ÌTÀN 31
Mósè Àti Áárónì Lọ Rí Fáráò
NÍGBÀ tí Mósè padà dé Íjíbítì, ó sọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu náà. Nígbà tí Mósè àti Áárónì sì fi àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí han àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn èèyàn náà ló gbà pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn.
Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì lọ rí Fáráò. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ fún ọjọ́ mẹ́ta, kí wọ́n lè sìn mí ní aginjù.”’ Ṣùgbọ́n Fáráò dáhùn pé: ‘Èmi ò gba Jèhófà gbọ́. Mi ò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ.’
Inú bí Fáráò gidigidi pé àwọn èèyàn náà fẹ́ gba àkókò díẹ̀ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ láti lọ jọ́sìn Jèhófà. Nítorí náà, ó fi agbára mú wọn láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ kárakára. Ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá Mósè lẹ́bi nítorí ìwà ìkà táwọn ará Íjíbítì ń hù sí wọn, èyí sì ba Mósè nínú jẹ́ gidigidi. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Mósè pé kó má dààmú. Jèhófà wí pé: ‘Èmi yóò mú kí Fáráò jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ.’
Mósè àti Áárónì tún padà lọ rí Fáráò. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ṣe iṣẹ́ ìyanu kan. Áárónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò ńlá. Ni àwọn amòye Fáráò bá ju ọ̀pá tiwọn náà sílẹ̀, ó sì di ejò. Àmọ́, iwọ wò ó! Ejò Áárónì ń gbé ejò àwọn amòye náà mì. Síbẹ̀, Fáráò kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó lọ.
Nítorí náà, ó tó àkókò báyìí kí Jèhófà kọ́ Fáráò lọ́gbọ́n. Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe ṣe é? Ìyọnu, tàbí àwọn ìjàngbọ̀n ńlá mẹ́wàá ló mú wá sórí Íjíbítì.
Lọ́pọ̀ ìgbà, tí ìyọnu náà bá ti ṣẹlẹ̀, Fáráò á ránṣẹ́ pe Mósè, á sì wí fún un pé: ‘Dá ìyọnu yìí dúró, màá sì jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ.’ Ṣùgbọ́n gẹ́rẹ́ tí ìyọnu náà ò bá ti ṣẹlẹ̀ mọ́ ni Fáráò á tún yí ọkàn padà bírí. Kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ìyọnu kẹwàá ṣẹlẹ̀, Fáráò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀.
Ǹjẹ́ o mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìyọnu mẹ́wàá náà? Ṣí ìwé rẹ síwájú kó o sì jẹ́ ká kọ́ nípa wọn.