọ́ kékeré mú. Kódà, Jèhófà kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.—Málákì 2:15, 16.
Kí nìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí tọkọtaya fi lè kọra wọn sílẹ̀? Ohun kan ni pé Jèhófà kórìíra panṣágà àti àgbèrè. (Jẹ́nẹ́sísì 39:9; 2 Sámúẹ́lì 11:26, 27; Sáàmù 51:4) Ó tiẹ̀ kórìíra àgbèrè débi pé ó gbà kí tọkọtaya torí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀. (Bó o bá fẹ́ ka ohun tí àgbèrè túmọ̀ sí, wo Orí 9, ìpínrọ̀ 7, níbi tá a ti ṣàlàyé àgbèrè.) Jèhófà fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ bá dalẹ̀ láǹfààní láti yàn bóyá á ṣì máa bá a gbé tàbí ó máa fẹ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Torí náà, bí ọkọ tàbí aya ẹni tó dalẹ̀ náà bá yàn láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Síbẹ̀, ìjọ Ọlọ́run ò fi dandan gbọ̀n lé e pé kí ẹnikẹ́ni kọra wọn sílẹ̀. Kódà, lábẹ́ àwọn ipò kan, ọkọ tàbí aya ẹni tó dalẹ̀ náà ṣì lè fẹ́ máa gbé pẹ̀lú rẹ̀, pàápàá bó bá ronú pìwà dà látọkàn wá. Bó ti wù kó rí ṣá, àwọn tí wọ́n nídìí tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti kọra wọn sílẹ̀ gbọ́dọ̀ dá pinnu ohun tí wọ́n á ṣe, kí wọ́n sì fara mọ́ ibi tọ́ràn náà bá já sí.—Gálátíà 6:5.
Lábẹ́ àwọn ipò kan tó le koko, àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á pínyà tàbí káwọn kọ ọkọ tàbí aya àwọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe àgbèrè. Lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé kí ẹni tó pínyà yẹn “wà láìlọ́kọ [tàbí, láìláya], bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀” náà. (1 Kọ́ríńtì 7:11) Irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ kò lómìnira láti tún fẹ́ ẹlòmíì. (Mátíù 5:32) Gbé àwọn ipò líle koko díẹ̀ táwọn kan ti torí ẹ̀ pínyà yẹ̀ wò.
Mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọ́ bùkátà ìdílé. Ìdílé kan lè tòṣì, kí wọ́n má sì láwọn ohun kòṣeémánìí, torí pé ọkọ ò pèsè ohun tó yẹ fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára rẹ̀ gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún . . . àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Bírú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ bá kọ̀ láti yí ìwà rẹ̀ padà, aya ní láti pinnu bóyá ó yẹ kóun fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, káwọn sì pínyà, kóun àtàwọn ọmọ má bàa máa ráágó. Àmọ́ ṣá o, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ gbé ẹ̀sùn èyíkéyìí tí Kristẹni kan bá mú wá pé ọkọ òun ò pèsè jíjẹ, mímu àti aṣọ fún ìdílé rẹ̀ yẹ̀ wò dáádáá. Bí ọkọ bá kọ̀ láti bójú tó ìdílé rẹ̀, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́ o.
Lílù ní àlùbami. Báwọn tó fẹ́ra wọn sílé bá ń lura wọn bí ẹní lu bàrà, ẹni tọ́wọ́ ìyà náà ń dùn lè di aláàárẹ̀ tàbí kí ìwàláàyè rẹ̀ wà nínú ewu. Bí ẹni tó ń lu ẹnì kejì rẹ̀ bá jẹ́ Kristẹni, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀ràn náà wò. Kéèyàn máa bínú fùfù, kó sì máa ṣe ohun tó lè pa ẹlòmíì lára, lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́.—Gálátíà 5:19-21.
Mímú kó nira láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Ọkọ tàbí aya lè máa ṣe ohun tó máa mú kó nira fún ẹnì kejì rẹ̀ láti máa kópa nínú ìjọsìn tòótọ́ tàbí kó tiẹ̀ máa fipá mú un láti rú òfin Ọlọ́run láwọn ọ̀nà kan. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ ìjọsìn rẹ̀ di akúrẹtẹ̀ ní láti pinnu bóyá ọ̀nà tó dára jù lọ fóun láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn” ni pé kóun fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, kóun sì pínyà pẹ̀lú ẹnì kejì òun.—Ìṣe 5:29.
Nínú gbogbo ọ̀ràn tí ìṣòro tó légbá kan bá ti wáyé bí irú èyí tó wà lókè yìí, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ fi dandan lé e pé kí ẹni tọ́ràn kàn pínyà tàbí kó máa bá a yí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó lóye òtítọ́ jinlẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ onítọ̀hún àtàwọn alàgbà lè ṣaájò kí wọ́n sì fi Bíbélì gbà wọ́n nímọ̀ràn, wọn ò lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọkọ àti aya. Ojú Jèhófà nìkan ló tó o. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ohun tó ń bọlá fún Ọlọ́run tàbí ètò ìgbéyàwó bí Kristẹni tó jẹ́ aya tàbí ọkọ bá ń ṣe àbùmọ́ àwọn ìṣòro tó ń wáyé nínú ilé wọn torí àtilè pínyà kí wọ́n sì máa gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Béèyàn bá dọ́gbọ́n sí i kóun àti ẹnì kejì rẹ̀ lè pínyà, ojú Jèhófà tó o, bó ti wù kó gbìyànjú láti fọ̀rọ̀ náà pa mọ́ tó. Àní sẹ́, “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Àmọ́, bó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ léwu gan-an, kí ẹnikẹ́ni má ṣe wá ẹ̀sùn sí Kristẹni èyíkéyìí lẹ́sẹ̀, bó bá parí ẹ̀ sí pé káwọn kúkú pínyà. Ó ṣe tán, “gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 14:10-12.
O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
Nítorí náà, kò yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ fi ìwàǹwára kó wọnú ìgbéyàwó, ní gbàrà tí òòfà ìbálòpọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nínú wọn. Ìgbéyàwó ń béèrè pé ká wọnú ẹ̀jẹ́, èèyàn sì gbọ́dọ̀ dàgbà dénú kí ó bàa lè pa ẹ̀jẹ́ yẹn mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ó sàn kéèyàn dúró, kí ó “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe”—èyíinì ni ìgbà tí òòfà ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, tí ó sì lè tètè kó síni lórí. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ẹ sì wo bó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tó, kí ẹni tó ti tójúúbọ́, tí ọ̀ràn ìgbéyàwó ń jẹ lọ́kàn, lọ ṣe ìṣekúṣe, kìkì nítorí pé kò tíì rí ẹni tó máa fẹ́!
Bíbélì Kíkà
APRIL 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 10-13
“Jèhófà Jẹ́ Olóòótọ́”
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà kò ní “jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.” (1 Kọ́r. 10:13) Ṣé èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà ti kọ́kọ́ máa ń díwọ̀n ohun tá a lè mú mọ́ra kó tó wá pinnu irú àdánwò táá jẹ́ kó dé bá wa?
▪ Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó lè mú kéèyàn rò. Arákùnrin kan tí ọmọ rẹ̀ ṣekú para rẹ̀ béèrè pé: ‘Ṣé Jèhófà ti kọ́kọ́ díwọ̀n bóyá èmi àtìyàwó mi á lè mú ikú ọmọ wa mọ́ra kó tó wá gbà kọ́mọ náà ṣekú para rẹ̀ ni? Ṣé torí pé Jèhófà ti pinnu pé àá lè fara dà á ló fi jẹ́ kó ṣẹlẹ̀?’ Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé Jèhófà máa ń darí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́nà bẹ́ẹ̀?
Nígbà tá a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, ohun tá a rí ni pé: Kò sí ẹ̀rí èyíkéyìí nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jèhófà kọ́kọ́ máa ń díwọ̀n ìṣòro tàbí àdánwò tá a lè fara dà kó tó wá pinnu irú ìṣòro tàbí àdánwò tó máa jẹ́ kó dé bá wa. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí mẹ́rin tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
Àkọ́kọ́, Jèhófà fún àwa èèyàn ní òmìnira. Ó fún wa láǹfààní láti yan ohun tá a máa fayé wa ṣe. (Diu. 30:19, 20; Jóṣ. 24:15) Tá a bá yàn láti ṣe ohun tó tọ́, a lè bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà. (Òwe 16:9) Àmọ́ tá a bá yàn láti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa náà la máa jìyà ohun tó bá tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. (Gál. 6:7) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jèhófà ń pinnu àdánwò tó máa dé bá wa, ṣé a lè sọ pé ó fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá lóòótọ́?
Èkejì, Jèhófà máa ń fàyè gba “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9:11) Ìjàǹbá lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni torí pé onítọ̀hún rin àrìnfẹsẹ̀sí tàbí pé ó ṣe kòńgẹ́ aburú. Bí àpẹẹrẹ, Jésù mẹ́nu ba ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan níbi tí ilé gogoro ti wó pa àwọn èèyàn méjìdínlógún [18], ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló fà á. (Lúùkù 13:1-5) Ṣó wá bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kí àjálù kan tó ṣẹlẹ̀ ni Ọlọ́run ti máa ń pinnu ẹni tó máa bá àjálù náà lọ àtẹni tó máa yè é?
Ẹ̀kẹta, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa fi hàn bóyá òun á jẹ́ olóòótọ́ tàbí òun ò ní jólóòótọ́. A ò ní gbàgbé pé Sátánì fẹ̀sùn kan gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà pé a ò ní jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tí ìṣòro tàbí àdánwò bá dé bá wa. (Jóòbù 1:9-11; 2:4; Ìṣí. 12:10) Tí Jèhófà kò bá jẹ́ káwọn àdánwò kan dé bá wa torí pé ó ti díwọ̀n pé a ò ní lè fara dà á, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Sátánì kò ní já sóòótọ́ pé ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló jẹ́ ká máa sìn ín?
Ẹ̀kẹrin, kò di dandan kí Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Tá a bá sọ pé Jèhófà ti kọ́kọ́ máa ń pinnu àwọn àdánwò tó máa dé bá wa, ohun tá à ń sọ ni pé ó mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, èrò yìí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Kò sí àní-àní pé Ọ̇lọ́run lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Aísá. 46:10) Àmọ́ Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń yan ohun tó bá fẹ́ mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. (Jẹ́n. 18:20, 21; 22:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè mọ ọjọ́ ọ̀la wa, síbẹ̀ kì í dí wa lọ́wọ́ àtilo òmìnira tá a ní. Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tá a retí pé kí Ọlọ́run ṣe nìyẹn? Ó ṣe tán, kì í ṣe amúnisìn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣi agbára tó ní lò.—Diu. 32:4; 2 Kọ́r. 3:17.
Kí wá ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: ‘Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra’? Kì í ṣe ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa ṣáájú àdánwò lohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bíkòṣe ohun tó máa ń ṣe fún wa lásìkò tá à ń kojú àdánwò. Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí àdánwò tó lè dé bá wa tí Jèhófà máa fi wá sílẹ̀ tá a bá ṣáà ti gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 55:22) Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀.
Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àwọn àdánwò tá à ń kojú jẹ́ èyí tó “wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn.” Ìyẹn ni pé, àdánwò tó ń dé bá ọ̀pọ̀ èèyàn làwa náà ń kojú. Irú àwọn àdánwò tó wọ́pọ̀ yìí kì í ṣe èyí tá ò lè borí, àmọ́ a gbọ́dọ̀ gbára lé Ọlọ́run. (1 Pét. 5:8, 9) Kí Pọ́ọ̀lù tó sọ ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, ó ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ìdẹwò tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù. (1 Kọ́r. 10:6-11) Ìdẹwò tó wọ́pọ̀ fáwa èèyàn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà kojú nínú aginjù, kò sì ṣòro fáwọn olóòótọ́ lára wọn láti borí àwọn ìdẹwò náà. Àmọ́, ó yani lẹ́nu pé ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn kan nínú wọn” ṣàìgbọràn. Ó mà ṣe o, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè torí pé wọn ò gbára lé Ọlọ́run.
Ìdí kejì ni pé, “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́.” Àkọsílẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ látọdúnmọ́dún jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń fìfẹ́ dúró ti “àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Diu. 7:9) Àkọsílẹ̀ yẹn tún fi hàn pé ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Torí pé Jèhófà jẹ́ olóòótọ́, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè fọkàn tán ìlérí tó ṣe. Ohun méjì ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa tí àdánwò bá dé bá wa: (1) Kò ní jẹ́ kí àdánwò náà le débi pé a ò ní lè fara dà á, àti pé (2) “yóò . . . ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa.
Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe ọ̀nà àbájáde fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà ìṣòro? Ohun kan ni pé ó lè mú ìṣòro tàbí àdánwò kúrò tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ká rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, Jèhófà “yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń ṣe “ọ̀nà àbájáde” ní ti pé ó máa ń pèsè ohun tá a nílò ká lè fara da àdánwò náà láìbọ́hùn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mélòó kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀:
▪ Ó máa “ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:3, 4) Jèhófà máa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè láti mú kí ọkàn wa balẹ̀, kára sì tù wá.—Mát. 24:45; Jòh. 14:16; Róòmù 15:4.
▪ Ó lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa. (Jòh. 14:26) Nígbà ìṣòro, ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká rántí àwọn àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì tàbí àwọn ìlànà kan táá jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
▪ Ó lè lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́.—Héb. 1:14.
▪ Ó lè lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wa tàbí kí wọ́n ṣe ohun táá fún wa lókun.—Kól. 4:11.
Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, kí wá lohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13? Jèhófà kì í yan àwọn àdánwò tó máa dé bá wa. Àmọ́ tí ìṣòro tàbí àdánwò bá dé bá wa, ohun tó dájú ni pé: Tá a bá gbára lé Jèhófà pátápátá, kò ní jẹ́ kí àdánwò náà kọjá agbára wa. Yàtọ̀ síyẹn, yóò ṣe ọ̀nà àbájáde fún wa ká lè fara dà á. Ẹ ò rí i pé èyí fini lọ́kàn balẹ̀!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí 1 Kọ́ríńtì 10:8 fi sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ṣubú lọ́jọ́ kan ṣoṣo nígbà tí Númérì 25:9 sọ pé ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì [24,000] ni?
Onírúurú nǹkan ló lè fa ìyàtọ̀ nínú iye tí ẹsẹ Bíbélì méjèèjì yìí sọ. Àlàyé kan tó rọrùn jù lọ nípa rẹ̀ ni pé, ó lè jẹ́ pé iye tó jẹ́ gan-an bọ́ sáàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] àti ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì [24,000], tó fi jẹ́ pé a lè kúkú pè é ní ọ̀kan nínú ọ̀nà méjèèjì.
Tún wo àlàyé mìíràn tó ṣeé ṣe kó jẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Ṣítímù láti fi ṣe ìkìlọ̀ fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì, tó jẹ́ ìlú kan táwọn èèyàn mọ̀ mọ́ ìwàkiwà. Ó kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” Àwọn tí Jèhófà pa nítorí híhu ìwà àgbèrè nìkan ni Pọ́ọ̀lù kàn tọ́ka sí, ó ní wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún.—1 Kọ́ríńtì 10:8.
Àmọ́ ní ti Númérì orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó sọ fún wa pé: “Bí Ísírẹ́lì ṣe so ara rẹ̀ mọ́ Báálì ti Péórù nìyẹn; ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí Ísírẹ́lì.” Ìyẹn ni Jèhófà fi pàṣẹ pé kí Mósè pa “gbogbo àwọn olórí nínú àwọn ènìyàn náà.” Mósè wá pàṣẹ pé kí àwọn onídàájọ́ ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. Níkẹyìn, nígbà tí Fíníhásì gbéra tó sì pa ọmọ Ísírẹ́lì tó mú ọmọbìnrin Mídíánì wá sínú ibùdó, “òjòjò àrànkálẹ̀ náà dáwọ́ dúró.” Gbólóhùn tó parí ìtàn náà ni: “Àwọn tí ó sì kú nínú òjòjò àrànkálẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì.”—Númérì 25:1-9.
Ẹ̀rí fi hàn pé àti “àwọn olórí nínú àwọn ènìyàn náà” táwọn onídàájọ́ pa àtàwọn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pa ló pa pọ̀ jẹ́ iye tí ìwé Númérì sọ yìí. Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn olórí táwọn onídàájọ́ pa tó ẹgbẹ̀rún, tí àròpọ̀ àwọn tó kú fi jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì. Yálà àwọn olórí tàbí baba ìsàlẹ̀ wọ̀nyí ṣàgbèrè ni o, tàbí wọ́n kópa nínú ayẹyẹ wọn, tàbí wọ́n fọwọ́ sí àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ o, wọ́n ṣáà jẹ̀bi ẹ̀sùn níní “ìsopọ̀ pẹ̀lú Báálì Péórù.”
Ìwé kan tó ṣàlàyé lórí Bíbélì sọ pé gbólóhùn náà, “ní ìsopọ̀ pẹ̀lú,” tí a lò níhìn-ín lè túmọ̀ sí “kéèyàn so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹnì kan.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ àwọn tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ “ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Báálì Péórù,” wọ́n ba ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run jẹ́. Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà gbẹnu wòlíì Hóséà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Àwọn fúnra wọn wọlé tọ Báálì ti Péórù, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tí ń tini lójú, wọ́n sì wá di ìríra bí ohun ìfẹ́ wọn.” (Hóséà 9:10) Ìdájọ́ Ọlọ́run tọ́ sáwọn tó dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò lóòótọ́. Ìyẹn ni Mósè ṣe rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Ojú ẹ̀yin fúnra yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀ràn Báálì ti Péórù, pé olúkúlùkù ọkùnrin tí ó rìn tọ Báálì ti Péórù lẹ́yìn ni ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa rẹ́ ráúráú kúrò ní àárín rẹ.”—Diutarónómì 4:3.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ó yẹ kí arábìnrin kan borí rẹ̀ tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí arákùnrin wà?
▪ Nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, a sọ lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” pé ó yẹ kí arábìnrin borí rẹ̀ tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi ti ọkùnrin tí ó jẹ́ akéde wà, yálà ọkùnrin náà ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì ṣèrìbọmi. Nígbà tí a tún gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò dáadáa, a rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe sí ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀.
Tí arábìnrin kan bá lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì jẹ́ pé akéde tó ti ṣèrìbọmi ni ọkùnrin tí wọ́n jọ lọ, ó yẹ kí arábìnrin náà borí rẹ̀. Á fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Jèhófà gbé kalẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, torí pé ohun tó yẹ kí arákùnrin ṣe ló ń ṣe yẹn. (1 Kọ́r. 11:5, 6, 10) Tí arábìnrin náà bá sì fẹ́, ó lè ní kí arákùnrin tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó bá kúnjú ìwọ̀n láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì lè ṣe é.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tí ọkùnrin tó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi bá tẹ̀ lé arábìnrin kan lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí arákùnrin náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀, tí kò bá borí ní irú ipò yìí kò lòdì sí Ìwé Mímọ́. Àmọ́, àwọn arábìnrin kan lè wò ó pé ẹ̀rí ọkàn àwọn ò gbé e pé káwọn má borí kódà bí ọkùnrin tó tẹ̀ lé àwọn ò tiẹ̀ tíì ṣèrìbọmi, torí náà tí wọ́n bá fẹ́ wọ́n lè borí.
Bíbélì Kíkà
APRIL 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 14-16
Ọlọ́run Máa Di “Ohun Gbogbo fún Kálukú”
“Ikú Ni A Ó Sọ Di Asán”
10 “Òpin” náà ni òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí Jésù yóò fi Ìjọba náà lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdúróṣinṣin. (Ìṣípayá 20:4) Ète Ọlọ́run “láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi” ni a ó ti mú ṣẹ. (Éfésù 1:9, 10) Àmọ́ ṣá o, Kristi yóò ti kọ́kọ́ run “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára” tí ó tako ìfẹ́ Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ. Èyí kọjá ìparun tí yóò wáyé ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:16; 19:11-21) Pọ́ọ̀lù wí pé: “[Kristi] gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:25, 26) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ohun tí ó tan mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú Ádámù ni a óò ti mú kúrò. Ó dájú pé nígbà yẹn, Ọlọ́run yóò ti sọ “ibojì ìrántí” dòfìfo nípa mímú àwọn òkú padà bọ̀ sí ìyè.—Jòhánù 5:28.
Ìjọba Náà Mú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ ní Ayé
21 Ṣùgbọ́n ohun tí àìsàn sábà máa ń yọrí sí ńkọ́, tó jẹ́ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ fà, ìyẹn ikú? Òun náà ni “ọ̀tá ìkẹyìn,” ọ̀tá kan tó jẹ́ pé ó máa ń ṣá gbogbo èèyàn aláìpé balẹ̀ bópẹ́ bóyá. (1 Kọ́r. 15:26) Ṣùgbọ́n, ṣé ikú wá ju ohun tí Jèhófà lè borí? Wo àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ, ó ní: “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Ǹjẹ́ o lè fojú inú rí bí ìgbà yẹn ṣe máa rí? Kò ní sí ètò ìsìnkú, itẹ́ òkú àti ẹkún ìbànújẹ́ mọ́ rárá! Kàkà bẹ́ẹ̀, omijé ayọ̀ la ó máa rí bí Jèhófà ṣe ń jí àwọn òkú dìde ní ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ tó mórí ẹni yá gágá! (Ka Aísáyà 26:19.) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, àìmọye ọgbẹ́ oró tí ikú ti dá yóò sàn pátá.
Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!
17 Kò sí ọ̀rọ̀ míì tá a tún lè fi ṣàpèjúwe ohun tó jẹ́ òpin ológo náà ju pé “kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ẹ jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì nígbà tí Ádámù àti Éfà jẹ́ ẹni pípé tí wọ́n sì jẹ́ ara ìdílé alálàáfíà ti Jèhófà tó wà ní ìṣọ̀kan. Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run ló ń ṣàkóso àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní tààràtà, ìyẹn àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. Wọ́n láǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀ ní tààràtà, wọ́n lè sìn ín, wọ́n sì lè rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Ó jẹ́ “ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w12 9/1 9, àpótí
Ṣé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù Kà Á Léèwọ̀ fún Àwọn Obìnrin Láti Sọ̀rọ̀ Ni?
“Nínú Bíbélì àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú àwọn ìjọ.” (1 Kọ́ríńtì 14:34) Kí ló ní lọ́kàn? Ṣé ó wá kà wọ́n sí ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní làákàyè ni? Rárá o. Ńṣe ló tiẹ̀ sábà máa ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tí àwọn obìnrin ń kọ́ni. (2 Tímótì 1:5; Títù 2:3-5) Àwọn obìnrin nìkan kọ́ ni Pọ́ọ̀lù sì fún ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nínú ìwé tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ fún àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn sísọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì náà pé kí wọ́n “dákẹ́” nígbà tí onígbàgbọ́ míì bá ń sọ̀rọ̀. (1 Kọ́ríńtì 14:26-30, 33) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn obìnrin kan wà to ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni, tí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ yìí sì ń gùn wọ́n, débi pé wọ́n ń já lu ọ̀rọ̀ ẹni tó ń sọ àsọyé lọ́wọ́ láti béèrè àwọn ìbéèrè, èyí tó jẹ́ àṣà wọn nígbà yẹn ní ilẹ̀ Gíríìsì. Kí irú nǹkan rúdurùdu bẹ́ẹ̀ má bàa wáyé ni Pọ́ọ̀lù ṣe gba àwọn obìnrin níyànjú pé kí wọ́n “bi àwọn ọkọ tiwọn léèrè ní ilé.”—1 Kọ́ríńtì 14:35.
it-1 1197-1198
Àìdíbàjẹ́
Àwọn tó máa jọba pẹ̀lú Kristi máa ní irú àjíǹde kan náà tí Jésù ní, kì í ṣe pé wọ́n kàn máa ní ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n sì máa di ẹ̀dá ẹ̀mí nìkan, wọ́n tún máa ní àìkú àti àìdíbàjẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n sì kú nínú ẹran ara tó máa ń díbàjẹ́, wọ́n máa gba ara tó jẹ́ ti ẹ̀mí, èyí tí kò lè díbàjẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 15:42-54. Torí náà, ẹ̀rí fi hàn pé àìkú tí wọ́n ní yìí ń tọ́ka sí irú ìgbé ayé tí wọ́n ń gbádùn, ní ti pé kò lè dópin láé, kò sì lè pa run. Ó sì tún ṣe kedere pé àìdíbàjẹ́ ń tọ́ka sí irú ara tí Ọlọ́run fún wọn, irú èyí tí kò lè bà jẹ́, tí kò lè pa run tàbí jẹrà lọ́nàkọnà. Torí náà, ó jọ pé ńṣe ni Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa wà láàyè lọ láìgbára lé ohunkóhun tó lè fún wọn lágbára bíi tàwọn ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù. Ẹ̀rí yìí fi hàn pé Ọlọ́run fọkàn tán wọn, èyí sì wú wa lórí gan-an. Lóòótọ́, wọn ò gbára lé ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun láti máa wà láàyè, àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò lágbára lórí wọn mọ́. Bíi ti Kristi Jésù tó jẹ́ Orí wọn, wọ́n ń fi ara wọn sábẹ́ ìdarí Baba wọn, wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—1Kọ 15:23-28; wo àìkú; ọkàn.
Bíbélì Kíkà
APRIL 29–MAY 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 1-3
“Jèhófà—‘Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo’ ”
‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
4 Jèhófà, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Ó ṣe tán, òun náà ti pàdánù àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́, àwọn bí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, Mósè àti Ọba Dáfídì. (Núm. 12:6-8; Mát. 22:31, 32; Ìṣe 13:22) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó dá wa lójú pé taratara ni Jèhófà fi ń retí ìgbà tó máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde. (Jóòbù 14:14, 15) Nígbà tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á láyọ̀, wọ́n á sì ní ìlera tó jí pépé. Yàtọ̀ síyẹn, “ẹni tí [Ọlọ́run] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe,” ìyẹn Jésù Ọmọ rẹ̀ náà kú ikú oró. (Òwe 8:22, 30) Kò sí bá a ṣe lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe máa dun Jèhófà tó.—Jòhánù 5:20; 10:17.
‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
14 Ká sòótọ́, a lè má mọ ohun tá a máa sọ fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé “ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ọ̀pọ̀ máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú ìwé Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. Àmọ́ o, ohun tó dáa jù ni pé ká “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Arábìnrin Gaby tí ọkọ rẹ̀ kú sọ pé: “Ṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu. Àmọ́ ara máa ń tù mí táwọn ọ̀rẹ́ mi bá wá kí mi táwọn náà sì ń sunkún. Bí wọ́n ṣe ń sunkún yẹn máa ń mú kí n gbà pé mi ò dá nìkan ṣọ̀fọ̀.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w16.04-E 32
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “àmì ìdánilójú” àti “èdìdì” tí àwọn ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run?—2 Kọ́r. 1:21, 22; àlàyé ìsàlẹ̀
▪ Àmì ìdánilójú: Ìwé ìwádìí kan sọ pé, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àmì ìdánilójú” nínú 2 Kọ́ríńtì 1:22 jẹ́ “ọ̀rọ̀ òfin àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò níbi ìṣòwò” tó túmọ̀ sí “owó téèyàn kọ́kọ́ san, àsansílẹ̀, ẹ̀jẹ́, èyí tí ẹnì kan máa ń san ṣáájú, ó kàn wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára owó nǹkan tó fẹ́ rà, tó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ de ohun tó fẹ́ rà yẹn mọ́lẹ̀ tàbí kó fi ìdí àdéhùn kan múlẹ̀.” Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ san fún wọn tàbí èrè tí Ọlọ́run máa fún wọn wà nínú 2 Kọ́ríńtì 5:1-5, ìyẹn ni pé wọ́n máa gba ara tó jẹ́ ẹ̀mí, tí kò lè díbàjẹ́ ní ọ̀run. Wọ́n tún máa gba ẹ̀bùn àìleèkú.—1 Kọ́r. 15:48-54.
Nínú èdè Gíríìkì òde òní, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ tó jọ èyí fún òrùka ìgbéyàwó. Torí náà, àpèjúwe yìí bá a mu fún àwọn tó máa di ìyàwó Kristi lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—2 Kọ́r. 11:2; Ìfi. 21:2, 9.
▪ Èdìdì: Láyé àtijọ́, wọ́n máa ń fi èdìdì mọ ẹni tó ni nǹkan, wọ́n máa ń fi mọ ohun tó jẹ́ ojúlówó tàbí kí wọ́n fi de àdéhùn táwọn kan ṣe. Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, ẹ̀mí mímọ́ ti gbé “èdìdì” lé wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n sì ti di ohun ìní Ọlọ́run. (Éfé. 1:13, 14) Àmọ́, èdìdì yìí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n pátápátá, tó bá kù díẹ̀ kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ tàbí kí wọ́n tó kú ni Jèhófà máa fún wọn ní èdìdì ìkẹyìn.—Éfé. 4:30; Ìfi. 7:2-4.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa “ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun”?
▪ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run . . . ń ṣamọ̀nà wa . . . nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tí ó sì ń mú kí a tipasẹ̀ wa gbọ́ òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ní ibi gbogbo! Nítorí fún Ọlọ́run, àwa jẹ́ òórùn dídùn Kristi láàárín àwọn tí a ń gbà là àti láàárín àwọn tí ń ṣègbé; fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òórùn tí ń jáde láti inú ikú sí ikú, fún àwọn ti ìṣáájú òórùn tí ń jáde láti inú ìyè sí ìyè.”—2 Kọ́ríńtì 2:14-16.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ayẹyẹ táwọn ará Róòmù máa ń ṣe láti ṣàyẹ́sí ọ̀gágun kan fún àṣeyọrí rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè wọn. Lákòókò ayẹyẹ yìí, wọ́n máa ń ṣàfihàn àwọn ohun tí wọ́n kó ti ogun bọ̀ àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n, àwọn akọ màlúù tí wọ́n máa fi rúbọ náà máa ń wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn á máa yin ọ̀gágun náà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Lẹ́yìn àfihàn yìí, wọ́n á wá fi àwọn akọ màlúù náà rúbọ, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.
Ìwé The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé, àfiwé nípa “òórùn dídùn Kristi” tó ń ṣàpẹẹrẹ ìyè fún àwọn kan àti ikú fún àwọn míì yìí “ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti inú bí àwọn ará Róòmù ṣe máa ń fi ohun olóòórùn rúbọ nígbà ìtọ́wọ̀ọ́rìn ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá.” “Òórùn dídùn tó ń ṣàpẹẹrẹ àṣeyọrí aṣẹ́gun náà ń rán àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú náà létí ikú tó ṣeé ṣe kó máa dúró dè wọ́n.”
Bíbélì Kíkà