A4
Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà יהוה, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Bíbélì yìí túmọ̀ lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà sí “Jèhófà.” Òun sì ni orúkọ tó fara hàn jù lọ nínú Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì lo ọ̀pọ̀ orúkọ oyè àti àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe bí “Olódùmarè,” “Ẹni Gíga Jù Lọ” àti “Olúwa” fún Ọlọ́run, lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà ni wọ́n máa ń lò nígbà tí wọ́n bá ń pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan.
Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ní kí àwọn tó kọ Bíbélì lo orúkọ òun. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mí sí wòlíì Jóẹ́lì láti kọ̀wé pé: ‘Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà.’ (Jóẹ́lì 2:32) Ó sì tún mí sí onísáàmù kan láti kọ̀wé pé: “Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.” (Sáàmù 83:18) Kódà nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje (700) ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú ìwé Sáàmù nìkan ṣoṣo, ìyẹn ìwé tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ewì kọ káwọn èèyàn Ọlọ́run lè máa kọ ọ́ lórin tàbí kí wọ́n máa kà á látorí. Kí wá nìdí tí orúkọ Ọlọ́run ò fi sí nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì? Kí nìdí tí Bíbélì yìí fi lo orúkọ náà, “Jèhófà”? Kí sì ni Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí?
Kí nìdí tí orúkọ Ọlọ́run kò fi sí nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì? Oríṣiríṣi nǹkan ló fà á. Àwọn kan gbà pé kò pọn dandan kí Ọlọ́run Olódùmarè dá ní orúkọ kan tó yàtọ̀ tí a ó máa fi pè é. Ní ti àwọn èèyàn míì, ó jọ pé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ni wọ́n tẹ̀ lé, èyí tó sọ pé káwọn èèyàn má ṣe lo orúkọ Ọlọ́run kí wọ́n má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́. Àwọn míì sì gbà pé torí pé kò sí ẹni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run gangan, ó kúkú sàn kí àwọn lo orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run.” Àmọ́, kò sí èyí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nínú àwọn ohun tí wọ́n sọ yìí. Àwọn ìdí tí a fi sọ bẹ́ẹ̀ rèé:
Àwọn tó sọ pé kò pọn dandan kí Ọlọ́run Olódùmarè dá ní orúkọ kan tó yàtọ̀ tí a lè máa fi pè é ti gbàgbé pé orúkọ Ọlọ́run gangan wà nínú àwọn ẹ̀dà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n fi ọwọ́ kọ ní àtijọ́, títí kan àwọn ẹ̀dà tí wọ́n tọ́jú pa mọ́ kí Kristi tó wá sáyé. Bí a ṣe sọ, Ọlọ́run ló ní kí wọ́n kọ orúkọ òun sínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà. Torí náà, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ ká mọ orúkọ òun ká sì máa lò ó.
Àwọn atúmọ̀ èdè tó yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì torí pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù gbójú fo ohun pàtàkì kan. Ohun náà ni pé bí àwọn akọ̀wé Júù kan tiẹ̀ kọ̀ láti pe orúkọ Ọlọ́run, wọn ò yọ orúkọ náà kúrò nínú ẹ̀dà Bíbélì wọn. Kódà, orúkọ náà fara hàn ní ọ̀pọ̀ ibi nínú àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n rí ní Kúmúránì, nítòsí Òkun Òkú. Bí àwọn atúmọ̀ èdè kan ṣe fi orúkọ oyè náà “OLÚWA” tí wọ́n fi lẹ́tà gàdàgbà kọ rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, jẹ́ ká mọ̀ pé orúkọ náà wà nínú ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ti àtijọ́. Síbẹ̀, ìbéèrè kan wà tó yẹ ká wá ìdáhùn sí. Ìbéèrè náà ni pé, Kí nìdí tí àwọn atúmọ̀ èdè yìí fi rò pé àwọn lómìnira láti fi orúkọ míì rọ́pò orúkọ Ọlọ́run tàbí kí wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbà pé orúkọ náà fara hàn nínú Bíbélì ní ìgbà tó pọ̀ gan-an? Ta ni wọ́n rò pé ó fún wọn láṣẹ láti fi orúkọ míì rọ́pò orúkọ Ọlọ́run? Àwọn nìkan ló lè sọ.
Àwọn tó sọ pé kí ẹnikẹ́ni má lo orúkọ Ọlọ́run torí pé kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ṣì ń lo orúkọ Jésù ní fàlàlà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń pe Jésù ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ń pè é lónìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ye·shuʹa‛ ni àwọn Júù tó di Kristẹni ń pe Jésù, tí wọ́n sì ń pe orúkọ oyè náà “Kristi” ní Ma·shiʹach tàbí “Mèsáyà.” Àwọn Kristẹni tó ń sọ èdè Gíríìkì ń pè é ní I·e·sousʹ Khri·stosʹ, àwọn Kristẹni tó ń sọ èdè Látìn sì ń pè é ní Ieʹsus Chriʹstus. Nígbà tí Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì, ohun tí wọ́n ń pe orúkọ Jésù lédè Gíríìkì ni wọ́n kọ sínú Bíbélì, èyí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu torí pé bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Jésù lédè wọn làwọn náà ń pè é. Lọ́nà kan náà, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun rí i pé ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn lo “Jèhófà” fún orúkọ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ bí àwọn tó jẹ́ Hébérù nígbà àtijọ́ ṣe ń pè é gẹ́lẹ́ nìyẹn.
Kí nìdí tí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi lo “Jèhófà” fún orúkọ Ọlọ́run? Lédè Gẹ̀ẹ́sì, kọ́ńsónáǹtì YHWH ni wọ́n máa ń lò fún lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin (יהוה), tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. Bó ṣe rí nínú gbogbo ìwé àtijọ́ tí wọ́n kọ lédè Hébérù, kọ́ńsónáǹtì ni lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà, kò ní fáwẹ́ẹ̀lì. Nígbà táwọn èèyàn ṣì ń sọ èdè Hébérù àtijọ́ déédéé, ó rọrùn fún ẹni tó bá ń kàwé láti fi àwọn fáwẹ́ẹ̀lì tó yẹ sáàárín àwọn kọ́ńsónáǹtì náà.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tán, àwọn ọ̀mọ̀wé Júù ṣètò àwọn àmì kan tí wọ́n fi lè mọ irú fáwẹ́ẹ̀lì tó yẹ kí wọ́n lò nígbà tí wọ́n bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù. Àmọ́, nígbà yẹn ọ̀pọ̀ Júù ló gba ẹ̀kọ́ èké náà gbọ́ pé kò dáa kéèyàn máa pe orúkọ Ọlọ́run sókè, torí náà wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ míì rọ́pò rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó jọ pé nígbà tí wọ́n bá ṣe àdàkọ lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà, wọ́n máa ń kọ àwọn fáwẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi rọ́pò orúkọ náà mọ́ lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. Torí náà, àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ní àwọn àmì fáwẹ́ẹ̀lì yẹn nínú kò jẹ́ kéèyàn mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run gangan lédè Hébérù nígbà àtijọ́. Àwọn kan rò pé “Yahweh” ni wọ́n ń pe orúkọ náà, àwọn míì sì sọ onírúurú ọ̀nà míì tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa gbà pè é. Nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, wọ́n rí apá kan lára ìwé Léfítíkù tí wọ́n dà kọ lédè Gíríìkì tó lo Iao fún orúkọ Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí Iao yìí, àwọn òǹkọ̀wé èdè Gíríìkì nígbà àtijọ́ dábàá pé a tún lè pe orúkọ náà ní Iae, I·a·beʹ àti I·a·ou·eʹ. Àmọ́, kò sídìí tí a fi ní láti fi dandan lé e pé ọ̀nà kan ló sàn jù láti gbà pè é. Kókó ibẹ̀ ni pé a ò mọ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ṣe ń pe orúkọ náà lédè Hébérù. (Jẹ́nẹ́sísì 13:4; Ẹ́kísódù 3:15) Ohun tí a mọ̀ ni pé Ọlọ́run lo orúkọ rẹ̀ léraléra nígbà tó ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀. A tún mọ̀ pé wọ́n máa ń fi orúkọ yẹn pè é, wọ́n sì máa ń lo orúkọ náà fàlàlà nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.—Ẹ́kísódù 6:2; 1 Àwọn Ọba 8:23; Sáàmù 99:9.
Kí wá nìdí tí Bíbélì yìí fi lo “Jèhófà” fún orúkọ Ọlọ́run? Ìdí ni pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń pe orúkọ Ọlọ́run ní “Jehovah” lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Ọdún 1530 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí orúkọ Ọlọ́run gangan fara hàn nínú Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì nínú Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ tí William Tyndale túmọ̀. Ohun tó lò fún orúkọ Ọlọ́run ni “Iehouah.” Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì ń yí pa dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orúkọ náà lọ́nà tó bóde mu. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1612 nígbà tí Henry Ainsworth túmọ̀ ìwé Sáàmù, “Iehovah” ló lò jálẹ̀ ìwé náà. Àmọ́, ní ọdún 1639, nígbà tí wọ́n ṣe àtúnṣe ìtumọ̀ náà tí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde pẹ̀lú Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́, “Jehovah” ni wọ́n lò. Lọ́dún 1901, àwọn atúmọ̀ èdè tó ṣe Bíbélì American Standard Version lo “Jehovah” níbi tí orúkọ Ọlọ́run bá ti fara hàn lédè Hébérù.
Nígbà tí Joseph Bryant Rotherham, ọ̀mọ̀wé kan nípa Bíbélì táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, ń ṣàlàyé ìdí tó fi lo “Jehovah” dípò “Yahweh” nínú ìwé tó ṣe lọ́dún 1911, ìyẹn Studies in the Psalms, ó sọ pé òun fẹ́ láti lo “orúkọ tí gbogbo èèyàn tó ń ka Bíbélì á tètè dá mọ̀ (tí wọ́n á sì tẹ́wọ́ gbà).” Ohun tó jọ èyí náà ni ọ̀mọ̀wé A. F. Kirkpatrick sọ lọ́dún 1930, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa lílo “Jehovah” fún orúkọ Ọlọ́run. Ó ní: “Èrò àwọn onímọ̀ gírámà òde òní ni pé Yahveh tàbí Yahaveh ló yẹ káwọn èèyàn máa pe orúkọ náà; àmọ́ ó jọ pé JEHOVAH làwọn èèyàn mọ̀ dáadáa lédè Gẹ̀ẹ́sì àti pé kì í ṣe bí àwọn èèyàn ṣe ń pe orúkọ náà gangan ló ṣe pàtàkì, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ni ká mọ̀ pé Orúkọ Ọlọ́run ni, kì í wulẹ̀ ṣe orúkọ oyè bí ‘Olúwa.’”
Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà? Inú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “láti di” ni orúkọ náà, Jèhófà ti wá. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sì sọ pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù yìí sábà máa ń fi hàn pé ohun kan tàbí ẹnì kan mú kí nǹkan kan di ṣíṣe. Nítorí náà, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun lóye pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Èrò àwọn ọ̀mọ̀wé kò ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ náà, torí náà a ò lè fi dandan lé e pé ìtumọ̀ yìí ló sàn jù. Àmọ́, ìtumọ̀ yìí bá Jèhófà mu gan-an torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ó sì máa ń mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Kì í wulẹ̀ ṣe pé ó dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá olóye inú rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe ń wáyé, ó ń mú kí ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.
Torí náà, ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà kò mọ sórí ọ̀rọ̀ ìṣe míì tó fara hàn nínú Ẹ́kísódù 3:14, tó sọ pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́” tàbí “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” Tí a bá ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, gbólóhùn yìí kò tó láti ṣàlàyé gbogbo ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú ká mọ apá kan lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, tó ń fi hàn pé ó ń di ohunkóhun tó bá yẹ nínú ipò kọ̀ọ̀kan láti lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ yìí wà lára orúkọ náà, Jèhófà, kò mọ sí dídi ohunkóhun tí òun fúnra rẹ̀ lè dà. Ó tún kan ohun tó ń mú kó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti bó ṣe ń mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.