Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ṣó Yẹ Kí N Máa Lọ Ságbo Ijó Alẹ́?
“Ó ní nǹkan tí mò ń wá lọ síbẹ̀—mo kàn fẹ́ lọ gbádùn ara mi ni.”—Shawn.
“Ká sòótọ́, ibẹ̀ yẹn dùn jọ̀ọ́—ìgbádùn rẹpẹtẹ wà níbẹ̀! Ijó ń lọ rẹbutu ni, àjómọ́jú kẹlẹlẹ.” —Ernest.
AGBO ijó alẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ló tún gbòde báyìí láti bí ọdún mélòó kan. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń wá ìgbádùn kiri kì í sì í wọ́n nírú agbo ijó alẹ́ bẹ́ẹ̀.
Kò sẹ́ni tí ò mọ̀ pé ó yẹ ká lásìkò tá ó fi gbádùn ara wa. Bíbélì sì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà jíjó” pàápàá wà. (Oníwàásù 3:4, Bibeli Mimọ) Àmọ́, ṣé agbo ijó alẹ́ lo ti lè rí ìgbádùn tó yẹ ọmọlúwàbí? Àbí ó yẹ kó o rò ó síwá sẹ́yìn kó o tó lọ síbẹ̀?
“Àríyá Oníwà Ẹhànnà”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò dẹ́bi fún àríyá tó mọ níwọ̀n, síbẹ̀ ó kì wá nílọ̀ nípa “àríyá aláriwo,” tàbí “àríyá oníwà ẹhànnà.” (Gálátíà 5:19-21; Byington) Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, àríyá aláriwo sábà máa ń yọrí sí ìwà àìníkòóra-ẹni-níjàánu. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná! Háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì àti fèrè, àti wáìnì sì ní láti wà níbi àsè wọn; ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò.”—Aísáyà 5:11, 12.
“Ọtí tí ń pani” ń ṣàn láwọn ibẹ̀ yẹn, orinkórin sì ni wọ́n ń kọ. Láti àárọ̀ kùtù ni wọ́n ti máa ń bẹ̀rẹ̀, ó sì di alẹ́ pátápátá kí wọ́n tó ṣíwọ́. Tún kíyè sí báwọn tó wà níbi àríyá yẹn ṣe ń hùwà o, bí ẹni pé Ọlọ́run ò sí! Ìdí abájọ rèé tí Ọlọ́run fi dẹ́bi fún irú àríyá bẹ́ẹ̀. Irú ojú wo tiẹ̀ ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ lágbo ijó alẹ́ táwọn ọ̀dọ́ ń lọ lóde òní?
Ẹ jẹ́ ká gbé e yẹ̀ wò. Ohun kan ni pé, láwọn ilé ijó kan, irú ijó ẹhànnà kan báyìí ni wọ́n máa ń jó ṣáá. Ìwé ìròyìn kan sọ pé “ọdún mélòó kan lẹ́yìn 1980 ni irú ijó yìí bẹ̀rẹ̀ láwọn ilé ijó tí wọ́n ti ń kọ orin amórígbóná lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ . . . láti orí ‘ijó fìdí-lùdí, fàyà-làyà’ níbi táwọn tó ń jó á ti máa rọ́ lura wọn.” Nígbà tí wọ́n bá ń jó irú ijó yìí, wọ́n á máa fò sókè sódò, wọ́n á máa gbọnrí wìrìwìrì, wọ́n á máa kanrí mọ́lẹ̀, wọ́n á sì tún máa kọlu ara wọn. Dídá lápá tàbí lẹ́sẹ̀ tàbí fífi ibòmíì pa ò jẹ́ tuntun níbi tí wọ́n bá ti ń jó irú ijó yìí, bẹ́ẹ̀ sì làwọn míì máa ń dá lẹ́yìn tàbí kí wọ́n forí pa. Àwọn míì tiẹ̀ ti gbabẹ̀ kú. Ìyẹn nìkan kọ́ o, láwọn ilé ijó kan, àwọn èrò á fọwọ́ gbé ẹnì kan sókè tóun náà á wá máa ta ara ẹ̀ látaré lórí ọwọ́ wọn bí ẹni pé wọ́n ń ṣe eré ìdárayá. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti ṣe irú eré géle yìí ni wọ́n ti jábọ́ tí wọ́n sì ṣèṣe. Wọ́n sábà máa ń fọwọ́ pa àwọn ọmọbìnrin lára tàbí kí wọ́n máa fọwọ́ kàn wọ́n níbi tí ò yẹ.
Láìsí àníàní, inú Ọlọ́run ò dùn sírú ìwà bẹ́ẹ̀. Ṣebí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pàṣẹ fáwọn Kristẹni “láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.”—Títù 2:12.
Orin àti Oògùn Líle
Tún wo irú àwọn orin tí wọ́n máa ń kọ lágbo ijó alẹ́. Orin onílù kíkankíkan tí ọ̀rọ̀ rírùn kún inú rẹ̀, ni wọ́n máa ń kọ láwọn ibì kan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láwọn ilé ijó mìíràn orin ọlọ́rọ̀ wótowòto tàbí orin ṣajẹ ni wọ́n máa ń kọ ní tiwọn. Ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, ìwà jàgídíjàgan àti ìdìtẹ̀ ni wọ́n ń kọ lórin. Tó o bá wá ń fetí sí irú orin báyẹn lágbo ijó alẹ́, ṣé o rò pé kò ní ṣe ẹ́ ní nǹkan kan? David Hollingworth, onímọ̀ nípa ibi ìgbafàájì alẹ́ sọ pé: “Ipa kékeré kọ́ ni orin ń ní lórí ìrònú àti ìwà àwọn èèyàn. Báwọn èèyàn bá pọ̀ lójú kan náà tí wọ́n ń gbọ́ orin burúkú, ẹ̀mí ẹhànnà lè gbé gbogbo wọn wọ̀.” Abájọ tí ìjà fi sábà máa ń bẹ́ sílẹ̀ níbi ijó alẹ́ lọ́pọ̀ ìlú ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ohun táwọn èèyàn gbà pé ó ń fa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹ̀yìn àwọn olórin tí wọn ò rí nǹkan míì kọ lórin ju ọ̀rọ̀ rírùn àti ìwà jàgídíjàgan lọ.a
Lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, lílo oògùn olóró náà ti di ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe níbi ijó alẹ́. Olùṣèwádìí kan sọ pé “bí oríṣiríṣi àwọn oògùn olóró ṣe pọ̀ níta báyìí àti báwọn èèyàn ṣe ń lò wọ́n ló jẹ́ káwọn tó ń lọ sí ilé ijó alẹ́ máa pọ̀ sí i.” Àwọn oògùn kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ń pè ní oògùn ijó. Àwọn kan lára àwọn tó máa ń lọ sílé ijó alẹ́ tiẹ̀ máa ń lo àwọn àdàlù oògùn. Lára àwọn oògùn tí wọ́n sábà máa ń dà pọ̀ ni ketamine, èyí tó lè rani níyè, tó lè fa ṣíṣe wérewère, àìlèmí dáadáa àti àìsàn inú iṣan. Oògùn tó ń jẹ́ methamphetamine máa ń fa títètè gbàgbé nǹkan, kí ara gbẹ̀kan, kéèyàn máa ṣèjàngbọ̀n, ó sì lè fa àìsàn ọkàn tàbí tinú iṣan. Oògùn míì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni èyí tí wọ́n fi èròjà amphetamine ṣe tí wọ́n ń pè ní ecstasy. Ó máa ń da àwọn tó bá lò ó lọ́kàn rú, ó máa ń kó wọn láyà sókè, ọkàn wọn á máa lù kìkì jù, ẹ̀jẹ̀ wọn á máa ru, wọ́n á sì máa ní akọ ìgbóná. A ti rí lára àwọn tí wọ́n lo oògùn yìí tí wọ́n ti kú.
Lílo oògùn tí òfin dè ta ko àṣẹ tí Bíbélì pa pé “kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ṣó bọ́gbọ́n mu fún ẹ láti lọ jókòó síbi tí wọ́n ti ń lo oògùn olóró bó ṣe wù wọ́n?
Ẹgbẹ́ Búburú
Rántí ìkìlọ̀ tá a sábà máa ń tẹnu mọ́ yẹn pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Bíi tàwọn tó máa ń lọ síbi àríyá aláriwo láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ó dà bíi pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ tó sábà máa ń lọ síbi tí wọ́n ti ń jíjó alẹ́ kò wọ́nà báwọn á ṣe ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kódà, a tiẹ̀ lè pe àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ní “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:4) Ṣé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ jọ fẹ́ máa ṣe wọlé wọ̀de?
Àwọn kan lè rò pé lílọ ságbo ijó alẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tó jẹ́ Kristẹni lè dín ewu tó wà níbẹ̀ kù. Àmọ́, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni tí wọ́n jẹ́ “àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ . . . nínú ìwà” ní tòótọ́ kò ní fẹ́ lọ. (1 Tímótì 4:12) Ká tiẹ̀ wá ní àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan kóra wọn lọ síbi ijó alẹ́ tí wọ́n sì gbìyànjú láti wà pa pọ̀, wọ́n á pàpà rí i pé ibi tí wọ́n ti ń kọrin jágbajàgba tí wọ́n sì ti ń hùwà tí ò bójú mu làwọn ṣì wà. Wọ́n lè bá ìṣòro tó kọjá agbára wọn pàdé bí àwọn míì bá ní kí wọ́n báwọn jó lójú agbo. Kódà, àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ti bá èèyàn jà níbẹ̀! Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
Ijó Tó Ń Rùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè
Ẹ jẹ́ ká tún gbé irú ijó tí wọ́n ń jó níbẹ̀ yẹ̀ wò. Irú ijó àràmàǹdà kan báyìí tún ti gbayì nílẹ̀ Amẹ́ríkà láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọn ò tíì pọ́mọ ogun ọdún. Wọ́n sábà máa ń jó irú ijó bẹ́ẹ̀ sí orin ọlọ́rọ̀ wótowòto tí wọ́n sì máa ń la ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ mọ́lẹ̀ nínú irú orin bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí ẹni tó ń bá ẹlòmíì lò pọ̀ lọ́wọ́ ni wọ́n ṣe máa ń jó ijó ọ̀hún. Àwọn kan ti pe ìṣesí wọn nígbà tí wọ́n bá ń jó irú ijó bẹ́ẹ̀ ní ‘ìbálòpọ̀ láìbọ́ṣọ lọ́rùn.’
Ṣé ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni á fẹ́ báwọn jó irú ijó yìí? Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá fẹ́ kí inú Ọlọ́run, ẹni tó pàṣẹ pé ká máa “sá fún àgbèrè,” dùn sí òun. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Àwọn mìíràn lè ronú pé, ‘Ohun tó bá ṣe táwọn ẹlòmíì fi ń ṣe é, kò lè fi bẹ́ẹ̀ burú.’ Àmọ́ sá, ogunlọ́gọ̀ èrò lè sùn kí wọ́n kọrí síbì kan náà o. (Ẹ́kísódù 23:2) Kó o bàa lè ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run, kọ̀ jálẹ̀ fáwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ tí wọ́n bá fẹ́ tì ọ́ ṣe nǹkan tí ò dáa!—1 Pétérù 4:3, 4.
Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dára
Ohun tá à ń sọ yìí ò fi hàn pé gbogbo ijó ló burú o. Bíbélì sọ fún wa pé ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ Ọba Dáfídì lẹ́yìn tó ti gbé àpótí májẹ̀mú mímọ́ náà wọ Jerúsálẹ́mù débi pé ó “ń fi gbogbo agbára rẹ̀ jó yí ká.” (2 Sámúẹ́lì 6:14) Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá, “ohùn orin àwọn òṣèré àti ijó” wà lára ayọ̀ táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nítorí pé ọmọ náà padà wálé.—Lúùkù 15:25.
Irú àwọn ijó kan náà wà tó lè bá àwọn Kristẹni tó wà ládùúgbò rẹ lára mu. Síbẹ̀ náà, láti má ṣàṣejù, ó gba ọgbọ́n inú àti làákàyè. Ó sàn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ kéèyàn gbádùn ara rẹ̀ pẹ̀lú orin àti ijó níbi táwọn Kristẹni pagbo sí tó sì ní ìdarí àti àbójútó tó péye ju ibi ìgbafàájì táwọn ọ̀dọ́ kóra jọ sí lọ. Níbi táwọn Kristẹni bá kóra jọ sí, tí àbójútó tó péye sì wà, àwọn ọ̀dọ́ kì í ya ara wọn sọ́tọ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń kóra jọ pẹ̀lú àwọn Kristẹni yòókù àtàgbà àtọmọdé.
Lóòótọ́ ni pé àwọn ilé oúnjẹ àti ọtí tó dáa lè wà ládùúgbò tìẹ tó jẹ́ pé orin àti ijó tó dáa ni wọ́n máa ń kọ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, kó o tó lọ sí irú ibẹ̀, ó yẹ kó o béèrè àwọn ìbéèrè bí: Irú ibo làwọn èèyàn mọ ibẹ̀ yẹn sí? Ṣé kìkì àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń jẹ̀ síbẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ irú ibẹ̀ yẹn lè yẹ ọmọlúàbí? Irú orin wo ni wọ́n máa kọ níbẹ̀? Irú ijó wo ni wọ́n máa ń jó níbẹ̀? Ṣé àwọn òbí mi á fọwọ́ sí i pé kí n lọ? Bíbéèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kó o fi ìka àbámọ̀ bọnu.
Shawn, tó sọ̀rọ̀ tá a kọ sí ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí kó gbogbo ọ̀rọ̀ náà pọ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí. Kó tó di Kristẹni, ó máa ń lọ sílé ijó dáadáa. Ó rántí pé: “Ìwà pálapàla pọ̀ láwọn ilé ijó alaalẹ́. Orinkórin ni wọ́n máa ń kọ níbẹ̀ tí wọ́n sì máa ń jó ijó àwọn oníṣekúṣe, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó lọ síbẹ̀ ló ní ètekéte lọ́kàn—wọ́n ń wá ẹni tí wọ́n máa gbé lọ bá ṣe ìṣekúṣe.” Shawn ṣíwọ́ lílọ sí ilé fàájì yẹn lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tójú ẹ̀ ti rí màbo, ó sọ èrò tiẹ̀, ó ní: “Àwọn ilé ijó wọ̀nyẹn kì í ṣe ibi tó yẹ kí Kristẹni máa lọ.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìdí Tí Orin Fi Ń Lágbára Lórí Wa,” tó wà nínú Jí! ìtẹ̀jáde October 8, 1999.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ọ̀dọ́ kan ti bá ìṣòro tó kọjá agbára wọn pàdé nígbà tí wọ́n lọ sílé ijó alẹ́