Máa Fi Ìgbatẹnirò Hàn fún Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ
ṢÀṢÀ ni àwọn èèyàn tó ń lo àkókò àti okun tó pọ̀ tó ti àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ. Ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ pọ̀ gan-an. Wọ́n ní láti bójú tó ìdílé wọn, ìyẹn sì ní ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú. Yàtọ̀ sí kí wọ́n ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, wọ́n tún ní láti lọ ra nǹkan lọ́jà, gbọ́únjẹ, ṣe ìmọ́tótó ilé, kí wọ́n sì tọ́ ọmọ. Wọ́n tún ní láti bójú tó ọ̀ràn ìlera, kí wọ́n ṣeré ìnàjú, kí wọ́n sì bójú tó ohun tó ń jẹ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn, tó bá sì ṣeé ṣe, kí àwọn náà wá àyè láti gbọ́ ti ara wọn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tó ń da tọ́mọ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láwùjọ wa lóde òní, síbẹ̀ èèyàn lè má fiyè sí wọn. Ìyá kan sọ pé bí ọ̀ràn ṣe rí nìyẹn, ó ní, “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá tọ́mọ ni mo tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ.” Kí lo lè ṣe láti fi hàn pé ò ń fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ? Ṣé ó yẹ kó o bìkítà nípa wọn? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìdí mẹ́ta tó fi yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ìdí Tó Fi Yẹ Kéèyàn Gba Tiwọn Rò
Ọ̀pọ̀ òbí tó ń dá tọ́mọ ló nílò ìrànlọ́wọ́. Opó kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì [41] tó ní ọmọ méjì sọ pé, “Ìgbà míì wà tí mi ò kí ń mọ ohun tí ǹ bá ṣe, ojúṣe mi ti pọ̀ jù.” Ipò àìbáradé tí àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kú máa ń wà, wíwà láìrí ẹni dá sí ọ̀ràn ẹni tàbí àwọn ipò míì tí kò rọgbọ, ti mú kí ọ̀pọ̀ òbí tó ń dá tọ́mọ ní irú èrò tí ìyá kan ní, ó sọ pé: “À ń fẹ́ ohun tó máa mú ìtura bá wa, a sì nílò rẹ̀ lójú méjèèjì!”
Yóò fi kún ayọ̀ rẹ. Ǹjẹ́ o ti ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó gbé ẹrù wíwúwo rí? Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, inú rẹ á dùn pé o ran ẹnì náà lọ́wọ́. Bákan náà, nígbà míì, ẹrù tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ ń gbé lè wúwo jù fún ẹnì kan. Tó o bá ràn wọ́n lọ́wọ́, wàá rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 41:1, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀.”
Ó ń múnú Ọlọ́run dùn. Ìwé Jákọ́bù 1:27 sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.” Èyí kan bíbójú tó àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ.a Ìwé Hébérù 13:16 sọ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”
Lẹ́yìn tá a ti mọ ìdí mẹ́ta tó fi yẹ ká gba ti àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ rò, jẹ́ ká wo ohun tó o lè ṣe láti ṣèrànwọ́ àti bó o ṣe lè rí i dájú pé ìrànlọ́wọ́ náà yóò ṣàǹfààní fún wọn.
Lo Òye Láti Mọ Ohun Tí Wọ́n Nílò
Lójú ẹni, ó lè jọ pé ohun tó dára ni kéèyàn bi òbí tó ń dá tọ́mọ pé, “Ìrànlọ́wọ́ wo ni mo lè ṣe fún ẹ?” Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, èyí kì í sábà mú kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n fẹ́. Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú Sáàmù 41:1, ó dábàá pé “fi ìgbatẹnirò hùwà.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a lò níbí yìí lè túmọ̀ sí “ríronú jinlẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí èèyàn ṣe ohun tó ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíì.”
Nítorí náà, o ní láti ronú jinlẹ̀ lórí ìṣòro tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ ní, kó o bàa lè mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́. Máa fiyè sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, má kàn máa wo nǹkan gààràgà. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Tó bá jẹ́ èmi ni mo wà ní ipò yìí, kí ni máa fẹ́ káwọn èèyàn ṣe fún mi?’ Òótọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ òbí tó ń dá tọ́mọ ló máa sọ fún ẹ pé, kò sí bó o ṣe lè ṣe tó, o kò lè lóye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ, àyàfi tó o bá wà ní ipò náà. Síbẹ̀, ṣíṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti bá wọn kẹ́dùn nítorí ipò tí wọ́n wà, yóò jẹ́ kó o lè fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pípé Ti Ọlọ́run
Tó bá di pé ká bójú tó àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ tìfẹ́tìfẹ́, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n ṣe bíi Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló sọ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe bójú tó àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba tó sì gba tiwọn rò, kò sì yọ àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ sílẹ̀. Tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bójú tó àwọn ẹni rírẹlẹ̀ yìí, a ó kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fún wọn lọ́nà tó ṣàǹfààní. Àwọn ohun mẹ́rin ló wà tá a máa gbé yẹ̀ wò lórí ọ̀ràn yìí.
Wá àyè láti tẹ́tí sí wọn
Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, ó sọ pé “láìkùnà” òun yóò “gbọ́ igbe ẹkún” àwọn aláìní. (Ẹ́kísódù 22:22, 23) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere yìí? Àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ sábà máa ń dá nìkan wà, tí wọn kì í sì í rí àgbàlagbà bíi tiwọn bá sọ̀rọ̀. Màmá kan tó ń dá tọ́mọ kédàárò pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ mi bá ti lọ sùn, ńṣe ni mo máa ń sunkún nígbà míì. Mi ò kì í lè fara da ìdánìkanwà náà nígbà míì.” Tó bá yẹ, ǹjẹ́ o lè wà nítòsí láti “gbọ́ igbe ẹkún” òbí tó ń dá tọ́mọ tó lè fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Tí ọkùnrin tàbí obìnrin bá ń fetí sí òbí tó ń dá tọ́mọ, kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní ipò tí kò ní jẹ́ kí àwọn méjèèjì hùwà pálapàla, èyí yóò sì ran àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro wọn.
Sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn
Jèhófà mí sí ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn orin tàbí sáàmù tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìjọsìn. Fojú inú wo ìṣírí tí àwọn opó àtàwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rí gbà nígbà tí wọ́n bá ń kọrin tí Ọlọ́run mí sí, tó ń rán wọn létí pé Jèhófà jẹ́ “baba” àti “onídàájọ́” fún wọn àti pé ó máa pèsè ìtura fún wọn. (Sáàmù 68:5; 146:9) Àwa náà lè sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ kò ní gbàgbé fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lógún ọdún, tayọ̀tayọ̀ ni Ruth, tó jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ fi máa ń rántí ọ̀rọ̀ kan tí bàbá kan tó ní ìrírí sọ fún un pé: “Mo gbóríyìn fún ẹ gan-an bó o ṣe ń tọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì yìí lọ́nà rere. Máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.” Ruth sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn mú kórí mí wú gan-an.” Ní tòdodo, “ọ̀rọ̀ rere jẹ́ oògùn tó dára” ó sì lè fún àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ níṣìírí gan-an ju bá a ti rò lọ. (Òwe 15:4, Bíbélì Contemporary English Version) Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ohun kan ní pàtó tó o fi lè gbóríyìn látọkànwá fún òbí kan tó ń dá tọ́mọ?
Fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò tó bá yẹ bẹ́ẹ̀
Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, ètò wà fún àwọn opó àtàwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba láti rí oúnjẹ gbà lọ́nà tó ń buyì kúnni. Látinú ìpèsè yìí, àwọn ẹni rírẹlẹ̀ yìí máa ń rí oúnjẹ tí ó tó ‘jẹ, wọ́n sì ń tẹ́ ara wọn lọ́rùn.’ (Diutarónómì 24:19-21; 26:12, 13) Àwa náà lè lo òye láti pèsè ohun táwọn òbí tó ń dá tọ́mọ nílò lọ́nà tó máa buyì kún wọn. Ǹjẹ́ o lè gbé oúnjẹ tàbí àwọn nǹkan ìpápánu lọ sí ilé wọn? Ǹjẹ́ o ní aṣọ tí òbí kan tó ń dá tọ́mọ tàbí ọmọ wọn lè lò? Àbí o lè fowó ṣèrànwọ́ fún òbí tó ń dá tọ́mọ kó lè ra àwọn ohun kan tí ìdílé rẹ̀ nílò?
Bá wọn kẹ́gbẹ́
Jèhófà pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ kí àwọn opó àtàwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba máa wà níbi àjọyọ̀ ọdọọdún ti orílẹ̀-èdè náà, níbi tí wọ́n á ti gbádùn ara wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Kódà, ó sọ fún wọn pé: “Kí [wọ́n] . . . máa yọ̀.” (Diutarónómì 16:10-15) Bákan náà lóde òní, a gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì,” kí wọ́n sì máa wá àyè láti ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìbákẹ́gbẹ́ wọn lárinrin. (1 Pétérù 4:9) O ò ṣe pe òbí kan tó ń dá tọ́mọ àtàwọn ọmọ rẹ̀ wá sílé rẹ láti wá jẹun. Kò pọn dandan pé kó jẹ́ nǹkan tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Lákòókò kan tí Jésù wà nílé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń gbádùn ara wọn, ó sọ pé, “nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò.”—Lúùkù 10:42.
Wọn Yóò Mọrírì Ìgbatẹnirò Tó O Fi Hàn
Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ ni Kathleen, ó ti tọ́ ọmọ mẹ́ta dàgbà, ohun tó sọ ni pé, òun kò lè gbàgbé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó sọ pé, “Má ṣe retí ohunkóhun, àmọ́ mọyì ohun gbogbo.” Ọ̀pọ̀ òbí tó ń dá tọ́mọ bíi Kathleen, ló mọ ojúṣe wọn láti tọ́ àwọn ọmọ wọn fúnra wọn. Nítorí náà, wọn kò retí pé káwọn ẹlòmíì bá wọn ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, kò sí àní-àní pé wọ́n mọyì ohunkóhun téèyàn bá ṣe fún wọn. Wàá fi kún ayọ̀ wọn àti ìdùnnú tìrẹ náà tó o bá ń fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Jèhófà Ọlọ́run “yóò san ẹ́ lẹ́san ohun tó o ti ṣe.”—Òwe 19:17, Bíbélì New Century Version.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà, “òbí tó ń dá tọ́mọ” kò sí nínú Bíbélì, àmọ́ wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “opó” àti “ọmọdékùnrin aláìníbaba” nínú rẹ̀. Èyí fi hàn pé, àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ wọ́pọ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.—Aísáyà 1:17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìgbà wo lo pe òbí kan tó ń dá tọ́mọ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílé rẹ kẹ́yìn láti wá jẹun? O ò ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ láìpẹ́