A3
Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
Ẹni tó ni Bíbélì, tó sì jẹ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá ni kò jẹ́ kó pa run. Òun ló mú kí ọ̀rọ̀ yìí wà lákọsílẹ̀ pé:
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.”—Àìsáyà 40:8.
Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ níbẹ̀rẹ̀ lédè Hébérù àti Árámáíkìa àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kò sí mọ́ lóde òní. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló mú kó dá wa lójú pé àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì òde òní bá àwọn àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí níbẹ̀rẹ̀ mu lóòótọ́?
ÀWỌN ADÀWÉKỌ KÒ JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN PA RUN
Ní ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, lára ohun tó dáhùn ìbéèrè yìí wà nínú àṣẹ kan tí Ọlọ́run pa nígbà àtijọ́, pé kí àwọn èèyàn máa ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́.b Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣe ẹ̀dà Òfin tí àwọn fúnra wọn á máa kà. (Diutarónómì 17:18) Bákan náà, Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọmọ Léfì tọ́jú ìwé Òfin, kí wọ́n sì máa fi kọ́ àwọn èèyàn. (Diutarónómì 31:26; Nehemáyà 8:7) Lẹ́yìn tí àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, àwọn adàwékọ tàbí àwọn akọ̀wé òfin (ìyẹn, àwọn Sóférímù) bẹ̀rẹ̀ sí í da ìwé kọ. (Ẹ́sírà 7:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn adàwékọ yẹn ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dà ìwé mọ́kàndínlógójì (39) tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
Láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn akọ̀wé òfin fara balẹ̀ da àwọn ìwé yìí kọ. Láàárín Àkókò Ọ̀làjú (500-1500 S.K.), àwùjọ àwọn akọ̀wé òfin Júù tí wọ́n ń pè ní Másórétì náà tún ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́. Odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó pẹ́ jù lọ tí àwọn Másórétì kọ ni wọ́n ń pè ní Leningrad Codex, ó sì ti wà láti nǹkan bí ọdún 1008 sí 1009 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, nígbà tó di àárín ọ̀rúndún ogún, wọ́n rí àwọn apá kan nínú Bíbélì àfọwọ́kọ tàbí àwọn àjákù tí ó tó igba ó lé ogún (220) lára Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Ó ju ẹgbẹ̀rún ọdún tí àwọn ìwé yẹn ti wà ṣáájú Leningrad Codex. Nígbà tí a fi ohun tó wà nínú Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú wéra pẹ̀lú Leningrad Codex, kókó pàtàkì kan wá ṣe kedere: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìyàtọ̀ kan wà nínú bí wọ́n ṣe to àwọn ọ̀rọ̀ inú Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, kò sí ìkankan nínú àwọn ìyàtọ̀ yẹn tó yí kókó ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pa dà.
Ní ti ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ńkọ́? Àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi àti díẹ̀ lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn ló kọ àwọn ìwé yìí. Àwọn Kristẹni ìgbà yẹn tẹ̀ lé àṣà àwọn akọ̀wé òfin Júù, àwọn náà ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé yẹn. (Kólósè 4:16) Bí Olú Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Diocletian àtàwọn míì ṣe gbìyànjú tó láti pa gbogbo ìwé táwọn Kristẹni ìgbà yẹn ń lò run, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àjákù Ìwé Mímọ́ tó ti wà tipẹ́ àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ ló ṣì wà títí dòní.
Wọ́n tún túmọ̀ àwọn ìwé táwọn Kristẹni kọ sí àwọn èdè míì. Lára àwọn èdè àtijọ́ tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí nígbà yẹn ni Àméníà, Coptic, Ethiopic, Georgian, Látìn àti Síríákì.
ÀWỌN ÌWÉ BÍBÉLÌ LÉDÈ HÉBÉRÙ ÀTI GÍRÍÌKÌ TÍ A FI TÚMỌ̀ BÍBÉLÌ YÌÍ
Kì í ṣe gbogbo Bíbélì àfọwọ́kọ àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ inú wọn dọ́gba. Báwo wá la ṣe lè mọ ohun tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀?
Ńṣe ni ọ̀rọ̀ yẹn dà bí ìgbà tí olùkọ́ kan sọ fún ọgọ́rùn-ún (100) akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n ṣe àdàkọ orí kan nínú ìwé kan. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwé tí gbogbo wọn ṣe àdàkọ látinú rẹ̀ sọ nù, téèyàn bá fi ìwé ọgọ́rùn-ún (100) yẹn wéra, ó lè mọ ohun tó wà nínú ìwé tó sọ nù yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yẹn lè ṣe àwọn àṣìṣe kan, bóyá ni gbogbo wọn máa ṣe àṣìṣe kan náà. Bákan náà, nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé bá fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìwé àjákù àtàwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ àtijọ́ tí wọ́n rí wéra, wọ́n á rí àṣìṣe táwọn adàwékọ ṣe, wọ́n á sì mọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀.
“A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ìwé àtijọ́ kankan tí wọ́n da ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kọ lọ́nà tó péye bíi Bíbélì”
Kí ló mú kó dá wa lójú pé wọ́n ṣe àdàkọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó péye? Nígbà tí ọ̀mọ̀wé William H. Green ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó ní: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ìwé àtijọ́ kankan tí wọ́n da ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kọ lọ́nà tó péye bíi Bíbélì.” Nígbà tí ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ F. F. Bruce ń sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì táwọn kan ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tó fi hàn pé àwọn ìwé inú Májẹ̀mú Tuntun lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju ọ̀pọ̀ ìwé tí àwọn gbajúgbajà òǹṣèwé kọ lọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sẹ́ni tó jẹ́ yẹ àwọn òǹkọ̀wé yìí lọ́wọ́ wò láti mọ̀ bóyá òótọ́ ni wọ́n kọ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.” Ó tún sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé Májẹ̀mú Tuntun ni àpapọ̀ àwọn ìwé tí àwọn gbajúgbajà òǹṣèwé yìí kọ, kò sẹ́ni tó máa sọ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò péye.”
Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù: Bíbélì Biblia Hebraica tí Rudolf Kittel ṣe la fi túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Lédè Hébérù (1953 sí 1960). Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n ṣàtúnṣe sí ti jáde, irú bíi Biblia Hebraica Stuttgartensia àti Biblia Hebraica Quinta, àwọn ohun tuntun tí wọ́n rí nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ sì wà nínú wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kọ àwọn ìwé yìí ṣe ẹ̀dà ohun tó wà nínú Leningrad Codex nígbà tí wọ́n ń kọ àwọn ìwé náà, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra tí wọ́n rí nínú àwọn ìwé míì sínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àwọn ìwé bíi Samaritan Pentateuch (Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Àwọn Ará Samáríà), Dead Sea Scrolls (Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú), Greek Septuagint (Bíbélì Septuagint Lédè Gíríìkì), Aramaic Targums, Latin Vulgate (Bíbélì Vulgate Lédè Látìn), Syriac Peshitta (Bíbélì Peshitta Lédè Síríákì). A ṣèwádìí nínú Biblia Hebraica Stuttgartensia àti Biblia Hebraica Quinta nígbà tí à ń ṣiṣẹ́ lórí Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí à ń lò báyìí.
Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì: Ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, ọ̀mọ̀wé B. F. Westcott àti F.J.A. Hort fi àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ àtàwọn ìwé àjákù tó wà wéra bí wọ́n ṣe ń ṣe àkójọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, tí wọ́n gbà pé ó jọ èyí tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀ jù lọ. Ní nǹkan bí ọdún 1950, àkójọ tí wọ́n ṣe yìí ni Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun gbé ìtúmọ̀ wọn kà. Wọ́n tún lo àwọn ìwé àtijọ́ tí wọ́n fi òrépèté ṣe, èyí táwọn olùṣèwádìí gbà pé ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì àti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a ti rí àwọn ìwé míì tí wọ́n fi òrépèté ṣe. Bákan náà, àwọn ìwádìí míì táwọn ọ̀mọ̀wé ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí tún fara hàn nínú àwọn àkójọ tí Nestle àti Aland àti United Bible Societies ṣe. A lò lára àwọn ìwádìí yìí nígbà tí à ń ṣe àtúnṣe Bíbélì yìí.
Nígbà tí a ṣàyẹ̀wò àwọn ìwádìí tí wọ́n kó jọ yìí, ó wá ṣe kedere pé àwọn ẹsẹ kan wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nínú àwọn Bíbélì àtijọ́, irú bíi King James Version, tó jẹ́ pé wọn ò sí nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, àwọn adàwékọ ló fi àwọn ẹsẹ yẹn kún un nígbà tó yá. Àmọ́, torí pé ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún làwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì ti fohùn ṣọ̀kan lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn ẹsẹ inú Bíbélì, bí wọ́n ṣe yọ àwọn ẹsẹ yìí kúrò ti mú kí àlàfo wà láwọn ẹsẹ yìí nínú ọ̀pọ̀ jù lọ Bíbélì. Àwọn ẹsẹ náà ni Mátíù 17:21; 18:11; 23:14; Máàkù 7:16; 9:44, 46; 11:26; 15:28; Lúùkù 17:36; 23:17; Jòhánù 5:4; Ìṣe 8:37; 15:34; 24:7; 28:29 àti Róòmù 16:24. Nínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé wà láwọn ẹsẹ tí a yọ kúrò yẹn.
Bákan náà, lórí ọ̀rọ̀ ti ìparí gígùn tó wà ní Máàkù 16 (ẹsẹ 9-20), ìparí kúkúrú tó wà ní Máàkù 16 àti àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Jòhánù 7:53–8:11, ẹ̀rí fi hàn pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn ẹsẹ yìí nínú àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ níbẹ̀rẹ̀. Torí náà, a ò fi àwọn ọ̀rọ̀ ayédèrú yẹn sínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí.c
A ti ṣe àtúnṣe sáwọn ọ̀rọ̀ míì kó lè bára mu pẹ̀lú ohun táwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn ìwé Bíbélì kan tí wọ́n fọwọ́ kọ, Mátíù 7:13 kà pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò.” Nínú àwọn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a ṣe tẹ́lẹ̀, ẹsẹ yẹn ò sọ pé ọ̀nà ìparun ní “ẹnubodè.” Àmọ́, nígbà tí a ṣèwádìí síwájú sí i nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ yẹn, a rí ẹ̀rí tó fi hàn pé “ẹnubodè” wà nínú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ níbẹ̀rẹ̀. Torí náà, a ti fi sínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí. Ó tó ibi mélòó kan tí a ṣe irú àtúnṣe yìí sí. Àmọ́ àwọn àtúnṣe kéékèèké ni, kò sì yí ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa dà.
a Láti ibí yìí lọ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù la ó máa pè é.
b Ọ̀kan lára ìdí tó fi pọn dandan pé kí wọ́n ṣe ẹ̀dà àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ níbẹ̀rẹ̀ ni pé orí àwọn nǹkan tó lè bà jẹ́ ni wọ́n kọ wọ́n sí.
c Àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ yìí fi jẹ́ ayédèrú wà nínú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé inú New World Translation of the Holy Scriptures—With References, tí a ṣe lọ́dún 1984.