Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Léfítíkù
KÒ tíì pé ọdún kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn àwọn ará Íjíbítì. Ọlọ́run sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè tuntun kan, ilẹ̀ Kénáánì ni wọ́n sì forí lé. Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí òun tẹ orílẹ̀-èdè mímọ́ kan dó sórí ilẹ̀ náà. Àmọ́, ìgbésí ayé tí àwọn ọmọ Kénáánì ń gbé burú jáì, ìjọsìn wọn ò sì sunwọ̀n rárá. Nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìlànà tó máa yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìjọsìn rẹ̀. Inú ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ Léfítíkù làwọn ìlànà náà wà. Ó jọ pé ọdún 1512 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wòlíì Mósè kọ ìwé náà ní aginjù Sínáì, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ láàárín oṣù òṣùpá kan ṣoṣo ni ìwé náà pìtàn rẹ̀. (Ẹ́kísódù 40:17; Númérì 1:1-3) Gbọnmọ-gbọnmọ ni Jèhófà sọ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ mímọ́.—Léfítíkù 11:44; 19:2; 20:7, 26.
Àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà lóde òní kò sí lábẹ́ Òfin tí Ọlọ́run tipa Mósè fi fúnni. Ikú Jésù Kristi ti wọ́gi lé Òfin yẹn. (Róòmù 6:14; Éfésù 2:11-16) Àmọ́ ṣá o, àwọn ìlànà tó wà nínú ìwé Léfítíkù lè ṣe wá láǹfààní, a sì lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run wa látinú rẹ̀.
ỌRẸ ẸBỌ MÍMỌ́—ÀWỌN KAN JẸ́ ÀTINÚWÁ, ÒMÍRÀN JẸ́ Ọ̀RANYÀN
Àwọn kan lára ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ rírú tí Òfin là kalẹ̀ jẹ́ àtinúwá, àwọn mìíràn sì jẹ́ ọ̀ranyàn. Bí àpẹẹrẹ, àtinúwá ni ọrẹ ẹbọ sísun. Wọ́n máa ń gbé ẹbọ náà fún Ọlọ́run lódindi ni, àní gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe fi odindi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ tinútinú gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. Ńṣe ni wọ́n máa ń pín ẹbọ ìdàpọ̀ tó jẹ́ àtinúwá. Wọ́n á fún Ọlọ́run lára rẹ̀ lórí pẹpẹ, àlùfáà á jẹ nínú rẹ̀, ẹni tó sì mú ẹbọ náà wá yóò jẹ ńbẹ̀. Bákan náà, ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, oúnjẹ àjọjẹ ni Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 10:16-22.
Ọ̀ranyàn ni ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi. Wọ́n máa ń fi ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá. Ní ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, wọ́n fi ń ṣe ètùtù sí Ọlọ́run nígbà tẹ́nì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tàbí kí wọ́n fi dá ẹ̀tọ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ tó sì ti ronú pìwà dà padà, tàbí kí á lò ó lọ́nà méjèèjì. Wọ́n tún máa ń rú ọrẹ ẹbọ ọkà láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń pèsè fún wọn. A nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí nítorí pé àwọn ẹbọ tí májẹ̀mú Òfin náà là kalẹ̀ ń tọ́ka sí Jésù Kristi àti ẹbọ rẹ̀, ó tún ń tọ́ka sáwọn àǹfààní tá à ń rí látinú ẹbọ náà.—Hébérù 8:3-6; 9:9-14; 10:5-10.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
2:11, 12—Kí nìdí tí Jèhófà kò fi tẹ́wọ́ gba oyin “gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun”? Kò lè jẹ́ oyin látinú afárá ni ẹsẹ yìí ń sọ o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba oyin tí ẹsẹ yìí ń sọ “gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun,” oyin náà ṣì wà lára “àkọ́so . . . gbogbo èso pápá.” (2 Kíróníkà 31:5) Ó ní láti jẹ́ pé oje tàbí omi èso ni oyin yìí. Níwọ̀n bí irú oyin yìí ti máa ń kan, Ọlọ́run ò gbà kí wọ́n fi rú ọrẹ ẹbọ lórí pẹpẹ.
2:13—Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ fi iyọ̀ sí “gbogbo ọrẹ ẹbọ”? Kì í ṣe láti lè mú kó ládùn ni wọ́n ṣe ń fi iyọ̀ sí i. Káàkiri ayé làwọn èèyàn ti má ń fi iyọ̀ sí nǹkan kó má bàa tètè bà jẹ́. Nítorí náà, ó lè jẹ́ nítorí tí iyọ̀ dúró fún nǹkan tí kì í bà jẹ́ àti nǹkan tí kì í jẹrà ni wọ́n ṣe máa ń fi sí ọrẹ ẹbọ.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
3:17. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rá la kà sí apá tó dára jù lára ẹran, sísọ tá á sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ́ yóò máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé Jèhófà ló ni apá tó dára jù yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 45:18) Èyí rán àwa náà létí pé gbogbo ọkàn ló yẹ ká máa fi sin Jèhófà.—Òwe 3:9, 10; Kólósè 3:23, 24.
7:26, 27. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Lójú Ọlọ́run, ẹ̀jẹ̀ dúró fún ìwàláàyè. Léfítíkù 17:11 sọ pé: “Ọkàn [ìwàláàyè] ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀.” Bákan náà lónìí, àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ ta kété sí ẹ̀jẹ̀.—Ìṣe 15:28, 29.
A DÁ ẸGBẸ́ ÀLÙFÁÀ MÍMỌ́ SÍLẸ̀
Àwọn wo ló ni ojúṣe láti máa bójú tó àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ rírú ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ? Àwọn àlùfáà la gbé iṣẹ́ náà fún. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kó fi Áárónì jẹ àlùfáà àgbà, kó sì fi àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rin jẹ àlùfáà lábẹ́ bàbá wọn. Odindi ọjọ́ méje gbáko ni wọ́n fi ṣe ètò ìfinijoyè náà, ẹgbẹ́ àlùfáà náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
9:9—Kí ni ìjẹ́pàtàkì dída ẹ̀jẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ àti fífi í sára onírúurú nǹkan? Èyí fi hàn pé Jèhófà fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa fi ẹ̀jẹ̀ ṣe ètùtù. Ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo ètùtù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé.”—Hébérù 9:22.
10:1, 2—Kí ló ṣeé ṣe kó wé mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Nádábù àti Ábíhù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áárónì? Kò pẹ́ sígbà tí Nádábù àti Ábíhù hùwà tí kò tọ́ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà tí wọ́n ń ṣe ni Jèhófà ṣòfin pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani nígbà tó bá ń ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìjọsìn. (Léfítíkù 10:9) Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọtí làwọn ọmọ Áárónì méjèèjì mu yó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì ròyìn yìí. Àmọ́, ohun tó fa ikú wọn gan-an ni rírú tí wọ́n lọ “rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu níwájú Jèhófà, èyí tí òun kò lànà rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.”
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
10:1, 2. Lónìí, àwọn tó ń mú ipò iwájú lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Síwájú sí i, wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá àyè wọn bí wọ́n ṣe ń bójú tó ẹrú iṣẹ́ wọn.
10:9. A ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ nígbà tí a bá mutí.
ÌJỌSÌN MÍMỌ́ Ń FẸ́ PÉ KÍ Á WÀ NÍ MÍMỌ́ TÓNÍTÓNÍ
Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn òfin tá a là kalẹ̀ nípa ẹranko tó mọ́ àtèyí tí kò mọ́ gbà ṣàǹfààní fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Títẹ̀lé àwọn òfin náà kò ní jẹ́ kí wọ́n kó èèràn kòkòrò àrùn, yóò sì túbọ̀ mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó wà làwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n. Àwọn òfin yòókù sọ nípa ẹni tó bá tipa òkú ẹran tàbí ti ènìyàn di aláìmọ́, ìwẹ̀mọ́ àwọn obìnrin lẹ́yìn ọmọ bíbí, àwọn ìlànà tó jẹ mọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ àti jíjẹ́ aláìmọ́ nítorí ohun tó jáde látinú ẹ̀yà ìbímọ ọkùnrin àti obìnrin. Àwọn àlùfáà ló máa ń bójú tó ọ̀ràn àwọn tó bá di aláìmọ́.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
12:2, 5—Kí nìdí tọ́mọ bíbí fi sọ àwọn obìnrin di “aláìmọ́”? Ọlọ́run dá ẹ̀yà ìbímọ ènìyàn kí á lè fi mú ẹ̀dá ènìyàn pípé wá sáyé. Àmọ́ nítorí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún, àìpé òun ẹ̀ṣẹ̀ là ń bí mọ́ àwọn ọmọ. Àkókò ráńpẹ́ tí wọ́n fi jẹ́ “aláìmọ́” nígbà ìbímọ àti nítorí àwọn nǹkan mìíràn, irú bíi nǹkan oṣù àti dída àtọ̀ máa ń jẹ́ kí wọ́n rántí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún. (Léfítíkù 15:16-24; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Òfin tá a fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìwẹ̀mọ́ yóò jẹ́ kí wọ́n lóye ìdí tí wọ́n fi nílò ẹbọ ìràpadà láti fi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé àti láti sọ aráyé di pípé. Nítorí èyí, Òfin náà di “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ [wọn] tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—Gálátíà 3:24.
15:16-18—Kí ni ‘dída àtọ̀’ tí àwọn ẹsẹ yìí ń sọ? Ó jọ pé dída àtọ̀ lójú oorun àti ìbálòpọ̀ láàárín ọkọ àti aya ni.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
11:45. Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ó sì sọ pé káwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí òun jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú. Wọ́n ní láti jẹ́ mímọ́, kí wọ́n sì máa bá a lọ láti wà ní mímọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—2 Kọ́ríńtì 7:1; 1 Pétérù 1:15, 16.
12:8. Jèhófà jẹ́ kí àwọn tálákà fi ẹyẹ rú ọrẹ ẹbọ dípò àgùntàn tí ó wọ́nwó. Ó gba tàwọn tálákà rò.
A GBỌ́DỌ̀ JẸ́ MÍMỌ́
Ọjọ́ Ètùtù ni wọ́n máa ń rú ẹbọ tó ṣe pàtàkì jù. Wọ́n á fi akọ màlúù kan rúbọ fún àwọn àlùfáà àti ẹ̀yà Léfì. Wọ́n á fi ewúrẹ́ kan rúbọ fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí kì í ṣe iṣẹ́ àlùfáà. Wọ́n á wá rán ewúrẹ́ mìíràn lọ sínú aginjù lóòyẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn lé e lórí tán. Ọrẹ ẹbọ kan ṣoṣo ni wọ́n ka ewúrẹ́ méjèèjì yìí sí. Gbogbo èyí fi hàn pé a óò fi Jésù Kristi rúbọ, àti pé yóò ko ẹ̀ṣẹ̀ lọ.
Àwọn òfin nípa ẹran jíjẹ àtàwọn ọ̀ràn mìíràn jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ mímọ́ nígbà tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà. Ìdí nìyẹn táwọn àlùfáà fi ní láti jẹ́ mímọ́. Àjọ̀dún mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó máa ń wáyé lọ́dọọdún jẹ́ àkókò láti yọ ayọ̀ ńlá àti láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá. Jèhófà tún fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òfin nípa ẹni tí kò bá fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀, pípa Sábáàtì àti Júbílì mọ́ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà sáwọn tálákà àtàwọn ẹrú. A sọ ìbùkún tí wọn yóò rí gbà tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run, a sì sọ ègún tó máa wá sórí wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. Òfin tún sọ nípa ọrẹ tí wọ́n máa mú wá tó bá kan ọ̀ràn ẹ̀jẹ́ àti ìdíyelé, àkọ́bí àwọn ẹran àti sísan ìdámẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí “ohun mímọ́ lójú Jèhófà.”
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
16:29—Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbà ‘ṣẹ́ ọkàn wọn níṣẹ̀ẹ́’? Ìlànà tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé ní Ọjọ́ Ètùtù yìí ní í ṣe pẹ̀lú títọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé gbígbààwẹ̀ lọ́jọ́ náà wé mọ́ gbígbà pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ààwẹ̀ gbígbà ni ọ̀rọ̀ náà ‘ṣíṣẹ́ ọkàn níṣẹ̀ẹ́’ ń tọ́ka sí.
19:27—Kí ni àṣẹ pé kí wọ́n má ṣe ‘gé kànnàǹgó kúrú’ tàbí ‘ba ìpẹ̀kun irùngbọ̀n jẹ́’ túmọ̀ sí? A fún àwọn Júù ní òfin yìí kí wọ́n máa bàa máa gé irùngbọ̀n wọn tàbí irun wọn bíi ti àwọn kèfèrí kan. (Jeremáyà 9:25, 26; 25:23; 49:32) Àmọ́, òfin tí Ọlọ́run fún àwọn Júù kò túmọ̀ sí pé wọ́n ò gbọ́dọ̀ gé irùgbọ̀n wọn tàbí irun wọn rárá o.—2 Sámúẹ́lì 19:24.
25:35-37—Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ gba èlé rárá ni? Tó bá jẹ́ pé okòwò lẹni tó yáwó fẹ́ fowó ọ̀hún ṣe, ẹni tó yá a lówó lè gba èlé. Àmọ́, Òfin sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba èlé lórí owó tẹ́nì kan yá láti fi gbọ́ tara rẹ̀ nítorí pé kò lówó lọ́wọ́. Kò tọ̀nà kí ẹnì kan máa jèrè lára ọmọnìkejì rẹ̀ tó di ẹdun arinlẹ̀ nítorí pé nǹkan ò lọ déédéé fún un mọ́.—Ẹ́kísódù 22:25.
26:19—Báwo ni ‘ojú ọ̀run ṣe lè dá bí irin, kí ilẹ̀ sì dà bí bàbà’? Nítorí ọ̀dá, ńṣe ni ìrísí ojú ọ̀run tó bo ilẹ̀ Kénáánì yóò le bí irin, tí kò níhò kankan. Láìsí òjò, ilẹ̀ yóò ní àwọ̀ bàbà, tó ń dán bí ìrìn.
26:26—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà, ‘obìnrin mẹ́wàá yóò yan búrẹ́dì nínú ààrò kan’? Bó ṣe yẹ kó rí ni pé kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ààrò tiẹ̀ lọ́tọ̀ tó ti máa yan gbogbo búrẹ́dì tó bá fẹ́ yan. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tọ́ka sí ìyàn tó máa mú débi pé ààrò kan ṣoṣo yóò tóó yan gbogbo búrẹ́dì tí obìnrin mẹ́wàá bá fẹ́ yan. Ọ̀kan lára ohun tá a ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ nìyẹn tí wọ́n ò bá wà ní mímọ́.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
20:9. Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn apààyàn ló fi ń wo ẹni tó ń kórìíra ọmọnìkejì rẹ̀ títí kan ẹni tó máa ń hùwà ipá. Nítorí èyí, Ọlọ́run sọ pé ìyà tá a máa fi jẹ ẹni tó bá pa òbí ẹ̀ la ó fi jẹ́ ẹni tó bá ń kẹ́gàn òbí rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí sún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?—1 Jòhánù 3:14, 15.
22:32; 24:10-16, 23. A ò gbọ́dọ̀ kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ ká máa yin orúkọ rẹ̀, ká sì máa gbàdúrà fún ìsọdimímọ́ orúkọ náà.—Sáàmù 7:17; Mátíù 6:9.
BÍ ÌWÉ LÉFÍTÍKÙ ṢE KAN ÌJỌSÌN WA
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sí lábẹ́ Òfin Mósè lónìí. (Gálátíà 3:23-25) Àmọ́ níwọ̀n bí ìwé Léfítíkù ti jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà nípa onírúurú nǹkan, ó kan ìjọsìn wa.
Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a yàn fún kíkà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti múra sílẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó dájú pé inú rẹ yóò dùn láti rí i pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun jẹ́ mímọ́. Ìwé Bíbélì yìí tún lè mú kó o fi gbogbo agbára àti òye rẹ sin Ẹni Gíga Jù Lọ náà, kí ó sì máa bá a lọ láti wà ní mímọ́ fún ògo rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn ẹbọ tí májẹ̀mú Òfin là kalẹ̀ ń tọ́ka sí Jésù Kristi àti ẹbọ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àjọyọ̀ àwọn Àkàrà Aláìwú jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àjọyọ̀ ọdọọdún, irú bi Àjọyọ̀ Àtíbàbà jẹ́ àkókò láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà