Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
8 Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Sítéfánù.+
Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó lágbára sí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà, àwọn àpọ́sítélì nìkan ni kò tú ká.+ 2 Àmọ́ àwọn ọkùnrin olùfọkànsìn gbé Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ gan-an nítorí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìkà sí ìjọ. Bó ṣe ń jáde nínú ilé kan ló ń wọ òmíì, ó ń wọ́ tọkùnrin tobìnrin jáde, ó sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n.+
4 Síbẹ̀, àwọn tó ti tú ká ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà, wọ́n ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.+ 5 Lásìkò yìí, Fílípì lọ sí ìlú* Samáríà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Kristi fún wọn. 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn pọkàn pọ̀ sórí ohun tí Fílípì ń sọ, wọ́n ń fetí sílẹ̀, wọ́n sì ń wo àwọn iṣẹ́ àmì tó ń ṣe. 7 Nítorí ọ̀pọ̀ ló ní àwọn ẹ̀mí àìmọ́, àwọn ẹ̀mí yìí á kígbe ní ohùn rara, wọ́n á sì jáde.+ Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ àti àwọn tó yarọ rí ìwòsàn. 8 Nítorí náà, ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní ìlú yẹn.
9 Lákòókò yẹn, ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Símónì ní ìlú náà, ṣáájú àkókò yìí, ó ti ń ṣe iṣẹ́ idán pípa, ó ń mú kí ẹnu ya orílẹ̀-èdè Samáríà, ó sì ń sọ pé ẹni ńlá ni òun. 10 Gbogbo wọn, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ, ló ń fiyè sí i, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Ọkùnrin yìí ni Agbára Ọlọ́run, tí à ń pè ní Títóbi.” 11 Nítorí náà, wọ́n á fiyè sí i torí pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tó ti ń fi iṣẹ́ idán rẹ̀ mú kí ẹnu yà wọ́n. 12 Àmọ́ nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́, ẹni tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run+ àti orúkọ Jésù Kristi, tọkùnrin tobìnrin wọn sì ń ṣèrìbọmi.+ 13 Símónì náà di onígbàgbọ́, lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó wà pẹ̀lú Fílípì;+ ó sì ń yà á lẹ́nu bó ṣe ń rí àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tó ń ṣẹlẹ̀.
14 Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Samáríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù sí wọn; 15 àwọn yìí wá, wọ́n sì gbàdúrà fún wọn kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mímọ́.+ 16 Nítorí kò tíì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn, a kàn ṣì batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa ni.+ 17 Nígbà náà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.
18 Nígbà tí Símónì rí i pé àwọn èèyàn ń rí ẹ̀mí gbà tí àwọn àpọ́sítélì bá ti gbọ́wọ́ lé wọn, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó sọ pé: “Ẹ fún èmi náà ní àṣẹ yìí, kí ẹnikẹ́ni tí mo bá gbé ọwọ́ mi lé lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” 20 Àmọ́ Pétérù sọ fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, torí o rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.+ 21 O kò ní ipa tàbí ìpín kankan nínú ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé ọkàn rẹ kò tọ́ lójú Ọlọ́run. 22 Torí náà, ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ yìí, kí o sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà* pé, tó bá ṣeé ṣe, kí ó dárí èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ jì ọ́; 23 torí mo rí i pé májèlé kíkorò* àti ẹrú àìṣòdodo ni ọ́.” 24 Ni Símónì bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ bá mi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà* kí ìkankan nínú ohun tí ẹ sọ má bàa ṣẹlẹ̀ sí mi.”
25 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti jẹ́rìí kúnnákúnná, tí wọ́n sì ti sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,* wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere ní ọ̀pọ̀ abúlé àwọn ará Samáríà.+
26 Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà*+ bá Fílípì sọ̀rọ̀, ó ní: “Dìde kí o sì lọ sí gúúsù ní ọ̀nà tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Gásà.” (Èyí jẹ́ ọ̀nà aṣálẹ̀.) 27 Ló bá dìde, ó lọ, sì wò ó! ìwẹ̀fà* ará Etiópíà kan, ọkùnrin tó wà nípò àṣẹ lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, òun ló ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀. Ó lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù,+ 28 ó sì ń pa dà bọ̀, ó jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè. 29 Nítorí náà, ẹ̀mí sọ fún Fílípì pé: “Lọ, kí o sì sún mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí.” 30 Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì gbọ́ tí ó ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè, ó wá bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lóye* ohun tí ò ń kà?” 31 Ó dáhùn pé: “Báwo ni mo ṣe lè lóye, láìjẹ́ pé ẹnì kan tọ́ mi sọ́nà?” Torí náà, ó rọ Fílípì pé kó gòkè, kó sì jókòó pẹ̀lú òun. 32 Àyọkà Ìwé Mímọ́ tó ń kà nìyí: “Wọ́n mú un wá bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á, bí ọ̀dọ́ àgùntàn tó dákẹ́ níwájú àwọn tó ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò la ẹnu rẹ̀.+ 33 Nígbà tí wọ́n ń pẹ̀gàn rẹ̀, wọn ò ṣe ìdájọ́ òdodo fún un.+ Ta ló máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”+
34 Ìwẹ̀fà náà wá béèrè lọ́wọ́ Fílípì pé: “Mo bẹ̀ ọ́, ta ni wòlíì náà ń sọ nípa rẹ̀? Ṣé nípa ara rẹ̀ ni àbí ẹlòmíì?” 35 Ni Fílípì bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ yìí, ó sì kéde ìhìn rere nípa Jésù fún un. 36 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, wọ́n dé ibi tí omi wà, ìwẹ̀fà náà sì sọ pé: “Wò ó! Omi rèé; kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” 37* —— 38 Ló bá pàṣẹ pé kí kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà dúró, Fílípì àti ìwẹ̀fà náà wá wọ inú omi, Fílípì sì ṣèrìbọmi fún un. 39 Nígbà tí wọ́n jáde nínú omi, ní kíá, ẹ̀mí Jèhófà* darí Fílípì lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́, àmọ́ ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. 40 Ní ti Fílípì, ó bá ara rẹ̀ ní Áṣídódù, ó gba ìpínlẹ̀ náà kọjá, ó sì ń kéde ìhìn rere fún gbogbo àwọn ìlú títí ó fi dé Kesaríà.+