Ṣé Èèyàn Ń Pa Oúnjẹ Ara Rẹ̀ Run Ni?
“Ohun tó ń yọ wá lẹ́nu lónìí kì í [ṣe] gbèsè tàbí ìdíje láàárín àwọn táa jọ ń gbáyé, àmọ́ ohun ọ̀hún ni ìfẹ́ láti máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tó sì tẹ́ wa lọ́rùn láìsí pé a ń pa àwọn ohun alààyè mìíràn tó so ìgbésí ayé wa ró run. Kò tíì sígbà kankan rí tọ́mọ ẹ̀dá dojú kọ irú ewu bẹ́ẹ̀: ìyẹn pípa àwọn ohun tó ń mú wa wà láàyè run.”—Onímọ̀ nípa àbùdá, David Suzuki.
ÈSO ápù jẹ́ èso kan téèyàn lè má fi bẹ́ẹ̀ kà sí. Tó bá jẹ́ ibi tí èso yìí ti pọ̀ yanturu lò ń gbé, o lè máa rò pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe wà káàkiri, o tiẹ̀ lè máa rò pé èyí tó bá wù ẹ́ lo lè jẹ lára oríṣiríṣi wọn tó wà. Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ̀ pé oríṣi ápù tó wà fún jíjẹ lónìí kò tó nǹkan mọ́ táa bá fi wé oríṣi tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn?
Láàárín ọdún 1804 sí 1905, oríṣi èso ápù tí wọ́n ń gbìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó ẹgbẹ̀rún méje àti méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [7,098]. Lọ́jọ́ tòní, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti mọ́kànlélọ́gọ́fà [6,121], ìyẹn ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ti kú àkúrun. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fún èso píà. Nǹkan bí ìpín méjìdínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lára oríṣi ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin [2,683] tí wọ́n ń gbìn nígbà kan rí ló ti kú àkúrun báyìí. Táa bá sì ní ká fẹnu ba ti ewébẹ̀, oríṣi tí kò sí mọ́ nínú àwọn yẹn pọ̀ lọ jàra. Ohun kan ń pòórá báyìí o, ohun náà ni níní oríṣiríṣi irè oko—kì í ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ irú ọ̀wọ́ wọn nìkan ló ń dàwátì, ó tún kan oríṣiríṣi ẹ̀yà tó wà nínú àwọn ọ̀wọ́ yìí pẹ̀lú. Láàárín ọgọ́rin ọdún péré, onírúurú ẹ̀yà ewébẹ̀ tí wọ́n ń gbìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi ìpín mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún dín kù! Àmọ́ ṣé nǹkan bàbàrà kan wà nínú bí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra ni?
Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iyàn jíjà ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí bóyá bí àwọn ohun ọ̀gbìn ṣe wà ní oríṣiríṣi ẹ̀yà ní ìwúlò kankan, àwọn tó mọ tinú-tòde ọ̀ràn nípa àyíká sọ pé wọ́n ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n ní bó ṣe ṣe pàtàkì fún àwọn nǹkan táa ń gbìn fún jíjẹ náà ló tún ṣe pàtàkì fáwọn tá ò lò tí wọ́n wà nínú igbó, nínú ẹgàn, àti láwọn ilẹ̀ koríko tó wà láyé. Kí ìyàtọ̀ wà láàárín irú ọ̀wọ́ kan tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, bí onírúurú ìrẹsì tó yàtọ̀ síra ṣe wà yóò jẹ́ kó túbọ̀ ṣeé ṣe pé, tí àrùn tó máa ń pa ìrẹsì bá kọ lu àwọn kan, irú ọ̀wọ́ àwọn kan yóò ṣì wà tí kòkòrò náà kò ní rí gbé ṣe. Ìdí rèé tí ìwé kan, tí Ẹ̀ka Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé kọ fi sọ láìpẹ́ yìí pé, ohun kan ṣoṣo tó lè jẹ́ kí aráyé mọ ewu tó wà nínú dídín oríṣiríṣi ẹ̀yà ohun ọ̀gbìn tó wà láyé kù ni àkóbá tó máa ṣe fún ìpèsè oúnjẹ wa.
Ó kéré tán, ọ̀nà méjì ni kíkú àkúrun àwọn ohun ọ̀gbìn lè gbà ṣàkóbá: lákọ̀ọ́kọ́, ó máa ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀yà tó fara jọ irúgbìn náà pòórá, àwọn yẹn ló sì ṣeé ṣe kó jẹ́ orísun àbùdá tó máa mú àwọn míì jáde lọ́jọ́ iwájú, èkejì, ó máa ń dín oríṣiríṣi àwọn irú ọ̀wọ́ táa máa ń gbìn kù. Fún àpẹẹrẹ, níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, oríṣiríṣi ìrẹsì ìbílẹ̀ tí wọ́n ń gbìn ní Éṣíà lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún, tí oríṣi ti ilẹ̀ Íńdíà nìkan kò sì dín sí nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000]. Ní báyìí, gbogbo ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ìrẹsì tí ilẹ̀ Íńdíà ń gbìn kò ju oríṣi mẹ́wàá péré lọ. Kìkì oríṣi márùn-ún péré ló kù nínú oríṣi ìrẹsì bí ẹgbẹ̀rún méjì tí ilẹ̀ Sri Lanka ní tẹ́lẹ̀. Mẹ́síkò, tó ti jẹ́ ilé ọkà ìbílẹ̀ rí, ló wá jẹ́ pé kìkì oríṣi ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún téèyàn lè rí níbẹ̀ láwọn ọdún 1930 ló kù tí wọ́n ń gbìn báyìí.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ oúnjẹ nìkan kọ́ nìṣòro tó wà nílẹ̀ o. Nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn egbòogi tí wọ́n ń ṣe fún títà ni wọ́n ń rí lára nǹkan ọ̀gbìn, bẹ́ẹ̀ sì ni ṣíṣàwárí àwọn irúgbìn tuntun tó wúlò fún egbòogi ò dáwọ́ dúró. Síbẹ̀, àwọn irúgbìn kò yéé kú àkúrun. Ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn ohun tó so ẹ̀mí wa ró la ń pa run yìí?
Níbàámu pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Ìdáàbòbo Ìṣẹ̀dá Lágbàáyé, nínú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún ọ̀wọ́ irúgbìn àti ẹranko tí wọ́n ṣèwádìí wọn, àwọn tó ṣeé ṣe kó kú àkúrun lé lẹ́gbẹ̀rún mọ́kànlá. Láwọn ilẹ̀ bí Indonesia, Malaysia, àti Látìn Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti gé igbó lọ bí ilẹ̀ bí ẹní nítorí iṣẹ́ ọ̀gbìn, àwọn olùwádìí ò lè sọ pé iye báyìí pàtó ni ọ̀wọ́ irúgbìn tó ṣeé ṣe kó ti kú àkúrun, tàbí tó tiẹ̀ ti kú run pátápátá. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwé ìròyìn The UNESCO Courier ní àwọn kan sọ pé ńṣe ni àkúrun yìí ń bá a lọ ní “pẹrẹu lọ́nà tó mú ewu lọ́wọ́.”
Òótọ́ ni pé ilẹ̀ ayé ṣì ń pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu. Àmọ́, yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀dá ènìyàn tí iye rẹ̀ ń pọ̀ bí eṣú yìí fi máa bọ́ ara rẹ̀ bí oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ ayé bá ń dín kù? Àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ti ń wá ọgbọ́n ta sírú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró irúgbìn pa mọ́ sí èyí tí wọ́n lè wá fàbọ̀ bá táwọn irúgbìn pàtàkì bá pòórá. Àwọn ọgbà ọ̀gbìn kan sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn pa mọ́. Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe àwọn irinṣẹ́ tuntun lílágbára tó ń yí àbùdá padà. Àmọ́ ṣé kíkó hóró èso pa mọ́ àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè yanjú ìṣòro yìí lóòótọ́? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á bójú tó ìbéèrè yìí.