ORIN 111
Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
1. Bí a ṣe ń rí tí àwọn èèyàn
Tó ń dara pọ̀ mọ́ wa ń pọ̀ sí i,
Látinú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè
Mú káyọ̀ wa pọ̀ púpọ̀ gan-an.
À ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́
Tí à ń kọ́ nínú Bíbélì.
À ń fi àwọn ẹ̀kọ́ yìí sílò;
Èyí ń mú káyọ̀ wa pọ̀ sí i.
Ayọ̀ ti wá kúnnú ọkàn wa,
Ayọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà.
Bí ‘ṣòro àtìpọ́njú bá dé,
Jèhófà yóò fún wa lókun.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa,
Àwọn iṣẹ́ rẹ ń dùn mọ́ wa.
Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi;
Oore àtagbára rẹ pọ̀!
2. Ayọ̀ wa kún bá a ṣe ń ríṣẹ́ rẹ
Lójú ọ̀run, lórí ilẹ̀;
Omi òkun sì lọ salalu,
A fìyìn fún ọ, Jèhófà.
A ti bí Ìjọba Ọlọ́run,
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń mú bọ̀.
À ń wàásù rẹ̀ lọ bí aṣẹ́gun,
À ń fayọ̀ kéde fáráyé.
Ayọ̀ àìlópin wọlé dé tán,
Ìgbà ọ̀tun sì ti dé tán.
Ọ̀run àtayé tuntun yóò mú
Ìdùnnú ayérayé wá.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa,
Àwọn iṣẹ́ rẹ ńdùn mọ́ wa.
Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi;
Oore àtagbára rẹ pọ̀!
(Tún wo Diu. 16:15; Àìsá. 12:6; Jòh. 15:11.)