Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìtàn Bíbélì
Ìtàn 1
Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣẹ̀dá Àwọn Nǹkan
Ibo ni gbogbo àwọn nǹkan rere ti wá? Ǹjẹ́ o lè dárúkọ ohun rere kan tí Ọlọ́run dá?
Kí ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá?
Kí ló mú kí áńgẹ́lì tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tó kù?
Sọ bi ilẹ̀ ayé ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀. (Wo àwòrán.)
Kí ni Ọlọ́run ṣe láti mú kí ilẹ̀ ayé ṣe é gbé fún àwọn ẹranko àti èèyàn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jeremáyà 10:12.
Kí ni àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá a rí nípasẹ̀ àwọn ohun tó dá? (Aísá. 40:26; Róòmù 11:33)
Ka Kólósè 1:15-17.
Ipa wo ni Jésù kó nínú ìṣẹ̀dá, irú ojú wo ló sì yẹ kí èyí mú ká máa fi wò Jésù? (Kól. 1:15-17)
-
Báwo ni ayé ṣe bẹ̀rẹ̀? (Jẹ́n. 1:1)
Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá? (Jẹ́n. 1:3-5)
Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì ìṣẹ̀dá. (Jẹ́n. 1:7, 8)
Ìtàn 2
Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
Báwo ni Ọlọ́run ṣe múra ilẹ̀ ayé sílẹ̀ dè wá?
Sọ oríṣiríṣi àwọn ẹranko tí Ọlọ́run dá. (Wo àwòrán.)
Kí nìdí tí ọgbà Édẹ́nì fi ṣàrà ọ̀tọ̀?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí gbogbo orí ilẹ̀ ayé rí?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni Ọlọ́run dá ní ọjọ́ kẹta ìṣẹ̀dá? (Jẹ́n. 1:12)
Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin ìṣẹ̀dá? (Jẹ́n. 1:16)
Irú àwọn ẹranko wo ni Ọlọ́run dá ní ọjọ́ karùn-ún àti ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá? (Jẹ́n. 1:20, 21, 25)
-
Àwọn igi pàtàkì méjì wo ni Ọlọ́run dá sínú ọ̀gbà, kí sì ni wọ́n dúró fún?
Ìtàn 3
Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
Kí ni àwòrán Ìtàn 3 fi yàtọ̀ sí àwòrán Ìtàn 2?
Ta ló dá ọkùnrin àkọ́kọ́, kí sì ni orúkọ ọkùnrin náà?
Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé fún Ádámù?
Kí nìdí ti Ọlọ́run fi mú kí Ádámù sun oorun àsùnwọra?
Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí Ádámù àti Éfà wà láàyè pẹ́ tó, iṣẹ́ wo ló sì fẹ́ kí wọ́n ṣe?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Sáàmù 83:18.
Kí ni orúkọ Ọlọ́run, ipò aláìlẹ́gbẹ́ wo sì ni Ọlọ́run wà? (Jer. 16:21; Dán. 4:17)
-
Kí ni Ọlọ́run dá gbẹ̀yìn ní ọjọ́ kẹfà, báwo sì ni ohun tó dá yìí ṣe yàtọ̀ sí àwọn ẹranko? (Jẹ́n. 1:26)
Kí ni Jèhófà pèsè fún àtèèyàn àtẹranko láti máa jẹ? (Jẹ́n. 1:30)
-
Kí ni Ádámù gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè fún àwọn ẹranko ní orúkọ? (Jẹ́n. 2:19)
Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 2:24 ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó, ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀? (Mát. 19:4-6, 9)
Ìtàn 4
Ìdí Tí Wọ́n Fi Pàdánù Ibùgbé Wọn
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà?
Kí nìdí tí Jèhófà fi lé wọn jáde?
Kí ni ejò kan sọ fún Éfà?
Ta ló mú kí ejò náà bá Éfà sọ̀rọ̀?
Kí ló mú kí Ádámù àti Éfà pàdánù ibùgbé wọn ẹlẹ́wà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17 àti 3:1-13, 24.
Báwo ni ìbéèrè tí ejò béèrè lọ́wọ́ Éfà kò ṣe bá ohun tí Jèhófà wí mu? (Jẹ́n. 3:1-5; 1 Jòh. 5:3)
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo la lè rí kọ́ lára Éfà? (Fílí. 4:8; Ják. 1:14, 15; 1 Jòh. 2:16)
Ọ̀nà wo ni Ádámù àti Éfà kò fi gbà pé àwọn jẹ̀bi? (Jẹ́n. 3:12, 13)
Báwo ni àwọn kérúbù tí Ọlọ́run fi sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì ṣe fi hàn pé àwọn ò kúrò lẹ́yìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ? (Jẹ́n. 3:24)
Ka Ìṣípayá 12:9.
Báwo ni Sátánì ṣe kẹ́sẹ járí tó nínú mímú kí àwọn èèyàn kẹ̀yìn sí àkóso Ọlọ́run? (1 Jòh. 5:19)
Ìtàn 5
Ìgbésí Ayé Líle Koko Bẹ̀rẹ̀
Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Ádámù àti Éfà ní òde ọgbà Édẹ́nì?
Kí ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà, kí ló sì fà á?
Kí nìdí táwọn ọmọ Ádámù àti Éfà fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú?
Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Jèhófà ni, báwo ni ìgbésí ayé ì bá ti rí fún àwọn àtàwọn ọmọ wọn?
Báwo ni ìwà àìgbọràn tí Éfà hù ṣe mú ìnira bá a?
Kí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin méjèèjì àkọ́kọ́ tí Ádámù àti Éfà bí?
Ta ni àwọn ọmọ mìíràn tó wà nínú àwòrán yẹn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:16-23 àti 4:1, 2.
Ipa wo ni ègún tó wà lórí ilẹ̀ ní lórí ìgbésí ayé Ádámù? (Jẹ́n. 3:17-19; Róòmù 8:20, 22)
Kí nìdí tí orúkọ Éfà, tó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Wà Láàyè,” fi bá Éfà mu? (Jẹ́n. 3:20)
Báwo ni Jèhófà ṣe gba ti Ádámù àti Éfà rò, kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀? (Jẹ́n. 3:7, 21)
Ka Ìṣípayá 21:3, 4.
Àwọn nǹkan wo ni wàá fẹ́ kó di “ohun àtijọ́”?
Ìtàn 6
Ọmọ Rere àti Ọmọ Búburú
Iṣẹ́ wo ni Kéènì àti Ébẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe?
Ọrẹ wo ni Kéènì àti Ébẹ́lì mú wá fún Jèhófà?
Kí nìdí tí inú Jèhófà fi dùn sí ọrẹ Ébẹ́lì, kí sì nìdí tí inú rẹ̀ kò fi dùn sí ti Kéènì?
Irú èèyàn wo ni Kéènì yà, ìkìlọ̀ wo sì ni Jèhófà fún un?
Kí ni Kéènì ṣe nígbà tí òun àti àbúrò rẹ̀ nìkan wà lóko?
Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kéènì lẹ́yìn tó pa àbúrò rẹ̀ tán.
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni Jèhófà sọ nípa ipò eléwu tí Kéènì wà? (Jẹ́n. 4:7)
Báwo ni Kéènì ṣe fi irú ẹni tó jẹ́ nínú lọ́hùn-ún hàn? (Jẹ́n. 4:9)
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀? (Jẹ́n. 4:10; Aísá. 26:21)
-
Kí nìdí tí inú fi bí Kéènì gidigidi, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n fún wa lónìí? (Jẹ́n. 4:4, 5; Òwe 14:30; 28:22)
Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé àwa ṣì lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kódà bí gbogbo àwọn ará ilé wa bá kọ Jèhófà sílẹ̀? (Sm. 27:10; Mát. 10:21, 22)
Ka Jòhánù 11:25.
Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú nípa àwọn tó bá kú nítorí òdodo? (Jòh. 5:24)
Ìtàn 7
Ọkùnrin Onígboyà
Kí nìdí tá a fi sọ pé Énọ́kù yàtọ̀?
Kí nìdí táwọn èèyàn nígbà ayé Énọ́kù fi ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan búburú?
Àwọn nǹkan búburú wo làwọn èèyàn ń ṣe? (Wo àwòrán.)
Kí nìdí tí Énọ́kù fi ní láti jẹ́ onígboyà?
Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ń pẹ́ láyé tó nígbà yẹn, ṣùgbọ́n ọdún mélòó ni Énọ́kù lò láyé?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Énọ́kù kú?
Àfikún ìbéèrè:
-
Irú àjọṣe wo ni Énọ́kù ní pẹ̀lú Jèhófà? (Jẹ́n. 5:24)
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ta lẹni tó tíì pẹ́ jù láyé, ọdún mélòó sì lẹni náà lò kó tó kú? (Jẹ́n. 5:27)
Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5.
Báwo ni ipò ayé ṣe burú tó lẹ́yìn tí Énọ́kù kú, báwo ló sì ṣe dà bí ìgbà tiwa yìí? (2 Tím. 3:13)
Ka Hébérù 11:5.
Ànímọ́ wo ni Énọ́kù ní tó fi “wu Ọlọ́run dáadáa,” kí lèyí sì yọrí sí? (Jẹ́n. 5:22)
Ka Júúdà 14, 15.
Báwo làwọn Kristẹni lónìí ṣe lè fara wé ìgboyà Énọ́kù nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ogun Amágẹ́dọ́nì tó ń bọ̀? (2 Tím. 4:2; Héb. 13:6)
Ìtàn 8
Àwọn Òmìrán ní Ayé
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run gbọ́ ọ̀rọ̀ sí Sátánì lẹ́nu?
Kí nìdí tí díẹ̀ lára àwọn áńgẹ́lì fi ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọ̀run tí wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé?
Kí nìdí tí kò fi tọ̀nà pé kí àwọn áńgẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé, kí wọ́n sì da àwọ̀ èèyàn bora?
Kí ni àwọn ọmọ tí àwọn áńgẹ́lì bí wọ̀nyí fi yàtọ̀?
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí, kí ni àwọn ọmọ àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí ṣe nígbà tí wọ́n di òmìrán?
Lẹ́yìn Énọ́kù, èèyàn rere wo ló gbé láyé, kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ràn rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:1-8.
Kí ni Jẹ́nẹ́sísì 6:6 fi hàn nípa ohun tí ìwà wa lè mú bá Jèhófà? (Sm. 78:40, 41; Òwe 27:11)
Ka Júúdà 6.
Kí ni ohun tí àwọn áńgẹ́lì tíkò “dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀” nígbà ayé Nóà rán wá létí rẹ̀ lónìí? (1 Kọ́r. 3:5-9; 2 Pét. 2:4, 9, 10)
Ìtàn 9
Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
Àwọn mélòó ló wà nínú ìdílé Nóà, kí sì ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
Nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ rí wo ni Ọlọ́run sọ pé kí Nóà ṣe, kí sì nìdí?
Kí ni àwọn èèyàn ṣe nígbà tí Nóà sọ fún wọn nípa áàkì náà?
Kí ni Ọlọ́run sọ pé kí Nóà ṣe sí àwọn ẹranko?
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ áàkì náà, kí ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní láti ṣe?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ló mú kí Nóà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ tó ta yọ? (Jẹ́n. 6:9, 22)
Kí ni èrò Jèhófà nípa ìwà ipá, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí mú wa ronú lórí irú eré tá à ń ṣe àti irú eré tá à ń wò? (Jẹ́n. 6:11, 12; Sm. 11:5)
Báwo la ṣe lè ṣe bíi ti Nóà nígbà tí Jèhófà bá tipasẹ̀ ètò rẹ̀ sọ ohun tó yẹ ká ṣe? (Jẹ́n. 6:22; 1 Jòh. 5:3)
Ka Jẹ́nẹ́sísì 7:1-9.
Báwo ni kíkà tí Jèhófà ka Nóà tó jẹ́ èèyàn aláìpé sí olódodo ṣe fún wa níṣìírí lónìí? (Jẹ́n. 7:1; Òwe 10:16; Aísá. 26:7)
Ìtàn 10
Ikún-Omi Ńlá
Kí nìdí tí kò fi ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti wọnú ọkọ̀ náà mọ́ ní gbàrà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀?
Ọ̀sán àti òru mélòó ni Jèhófà fi jẹ́ kí òjò rọ̀, báwo ni omi náà si ṣe kún tó?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọkọ̀ náà bí omi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bo ilẹ̀ ayé?
Ǹjẹ́ àwọn òmìrán yè bọ́ nínú Ìkún-omi náà, kí ló sì gbẹ̀yìn àwọn bàbá wọn?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọkọ̀ náà lẹ́yìn oṣù márùn-ún?
Kí nìdí tí Nóà fí jẹ́ kí ẹyẹ ìwò jáde nínú ọkọ̀ áàkì?
Báwo ni Nóà ṣe mọ̀ pé omi tó wà lórí ilẹ̀ ayé ti gbẹ?
Kí ni Ọlọ́run sọ fún Nóà lẹ́yìn tí òun àti ìdílé rẹ̀ ti wà nínú ọkọ̀ fún ohun tó lé lọ́dún kan?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni ìparun àwọn ohun abẹ̀mí tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe rinlẹ̀ tó? (Jẹ́n. 7:23)
Báwo ló ṣe pẹ́ tó kí Ìkún-omi náà tó lọ sílẹ̀? (Jẹ́n. 7:24)
-
Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 8:17 ṣe fi hàn pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò yí padà? (Jẹ́n. 1:22)
-
Nígbà tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ áńgẹ́lì padà dé ọ̀run, ìdájọ́ wo ni wọ́n gbà? (Júúdà 6)
Báwo ni ìtàn Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe mú ká túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò gba àwọn èèyàn rẹ̀ là? (2 Pét. 2:9)
Ìtàn 11
Òṣùmàrè Àkọ́kọ́
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí, kí ni Nóà ṣe nígbà tó kọ́kọ́ jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì?
Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ lẹ́yìn Ìkún-omi?
Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe?
Nígbà tá a bá rí òṣùmàrè, kí ló yẹ ká máa rántí?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo la ṣe lè mú “òórùn amáratuni” wá fún Jèhófà lónìí? (Jẹ́n. 8:21; Héb. 13:15, 16)
Kí ni Jèhófà rí nínú ọkàn èèyàn, nítorí náà, kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún? (Jẹ́n. 8:21; Mát. 15:18, 19)
-
Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé dá? (Jẹ́n. 9:10, 11)
Títí di ìgbà wo ni májẹ̀mú òṣùmàrè yóò fi wà? (Jẹ́n. 9:16)
Ìtàn 12
Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro
Ta ni Nímírọ́dù, irú ẹni wo ni Ọlọ́run sì kà á sí?
Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe bíríkì gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí?
Kí nìdí tí inú Jèhófà kò fi dùn sí ilé tí wọ́n ń kọ́ yìí?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí wọ́n ṣíwọ́ kíkọ́ ilé gogoro náà?
Orúkọ wo ni wọ́n fi ń pe ìlú náà, kí lorúkọ náà sì túmọ̀ sí?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn náà lẹ́yìn tí Ọlọ́run dà wọ́n lédè rú?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jẹ́nẹ́sísì 10:1, 8-10.
Irú ànímọ́ wo ni Nímírọ́dù ní, ìkìlọ̀ wo sì lèyí jẹ́ fún wa? (Òwe 3:31)
-
Kí nìdí náà gan-an tí wọ́n fi ń kọ́ ilé ìṣọ́ ńlá, kí sì nìdí tí wọn kò fi lè kọ́ ọ parí? (Jẹ́n. 11:4; Òwe 16:18; Jòh. 5:44)
Ìtàn 13
Ábúráhámù—Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Irú àwọn èèyàn wo ló ń gbé ìlú Úrì?
Ta ni ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, ìgbà wo ni wọ́n bí i, ibo ló sì gbé?
Kí ni Ọlọ́run sọ pé kí Ábúráhámù ṣe?
Kí nìdí tí a fi pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
Àwọn wo ló tẹ̀ lé Ábúráhámù nígbà tó fi Úrì sílẹ̀?
Kí ni Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù nígbà tó dé ilẹ̀ Kénáánì?
Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù nígbà tó di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì ṣe jẹ́ síra wọn? (Jẹ́n. 11:27)
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Térà la sọ pé ó kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Kénáánì, báwo la ṣe mọ̀ pé Ábúráhámù ló mú kí wọ́n lọ síbẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? (Jẹ́n. 11:31; Ìṣe 7:2-4)
-
Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá gbòòrò sí i nígbà tí Ábúráhámù dé ilẹ̀ Kénáánì? (Jẹ́n. 12:7)
-
Kí ni Jèhófà yí orúkọ Ábúrámù padà sí nígbà tó di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, kí sì nìdí? (Jẹ́n. 17:5)
Àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú wo ni Jèhófà ṣèlérí fún Sárà? (Jẹ́n. 17:15, 16)
-
Ní Jẹ́nẹ́sísì 18:19, ojúṣe wo la là kalẹ̀ fún àwọn baba? (Diu. 6:6, 7; Éfé. 6:4)
Ìrírí wo ni Sárà ní tó fi hàn pé a ò lè fi ohunkóhun pa mọ́ fún Jèhófà? (Jẹ́n. 18:12, 15; Sm. 44:21)
Ìtàn 14
Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù, báwo ni Ọlọ́run sì ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán, báwo ni Ọlọ́run ṣe dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò?
Kí ni Ábúráhámù ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ìdí tí Ọlọ́run fi pàṣẹ yẹn fún un?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ábúráhámù yọ ọ̀bẹ jáde láti pa ọmọ rẹ̀?
Báwo ni ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ṣe lágbára tó?
Kí ni Ọlọ́run pèsè fún Ábúráhámù láti fi rúbọ, báwo ló sì ṣe pèsè rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí nìdí tí Ábúráhámù fi dá adọ̀dọ́ ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ? (Jẹ́n. 17:10-12; 21:4)
-
Báwo ni Ísákì ṣe fi hàn pé òun tẹrí ba fún Ábúráhámù bàbá rẹ̀, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú kan tó ní ìtumọ̀ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì? (Jẹ́n. 22:7-9; 1 Kọ́r. 5:7; Fílí. 2:8, 9)
Ìtàn 15
Ìyàwó Lọ́ọ̀tì Bójú Wẹ̀yìn
Kí ló fà á tí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì fi pínyà?
Kí nìdí tí Lọ́ọ̀tì fi yàn láti gbé ní Sódómù?
Irú àwọn èèyàn wo làwọn ará Sódómù?
Ìkìlọ̀ wo làwọn áńgẹ́lì méjì kan fún Lọ́ọ̀tì?
Kí nìdí tí aya Lọ́ọ̀tì fi di ọwọ̀n iyọ̀?
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aya Lọ́ọ̀tì?
Àfikún ìbéèrè:
-
Tó bá di pé ká yanjú ìṣòro láàárín ara wa, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára Ábúráhámù? (Jẹ́n. 13:8, 9; Róòmù 12:10; Fílí. 2:3, 4)
-
Báwo ni bí Jèhófà ṣe bá Ábúráhámù lò ṣe mú kó dá wa lójú pé Jèhófà àti Jésù yóò fi òdodo ṣèdájọ́? (Jẹ́n. 18:25, 26; Mát. 25:31-33)
-
Kí ni àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí fi hàn nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀? (Jẹ́n. 19:5, 13; Léf. 20:13)
Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú bí Lọ́ọ̀tì àti Ábúráhámù ṣe tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí sì ni a lè rí kọ́ nínú èyí? (Jẹ́n. 19:15, 16, 19, 20; 22:3)
Ka Lúùkù 17:28-32.
Irú ẹ̀mí wo ni ìyàwó Lọ́ọ̀tì ní sí àwọn nǹkan ìní tara, ọ̀nà wo sì lèyí gbà jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa? (Lúùkù 12:15; 17:31, 32; Mát. 6:19-21, 25)
Ka 2 Pétérù 2:6-8.
Bíi ti Lọ́ọ̀tì, báwo ló ṣe yẹ kí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé aláìṣèfé Ọlọ́run tá à ń gbé yìí rí lára wa? (Ìsík. 9:4; 1 Jòh. 2:15-17)
Ìtàn 16
Ísákì Rí Ìyàwó Rere Fẹ́
Ta ni ọkùnrin àti obìnrin tó wà nínú àwòrán yìí?
Kí ni Ábúráhámù ṣe láti wá ìyàwó fún ọmọ rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
Báwo ni àdúrà ìránṣẹ́ Ábúráhámù ṣe gbà?
Kí ni ìdáhùn Rèbékà nígbà tí wọ́n bi í bóyá ó gbà láti fẹ́ Ísákì?
Kí ló mú kí inú Ísákì padà dun?
Àfikún ìbéèrè:
-
Àwọn ànímọ́ rere wo ni Rèbékà fi hàn nígbà tó pàdé ìránṣẹ́ Ábúráhámù lẹ́bàá kànga? (Jẹ́n. 24:17-20; Òwe 31:17, 31)
Àpẹẹrẹ rere wo ni ètò tí Ábúráhámù ṣe fún Ísákì jẹ́ fún àwọn Kristẹni lónìí? (Jẹ́n. 24:37, 38; 1 Kọ́r. 7:39; 2 Kọ́r. 6:14)
Kí nìdí tó fi yẹ ká wáyè láti máa ṣàṣàrò bíi ti Ísákì? (Jẹ́n. 24:63; Sm. 77:12; Fílí. 4:8)
Ìtàn 17
Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra
Ta ni Ísọ̀ àti Jékọ́bù, báwo ni wọ́n sì ṣe yàtọ̀ síra?
Ọmọ ọdún mélòó ni Ísọ̀ àti Jékọ́bù nígbà tí Ábúráhámù bàbá bàbá wọn kú?
Kí ni Ísọ̀ ṣe tó ba ìyá àti bàbá rẹ̀ nínú jẹ́?
Kí nìdí tí inú fi bí Ísọ̀ gidigidi sí Jékọ́bù èkejì rẹ̀?
Ìtọ́ni wo ni Ísákì fún Jékọ́bù ọmọ rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìbejì tí Rèbékà bí? (Jẹ́n. 25:23)
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ojú tí Jékọ́bù fi ń wo ogún ìbí àti ojú tí Ísọ̀ fi ń wò ó? (Jẹ́n. 25:31-34)
Ka Jẹ́nẹ́sísì 26:34, 35; 27:1-46; àti 28:1-5.
Báwo ló ṣe hàn kedere pé Ísọ̀ ò mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí? (Jẹ́n. 26:34, 35; 27:46)
Kí Jékọ́bù bàa lè rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí ni Ísákì sọ pé kó ṣe? (Jẹ́n. 28:1-4)
Ka Hébérù 12:16, 17.
Kí ni àpẹẹrẹ Ísọ̀ fi hàn nípa ohun tó máa ń jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn tó bá fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ohun mímọ́?
Ìtàn 18
Jékọ́bù Lọ sí Háránì
Ta ni ọmọbìnrin tó wà nínú àwòrán yìí, kí sì ni Jékọ́bù ṣe fún un?
Kí ni Jékọ́bù ṣe tán láti ṣe kó bàa lè fẹ́ Rákélì?
Kí ni Lábánì ṣe nígbà tó tó àkókò fún Jékọ́bù láti gbé Rákélì níyàwó?
Kí ni Jékọ́bù gbà láti ṣe kí Rákélì lè di ìyàwó rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kódà nígbà tí Lábánì tan Jékọ́bù, báwo ni Jékọ́bù ṣe fi hàn pé èèyàn iyì lòun, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí? (Jẹ́n. 25:27; 29:26-28; Mát. 5:37)
Báwo ni àpẹẹrẹ Jékọ́bù ṣe fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ìfẹ́ gidi àti ìfẹ́ onígbòónára lásán? (Jẹ́n. 29:18, 20, 30; Orin Sól. 8:6)
Àwọn obìnrin mẹ́rin wo ló di ara ìdílé Jékọ́bù tí wọ́n sì bímọ fún un nígbà tó yá? (Jẹ́n. 29:23, 24, 28, 29)
Ìtàn 19
Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá
Kí lorúkọ àwọn ọmọ mẹ́fà tí Léà, ìyàwó àkọ́kọ́ Jékọ́bù bí fún un?
Kí lorúkọ àwọn ọmọ méjì tí Sílípà, ìránṣẹ́bìnrin Léà bí fun Jékọ́bù?
Kí lorúkọ àwọn ọmọ méjì tí Bílíhà, ìránṣẹ́bìnrin Rákélì bí fún Jékọ́bù?
Àwọn ọmọ méjì wo ni Rákélì bí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó bí ọmọ kejì?
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán, ọmọ mélòó ni Jékọ́bù bí, kí ló sì ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ wọn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jẹ́nẹ́sísì 29:32-35; 30:1-26; àti 35:16-19.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ọ̀ràn àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Jékọ́bù bí, báwo ni wọ́n ṣe sábà máa ń sọ àwọn ọmọkùnrin Hébérù lórúkọ láyé ìgbàanì?
Ka Jẹ́nẹ́sísì 37:35.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dínà nìkan ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀, báwo la ṣe mọ̀ pé Jékọ́bù ní ju ọmọbìnrin kan lọ? (Jẹ́n. 37:34, 35)
Ìtàn 20
Dínà Kó Sínú Ìjàngbọ̀n
Kí nìdí tí Ábúráhámù àti Ísákì kò fi fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn fẹ́ àwọn ará Kénáánì?
Ǹjẹ́ ó dùn mọ́ Jékọ́bù nínú pé ọmọbìnrin rẹ̀ yan àwọn ọmọbìnrin Kénáánì lọ́rẹ̀ẹ́?
Ta ni ọkùnrin tó ń wo Dínà nínú àwòrán yẹn, ohun búburú wo ló sì ṣe?
Nígbà tí Síméónì àti Léfì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dínà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, kí ni wọ́n ṣe?
Ǹjẹ́ Jékọ́bù fara mọ́ ìwà tí Síméónì àti Léfì hù yìí?
Báwo ni gbogbo ìjàngbọ̀n tí ìdílé yìí kó sí ṣe bẹ̀rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Ṣé ẹ̀ẹ̀kanlọ́gbọ̀n ni Dínà máa ń lọ bá àwọn ọmọbìnrin Kénáánì ṣeré? Ṣàlàyé. (Jẹ́n. 34:1)
Kí ló mú kí Dínà jẹ̀bí dé àyè kan lórí bó ṣe pàdánù ipò wúńdíá rẹ̀? (Gál. 6:7)
) Báwo làwọn ọ̀dọ́ lónìí ṣe lè fi hàn pé àwọn ti fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà ṣàríkọ́gbọ́n? (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33; 1 Jòh. 5:19)
Ìtàn 21
Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Kórìíra Rẹ̀
Kí nìdí táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù fi ń jowú rẹ̀, kí sì ni wọ́n ṣe?
Kí làwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù fẹ́ ṣe fún un, ṣùgbọ́n kí ni Rúbẹ́nì sọ?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn oníṣòwò ará Íṣímáẹ́lì dé?
Kí làwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe kí bàbá wọn bàa lè rò pé Jósẹ́fù ti kú?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù tẹ́nì kan bá hùwà àìtọ́ nínú ìjọ? (Jẹ́n. 37:2; Léf. 5:1; 1 Kọ́r. 1:11)
Kí ló mú káwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù hùwà tí ò dáa sí i? (Jẹ́n. 37:11, 18; Òwe 27:4; Ják. 3:14-16)
Kí ni Jékọ́bù ṣe tó jẹ́ ara ohun tẹ́ni tó ń ṣọ̀fọ̀ sábà máa ń ṣe? (Jẹ́n. 37:35)
Ìtàn 22
Wọ́n Ju Jósẹ́fù Sẹ́wọ̀n
Ọmọ ọdún mélòó ni Jósẹ́fù nígbà tí wọ́n mú un lọ sí Íjíbítì, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó débẹ̀?
Kí ló mú Jósẹ́fù dèrò ẹ̀wọ̀n?
Ojúṣe wo ni wọ́n fún Jósẹ́fù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n?
Nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n, kí ló ṣe fún agbọ́tí àti ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún Fáráò?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dá agbọ́tí sílẹ̀ lẹ́wọ̀n?
Àfikún ìbéèrè:
-
Níwọ̀n bí kò ti sí òfin Ọlọ́run kankan lákọsílẹ̀ tó sọ pé ìwà panṣágà kò dára nígbà ayé Jósẹ́fù, kí ló mú kí Jósẹ́fù sá kúrò lọ́dọ̀ aya Pọ́tífárì? (Jẹ́n. 2:24; 20:3; 39:9)
-
Ní ṣókí, sọ àlá tí agbọ́tí lá àti ìtumọ̀ tí Jèhófà fún Jósẹ́fù. (Jẹ́n. 40:9-13)
Àlá wo ni ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún ọba lá, kí ló sì túmọ̀ sí? (Jẹ́n. 40:16-19)
Báwo ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù lónìí? (Jẹ́n. 40:8; Sm. 36:9; Jòh. 17:17; Ìṣe 17:2, 3)
Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 40:20 ṣe jẹ́ ká mọ ìdí táwọn Kristẹni kì í fi í ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí? (Oníw. 7:1; Máàkù 6:21-28)
Ìtàn 23
Àwọn Àlá Fáráò
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Fáráò ní òru ọjọ́ kan?
Kí ló mú kí agbọ́tí náà rántí Jósẹ́fù lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
Gẹ́gẹ́ bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, àlá méjì wo ni Fáráò lá?
Kí ni Jósẹ́fù sọ pé àwọn àlá náà túmọ̀ sí?
Báwo ni Jósẹ́fù ṣe di ẹni tí ipò rẹ̀ ga jù ní Íjíbítì tá a bá yọwọ́ Fáráò?
Kí ló mú káwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù wá sí Íjíbítì, kí sì nìdí tí wọn ò fi dá a mọ̀?
Àlá wo ni Jósẹ́fù rántí, kí sì nìyẹn jẹ́ kó mọ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Jósẹ́fù ṣe gbé ògo fún Jèhófà, báwo sì ni àwọn Kristẹni ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lónìí? (Jẹ́n. 41:16, 25, 28; Mát. 5:16; 1 Pét. 2:12)
Báwo ni àwọn ọdún ọ̀pọ̀ tí àwọn ọdún ọ̀dá tẹ̀ lé ní Íjíbítì ṣe dà bí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn Jèhófà lónìí àti ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? (Jẹ́n. 41:29, 30; Ámósì 8:11, 12)
Ka Jẹ́nẹ́sísì 42:1-8 àti 50:20.
Ǹjẹ́ ó lòdì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti forí balẹ̀ fún èèyàn nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fún ipò tí ẹni yẹn wà, tó bá jẹ́ pé àṣà àdúgbò náà nìyẹn? (Jẹ́n. 42:6)
Ìtàn 24
Jósẹ́fù Dán Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ Wò
Kí ló fà á tí Jósẹ́fù fi fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé amí ni wọ́n?
Kí ló mú Jékọ́bù gbà pé kí wọ́n mú Bẹ́ńjámínì àbíkẹ́yìn rẹ̀ lọ sí Íjíbítì?
Báwo ni ife fàdákà Jósẹ́fù ṣe dé inú àpò Bẹ́ńjámínì?
Kí ni Júdà gbà láti ṣe kí wọ́n lè tú Bẹ́ńjámínì sílẹ̀?
Ìyípadà wo ló ti bá ìwà àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù?
Àfikún ìbéèrè:
-
Ẹ̀kọ́ rere wo làwọn tó ní ẹrù iṣẹ́ nínú ètò Jèhófà lónìí lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ ní Jẹ́nẹ́sísì 42:18? (Neh. 5:15; 2 Kọ́r. 7:1, 2)
-
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rúbẹ́nì ni àkọ́bí, báwo ló ṣe hàn pé Júdà ló di agbẹnusọ fáwọn arákùnrin rẹ̀? (Jẹ́n. 43:3, 8, 9; 44:14, 18; 1 Kíró. 5:2)
Báwo ni Jósẹ́fù ṣe dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wo, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? (Jẹ́n. 43:33, 34)
-
Gẹ́gẹ́ bí ara ọgbọ́n tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ò fi ní í dá a mọ̀, ta ni Jósẹ́fù pe ara rẹ̀? (Jẹ́n. 44:5, 15; Léf. 19:26)
Báwo làwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe fi hàn pé wọn ò ní ẹ̀mí owú tí wọ́n ní sí àbúrò wọn tẹ́lẹ̀ mọ́? (Jẹ́n. 44:13, 33, 34)
Ìtàn 25
Ìdílé Náà Ṣí Lọ sí Íjíbítì
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù fi ara rẹ̀ han àwọn arákùnrin rẹ̀?
Kí ni Jósẹ́fù fi àánú bá àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ?
Kí ni Fáráò sọ nígbà tó gbọ́ nípa àwọn arákùnrin Jósẹ́fù?
Báwo ni ìdílé Jékọ́bù ṣe tóbi tó nígbà tí wọ́n ṣí lọ sí Íjíbítì?
Kí la wá ń pe ìdílé Jékọ́bù báyìí, kí sì ló fà á?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni ìtàn Bíbélì nípa Jósẹ́fù ṣe fi hàn pé Jèhófà lè yí ohun táwọn èèyàn gbèrò láti fi ṣe ìpalára fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà sí ohun tó lè ṣe wọ́n láǹfààní? (Jẹ́n. 45:5-8; Aísá. 8:10; Fílí. 1:12-14)
-
Kí ni Jèhófà fi dá Jékọ́bù lójú nígbà tó ń lọ sí Íjíbítì? (Jẹ́n. 46:1-4)
Ìtàn 26
Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọlọ́run
Ta ni Jóòbù?
Kí ni Sátánì gbìyànjú láti ṣe, ǹjẹ́ ó kẹ́sẹ járí?
Kí ni Jèhófà fàyè gba Sátánì láti ṣe, kí sì nìdí?
Kí nìdí tí ìyàwó Jóòbù fi sọ fún un pé kó ‘bú Ọlọ́run kó sì kú’? (Wo àwòrán.)
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe lè rí i nínú àwòrán kejì, báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Jóòbù, kí sì nìdí?
Bí àwa náà bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bíi ti Jóòbù, ìbùkún wo la óò rí gbà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóòbù 1:1-22.
Báwo ni Kristẹni ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóòbù lónìí? (Jóòbù 1:1; Fílí. 2:15; 2 Pét. 3:14)
Ka Jóòbù 2:1-13.
Ọ̀nà tó yàtọ̀ síra wo ni Jóòbù àti ìyàwó rẹ̀ gbà hùwà nígbà tí Sátánì ń ṣenúnibíni sí wọn? (Jóòbù 2:9, 10; Òwe 19:3; Míkà 7:7; Mál. 3:14)
Ka Jóòbù 42:10-17.
Ìbáradọ́gba wo ló wà láàárín èrè tí Jóòbù gbà àti ohun tí Jésù gbà nítorí pé wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà délẹ̀délẹ̀? (Jóòbù 42:12; Fílí. 2:9-11)
Báwo ni ìbùkún tí Jóòbù rí gbà nítorí pé ó pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run ṣe jẹ́ orísun ìṣírí fún wa? (Jóòbù 42:10, 12; Héb. 6:10; Ják. 1:2-4, 12; 5:11)
Ìtàn 27
Ọba Búburú Kan Jẹ ní Íjíbítì
Ta ni ọkùnrin tó mú ẹgba dání nínú àwòrán yẹn, ta ló sì ń nà?
Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Kí nìdí tí ẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ará Íjíbítì?
Àṣẹ wo ni Fáráò pa fún àwọn obìnrin tó ń gbẹ̀bí fún àwọn obìnrin Ísírẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 1:6-22.
Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ fún Ábúráhámù? (Ẹ́kís. 1:7; Jẹ́n. 12:2; Ìṣe 7:17)
Báwo ni àwọn obìnrin Hébérù tó ń gbẹ̀bí ṣe fi hàn pé àwọn ka ẹ̀mí sí ohun iyebíye? (Ẹ́kís. 1:17; Jẹ́n. 9:6)
Báwo ni a ṣe san èrè fún àwọn agbẹ̀bí náà nítorí ṣíṣe tí wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà? (Ẹ́kís. 1:20, 21; Òwe 19:17)
Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti mú kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe nípa Irú-Ọmọ Ábúráhámù tó ṣèlérí forí ṣánpọ́n? (Ẹ́kís. 1:22; Mát. 2:16)
Ìtàn 28
Bá A Ṣe Gba Mósè Ọmọ Ọwọ́ Là
Ọmọ kékeré wo ló wà nínú àwòrán yìí, ìka ta ló sì dì mú yẹn?
Kí ni ìyá Mósè ṣe kí wọ́n má bàa pa Mósè?
Ta ni ọmọbìnrin kékeré tó wà nínú àwòrán yẹn, kí ló sì ṣe?
Nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò rí ọmọ kékeré náà, àbá wo ni Míríámù dá?
Kí ni ọmọbìnrin ọba náà sọ fún ìyá Mósè?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 2:1-10.
Àǹfààní wo ni ìyá Mósè ní tó fi lè tọ́ Mósè tó sì kọ́ ọ nígbà ọmọ ọwọ́, àpẹẹrẹ wo sì lèyí jẹ́ fún àwọn òbí lónìí? (Ẹ́kís. 2:9, 10; Diu. 6:6-9; Òwe 22:6; Éfé. 6:4; 2 Tím. 3:15)
Ìtàn 29
Ìdí Tí Mósè Fi Sá Lọ
Ibo ni Mósè tí dàgbà, ṣùgbọ́n kí ni Mósè mọ̀ nípa àwọn òbí rẹ̀?
Kí ni Mósè ṣe nígbà tó pé ọmọ ogójì ọdún?
Kí ni Mósè sọ fún ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jà, báwo sì ni ẹni náà ṣe fèsì?
Kí nìdí tí Mósè fi sá kúrò ní Íjíbítì?
Ibo ni Mósè sá lọ, ta ló sì bá pàdé níbẹ̀?
Kí ni Mósè ṣe fún ogójì ọdún lẹ́yìn tó sá kúrò ní Íjíbítì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 2:11-25.
Láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí Mósè fi kọ́ ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì sí, báwo ni Mósè ṣe fi hàn pé òun dúró ṣinṣin ti Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀? (Ẹ́kís. 2:11, 12; Héb. 11:24)
Ka Ìṣe 7:22-29.
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí Mósè ṣe ń gbìyànjú láti fúnra rẹ̀ yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ará Íjíbítì? (Ìṣe 7:23-25; 1 Pét. 5:6, 10)
Ìtàn 30
Igbó Tí Ń Jó
Kí ni orúkọ òkè tó wà nínú àwòrán yìí?
Sọ ohun àrà mérìíyìírí tí Mósè rí nígbà tó kó àwọn àgùntàn rẹ̀ lọ síbi òkè náà.
Kí ni ohùn kan sọ láti inú igbó tó ń jó náà, ohùn ta sì ni?
Kí ni Mósè sọ nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó lọ kó àwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò ní Íjíbítì?
Kí ni Ọlọ́run sọ pé kí Mósè sọ bí àwọn èèyàn náà bá bi í léèrè pé ta ló rán an?
Kí ni Mósè yóò ṣe láti fi hàn pé Ọlọ́run ló rán òun?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 3:1-22.
Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè ṣe ki wá láyà pé bí a bá tiẹ̀ rò pé a ò tóótun láti ṣe iṣẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n yàn fún wa, Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn? (Ẹ́kís. 3:11, 13; 2 Kọ́r. 3:5, 6)
Ka Ẹ́kísódù 4:1-20.
Ìyàtọ̀ wo ló wáyé nínú ìṣesí Mósè láàárín ogójì ọdún tó lò ní Mídíánì, ẹ̀kọ́ wo sì ni àwọn tó ń fẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ lè rí kọ́ látinú èyí? (Ẹ́kís. 2:11, 12; 4:10, 13; Míkà 6:8; 1 Tím. 3:1, 6, 10)
Kódà bí ètò Jèhófà bá bá wa wí, ìgbọ́kànlé wo ni àpẹẹrẹ Mósè lè mú ká ní? (Ẹ́kís. 4:12-14; Sm. 103:14; Héb. 12:4-11)
Ìtàn 31
Mósè àti Áárónì Lọ Rí Fáráò
Kí ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Mósè àti Áárónì ṣe mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà?
Kí ni Mósè àti Áárónì sọ fún Fáráò, kí sì ni ìdáhùn Fáráò?
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Áárónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀?
Báwo ni Jèhófà ṣe kọ́ Fáráò lọ́gbọ́n, kí sì ni Fáráò ṣe?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyọnu kẹwàá?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 4:27-31 àti 5:1-23.
Kí ni Fáráò ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Èmi kò mọ Jèhófà rárá”? (Ẹ́kís. 5:2; 1 Sám. 2:12; Róòmù 1:21)
-
Ọ̀nà wo ni Jèhófà ò gbà sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù? (Ẹ́kís. 3:13, 14; 6:3; Jẹ́n. 12:8)
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè rò pé òun kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún òun, síbẹ̀ òun ni Ọlọ́run fi iṣẹ́ náà rán, kí lèyí kọ́ wa? (Ẹ́kís. 6:12, 30; Lúùkù 21:13-15)
Ka Ẹ́kísódù 7:1-13.
Bí Mósè àti Áárónì ṣe fi ìgboyà kéde ìdájọ́ tí Ọlọ́run fi rán wọn sí Fáráò, àpẹẹrẹ wo ni wọ́n fi lélẹ̀ fún àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí? (Ẹ́kís. 7:2, 3, 6; Ìṣe 4:29-31)
Báwo ni Jèhófà ṣe fi àjùlọ han àwọn òrìṣà Íjíbítì? (Ẹ́kís. 7:12; 1 Kíró. 29:12)
Ìtàn 32
Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá
Lo àwòrán tó wà níbí láti fi ṣàlàyé ìyọnu mẹ́ta àkọ́kọ́ tí Jèhófà mú wá sórí Íjíbítì.
Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyọnu mẹ́ta àkọ́kọ́ àtàwọn ìyọnu yòókù?
Kí ni ìyọnu kẹrin, ìkarùn-ún àti ìkẹfà?
Sọ ìtàn ìyọnu keje, ìkẹjọ àti ìkẹsàn-án.
Kí ni Jèhófà sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kí ìyọnu kẹwàá tó wáyé?
Kí ni ìyọnu kẹwàá, kí ló sì ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e?
Àfikún ìbéèrè:
-
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún àwọn pidánpidán Íjíbítì láti ṣe ohun tó jọ ìyọnu méjì àkọ́kọ́ tí Jèhófà mú wá sórí Íjíbítì, kí ni wọ́n gbà tipátipá lẹ́yìn ìyọnu kẹta? (Ẹ́kís. 8:18, 19; Mát. 12:24-28)
Báwo ni ìyọnu kẹrin ṣe fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, kí sì ni mímọ̀ tá a mọ èyí máa mú káwa èèyàn Ọlọ́run fi sọ́kàn bí “ìpọ́njú ńlá” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ṣe ń sún mọ́lé? (Ẹ́kís. 8:22, 23; Ìṣí. 7:13, 14; 2 Kíró. 16:9)
Ka Ẹ́kísódù 8:24; 9:3, 6, 10, 11, 14, 16, 23-25; àti 10:13-15, 21-23.
Oríṣi àwùjọ èèyàn méjì wo ni Ìyọnu Mẹ́wàá náà fi hàn pé ó wà, ojú wo ló sì yẹ kí èyí mú ká máa fi wo àwọn àwùjọ méjèèjì náà? (Ẹ́kís. 8:10, 18, 19; 9:14)
Báwo ni Ẹ́kísódù 9:16 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí Jèhófà fi gbà kí Sátánì ṣì wà títí di ìsinsìnyí? (Róòmù 9:21, 22)
-
Báwo ni Ìrékọjá ṣe mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti rí ìgbàlà, kí sì ni Ìrékọjá náà ń tọ́ka sí? (Ẹ́kís. 12:21-23; Jòh. 1:29; Róòmù 5:18, 19, 21; 1 Kọ́r. 5:7)
Ìtàn 33
Líla Òkun Pupa Kọjá
Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mélòó, ló fi Íjíbítì sílẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé, àwọn wo ló sì tún bá wọn lọ?
Báwo ló ṣe rí lára Fáráò lẹ́yìn tó ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lọ, kí ló sì ṣe?
Kí ni Jèhófà ṣe láti dá àwọn ará Íjíbítì dúró kí wọ́n má bàa kọ lu àwọn èèyàn rẹ̀?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Mósè na ọ̀pá rẹ̀ sórí Òkun Pupa, kí sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ará Íjíbítì sáré lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú Òkun Pupa?
Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé inú àwọn dùn àti pé àwọn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó gba àwọn là?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Jèhófà ṣe rí i pé àwọn ará Íjíbítì san àsanpadà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí gbogbo ọdún tí wọ́n ti fi mú wọn lẹ́rú? (Ẹ́kís. 3:21, 22; 12:35, 36)
Ka Ẹ́kísódù 14:1-31.
Báwo ni ọ̀rọ̀ Mósè tó wà lákọọ́lẹ̀ ní Ẹ́kísódù 14:13, 14 á ṣe kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní nígbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá dé? (2 Kíró. 20:17; Sm. 91:8)
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa kọrin ìyìn sí i? (Ẹ́kís. 15:1, 2; Sm. 105:2, 3; Ìṣí. 15:3, 4)
Nígbà tí Míríámù àtàwọn obìnrin tó kù yin Jèhófà ní ẹ̀bá Òkun Pupa, àpẹẹrẹ wo ni wọ́n fi lélẹ̀ fún àwọn obìnrin Kristẹni lónìí? (Ẹ́kís. 15:20, 21; Sm. 68:11)
Ìtàn 34
Irú Oúnjẹ Tuntun Kan
Kí ni àwọn èèyàn ń kó nílẹ̀ nínú àwòrán yìí, kí sì ni wọ́n ń pè é?
Ìtọ́ni wo ni Mósè fún àwọn èèyàn náà nípa kíkó mánà?
Kí ni Jèhófà sọ pé kí àwọn èèyàn náà ṣe ní ọjọ́ kẹfà, kí sì nìdí?
Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jèhófà ṣe nígbà tí wọ́n tọ́jú mánà pa mọ́ di ọjọ́ keje?
Báwo ni àkókò tí Jèhófà fi fi mánà bọ́ àwọn èèyàn yẹn ṣe gùn tó?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 16:1-36 àti Númérì 11:7-9.
Gẹ́gẹ́ bí Ẹ́kísódù 16:8 ṣe fi hàn, kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Ọlọ́run yàn sípò nínú ìjọ Kristẹni? (Héb. 13:17)
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, kí ló ń rán wọn létí lójoojúmọ́ pé ó yẹ kí wọ́n gbára lé Jèhófà? (Ẹ́kís. 16:14-16, 35; Diu. 8:2, 3)
Kí ni ìtumọ̀ tó jẹ́ àpẹẹrẹ tí Jésù fún mánà, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní nínú “oúnjẹ tí ó ti ọ̀run wá”? (Jòh. 6:31-35, 40)
Ka Jóṣúà 5:10-12.
Ọdún mélòó ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jẹ mánà, báwo lèyí ṣe dán wọn wò, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú ìtàn yìí? (Ẹ́kís. 16:35; Núm. 11:4-6; 1 Kọ́r. 10:10, 11)
Ìtàn 35
Jèhófà Fún Wọn Ní Òfin Rẹ̀
Ní nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ibo ni wọ́n pàgọ́ sí?
Kí ni Jèhófà sọ pé òun fẹ́ kí àwọn èèyàn náà máa ṣe, kí sì ni ìdáhùn wọn?
Kí nìdí tí Jèhófà fi fún Mósè ní wàláà òkúta méjì?
Yàtọ̀ sí Òfin Mẹ́wàá, àwọn òfin mìíràn wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Òfin méjì wo ni Jésù Kristi sọ pé ó tóbi jù?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 19:1-25; 20:1-21; 24:12-18; àti 31:18.
Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà ní Ẹ́kísódù 19:8 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìyàsímímọ́ Kristẹni ń béèrè? (Mát. 16:24; 1 Pét. 4:1-3)
Ka Diutarónómì 6:4-6; Léfítíkù 19:18; àti Mátíù 22:36-40.
Báwo làwọn Kristẹni ṣe máa ń fi ìfẹ́ wọn hàn sí Ọlọ́run àti aládùúgbò? (Máàkù 6:34; Ìṣe 4:20; Róòmù 15:2)
Ìtàn 36
Ère Ọmọ Màlúù Oníwúrà
Nínú àwòrán, kí ni àwọn èèyàn yìí ń ṣe, kí sì nìdí?
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú, kí sì ni Mósè ṣe nígbà tó rí ohun táwọn èèyàn náà ń ṣe?
Kí ni Mósè sọ fún àwọn kan lára àwọn ọkùnrin pé kí wọ́n ṣe?
Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kí ìtàn yìí kọ́ wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 32:1-35.
Báwo ni ìtàn yìí ṣe jẹ́ ká rí ojú tí Jèhófà fi ń wo dída ìjọsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́? (Ẹ́kís. 32:4-6, 10; 1 Kọ́r. 10:7, 11)
Kí ló yẹ kí àwọn Kristẹni ṣọ́ra fún tí wọ́n bá ń yan eré ìnàjú tí wọ́n fẹ́ fi gbádùn ara wọn, irú bí orin àti ijó? (Ẹ́kís. 32:18, 19; Éfé 5:15, 16; 1 Jòh. 2:15-17)
Báwo ni ẹ̀yà Léfì ṣe fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ lórí ọ̀ràn dídúró gbọn-in lórí ohun tó jẹ́ òdodo? (Ẹ́kís. 32:25-28; Sm. 18:25)
Ìtàn 37
Àgọ́ Kan fún Ìjọsìn
Kí ni wọ́n ń pe ilé tó wà nínú àwòrán yìí, kí sì ni wọ́n ń lò ó fún?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Mósè pé kó kọ́ àgọ́ náà lọ́nà tí yóò fi rọrùn láti tú u palẹ̀?
Kí ni àpótí tó wà nínú yàrá kékeré ní ìkángun àgọ́ náà, kí ló sì wà nínú àpótí náà?
Ta ni Jèhófà yàn láti jẹ́ àlùfáà àgbà, kí sì ni iṣẹ́ àlùfáà àgbà?
Dárúkọ ohun mẹ́ta tó wà nínú yàrá ńlá inú àgọ́ náà.
Àwọn nǹkan méjì wo ló wà nínú àgbàlá àgọ́ náà, kí sì ni wọ́n ń lò wọ́n fún?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́kísódù 25:8-40; 26:1-37; 27:1-8; àti 28:1.
Kí ni àwọn kérúbù tó wà lórí “àpótí gbólóhùn ẹ̀rí náà” dúró fún? (Ẹ́kís. 25:20, 22; Núm. 7:89; 2 Ọba 19:15)
Ka Ẹ́kísódù 30:1-10, 17-21; 34:1, 2; àti Hébérù 9:1-5.
Kí nìdí tí Jèhófà fi tẹnu mọ́ ọn fún àwọn àlùfáà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ náà pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa jẹ́ kí ara wọn wà ní mímọ́, ọ̀nà wo ló sì yẹ ká gbà fi ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ sílò lónìí? (Ẹ́kís. 30:18-21; 40:30, 31; Héb. 10:22)
Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé àgọ́ ìjọsìn yẹn ò wúlò mọ́ àti pé májẹ̀mú Òfin náà ti kásẹ̀ nílẹ̀ ní àkókò tó kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni? (Héb. 9:1, 9; 10:1)
Ìtàn 38
Àwọn Amí Méjìlá
Kí lo ṣàkíyèsí nípa ìdìpọ̀ èso àjàrà tó wà nínú àwòrán yìí, ibo ló sì ti wá?
Kí nìdí tí Mósè fi rán àwọn amí méjìlá lọ sí ilẹ̀ Kénáánì?
Kí ni àwọn amí mẹ́wàá sọ nígbà tí wọ́n ń jábọ̀ fún Mósè?
Báwo ni àwọn amí méjì ṣe fi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà hàn, kí sì lorúkọ wọn?
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú, kí sì ló sọ fún Mósè?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 13:1-33.
Àwọn wo ni Mósè yàn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, àǹfààní ńlá wo ni wọ́n sì ní? (Núm. 13:2, 3, 18-20)
Kí nìdí tí èrò Jóṣúà àti Kálébù fi yàtọ̀ sí ti àwọn amí tó kù, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa? (Núm. 13:28-30; Mát. 17:20; 2 Kọ́r. 5:7)
Ka Númérì 14:1-38.
Ìkìlọ̀ wo nípa ríráhùn sí àwọn tó ń ṣojú fún Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé ló yẹ ká gbà? (Núm. 14:2, 3, 27; Mát. 25:40, 45; 1 Kọ́r. 10:10)
Báwo ni Númérì 14:24 ṣe fi hàn pé Jèhófà fi ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sọ́kàn? (1 Ọba 19:18; Òwe 15:3)
Ìtàn 39
Ọ̀pá Áárónì Yọ Òdòdó
Àwọn wo ló ta ko àṣẹ Mósè àti Áárónì, kí sì ni wọ́n sọ sí Mósè?
Kí ni Mósè sọ pé kí Kórà àtàwọn ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe?
Kí ni Mósè sọ fún àwọn èèyàn, kí ló sì ṣẹlẹ̀ ní kété tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Kórà àti àwọn ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
Kí ni Élíásárì, ọmọ Áárónì fi àwo tùràrí àwọn ọkùnrin tó kú náà ṣe, kí sì nìdí?
Kí nìdí tí Jèhófà fi mú kí ọ̀pá Áárónì yọ òdòdó? (Wo àwòrán.)
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 16:1-49.
Kí ni Kórà àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe, kí sì nìdí tó fi jẹ́ ìṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà? (Núm. 16:9, 10, 18; Léf. 10:1, 2; Òwe 11:2)
Èrò tí kò tọ̀nà wo ni Kórà àti àwọn ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá “ìjòyè àpéjọ” ní? (Núm. 16:1-3; Òwe 15:33; Aísá. 49:7)
-
Kí ni yíyọ tí ọ̀pá Áárónì yọ òdòdó fi hàn, kí sì nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí wọ́n fi pa mọ́ sínú àpótí ẹ̀rí? (Núm. 17:5, 8, 10)
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ ọ̀pá Áárónì tó yọ òdòdó? (Núm. 17:10; Ìṣe 20:28; Fílí. 2:14; Héb. 13:17)
Ìtàn 40
Mósè Lu Àpáta
Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù?
Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ráhùn lé lórí nígbà tí wọ́n pàgọ́ sí Kádéṣì?
Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè omi fáwọn èèyàn náà àtàwọn ẹran wọn?
Nínú àwòrán yìí, ta ni ọkùnrin tó ń nàka sí ara rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú sí Mósè àti Áárónì, ìyà wo ló sì fi jẹ wọ́n?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lórí Òkè Hórì, ta sì ló di àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 20:1-13, 22-29 àti Diutarónómì 29:5.
Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù? (Diu. 29:5; Mát. 6:31; Héb. 13:5; Ják. 1:17)
Ojú wo ni Jèhófà fi wo bí Mósè àti Áárónì ṣe kùnà láti yà á sí mímọ́ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Núm. 20:12; 1 Kọ́r. 10:12; Ìṣí. 4:11)
Kí la rí kọ́ látinú bí Mósè ṣe gba ìbáwí tí Jèhófà fún un? (Núm. 12:3; 20:12, 27, 28; Diu. 32:4; Héb. 12:7-11)
Ìtàn 41
Ejò Bàbà
Nínú àwòrán tó ò ń wò yìí, kí ló wé mọ́ ara òpó yìí, kí sì nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí Mósè gbé e kọ́ síbẹ̀?
Báwo ni àwọn èèyàn náà ṣe fi hàn pé aláìmoore làwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn?
Kí làwọn èèyàn náà sọ pé kí Mósè ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà ti rán ejò olóró sí wọn láti fìyà jẹ wọ́n?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí Mósè ṣe ejò bàbà?
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 21:4-9.
Ìkìlọ̀ wo la rí nínú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ráhùn nípa àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún wọn? (Núm. 21:5, 6; Róòmù 2:4)
Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lo ejò bàbà, kí sì ni Hesekáyà Ọba ṣe? (Núm. 21:9; 2 Ọba 18:1-4)
Ka Jòhánù 3:14, 15.
Báwo ni gbígbé ejò bàbà kọ́ sórí òpó igi ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe kan Jésù Kristi mọ́gi? (Gál. 3:13; 1 Pét. 2:24)
Ìtàn 42
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kan Sọ̀rọ̀
Ta ni Bálákì, kí sì nìdí tó fi ránṣẹ́ pe Báláámù?
Kí nìdí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù fi dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà?
Kí ni Báláámù gbọ́ tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ń sọ?
Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún Báláámù?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Báláámù ń gbìyànjú láti ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 21:21-35.
Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn ará Ámórì àti Ógù ọba Báṣánì? (Núm. 21:21, 23, 33, 34)
Ka Númérì 22:1-40.
Kí ló mú kí Báláámù gbìyànjú láti gbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣépè, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí? (Núm. 22:16, 17; Òwe 6:16, 18; 2 Pét. 2:15; Júúdà 11)
Ka Númérì 23:1-30.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Báláámù sọ̀rọ̀ bí ẹni pé Jèhófà ló ń jọ́sìn, báwo ni ìwà rẹ̀ ṣe fi hàn pé kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà? (Núm. 23:3, 11-14; 1 Sám. 15:22)
Ka Númérì 24:1-25.
Báwo ni ìtàn Bíbélì yìí ṣe mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìmúṣẹ àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe túbọ̀ lágbára? (Núm. 24:10; Aísá. 54:17)
Ìtàn 43
Jóṣúà Di Aṣáájú
Nínú àwòrán yìí, àwọn wo làwọn ọkùnrin méjì tó dúró ti Mósè yẹn?
Kí ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà?
Kí nìdí tí Mósè fi gun orí Òkè Nébò, kí sì ni Jèhófà sọ fún un?
Ẹni ọdún mélòó ni Mósè nígbà tó kú?
Kí ló ba àwọn èèyàn náà nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ló tún múnú wọn dùn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Númérì 27:12-23.
Iṣẹ́ bàǹtà-banta wo ni Jèhófà gbé fún Jóṣúà, kí ló sì fi hàn pé Jèhófà ń bójú tó àwọn èèyàn Rẹ̀ lónìí? (Núm. 27:15-19; Ìṣe 20:28; Héb. 13:7)
-
Kí nìdí tí Jèhófà kò fi gba Mósè àti Áárónì láyè láti sọdá sí Ilẹ̀ Ìlérí, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa? (Diu. 3:25-27; Núm. 20:12, 13)
-
Báwo ni ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí Jèhófà fún un? (Diu. 31:6-8, 23)
-
Ipa wo ló yẹ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lórí ìgbésí ayé wa? (Diu. 32:47; Léf. 18:5; Héb. 4:12)
-
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè kò fi ojúyòójú rí Jèhófà, kí ni Diutarónómì 34:10 sọ nípa àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà? (Ẹ́kís. 33:11, 20; Núm. 12:8)
Ìtàn 44
Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
Ibo ni Ráhábù ń gbé?
Ta ni àwọn ọkùnrin méjì tó wà nínú àwòrán yẹn, kí sì nìdí tí wọ́n fi wá sí Jẹ́ríkò?
Kí ni ọba Jẹ́ríkò pàṣẹ pé kí Ráhábù ṣe, kí sì ni Ráhábù sọ?
Báwo ni Ráhábù ṣe ran àwọn ọkùnrin méjì náà lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni òun náà sì sọ pé kí wọ́n ṣe fún òun?
Ìlérí wo làwọn amí náà ṣe fún Ráhábù?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 2:1-24.
Báwo ni ìlérí Jèhófà tó wà nínú Ẹ́kísódù 23:28 ṣe ní ìmúṣẹ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ gbógun ja Jẹ́ríkò? (Jóṣ. 2:9-11)
Ka Hébérù 11:31.
Báwo ni àpẹẹrẹ Ráhábù ṣe fi hàn pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì? (Róòmù 1:17; Héb. 10:39; Ják. 2:25)
Ìtàn 45
Bí Wọ́n Ṣe La Odò Jọ́dánì Kọjá
Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jèhófà ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bàa lè la Odò Jọ́dánì kọjá?
Kí ni ohun tó gba ìgbàgbọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó sọdá Odò Jọ́dánì?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí Jóṣúà ṣa òkúta méjìlá jọ látinú odò náà?
Kí ló ṣẹlẹ̀ gẹ́rẹ́ táwọn àlùfáà jáde kúrò nínú Odò Jọ́dánì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 3:1-17.
Bí àkọsílẹ̀ yìí ṣe fi hàn, kí ló yẹ ká ṣe bá a bá fẹ́ rí ìrànlọ́wọ́ àti ìbùkún Jèhófà gbà? (Jóṣ. 3:13, 15; Òwe 3:5; Ják. 2:22, 26)
Báwo ni Odò Jọ́dánì ṣe rí nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá sí Ilẹ̀ Ìlérí, báwo sì ni èyí ṣe gbé orúkọ Jèhófà ga? (Jóṣ. 3:15; 4:18; Sm. 66:5-7)
Ka Jóṣúà 4:1-18.
Kí nìdí tí wọ́n fi kó òkúta méjìlá látinú Odò Jọ́dánì tí wọ́n sì tò ó sí Gílígálì? (Jóṣ. 4:4-7)
Ìtàn 46
Odi Jẹ́ríkò
Kí ni Jèhófà sọ pé káwọn ọkùnrin tó ń jagun àtàwọn àlùfáà ṣe fún ọjọ́ mẹ́fà?
Kí ni àwọn ọkùnrin náà ní láti ṣe ní ọjọ́ keje?
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí odi Jẹ́ríkò?
Kí nìdí tí wọ́n fi so okùn pupa rọ̀ sójú fèrèsé?
Kí ni Jóṣúà sọ pé kí àwọn ọkùnrin tó ń jagun ṣe sí àwọn èèyàn àti ìlú náà, ṣùgbọ́n kí ni kí wọ́n ṣe sí fàdákà, wúrà, bàbà àti irin?
Kí ni Mósè sọ pé kí àwọn amí méjì náà ṣe?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 6:1-25.
Báwo ni yíyan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan yí ká Jẹ́ríkò ní ọjọ́ keje ṣe fara jọ iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí? (Jóṣ. 6:15, 16; Aísá. 60:22; Mát. 24:14; 1 Kọ́r. 9:16)
Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Jóṣúà 6:26 ṣe ṣẹ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, kí sì ni èyí kọ́ wa nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà? (1 Ọba 16:34; Aísá. 55:11)
Ìtàn 47
Olè Kan ní Ísírẹ́lì
Nínú àwòrán yìí, ta ni ọ̀gbẹ́ni tó ń ri àwọn ohun iyebíye tó kó láti Jẹ́ríkò mọ́lẹ̀ yẹn, àwọn wo ló sì ń ràn án lọ́wọ́?
Kí nìdí tí ohun tí Ákánì àti ìdílé rẹ̀ ṣe fi burú gan-an?
Kí ni Jèhófà sọ nígbà tí Jóṣúà béèrè ìdí tí àwọn ará Áì fi ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá wọn jà?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ákánì àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí wọ́n kó wọn wá síwájú Jóṣúà?
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni ìdájọ́ tó wá sórí Ákánì kọ́ wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 7:1-26.
Kí ni àdúrà Jóṣúà fi hàn nípa àjọṣe tó wà láàárín òun àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀? (Jóṣ. 7:7-9; Sm. 119:145; 1 Jòh. 5:14)
Kí ni àpẹẹrẹ Ákánì fi hàn, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa? (Jóṣ. 7:11, 14, 15; Òwe 15:3; 1 Tím 5:24; Héb. 4:13)
Ka Jóṣúà 8:1-29.
Kí ni ojúṣe tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní sí ìjọ Kristẹni lónìí? (Jóṣ. 7:13; Léf. 5:1; Òwe 28:13)
Ìtàn 48
Àwọn Ará Gíbéónì Ọlọgbọ́n
Báwo làwọn ará Gíbéónì ṣe yàtọ̀ sáwọn ará Kénáánì tó wà láwọn ìlú tó wà nítòsí?
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí làwọn ará Gíbéónì ṣe, kí sì nìdí?
Ìlérí wo ni Jóṣúà àtàwọn aṣáájú Ísírẹ́lì ṣe fún àwọn ará Gíbéónì, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n mọ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọba ìlú yòókù gbọ́ pé àwọn ará Gíbéónì ti bá àwọn ará Ísírẹ́lì ṣàdéhùn àlàáfíà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 9:1-27.
Níwọ̀n bí Jèhófà ti sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti “pa gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà rẹ́,” àwọn ànímọ́ wo ni dídá tí Jèhófà dá àwọn ará Gíbéónì sí fi hàn pé Jèhófà ní? (Jóṣ. 9:22, 24; Mát. 9:13; Ìṣe 10:34, 35; 2 Pét. 3:9)
Bí Jóṣúà ṣe dúró lórí májẹ̀mú tó bá àwọn ará Gíbéónì dá, àpẹẹrẹ rere wo ló fi lélẹ̀ fún àwa Kristẹni lónìí? (Jóṣ. 9:18, 19; Mát. 5:37; Éfé 4:25)
Ka Jóṣúà 10:1-5.
Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá lónìí ṣe ń fara wé àwọn ará Gíbéónì, kí ló wá ń ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí ìyẹn? (Jóṣ. 10:4; Sek. 8:23; Mát. 25:35-40; Ìṣí. 12:17)
Ìtàn 49
Oòrùn Dúró Sójú Kan
Kí ni Jóṣúà ń sọ nínú àwòrán yìí, kí sì nìdí?
Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jóṣúà àtàwọn jagunjagun rẹ̀ lọ́wọ́?
Àwọn ọba mélòó ni Jóṣúà ṣẹ́gun, ó sì gbà á tó ọdún mélòó?
Kí nìdí tí Jóṣúà fi pín ilẹ̀ Kénáánì?
Ẹni ọdún mélòó ni Jóṣúà nígbà tó kú, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn náà lẹ́yìn ìgbà yẹn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jóṣúà 10:6-15.
Kí ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà mú kí oòrùn àti òṣùpá dúró sójú kan fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dá wa lójú lónìí? (Jóṣ. 10:8, 10, 12, 13; Sm. 18:3; Òwe 18:10)
Ka Jóṣúà 12:7-24.
Ta lẹni náà gan-an tó mú kó ṣeé ṣe láti ṣẹ́gun àwọn ọba mọ́kànlélọ́gbọ̀n ní Kénáánì, kí sì nìdí tí mímọ̀ tá a mọ èyí fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí? (Jóṣ. 12:7; 24:11-13; Diu. 31:8; Lúùkù 21:9, 25-28)
Ka Jóṣúà 14:1-5.
Báwo ni wọ́n ṣe pín ilẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, kí sì ni èyí ń fi hàn nípa ogún tá a máa rí gbà ní Párádísè? (Jóṣ. 14:2; Aísá. 65:21; Ìsík. 47:21-23; 1 Kọ́r. 14:33)
-
Gẹ́gẹ́ bí Jóṣúà ṣe ṣe ní Ísírẹ́lì, ta ló ń dènà ìpẹ̀yìndà lónìí? (Oníd. 2:8, 10, 11; Mát. 24:45-47; 2 Tẹs 2:3-6; Títù 1:7-9; Ìṣí. 1:1; 2:1, 2)
Ìtàn 50
Àwọn Obìnrin Méjì Tó Nígboyà
Àwọn wo ni àwọn onídàájọ́, kí sì lorúkọ díẹ̀ nínú wọn?
Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni Dèbórà ní, kí sì nìyẹn ní nínú?
Nígbà tí Jábínì Ọba àti Sísérà olórí ọmọ ogun rẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọ̀rọ̀ Jèhófà wo ni Dèbórà sọ fún Bárákì Onídàájọ́, ta sì ni Dèbórà sọ pé ó máa gba ìyìn ohun tó máa ṣẹlẹ̀?
Báwo ni Jáẹ́lì ṣe fi hàn pé onígboyà obìnrin ni òun?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Jábínì Ọba?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe mú ìbínú Jèhófà wá sórí ara wọn, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí? (Oníd. 2:20; Òwe 3:1, 2; Ìsík. 18:21-23)
-
Báwo ni àwọn obìnrin Kristẹni lónìí ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbàgbọ́ àti ìgboyà látinú àpẹẹrẹ Dèbórà àti Jáẹ́lì? (Oníd. 4:4, 8, 9, 14, 21, 22; Òwe 31:30; 1 Kọ́r. 16:13)
-
Báwo ni a ṣe lè lo orin ìṣẹ́gun tí Bárákì àti Dèbórà kọ gẹ́gẹ́ bí àdúrà nípa ogun Amágẹ́dọ́nì tó ń bọ̀? (Oníd. 5:3, 31; 1 Kíró. 16:8-10; Ìṣí. 7:9, 10; 16:16; 19:19-21)
Ìtàn 51
Rúùtù àti Náómì
Báwo ni Náómì ṣe dé ilẹ̀ Móábù?
Ta ni Rúùtù àti Ópà?
Kí ni Rúùtù àti Ópà ṣe nígbà tí Náómì sọ fún wọn pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wọn?
Ta ni Bóásì, báwo ló sì ṣe ran Rúùtù àti Náómì lọ́wọ́?
Kí lorúkọ ọmọ tí Bóásì àti Rúùtù bí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká rántí rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Rúùtù 1:1-17.
Ọ̀rọ̀ dáadáa wo ni Rúùtù sọ tó fi hàn pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? (Rúùtù 1:16, 17)
Báwo ni èrò Rúùtù ṣe jọ ìṣesí àwọn “àgùntàn mìíràn” sí àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé lónìí? (Jòh. 10:16; Sek. 8:23)
Ka Rúùtù 2:1-23.
Àpẹẹrẹ rere wo ni Rúùtù fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́bìnrin lónìí? (Rúùtù 2:17, 18; Òwe 23:22; 31:15)
Ka Rúùtù 3:5-13.
Ojú wo ni Bóásì fi wo bí Rúùtù ṣe yọ̀ǹda láti fẹ́ ẹ dípò kó fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan?
Kí ni ìṣesí Rúùtù kọ́ wa nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? (Rúùtù 3:10; 1 Kọ́r. 13:4, 5)
Ka Rúùtù 4:7-17.
Báwo làwọn ọkùnrin Kristẹni lónìí ṣe lè dà bíi Bóásì? (Rúùtù 4:9, 10; 1 Tím. 3:1, 12, 13; 5:8)
Ìtàn 52
Gídíónì àti Ọ̀ọ́dúnrún Ọkùnrin Rẹ̀
Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe wà nínú wàhálà púpọ̀ gan-an, kí sì nìdí?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Gídíónì pé àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti pọ̀ jù?
Àwọn ọkùnrin mélòó ló kù lẹ́yìn tí Gídíónì sọ pé kí gbogbo àwọn tó ń bẹ̀rù padà sílé?
Wo àwòrán kí o sì ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe dín iye àwọn ọmọ ogun Gídíónì kù sí ọ̀ọ́dúnrún péré.
Báwo ni Gídíónì ṣe pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà, báwo sì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni Gídíónì ṣe láti rí àrídájú ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà?
Báwo la ṣe ń mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà lónìí? (Òwe 2:3-6; Mát. 7:7-11; 2 Tím. 3:16, 17)
-
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ṣe wà lójúfò àti bí àwọn kan kò ṣe wà lójúfò? (Oníd. 7:3, 6; Róòmù 13:11, 12; Éfé. 5:15-17)
Bí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwo Gídíónì, báwo la ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwo Gídíónì Títóbi Jù náà, Jésù Kristi? (Oníd. 7:17; Mát. 11:29, 30; 28:19, 20; 1 Pét. 2:21)
Báwo ni ohun tá a rí kà nínú Àwọn Onídàájọ́ 7:21 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí a ó fi jẹ́ kí ibikíbi tí Jèhófà bá yàn wá sí láti sìn nínú ètò rẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn? (1 Kọ́r. 4:2; 12:14-18; Ják. 4:10)
-
Nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín àwa àti arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Gídíónì gbà yanjú aáwọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Éfúráímù? (Òwe 15:1; Mát. 5:23, 24; Lúùkù 9:48)
Ìtàn 53
Ìlérí Jẹ́fútà
Ta ni Jẹ́fútà, ìgbà wo sì ló gbé ayé?
Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe fún Jèhófà?
Kí nìdí tí inú Jẹ́fútà fi bà jẹ́ nígbà tó ń padà bọ̀ láti ibi tó ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì?
Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà sọ nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí tí bàbá rẹ̀ ṣe?
Kí nìdí táwọn èèyàn fi nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin Jẹ́fútà?
Àfikún ìbéèrè:
-
Nínú àkọsílẹ̀ nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ìkìlọ̀ wo ló yẹ ká kíyè sí ká sì máa tẹ̀ lé? (Oníd. 10:6, 15, 16; Róòmù 15:4; Ìṣí 2:10)
Ka Àwọn Onídàájọ́ 11:1-11, 29-40.
Báwo la ṣe mọ̀ pé fífi tí Jẹ́fútà fi ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe “ọrẹ ẹbọ sísun” kò túmọ̀ sí pé ó fi ọmọ náà rúbọ nínú iná? (Oníd. 11:31; Léf. 16:24; Diu. 18:10, 12)
Ọ̀nà wo ni Jẹ́fútà gbà fi ọmọbìnrin rẹ̀ rúbọ?
Kí la rí kọ́ nínú ọwọ́ tí Jẹ́fútà fi mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ sí Jèhófà? (Oníd. 11:35, 39; Oníw. 5:4, 5; Mát. 16:24)
Báwo ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni nínú ọ̀ràn wíwá bí ọwọ́ wọn ṣe máa tẹ ọ̀kan lára onírúurú apá tí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pín sí? (Oníd. 11:36; Mát. 6:33; Fílí. 3:8)
Ìtàn 54
Ọkùnrin Tó Lágbára Jù Lọ
Kí ni orúkọ ọkùnrin tó lágbára jù lọ nínú àwọn ẹni tó tíì gbé ayé rí, ta ló sì fún un lágbára?
Nígbà kan, kí ni Sámúsìnì ṣe fún kìnnìún ńlá kan bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí?
Àṣírí wo ni Sámúsìnì ń sọ fún Dẹ̀lílà nínú àwòrán yìí, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ káwọn Filísínì rí i mú?
Báwo ni Sámúsìnì ṣe mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kú nínú àwọn Filísínì ọ̀tá lọ́jọ́ tí òun fúnra rẹ̀ kú?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn òbí lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́? (Oníd. 13:8; Sm. 127:3; Éfé. 6:4)
Ka Àwọn Onídàájọ́ 14:5-9 àti 15:9-16.
Nínu ìtàn bí Sámúsìnì ṣe pa kìnnìún, bó ṣe já okùn tuntun tí wọ́n fi dè é, àti bó ṣe fi egungun páárì akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa ẹgbẹ̀rún èèyàn, kí la rí kọ́ nípa bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́?
Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí? (Oníd. 14:6; 15:14; Sek. 4:6; Ìṣe 4:31)
-
Báwo ni ẹgbẹ́ búburú ṣe nípa lórí Sámúsìnì, kí la sì lè rí kọ́ nínú èyí? (Oníd. 16:18, 19; 1 Kọ́r. 15:33)
Ìtàn 55
Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run
Kí ni orúkọ ọmọkùnrin kékeré tó wà nínú àwòrán yìí, ta sì ni àwọn tó tún wà níbẹ̀?
Àdúrà wo ni Hánà gbà lọ́jọ́ kan nígbà tó lọ sínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, báwo sì ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀?
Ọmọ ọdún mélòó ni Sámúẹ́lì nígbà tí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà láti máa sìn, kí sì ni ìyá rẹ̀ máa ń ṣe fún un lọ́dọọdún?
Kí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Élì, irú èèyàn wo sì ni wọ́n?
Báwo ni Jèhófà ṣe pe Sámúẹ́lì, kí sì ni Ó sọ fún un?
Kí ni Sámúẹ́lì dì nígbà tó dàgbà, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó darúgbó?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Ẹlikénà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn olórí ìdílé nínú ọ̀ràn ṣíṣáájú ìdílé wọn nínú ìjọsìn tòótọ́? (1 Sám. 1:3, 21; Mát. 6:33; Fílí. 1:10)
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára Hánà nígbà tá a bá ń bójú tó ìṣòro tó fẹ́ pinni lẹ́mìí? (1 Sám. 1:10, 11; Sm. 55:22; Róòmù 12:12)
-
Báwo ni Élì ṣe bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Jèhófà lọ, báwo sì ni èyí ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa? (1 Sám. 2:22-24, 27, 29; Diu. 21:18-21; Mát. 10:36, 37)
-
Ìròyìn ìbànújẹ́ mẹ́rin wo ni ẹnì kan mú wá láti ojú ogun, kí sì ni èyí yọrí sí fún Élì?
Ka 1 Sámúẹ́lì 8:4-9.
Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ Jèhófà gidigidi, báwo la sì ṣe lè ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn láìyẹsẹ̀ lónìí? (1 Sám. 8:5, 7; Jòh. 17:16; Ják. 4:4)
Ìtàn 56
Sọ́ọ̀lù—Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì
Kí ni Sámúẹ́lì ń ṣe nínú àwòrán yìí, kí sì nìdí rẹ̀?
Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ràn Sọ́ọ̀lù, irú èèyàn wo sì ni Sọ́ọ̀lù?
Kí lorúkọ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, kí sì ni ọmọkùnrin náà ṣe?
Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi rúbọ dípò kó dúró de Sámúẹ́lì láti wá rú u?
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn Sọ́ọ̀lù?
Àfikún ìbéèrè:
Ka 1 Sámúẹ́lì 9:15-21 àti 10:17-27.
Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí kò fi hùwà òmùgọ̀ nígbà tí àwọn ọkùnrin kan ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa rẹ̀? (1 Sám. 9:21; 10:21, 22, 27; Òwe 17:27)
-
Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Sọ́ọ̀lù dá ní Gílígálì? (1 Sám. 10:8; 13:8, 9, 13)
-
Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wo ni Sọ́ọ̀lù dá nínú ọ̀ràn Ágágì ọba Ámálékì? (1 Sám. 15:2, 3, 8, 9, 22)
Àwíjàre wo ni Sọ́ọ̀lù wí fún ohun tó ṣe báwo ló sì ṣe gbìyànjú láti yí ẹ̀bi kúrò lórí ara rẹ̀? (1 Sám. 15:24)
Ìkìlọ̀ wo ló yẹ ká kọbi ara sí lónìí nígbà tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn? (1 Sám. 15:19-21; Sm. 141:5; Òwe 9:8, 9; 11:2)
Ìtàn 57
Ọlọ́run Yan Dáfídì
Kí lorúkọ ọ̀dọ́mọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, báwo la sì ṣe mọ̀ pé onígboyà ni?
Ibo ni Dáfídì ń gbé, kí sì ni orúkọ bàbá rẹ̀ àti bàbá bàbá rẹ̀?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Sámúẹ́lì pé kó lọ sí ilé Jésè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésè mú méje lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá fún Sámúẹ́lì?
Nígbà tí wọ́n mú Dáfídì wọlé, kí ni Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe fi ìgboyà tí Dáfídì ní àti bó ṣe gbára lé Jèhófà hàn kedere? (1 Sám. 17:37)
-
Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 16:7 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe ojúsàájú àti ẹ̀tanú sáwọn èèyàn torí ìrísí wọn? (Ìṣe 10:34, 35; 1 Tím. 2:4)
Báwo ni àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé tí Jèhófà bá mú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kúrò lára ẹnì kan, ẹ̀mí búburú lè rọ́pò rẹ̀ tàbí kó máa ṣe ẹni náà bíi kó sáà máa hùwàkiwà? (1 Sám. 16:14; Mát. 12:43-45; Gál. 5:16)
Ìtàn 58
Dáfídì àti Gòláyátì
Kí ni Gòláyátì pe ẹgbẹ́ ogun Ísírẹ́lì níjà láti ṣe?
Báwo ni Gòláyátì ṣe tóbi tó, ẹ̀bùn wo ni Sọ́ọ̀lù Ọba sì ṣèlérí pé òun á fún ẹni tó bá pa Gòláyátì?
Kí ni Dáfídì sọ nígbà tí Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé kò lè bá Gòláyátì jà nítorí Dáfídì ṣì kéré?
Báwo ni Dáfídì ṣe fi ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà hàn nígbà tó fún Gòláyátì lésì?
Bó o ṣe rí i nínú àwòrán, kí ni Dáfídì fi pa Gòláyátì, kí sì ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn Filísínì lẹ́yìn náà?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ló fà á tí Dáfídì kò fi bẹ̀rù, báwo la sì ṣe lè fara wé ìgboyà rẹ̀? (1 Sám. 17:37, 45; Éfé. 6:10, 11)
Kí nìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ yàgò fún ẹ̀mí ìbánidíje bíi ti Gòláyátì nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ìdárayá? (1 Sám. 17:8; Gál. 5:26; 1 Tím. 4:8)
Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run á ti òun lẹ́yìn? (1 Sám. 17:45-47; 2 Kíró. 20:15)
Dípò tí àkọsílẹ̀ yìí ì bá fi sọ ìtàn ogun tó wáyé láàárín ẹgbẹ́ ogun méjì, báwo ló ṣe fi hàn pé ìjà náà jẹ́ láàárín àwọn ọlọ́run èké àti Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà? (1 Sám. 17:43, 46, 47)
Báwo ni àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ṣe ń fara wé Dáfídì nínú ọ̀ràn gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà? (1 Sám. 17:37; Jer. 1:17-19; Ìṣí 12:17)
Ìtàn 59
Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ
Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi ń jowú Dáfídì, ṣùgbọ́n báwo ni Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù ṣe yàtọ̀?
Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan nígbà tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù?
Kí ni Sọ́ọ̀lù sọ pé Dáfídì gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè fi Míkálì ọmọbìnrin òun ṣe aya, kí sì nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
Nígbà tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí?
Báwo ni Míkálì ṣe gba ẹ̀mí Dáfídì là, kí sì ni Dáfídì ní láti ṣe fún ọdún méje?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni ìfẹ́ tí okùn rẹ̀ yi tó wà láàárín Jónátánì àti Dáfídì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn “àgùntàn mìíràn” àti “agbo kékeré”? (1 Sám. 18:1; Jòh. 10:16; Lúùkù 12:32; Sek. 8:23)
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì ló yẹ kó jogún ìtẹ́ Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀, báwo ni 1 Sámúẹ́lì 18:4 ṣe fi hàn pé Jónátánì ní ìtẹríba tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ẹni tí Jèhófà yàn pé kó jẹ́ ọba?
Báwo ni àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé owú jíjẹ lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ìkìlọ̀ wo nìyẹn sì jẹ́ fún wa? (1 Sám. 18:7-9, 25; Ják. 3:14-16)
-
Báwo ní Jónátánì ṣe fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nígbà tó lọ bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀? (1 Sám. 19:1, 4-6; Òwe 16:14)
Ìtàn 60
Ábígẹ́lì àti Dáfídì
Kí ni orúkọ obìnrin tó ń bọ̀ wá pàdé Dáfídì nínú àwòrán yìí, irú èèyàn wo sì ni?
Ta ni Nábálì?
Kí nìdí tí Dáfídì fi rán díẹ̀ nínú àwọn èèyàn rẹ̀ sí Nábálì fún ìrànlọ́wọ́?
Kí ni Nábálì sọ sáwọn èèyàn Dáfídì, kí sì ni Dáfídì ṣe?
Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe fi hàn pé ọlọgbọ́n obìnrin ni òun?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni àwọn ará ilé Dáfídì ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí àwa tá a para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ara Kristẹni máa ran ara wa lọ́wọ́? (Òwe 17:17; 1 Tẹs. 5:14)
-
Kí nìdí tí Ìwé Mímọ́ fi ṣàpèjúwe Nábálì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tí kò wúlò? (1 Sám. 25:2-5, 10, 14, 21, 25)
Kí ni àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni lónìí lè rí kọ́ lára Ábígẹ́lì? (1 Sám. 25:32, 33; Òwe 31:26; Éfé. 5:24)
Àwọn ohun búburú méjì wo ni Ábígẹ́lì kò jẹ́ kí Dáfídì ṣe? (1 Sám. 25:31, 33; Róòmù 12:19; Éfé. 4:26)
Báwo ni nǹkan tí Dáfídì ṣe sí ohun tí Ábígẹ́lì sọ ṣe lè ran àwọn ọkùnrin lọ́wọ́ lónìí láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn obìnrin wò wọ́n? (Ìṣe 21:8, 9; Róòmù 2:11; 1 Pét. 3:7)
Ìtàn 61
Wọ́n Fi Dáfídì Jọba
Kí ni Dáfídì àti Ábíṣáì ṣe nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń sùn nínú àgọ́ rẹ̀?
Ìbéèrè wo ni Dáfídì bi Sọ́ọ̀lù?
Ibo ni Dáfídì lọ lẹ́yìn tó kúrò lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù?
Kí ló ba Dáfídì lọ́kàn jẹ́ tó fi ṣe àkọsílẹ̀ orin arò kan?
Ẹni ọdún mélòó ni Dáfídì nígbà tí wọ́n fi jọba ní Hébúrónì, kí sì ni orúkọ díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀?
Ibo ni Dáfídì ti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba níkẹyìn?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú 1 Sámúẹ́lì 26:11 fi hàn nípa irú ojú tó fi ń wo ètò tí Ọlọ́run ṣe? (Sm. 37:7; Róòmù 13:2)
Tá a bá ṣe ẹnì kan lóore àmọ́ tó jẹ́ pé ibi ló fi san án fún wa, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú 1 Sámúẹ́lì 26:23 ṣe lè ran wá lọ́wọ́ láti máa ní èrò tó tọ́? (1 Ọba 8:32; Sm. 18:20)
Ka 2 Sámúẹ́lì 1:26.
Báwo làwọn Kristẹni lónìí ṣe lè ní “ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ẹnì kìíní-kejì” bí irú èyí tí Dáfídì àti Jónátánì ní síra wọn? (1 Pét. 4:8; Kól. 3:14; 1 Jòh. 4:12)
-
Ọdún mélòó ni Dáfídì fi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, ọ̀nà mélòó sì ni iye ọdún tó fi ṣàkóso náà pín sí? (2 Sám. 5:4, 5)
Ta ni Bíbélì fi hàn pé ó mú kí Dáfídì di ẹni ńlá, kí sì ni èyí rán wa létí rẹ̀ lónìí? (2 Sám. 5:10; 1 Sám. 16:13; 1 Kọ́r. 1:31; Fílí. 4:13)
Ìtàn 62
Wàhálà Nínú Ilé Dáfídì
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín sí ilẹ̀ Kénáánì?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà tí Dáfídì wà lórí òrùlé ààfin rẹ̀?
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí Dáfídì?
Nínú àwòrán, ta ni Jèhófà rán láti sọ fún Dáfídì nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí sì ni ọkùnrin náà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì?
Wàhálà wo ló bá Dáfídì?
Lẹ́yìn Dáfídì, ta ló di ọba Ísírẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe jẹ́ ààbò fún wa?
Báwo ni Dáfídì ṣe kó sínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ìkìlọ̀ wo nìyẹn sì jẹ́ fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí? (2 Sám. 11:2; Mát. 5:27-29; 1 Kọ́r. 10:12; Ják. 1:14, 15)
-
Ẹ̀kọ́ wo làwọn alàgbà àtàwọn òbí lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Nátánì gbà fún Dáfídì nímọ̀ràn? (2 Sám. 12:1-4; Òwe 12:18; Mát. 13:34)
Kí nìdí tí Jèhófà fi fi àánú hàn sí Dáfídì? (2 Sám. 12:13; Sm. 32:5; 2 Kọ́r. 7:9, 10)
Ìtàn 63
Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì
Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Sólómọ́nì, báwo ni Sólómọ́nì sì ṣe dáhùn?
Nítorí pé ìdáhùn Sólómọ́nì tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, kí ni Jèhófà ṣèlérí láti fún un?
Ìṣòro ńlá wo làwọn obìnrin méjì kan mú tọ Sólómọ́nì wá?
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe lè rí i nínú àwòrán yìí, báwo ni Sólómọ́nì ṣe yanjú ìṣòro náà?
Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, kí sì nìdí?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí ni àwọn ọkùnrin tí iṣẹ́ àbójútó nínú ètò Ọlọ́run wà níkàáwọ́ wọn lónìí lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí Sólómọ́nì sọ nínú 1 Àwọn Ọba 3:7? (Sm. 119:105; Òwe 3:5, 6)
Báwo ni ohun tí Sólómọ́nì béèrè pé kí Ọlọ́run fún òun ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tó dára láti béèrè nígbà tá a bá ń gbàdúrà? (1 Ọba 3:9, 11; Òwe 30:8, 9; 1 Jòh. 5:14)
Ìgbọ́kànlé wo ni ọ̀nà tí Sólómọ́nì gbà yanjú aáwọ̀ àwọn obìnrin méjì náà mú ká ní nínú àkóso tí Sólómọ́nì Títóbi Jù náà, Jésù Kristi máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? (1 Ọba 3:28; Aísá. 9:6, 7; 11:2-4)
-
Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn ìbéèrè Sólómọ́nì pé kó fún òun ní ọkàn ìgbọràn? (1 Ọba 4:29)
Tá a bá fi bí àwọn èèyàn ṣe sapá láti gbọ́ nípa ọgbọ́n Sólómọ́nì wò ó, ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (1 Ọba 4:29, 34; Jòh. 17:3; 2 Tím. 3:16)
Ìtàn 64
Sólómọ́nì Kọ́ Tẹ́ńpìlì
Báwo ló ṣe pẹ́ Sólómọ́nì tó kó tó parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, kí sì nìdí tí owó tó ná wọn fi pọ̀ gan-an?
Yàrá ńlá mélòó ló wà nínú tẹ́ńpìlì náà, kí sì ni wọ́n gbé sínú wọn?
Kí ni Sólómọ́nì sọ nínú àdúrà tó gbà nígbà tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí?
Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé inú òun dùn sí àdúrà Sólómọ́nì?
Kí ni àwọn ìyàwó Sólómọ́nì tì í ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì?
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú sí Sólómọ́nì, kí sì ni Jèhófà sọ fún un?
Àfikún ìbéèrè:
-
Pẹ̀lú irú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú 1 Kíróníkà 28:9, 10, kí ló yẹ ká máa sapá láti ṣe lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé wa? (Sm. 19:14; Fílí. 4:8, 9)
-
Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fi hàn pé kò sí ilé kankan téèyàn fọwọ́ kọ́ tó lè gba Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo Jù Lọ? (2 Kíró. 6:18; Ìṣe 17:24, 25)
Kí ni ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ nínú 2 Kíróníkà 6:32, 33 fi hàn nípa Jèhófà? (Ìṣe 10:34, 35; Gál. 2:6)
Ka 2 Kíróníkà 7:1-5.
Bíi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n rí ògo Jèhófà tí wọ́n sì fi ìyìn fún Jèhófà, tí àwa náà bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀, kí ló yẹ kí èyí sún wa ṣe? (2 Kíró. 7:3; Sm. 22:22; 34:1; 96:2)
-
Báwo ni ọ̀nà tí Sólómọ́nì gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ ṣe jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ títí dópin? (1 Ọba 11:4, 9; Mát. 10:22; Ìṣí. 2:10)
Ìtàn 65
Ìjọba Náà Pín sí Méjì
Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin méjì tó wà nínú àwòrán yìí, ta sì ni wọ́n?
Kí ni Áhíjà ṣe sí aṣọ tó wà lọ́rùn rẹ̀, kí sì ni ìtumọ̀ ohun tó ṣe yẹn?
Kí ni Sólómọ́nì gbìyànjú láti ṣe sí Jèróbóámù?
Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi fi Jèróbóámù jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá?
Kí nìdí tí Jèróbóámù fi ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà méjì, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ yẹn nígbà tó yá?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọba ẹ̀yà méjì àti tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù?
Àfikún ìbéèrè:
-
Irú èèyàn wo ni Jèróbóámù, kí sì ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún un tó bá pa òfin Ọlọ́run mọ́? (1 Ọba 11:28, 38)
-
Látinú àpẹẹrẹ búburú Rèhóbóámù, kí làwọn òbí àtàwọn alàgbà lè rí kọ́ nípa àṣìlò agbára? (1 Ọba 12:13; Oníw. 7:7; 1 Pét. 5:2, 3
Ta ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ tọ̀ lọ lónìí fún ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbọ́kàn lé bí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé? (1 Ọba 12:6, 7; Òwe 1:8, 9; 2 Tím. 3:16, 17; Héb. 13:7)
Kí ló sún Jèróbóámù láti dá ibi ìjọsìn méjì sílẹ̀ fún ère ọmọ màlúù oníwúrà, báwo lèyí sì ṣe fi hàn pé kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà rárá? (1 Ọba 11:37; 12:26-28)
Ta ló ṣíwájú àwọn èèyàn tó wà ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá láti kẹ̀yìn sí ìjọsìn tòótọ́? (1 Ọba 12:32, 33)
Ìtàn 66
Jésíbẹ́lì—Ayaba Búburú
Ta ni Jésíbẹ́lì?
Kí ló ba Áhábù Ọba lọ́kàn jẹ́ lọ́jọ́ kan?
Kí ni Jésíbẹ́lì ṣe kó bàa lè gba ọgbà àjàrà Nábótì fún Áhábù ọkọ rẹ̀?
Ta ni Jèhófà rán láti fìyà jẹ Jésíbẹ́lì?
Gẹ́gẹ́ bó o ṣe lè rí i nínú àwòrán, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jéhù dé sí ààfin Jésíbẹ́lì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka 1 Àwọn Ọba 16:29-33 àti 18:3, 4.
Báwo ni nǹkan ṣe burú tó ní Ísírẹ́lì nígbà ìṣàkóso Áhábù Ọba? (1 Ọba 14:9)
-
Báwo ni Nábótì ṣe jẹ́ onígboyà tó sì dúró ṣinṣin lórí ohun tí Jèhófà fẹ́? (1 Ọba 21:1-3; Léf. 25:23-28)
Látinú àpẹẹrẹ Áhábù, kí la rí kọ́ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn ṣe tó bá rí ìjákulẹ̀? (1 Ọba 21:4; Róòmù 5:3-5)
-
Kí la lè rí kọ́ látinú ìtara tí Jéhù fi ṣe ìfẹ́ Jèhófà? (2 Ọba 9:4-10; 2 Kọ́r. 9:1, 2; 2 Tím. 4:2)
Ìtàn 67
Jèhóṣáfátì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Ta ni Jèhóṣáfátì, ìgbà wo ló sì gbé ayé?
Kí ló mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ni ọ̀pọ̀ nínú wọn sì ṣe?
Ìdáhùn wo ni Jèhófà fún Jèhóṣáfátì?
Kí ni Jèhófà mú kó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ogun náà?
Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ lára Jèhóṣáfátì?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Jèhóṣáfátì ṣe fi ohun tó yẹ kí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe hàn nígbà tí wọ́n bá wà nínú ipò tó ń dáyà jáni? (2 Kíró. 20:12; Sm. 25:15; 62:1)
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò tíì sígbà kan tí Jèhófà ò ní ọ̀nà tó ń lò láti bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀nà wo ló ń lò láti bá wa sọ̀rọ̀ lónìí? (2 Kíró. 20:14, 15; Mát. 24:45-47; Jòh. 15:15)
Nígbà tí Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” báwo ni ọ̀rọ̀ wa ṣe máa dà bíi ti Jèhóṣáfátì? (2 Kíró. 20:15, 17; 32:8; Ìṣí. 16:14, 16)
Bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn míṣọ́nnárì ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Léfì, ipa wo ni wọ́n ń kó lónìí nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jákèjádò ayé? (2 Kíró. 20:19, 21; Róòmù 10:13-15; 2 Tím. 4:2)
Ìtàn 68
Àwọn Ọmọkùnrin Méjì Tó Jí Dìde
Ta ni àwọn mẹ́ta tó wà nínú àwòrán yìí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí ọmọdékùnrin tó wà níbẹ̀?
Àdúrà wo ni Èlíjà gbà nípa ọmọdékùnrin náà, kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
Kí lorúkọ olùrànlọ́wọ́ Èlíjà?
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Obìnrin ará Ṣúnémù kan fi lọ pe Èlíṣà pé kó wá sílé òun?
Kí ni Èlíṣà ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí ọmọ tó kú náà?
Agbára wo tí Jèhófà ní ni Jèhófà fi hàn nípasẹ̀ Èlíjà àti Èlíṣà?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni a ṣe dán ìgbọràn àti ìgbàgbọ́ Èlíjà wò? (1 Ọba 17:9; 19:1-4, 10)
Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ opó ará Sáréfátì fi jẹ́ èyí tó ta yọ? (1 Ọba 17:12-16; Lúùkù 4:25, 26)
Báwo ni ìrírí tí opó ará Sáréfátì ní ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 10:41, 42? (1 Ọba 17:10-12, 17, 23, 24)
-
Kí ni obìnrin ará Ṣúnémù fi kọ́ wa nípa àlejò ṣíṣe? (2 Ọba 4:8; Lúùkù 6:38; Róòmù 12:13; 1 Jòh. 3:17)
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi inú rere hàn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí? (Ìṣe 20:35; 28:1, 2; Gál. 6:9, 10; Héb. 6:10)
Ìtàn 69
Ọ̀dọ́mọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́
Kí ni ọmọdébìnrin yìí ń sọ fún obìnrin yìí nínú àwòrán tá à ń wò yìí?
Ta ni obìnrin tó wà nínú àwòrán yìí, kí sì ni ọmọdébìnrin yẹn ń ṣe nínú ilé rẹ̀?
Kí ni Èlíṣà rán ìránṣẹ́ rẹ̀ láti sọ fún Náámánì, kí ló sì fà á tí Náámánì fi bínú?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Náámánì gbọ́ ọ̀rọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
Kí nìdí tí Èlíṣà kò fi gba ẹ̀bùn tí Náámánì mú wá, ṣùgbọ́n kí ni Géhásì ṣe?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Géhásì, kí la sì lè rí kọ́ láti inú èyí?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni àpẹẹrẹ tí ọ̀dọ́mọbìnrin Ísírẹ́lì yìí fi lélẹ̀ ṣe lè fún àwọn ọ̀dọ́mọdé níṣìírí lónìí? (2 Ọba 5:3; Sm. 8:2; 148:12, 13)
Kí nìdí tó fi dára pé ká fi àpẹẹrẹ Náámánì sọ́kàn nígbà tẹ́nì kan bá gbà wá nímọ̀ràn láti inú Ìwé Mímọ́? (2 Ọba 5:15; Héb. 12:5, 6; Ják. 4:6)
Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ tá a bá fi àpẹẹrẹ Èlíṣà àti ti Géhásì wéra? (2 Ọba 5:9, 10, 14-16, 20; Mát. 10:8; Ìṣe 5:1-5; 2 Kọ́r. 2:17)
Ìtàn 70
Jónà àti Ẹja Ńlá
Ta ni Jónà, kí sì ni Jèhófà sọ pé kó ṣe?
Kí ni Jónà ṣe nítorí pé kò fẹ́ lọ síbi tí Jèhófà rán an?
Kí ni Jónà sọ fáwọn atukọ̀ pé kí wọ́n ṣe kí ìjì náà lè dáwọ́ dúró?
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jónà bó ṣe ń rì lọ sí ìsàlẹ̀ omi?
Ọjọ́ mélòó ni Jónà fi wà nínú ikùn ẹja ńlá náà, kí ló sì ṣe níbẹ̀?
Ibo ni Jónà lọ nígbà tó jáde kúrò nínú ẹja ńlá náà, kí sì ni èyí kọ́ wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jónà 1:1-17.
Bó ṣe hàn kedere, èrò wo ni Jónà ní nípa bí Ọlọ́run ṣe rán an pé kó lọ wàásù fáwọn ará Nínéfè? (Jónà 1:2, 3; Òwe 3:7; Oníw. 8:12)
Ka Jónà 2:1, 2, 10.
Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà ṣe mú ká ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà á gbọ́ àdúrà wa? (Sm. 22:24; 34:6; 1 Jòh. 5:14)
Ka Jónà 3:1-10.
Bí Jèhófà ò ṣe ṣíwọ́ lílo Jónà bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónà ò kọ́kọ́ fẹ́ ṣe iṣẹ́ tó gbé fún un, ìṣírí wo lèyí fún wa? (Sm. 103:14; 1 Pét 5:10)
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìrírí tí Jónà ní lọ́dọ̀ àwọn ará Nínéfè lórí ọ̀ràn ká máa fúnra wa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? (Jónà 3:6-9; Oníw. 11:6; Ìṣe 13:48)
Ìtàn 71
Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
Ta ni Aísáyà, ìgbà wo ló gbé ayé, kí ni Jèhófà sì fi hàn án?
Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Párádísè” túmọ̀ sí, kí lohun tí èyí sì rán ọ létí rẹ̀?
Kí ni Jèhófà sọ fún Aísáyà pé kó kọ nípa Párádísè tuntun náà?
Kí ló fà á tí Ádámù àti Éfà fi pàdánù ilé wọn ẹlẹ́wà?
Kí ni Jèhófà ṣèlérí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Aísáyà 11:6-9.
Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe àlàáfíà tó máa wà láàárín èèyàn àti ẹranko nínú ayé tuntun? (Sm. 148:10, 13; Aísá. 65:25; Ìsík. 34:25)
Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ṣe ń nímùúṣẹ tẹ̀mí láàárín àwọn èèyàn Jèhófà lónìí? (Róòmù 12:2; Éfé. 4:23, 24)
Ta ló yẹ kó gba ìyìn fún àyípadà sí rere tó ń bá ìwà àwọn èèyàn nísinsìnyí àti èyí tó máa bá a nínú ayé tuntun tó ń bọ̀? (Aísá. 48:17, 18; Gál. 5:22, 23; Fílí. 4:7)
Ka Ìṣípayá 21:3, 4.
Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé gbígbé tí Ọlọ́run ń bá aráyé gbé kò túmọ̀ sí pé ó wá sórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ pé ńṣe ló wà pẹ̀lú wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ? (Léf. 26:11, 12; 2 Kíró. 6:18; Aísá. 66:1; Ìṣí. 21:2, 3, 22-24)
Irú omijé àti ìrora wo ni kò ní sí mọ́? (Lúùkù 8:49-52; Róòmù 8:21, 22; Ìṣí. 21:4)
Ìtàn 72
Ọlọ́run Ran Hesekáyà Ọba Lọ́wọ́
Ta ni ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, kí sì nìdí tó fi wà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro?
Àwọn lẹ́tà wo ni Hesekáyà kó wá síwájú Ọlọ́run, àdúrà wo sì ni Hesekáyà gbà?
Irú ọba wo ni Hesekáyà jẹ́, iṣẹ́ wo sì ni Jèhófà rán sí i nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà?
Bó ṣe wà nínú àwòrán yẹn, kí ni áńgẹ́lì Jèhófà ṣe fún àwọn ará Ásíríà?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ẹ̀yà méjì náà wà ní àlàáfíà fún ìgbà díẹ̀, kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Hesekáyà?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Rábúṣákè agbẹnusọ ọba Ásíríà ṣe wá ọ̀nà láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di èyí tí kò lágbára? (2 Ọba 18:19, 21; Ẹ́kís. 5:2; Sm. 64:3)
Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hesekáyà nígbà tí àwọn alátakò bá ń ta kò wá? (2 Ọba 18:36; Sm. 39:1; Òwe 26:4; 2 Tím. 2:24)
-
Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà òde òní ṣe máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hesekáyà ní àkókò tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú? (2 Ọba 19:1, 2; Òwe 3:5, 6; Héb. 10:24, 25; Ják. 5:14, 15)
Ìyà onílọ̀ọ́po mẹ́ta wo ló jẹ Senakéríbù Ọba, ta sì ni èyí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ pé irú rẹ̀ tún máa ṣẹlẹ̀ sí? (2 Ọba 19:32, 35, 37; Ìṣí. 20:2, 3)
Ka 2 Àwọn Ọba 21:1-6, 16.
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Mánásè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba tó burú jù lọ nínú àwọn tó ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù? (2 Kíró. 33:4-6, 9)
Ìtàn 73
Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì
Ọmọ ọdún mélòó ni Jòsáyà nígbà tó di ọba, kí ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nígbà tó di ọdún méje tó ti ń ṣàkóso?
Kí lo rí tí Jòsáyà ń ṣe nínú àwòrán àkọ́kọ́ yẹn?
Kí ni àlùfáà àgbà rí nígbà tí àwọn mẹ́ta náà ń tún tẹ́ńpìlì ṣe?
Kí nìdí tí Jòsáyà fi fa aṣọ rẹ̀ ya?
Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ wo ni Húlídà wòlíì obìnrin sọ fún Jòsáyà?
Àfikún ìbéèrè:
-
Àpẹẹrẹ wo ni Jòsáyà fi lélẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ní ìṣòro nígbà ọmọdé wọn? (2 Kíró. 33:21-25; 34:1, 2; Sm. 27:10)
Àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì wo ni Jòsáyà gbé láti mú ìsìn tòótọ́ gbèrú ní ọdún kẹjọ, ọdún kejìlá, àti ọdún kejìdínlógún ìṣàkóso rẹ̀? (2 Kíró. 34:3, 8)
Lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe àtúnṣe ibi ìjọsìn wa, ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ tí Jòsáyà Ọba àti Hilikáyà Àlùfáà Àgbà fi lélẹ̀? (2 Kíró. 34:9-13; Òwe 11:14; 1 Kọ́r. 10:31)
Ìtàn 74
Ọkùnrin Kan Tí Kò Bẹ̀rù
Ta ni ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú àwòrán yìí?
Kí ni Jeremáyà rò nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé á di wòlíì òun, ṣùgbọ́n kí ni Jèhófà sọ fún un?
Iṣẹ́ wo ni Jeremáyà ò yéé jẹ́ fún àwọn èèyàn?
Báwo ni àwọn àlùfáà ṣe gbìyànjú láti pa Jeremáyà lẹ́nu mọ́, ṣùgbọ́n báwo ló ṣe fi hàn pé òun kò bẹ̀rù?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jeremáyà 1:1-8.
Bí àpẹẹrẹ Jeremáyà ṣe fi hàn, kí ló ń mú kí ẹnì kan tóótun láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (2 Kọ́r. 3:5, 6)
Kí ni àpẹẹrẹ Jeremáyà fún àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni òde òní níṣìírí láti ṣe? (Oníw. 12:1; 1 Tím. 4:12)
Ka Jeremáyà 10:1-5.
Àpèjúwe tó lágbára wo ni Jeremáyà lò láti fi hàn pé kò wúlò pé kéèyàn máa gbẹ́kẹ̀ lé ère? (Jer. 10:5; Aísá. 46:7; Háb. 2:19)
Ka Jeremáyà 26:1-16.
Báwo ni àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ṣe máa ń fi àṣẹ Jèhófà ‘pé kí Jeremáyà má ṣe mú ọ̀rọ̀ kankan kúrò’ sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń polongo iṣẹ́ ìkìlọ̀ náà lónìí? (Jer. 26:2; Diu. 4:2; Ìṣe 20:27)
Àpẹẹrẹ rere wo ni Jeremáyà fi lélẹ̀ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí lórí ọ̀rọ̀ kíkéde ìkìlọ̀ Jèhófà fún àwọn orílẹ̀-èdè? (Jer. 26:8, 12, 14, 15; 2 Tím. 4:1-5)
-
Ohun búburú wo ló ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Júdà nítorí pé wọn ò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu? (2 Ọba 24:2-4, 14)
Ìtàn 75
Ọmọkùnrin Mẹ́rin ní Bábílónì
Ta ni àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin tó wà nínú àwòrán yìí, kí ló sì fà á tí wọ́n fi wà ní Bábílónì?
Ètò wo ni Nebukadinésárì ṣe fún àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin náà, àṣẹ wo ló sì pa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
Kí ni Dáníẹ́lì sọ pé kí wọ́n ṣe fún òun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun mẹ́ta lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti ohun mímu?
Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta jẹ oúnjẹ ewébẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá, báwo ni ara wọ́n ṣe rí sí ara àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yòókù?
Báwo ni Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ṣe dé ààfin ọba, ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà sàn ju àwọn àlùfáà àti àwọn ọlọgbọ́n ọkùnrin lọ?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Dáníẹ́lì 1:1-21.
Ìsapá wo la ní láti ṣe tá a bá fẹ́ láti dènà ìdẹwò ká sì borí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa? (Dán. 1:8; Jẹ́n. 39:7, 10; Gál. 6:9)
Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà dán àwọn ọ̀dọ́ òde òní wò tàbí tí wọ́n lè gbà fagbára mú wọn láti máa ṣe ohun táwọn kan kà sí “oúnjẹ adùnyùngbà”? (Dán. 1:8; Òwe 20:1; 2 Kọ́r. 6:17–7:1)
Kí ni àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rin náà jẹ́ ká mọ̀ nípa gbígba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé? (Dán. 1:20; Aísá. 54:13; 1 Kọ́r. 3:18-20)
Ìtàn 76
Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run
Kí lo rí nínú àwòrán yẹn pé ó ń ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Ta ni Ìsíkíẹ́lì, àwọn nǹkan tí kò ṣeé gbọ́ sétí wo ni Jèhófà sì fi hàn án?
Nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní ọ̀wọ̀ fún Jèhófà, kí ni Jèhófà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn?
Kí ni Nebukadinésárì Ọba ṣe lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí i?
Kí nìdí tí Jèhófà fi yọ̀ọ̀da kí ìparun ńláǹlà yìí wá sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Kí ló fà á tí ilẹ̀ Ísírẹ́lì fi wà láìsí èèyàn kankan tí ń gbébẹ̀, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó tó fi wà bẹ́ẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Ta ni Sedekáyà, kí ló ṣẹlẹ̀ sí i, báwo sì ni èyí ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ? (2 Ọba 25:5-7; Ìsík. 12:13-15)
Ta ni Jèhófà dá lẹ́bi fún gbogbo ìwà àìṣòótọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù? (2 Ọba 25:9, 11, 12, 18, 19; 2 Kíró. 36:14, 17)
Ka Ìsíkíẹ́lì 8:1-18.
Báwo ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe fara wé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà tó ń jọ́sìn oòrùn? (Ìsík. 8:16; Aísá. 5:20, 21; Jòh. 3:19-21; 2 Tím. 4:3)
Ìtàn 77
Wọ́n Kọ̀ Láti Tẹrí Ba
Àṣẹ wo ni Nebukadinésárì, ọba Bábílónì pa fáwọn èèyàn?
Kí ló fà á táwọn ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́ta fi kọ̀ láti tẹrí ba fún ère oníwúrà?
Nígbà tí Nebukadinésárì fún àwọn Hébérù mẹ́ta náà ní àǹfààní mìíràn láti tẹrí ba, báwo ni wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
Kí ni Nebukadinésárì ní kí àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣe fún Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò?
Kí ni Nebukadinésárì rí nígbà tó wo inú ìléru náà?
Kí nìdí tí ọba fi yin Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò, àpẹẹrẹ wo ni wọ́n sì fi lélẹ̀ fún wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Dáníẹ́lì 3:1-30.
Kí làwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta náà ṣe tó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fara wé nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìdánwò ìdúróṣinṣin? (Dán. 3:17, 18; Mát. 10:28; Róòmù 14:7, 8)
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jèhófà kọ́ Nebukadinésárì? (Dán. 3:28, 29; 4:34, 35)
Ìtàn 78
Ìkọ̀wé Lára Ògiri
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọba Bábílónì ṣe àsè ńlá tó sì ń lo ife àti àwo tí wọ́n kó láti inú tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù?
Kí ni Bẹliṣásárì sọ fáwọn ọkùnrin ọlọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ni wọn ò lè ṣe?
Kí ni ìyá ọba sọ fún un pé kó ṣe?
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáníẹ́lì sọ fún ọba, kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán ọwọ́ láti kọ ọ̀rọ̀ sára ògiri?
Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàlàyé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ara ògiri náà?
Kí ló ṣẹlẹ̀ bí Dáníẹ́lì ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Dáníẹ́lì 5:1-31.
Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù tó mú Bẹliṣásárì nígbà tó rí ìkọ̀wé ara ògiri. (Dán. 5:6, 7; Sm. 19:9; Róòmù 8:35-39)
Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi ìgboyà ńlá hàn nígbà tó ń bá Bẹliṣásárì àtàwọn ìjòyè rẹ̀ sọ̀rọ̀? (Dán. 5:17, 18, 22, 26-28; Ìṣe 4:29)
Báwo ni àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì orí 5 ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run? (Dán. 4:17, 25; 5:21)
Ìtàn 79
Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún
Ta ni Dáríúsì, ojú wo ló sì fi ń wo Dáníẹ́lì?
Kí ni àwọn òjòwú ọkùnrin kan sún Dáríúsì ṣe?
Kí ni Dáníẹ́lì ṣe nígbà tó gbọ́ nípa òfin tuntun náà?
Kí nìdí tí inú Dáríúsì fi bà jẹ́ débi pé kò lè sùn, kí ló sì ṣe ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì?
Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe dá Dáríúsì lóhùn?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn búburú tí wọ́n ń gbìyànjú láti pa Dáníẹ́lì, kí ni Dáríúsì sì kọ ránṣẹ́ sí gbogbo èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Dáníẹ́lì 6:1-28.
Báwo ni ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì mọ́ Dáníẹ́lì ṣe rán wa létí ohun tí àwọn alátakò ti ṣe láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní? (Dán. 6:7; Sm. 94:20; Aísá. 10:1; Róòmù 8:31)
Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ṣe lè fara wé Dáníẹ́lì nínú ọ̀ràn títẹríba fún “àwọn aláṣẹ onípò gíga”? (Dán. 6:5, 10; Róòmù 13:1; Ìṣe 5:29)
Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì tó ń sin Ọlọ́run “láìyẹsẹ̀”? (Dán. 6:16, 20; Fílí. 3:16; Ìṣí. 7:15)
Ìtàn 80
Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Kúrò ní Bábílónì
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe?
Báwo ni Kírúsì ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà sọ ṣẹ?
Kí ni Kírúsì sọ fún àwọn tí ò lè lọ sí Jerúsálẹ́mù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
Kí ni Kírúsì fún àwọn èèyàn náà láti kó padà lọ sí Jerúsálẹ́mù?
Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pẹ́ tó lójú ọ̀nà kí wọ́n tó lè padà dé Jerúsálẹ́mù?
Ọdún mélòó ni ilẹ̀ náà fi wà láìsí ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo níbẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ọn pé ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ tóun sọ nípa Kírúsì máa ṣẹ? (Aísá. 55:10, 11; Róòmù 4:17)
Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Kírúsì ṣe fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú? (Aísá. 42:9; 45:21; 46:10, 11; 2 Pét. 1:20)
Ka Ẹ́sírà 1:1-11.
Bá a bá ṣe bíi tàwọn tí ò lè padà sí Jerúsálẹ́mù, báwo la ṣe máa ‘fún ọwọ́ àwọn tó ṣeé ṣe fún láti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lókùn’? (Ẹ́sírà 1:4, 6; Róòmù 12:13; Kól. 4:12)
Ìtàn 81
Gbígbẹ́kẹ̀lé Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run
Àwọn mélòó ló rin ìrìn àjò gígùn láti Bábílónì padà sí Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n rí nígbà tí wọ́n débẹ̀?
Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀, kí làwọn ọ̀tá wọn sì ṣe?
Ta ni Hágáì àti Sekaráyà, kí ni wọ́n sì sọ fáwọn èèyàn náà?
Kí ló fà á tí Táténáì fi kọ̀wé sí Bábílónì, ìdáhùn wo ló sì rí gbà?
Kí ni Ẹ́sírà ṣe nígbà tó gbọ́ pé tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nílò àtúnṣe?
Nínú àwòrán yìí, kí ni Ẹ́sírà ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣe, báwo ni Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀, kí lèyí sì kọ́ wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́sírà 3:1-13.
Tá a bá wà ní ibi tí kò ti sí ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run, kí ló yẹ ká máa bá a lọ láti ṣe? (Ẹ́sírà 3:3, 6; Ìṣe 17:16, 17; Héb. 13:15)
Ka Ẹ́sírà 4:1-7.
Àpẹẹrẹ wo ni Serubábélì fi lélẹ̀ fáwọn èèyàn Jèhófà lórí ọ̀ràn bíbá àwọn aláìgbàgbọ́ da ìjọsìn pọ̀? (Ẹ́kís. 34:12; 1 Kọ́r. 15:33; 2 Kọ́r. 6:14-17)
Ka Ẹ́sírà 5:1-5, 17 àti 6:1-22.
Kí nìdí tí kò fi ṣeé ṣe fáwọn alátakò láti dá kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà dúró? (Ẹ́sírà 5:5; Aísá. 54:17)
Ọ̀nà wo ni ohun tí àwọn àgbà ọkùnrin Júù ṣe gbà fún àwọn alàgbà nínú ìjọ níṣìírí láti máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àwọn alátakò? (Ẹ́sírà 6:14; Sm. 32:8; Róòmù 8:31; Ják. 1:5)
Ka Ẹ́sírà 8:21-23, 28-36.
Àpẹẹrẹ tí Ẹ́sírà fi lélẹ̀ wo ló yẹ ká tẹ̀ lé ká tó ṣe ohunkóhun? (Ẹ́sírà 8:23; Sm. 127:1; Òwe 10:22; Ják. 4:13-15)
Ìtàn 82
Módékáì àti Ẹ́sítérì
Ta ni Módékáì àti Ẹ́sítérì?
Kí ló dé tí Ahasuwérúsì Ọba fi fẹ́ ní ìyàwó mìíràn, ta ló sì yàn?
Ta ni Hámánì, kí ló sì mú un bínú gan-an?
Òfin wo ni wọ́n ṣe, kí ni Ẹ́sítérì sì ṣe lẹ́yìn tí Módékáì ránṣẹ́ sí i?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Hámánì, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí Módékáì?
Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ẹ́sítérì 2:12-18.
Báwo ni àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì ṣe fi hàn pé ó ṣàǹfààní téèyàn bá ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù”? (Ẹ́sítérì 2:15; 1 Pét. 3:1-5)
Ka Ẹ́sítérì 4:1-17.
Bí Ẹ́sítérì ṣe ní àǹfààní láti ṣe ohun tó jẹ́ kí ìjọsìn tòótọ́ lè máa tẹ̀ síwájú, àǹfààní wo ni àwa náà ní lónìí tó lè jẹ́ ká fi hàn pé a jẹ́ olùfọkànsìn àti adúróṣinṣin sí Jèhófà? (Ẹ́sítérì 4:13, 14; Mát. 5:14-16; 24:14)
Ka Ẹ́sítérì 7:1-6.
Bíi ti Ẹ́sítérì, báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí ṣe múra tán láti fojú winá inúnibíni tó bá jẹ́ pé ohun tó gbà nìyẹn? (Ẹ́sítérì 7:4; Mát. 10:16-22; 1 Pét. 2:12)
Ìtàn 83
Odi Jerúsálẹ́mù
Báwo ló ṣe rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kò sí odi tó yí Jerúsálẹ́mù ìlú wọn ká?
Ta ni Nehemáyà?
Kí ni iṣẹ́ Nehemáyà, kí sì nìdí tí iṣẹ́ náà fi ṣe pàtàkì?
Ìròyìn wo ló ba Nehemáyà nínú jẹ́, kí ló sì ṣe?
Báwo ni Atasásítà Ọba ṣe fi inú rere hàn sí Nehemáyà?
Báwo ni Nehemáyà ṣe ṣètò iṣẹ́ ìkọ́lé náà tí kò fi ṣeé ṣe fáwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti dá a dúró?
Àfikún ìbéèrè:
-
Báwo ni Nehemáyà ṣe wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà? (Neh. 2:4, 5; Róòmù 12:12; 1 Pét. 4:7)
Ka Nehemáyà 3:3-5.
Kí ni àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè rí kọ́ látinú ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà àwọn ará Tékóà àti àwọn tó jẹ́ “ọlọ́lá ọba” láàárín wọn? (Neh. 3:5, 27; 2 Tẹs. 3:7-10; 1 Pét. 5:5)
Ka Nehemáyà 4:1-23.
Kí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà nìṣó láìka àtakò gbígbóná janjan sí? (Neh. 4:6, 8, 9; Sm. 50:15; Aísá. 65:13, 14)
Ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà fún wa níṣìírí lónìí?
Ka Nehemáyà 6:15.
Kí ni bó ṣe ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn náà láti mọ odi Jerúsálẹ́mù tán láàárín oṣù méjì fi hàn nípa agbára ìgbàgbọ́? (Sm. 56:3, 4; Mát. 17:20; 19:26)
Ìtàn 84
Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò
Ta ni obìnrin tó wà nínú àwòrán yìí?
Kí ni Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà?
Báwo ni Gébúrẹ́lì ṣe ṣàlàyé fún Màríà pé ó máa bímọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì bá ọkùnrin kankan gbé rí?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Màríà lọ sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ̀?
Kí ni Jósẹ́fù rò nígbà tó gbọ́ pé Màríà máa bímọ, ṣùgbọ́n kí ló fà á tó fi yí èrò rẹ̀ padà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Lúùkù 1:26-56.
Kí ni Lúùkù 1:35 fi hàn nípa àìpé Ádámù tó wà lára ẹyin ọmọ tó wà nínú Màríà nígbà tí Ọlọ́run mú ìwàláàyè Ọmọ Rẹ̀ kúrò lọ́run tó sì mú kó di ọlẹ̀ nínú Màríà? (Hág. 2:11-13; Jòh. 6:69; Héb. 7:26; 10:5)
Báwo ni wọ́n ṣe bọlá fún Jésù ṣáájú ìbí rẹ̀ pàápàá? (Lúùkù 1:41-43)
Àpẹẹrẹ rere wo ni Màríà fi lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àkànṣe lóde òní? (Lúùkù 1:38, 46-49; 17:10; Òwe 11:2)
Ka Mátíù 1:18-25.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sọ Jésù ní Ìmánúẹ́lì, báwo ni ipa tó kó nígbà tó jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ṣe mú ìtumọ̀ orúkọ náà ṣẹ? (Mát. 1:22, 23; Jòh. 14:8-10; Héb. 1:1-3)
Ìtàn 85
Wọ́n Bí Jésù sí Ibùso Ẹran
Ta ni ọmọ kékeré tó wà nínú àwòrán yìí, ibo ni Màríà sì fẹ́ tẹ́ ẹ sí yìí?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ibùso ẹran tí àwọn ẹran wà ni wọ́n bí Jésù sí?
Nínú àwòrán yìí, àwọn wo ni àwọn ọkùnrin tó fẹ́ wọnú ibùso ẹran náà, kí sì ni áńgẹ́lì kan ti sọ fún wọn?
Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ ẹni pàtàkì?
Kí nìdí tá a fi lè pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Lúùkù 2:1-20.
Ipa wo ni Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì kó nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jésù? (Lúùkù 2:1-4; Míkà 5:2)
Báwo ni ẹnì kan ṣe lè di ẹni tá a kà mọ́ “àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà”? (Lúùkù 2:14; Mát. 16:24; Jòh. 17:3; Ìṣe 3:19; Héb. 11:6)
Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn onírẹ̀lẹ̀ ará Jùdíà bá rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n yọ̀ lórí ìbí olùgbàlà, kí ni ìdí tó ju ìyẹn lọ tó fi yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run yọ̀ lóde òní? (Lúùkù 2:10, 11; Éfé. 3:8, 9; Ìṣí. 11:15; 14:6)
Ìtàn 86
Àwọn Ọkùnrin Tí Ìràwọ̀ Kan Darí
Àwọn wo làwọn ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, kí ló dé tí ọ̀kan nínú wọn sì fi ń tọ́ka sí ìràwọ̀ kan tó ń tàn yanran?
Kí nìdí tí Hẹ́rọ́dù Ọba fi bínú, kí ló sì ṣe?
Ibo ni ìràwọ̀ tó ń tàn yanran náà darí àwọn ọkùnrin náà lọ, ṣùgbọ́n kí ló dé tí wọ́n fi gba ọ̀nà mìíràn lọ sí orílẹ̀-èdè wọn?
Àṣẹ wo ni Hẹ́rọ́dù pa, kí ló sì fà á?
Kí ni Jèhófà sọ pé kí Jósẹ́fù ṣe?
Ta ló mú kí ìràwọ̀ tuntun náà tàn, kí sì nìdí?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 2:1-23.
Jésù tó ọmọ ọdún mélòó nígbà táwọn awòràwọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ibo lòun àtàwọn òbí rẹ̀ sì ń gbé nígbà náà? (Mát. 2:1, 11, 16)
Ìtàn 87
Jésù Ọ̀dọ́mọdé Nínú Tẹ́ńpìlì
Ọmọ ọdún mélòó ni Jésù nínú àwòrán yìí, ibo ló sì wà yìí?
Kí ni Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ máa ń ṣe lọ́dọọdún?
Kí nìdí tí Jósẹ́fù àti Màríà fi padà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn ọjọ́ kan nígbà tí wọ́n ń padà lọ sílé?
Ibo ni Jósẹ́fù àti Màríà ti rí Jésù, kí sì nìdí tí ẹnu fi ya àwọn tó wà níbẹ̀?
Kí ni Jésù sọ fún Màríà ìyá rẹ̀?
Báwo la ṣe lè dà bíi Jésù nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Lúùkù 2:41-52.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin Mósè béèrè pé àwọn ọkùnrin nìkan ni kó máa lọ sí àjọyọ̀ ọdọọdún, àpẹẹrẹ rere wo ni Jósẹ́fù àti Màríà fi lélẹ̀ fún àwọn òbí lónìí? (Lúùkù 2:41; Diu. 16:16; 31:12; Òwe 22:6)
Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ lónìí pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn? (Lúùkù 2:51; Diu. 5:16; Òwe 23:22; Kól. 3:20)
Ka Mátíù 13:53-56.
Àwọn ọmọ ìyá Jésù mẹ́rin wo tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ni Bíbélì dárúkọ, báwo sì ni wọ́n ṣe lo méjì nínú wọn nínú ìjọ Kristẹni lẹ́yìn náà? (Mát. 13:55; Ìṣe 12:17; 15:6, 13; 21:18; Gál. 1:19; Ják. 1:1; Júúdà 1)
Ìtàn 88
Jòhánù Batisí Jésù
Ta ni àwọn ọkùnrin méjì tó wà nínú àwòrán yìí?
Báwo ni wọ́n ṣe ń batisí èèyàn?
Irú àwọn èèyàn wo ni Jòhánù máa ń batisí?
Kí ni ìdí pàtàkì tí Jésù fi ní kí Jòhánù batisí òun?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi hàn pé inú òun dùn sí bí Jésù ṣe ṣèrìbọmi?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ síbì kan tó sì dá wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́?
Kí ni orúkọ díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́, kí sì ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 3:13-17.
Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ìbatisí? (Sm. 40:7, 8; Mát. 28:19, 20; Lúùkù 3:21, 22)
Ka Mátíù 4:1-11.
Báwo ni bí Jésù ṣe lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó já fáfá ṣe fún wa ní ìṣírí láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé? (Mát. 4:5-7; 2 Pét. 3:17, 18; 1 Jòh. 4:1)
Ka Jòhánù 1:29-51.
Ta ni Jòhánù Arinibọmi darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí, báwo la sì ṣe lè fara wé e lónìí? (Jòh. 1:29, 35, 36; 3:30; Mát. 23:10)
Ka Jòhánù 2:1-12.
Báwo ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í fi ohunkóhun tó dára du àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (Jòh. 2:9, 10; Sm. 84:11; Ják. 1:17)
Ìtàn 89
Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́
Kí nìdí tí wọ́n fi ń ta ẹran nínú tẹ́ńpìlì?
Kí ló bí Jésù nínú?
Bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí, kí ni Jésù ṣe, kí ló sì pa láṣẹ fún àwọn ọkùnrin tó ń ta àdàbà?
Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ohun tó ń ṣe, kí ni wọ́n rántí?
Àgbègbè wo ni Jésù gbà nígbà tó ń padà sí Gálílì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jòhánù 2:13-25.
Tó o bá ronú nípa bí Jésù ṣe bínú sí àwọn olùpààrọ̀ owó nínú tẹ́ńpìlì, ojú wo ló yẹ kó o fi máa wo ọ̀ràn kárà-kátà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (Jòh. 2:15, 16; 1 Kọ́r. 10:24, 31-33)
Ìtàn 90
Pẹ̀lú Obìnrin Kan Lẹ́bàá Kànga
Kí nìdí tí Jésù fi dúró lẹ́bàá kànga kan ní Samáríà, ọ̀rọ̀ wo ló sì ń bá obìnrin kan sọ níbẹ̀?
Kí nìdí tí ẹnu fi ya obìnrin náà, kí ni Jésù sọ fún un, kí sì ni ìdí rẹ̀?
Irú omi wo ni obìnrin náà rò pé Jésù ń sọ, ṣùgbọ́n kí ni Jésù ní lọ́kàn gan-an?
Kí nìdí tí ohun tí Jésù mọ̀ nípa obìnrin náà fi yà á lẹ́nu gidigidi, báwo sì ni Jésù ṣe mọ nǹkan náà?
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ bí Jésù ṣe bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá kànga?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jòhánù 4:5-43.
Bá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn tí ẹ̀yà tàbí ìran wọn yàtọ̀ sí tiwa? (Jòh. 4:9; 1 Kọ́r. 9:22; 1 Tím. 2:3, 4; Títù 2:11)
Àwọn àǹfààní tẹ̀mí wo ni ẹni tó bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù yóò ní? (Jòh. 4:14; Aísá. 58:11; 2 Kọ́r. 4:16)
Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì hàn bí obìnrin ará Samáríà yẹn, tó ń hára gàgà láti sọ ohun tó kọ́ fáwọn ẹlòmíràn? (Jòh. 4:7, 28; Mát. 6:33; Lúùkù 10:40-42)
Ìtàn 91
Jésù Kọ́ Àwọn Èèyàn Lórí Òkè
Nínú àwòrán yìí, ibo ni Jésù ti ń kọ́ àwọn èèyàn, àwọn wo ló sì jókòó sún mọ́ ọn wọ̀nyẹn?
Kí lorúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá?
Ìjọba wo ni Jésù ń wàásù nípa rẹ̀?
Kí ni Jésù kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbàdúrà nípa rẹ̀?
Kí ni Jésù sọ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa ṣe sáwọn ẹlòmíì?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 5:1-12.
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí àti jíjọ́sìn Ọlọ́run ń jẹ wá lọ́kàn? (Mát. 5:3; Róòmù 10:13-15; 1 Tím. 4:13, 15, 16)
Ka Mátíù 5:21-26.
Báwo ni Mátíù 5:23, 24 ṣe tẹnu mọ́ ọn pé bá a ṣe ń ṣe sáwọn arákùnrin àti arábìnrin wa yóò nípa lórí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà? (Mát. 6:14, 15; Sm. 133:1; Kól. 3:13; 1 Jòh. 4:20)
Ka Mátíù 6:1-8.
Irú àwọn ìwà jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni wo ló yẹ kí Kristẹni máa ṣọ́ra fún? (Lúùkù 18:11, 12; 1 Kọ́r. 4:6, 7; 2 Kọ́r. 9:7)
Ka Mátíù 6:25-34.
Kí ni Jésù fi kọ́ni nípa ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún àwọn ohun tara tá a nílò? (Ẹ́kís. 16:4; Sm. 37:25; Fílí. 4:6)
Ka Mátíù 7:1-11.
Kí ni àpèjúwe tó wà ní Mátíù 7:5 kọ́ wa? (Òwe 26:12; Róòmù 2:1; 14:10; Ják. 4:11, 12)
Ìtàn 92
Jésù Jí Òkú Dìde
Tá ni bàbá ọmọbìnrin tó wà nínú àwòrán yìí, kí sì nìdí tí ìdààmú ọkàn fi bá òun àti ìyàwó rẹ̀?
Kí ni Jáírù ṣe nígbà tó rí Jésù?
Kí ló ṣẹlẹ̀ bí Jésù ṣe ń lọ sí ilé Jáírù, kí sì ni ẹnì kan wá sọ kí Jésù tó dé ibẹ̀?
Kí nìdí táwọn èèyàn tó wà ní ilé Jáírù ṣe ń fi Jésù rẹ́rìn-ín?
Lẹ́yìn tí Jésù mú mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti bàbá àti ìyá ọmọbìnrin náà wọnú yàrá tí ọmọbìnrin náà wà, kí ni Jésù ṣe?
Ta tún ni Jésù jí dìde, kí sì nìyẹn fi hàn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Lúùkù 8:40-56.
Báwo ni Jésù ṣe fi ìyọ́nú àti ìgbatẹnirò hàn sí obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀, kí sì ni àwọn alàgbà ìjọ lè rí kọ́ nínú èyí? (Lúùkù 8:43, 44, 47, 48; Léf. 15:25-27; Mát. 9:12, 13; Kól. 3:12-14)
Ka Lúùkù 7:11-17.
Kí nìdí tí ohun tí Jésù ṣe nígbà tó rí opó Náínì fi lè tu àwọn tí èèyàn wọn ti kú nínú? (Lúùkù 7:13; 2 Kọ́r. 1:3, 4; Héb. 4:15)
Ka Jòhánù 11:17-44.
Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé kò burú kí ẹni tí èèyàn rẹ̀ kú banú jẹ́? (Jòh. 11:33-36, 38; 2 Sám. 18:33; 19:1-4)
Ìtàn 93
Jésù Bọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn
Ohun búburú wo ló ṣẹlẹ̀ sí Jòhánù Arinibọmi, báwo ló sì ṣe rí lára Jésù?
Báwo ni Jésù ṣe bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó tẹ̀ lé e, báwo sì ni oúnjẹ tó ṣẹ́ kù ṣe pọ̀ tó?
Kí nìdí tí ẹ̀rù fi ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní òru, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí Pétérù?
Báwo ni Jésù ṣe bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní ìgbà kejì?
Kí nìdí tó fi máa dára gan-an nígbà tí Jésù tó jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run yàn bá ń ṣàkóso ayé?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 14:1-32.
Kí ni Mátíù 14:23-32 fi hàn nípa irú ẹni tí Pétérù jẹ́?
Báwo ni àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé Pétérù túbọ̀ ní ìwà àgbà tó sì borí ìwàǹwára rẹ̀? (Mát. 14:27-30; Jòh. 18:10; 21:7; Ìṣe 2:14, 37-40; 1 Pét. 5:6, 10)
Ka Mátíù 15:29-38.
Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọyì oúnjẹ tí Bàbá òun pèsè? (Mát. 15:37; Jòh. 6:12; Kól. 3:15)
Ka Jòhánù 6:1-21.
Báwo ni àwọn Kristẹni lóde òní ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó bá kan ọ̀ràn ìjọba ayé? (Jòh. 6:15; Mát. 22:21; Róòmù 12:2; 13:1-4)
Ìtàn 94
Jésù Fẹ́ràn Àwọn Ọmọdé
Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń bá ara wọn jiyàn lé lórí nígbà tí wọ́n ń ti ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn kan bọ̀?
Kí nìdí tí Jésù fi pe ọmọ kékeré kan tó sì mú un dúró ní àárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
Ọ̀nà wo ló yẹ kí àwọn àpọ́sítélì gbà gbìyànjú láti dà bí àwọn ọmọdé?
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn ọmọdé?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 18:1-4.
Kí nìdí tí Jésù fi fi àpèjúwe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? (Mát. 13:34, 36; Máàkù 4:33, 34)
Ka Mátíù 19:13-15.
Àwọn ànímọ́ tí àwọn ọmọdé ní wo ló yẹ kí àwa náà ní ká bàa lè rí ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run gbà? (Sm. 25:9; 138:6; 1 Kọ́r. 14:20)
Ka Máàkù 9:33-37.
Kí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa kéèyàn máa fẹ́ ní ipò ọlá? (Máàkù 9:35; Mát. 20:25, 26; Gál. 6:3; Fílí. 2:5-8)
Ka Máàkù 10:13-16.
Báwo ló ṣe rọrùn fún àwọn èèyàn láti máa sún mọ́ Jésù tó, kí sì ni àwọn alàgbà ìjọ lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jésù? (Máàkù 6:30-34; Fílí. 2:1-4; 1 Tím. 4:12)
Ìtàn 95
Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Ń Kọ́ni
Ìbéèrè wo ni ọkùnrin kan bi Jésù, kí sì nìdí tó fi béèrè?
Kí ni Jésù máa ń lò nígbà mìíràn láti kọ́ni, kí sì ni ohun tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Júù àti àwọn ará Samáríà?
Nínú ìtàn tí Jésù sọ, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Júù kan lójú ọ̀nà nígbà tó ń lọ sí Jẹ́ríkò?
Kí ni àlùfáà kan tó jẹ́ Júù àti ọmọ Léfì kan ṣe nígbà tí wọ́n dé ibi tí ọkùnrin náà wà?
Nínú àwòrán yìí, ta ló ń ṣèrànlọ́wọ́ fún Júù tí àwọn ọlọ́ṣà lù?
Nígbà tí Jésù parí ìtàn náà, ìbéèrè wo ló béèrè, báwo sì ni ọkùnrin náà ṣe dáhùn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Lúùkù 10:25-37.
Kàkà kí Jésù fúnra rẹ̀ sọ ìdáhùn, báwo ló ṣe ran ọkùnrin kan tó mọ Òfin gan-an lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan? (Lúùkù 10:26; Mát. 16:13-16)
Báwo ni Jésù ṣe lo àpèjúwe láti fi mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ yéé rò pé àwọn sàn ju àwọn ẹlòmíì tàbí àwọn ẹ̀yà míì lọ? (Lúùkù 10:36, 37; 18:9-14; Títù 1:9)
Ìtàn 96
Jésù Wo Àwọn Aláìsàn Sàn
Kí ni Jésù ń ṣe bó ṣe ń rin ìrìn àjò jákèjádò ilẹ̀ náà?
Nígbà tó di nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí Jésù ti ṣèrìbọmi, kí ló sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
Àwọn wo ló wà nínú àwòrán yìí, kí ni Jésù sì ṣe fún obìnrin yẹn?
Kí nìdí tí èsì tí Jésù fún àwọn aṣáájú ìsìn tó ta kò ó fi dójú tì wọ́n?
Nígbà tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dé ìtòsí Jẹ́ríkò, kí ni Jésù ṣe fún àwọn afọ́jú méjì tí wọ́n ń ṣagbe?
Kí nìdí tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ ìyanu?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 15:30, 31.
Báwo ni Jèhófà ṣe fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Jésù, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí nípa lórí ìmọ̀ tí a ní nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe ìlérí pé òun yóò ṣe fún wa nínú ayé tuntun? (Sm. 37:29; Aísá. 33:24)
Ka Lúùkù 13:10-17.
Báwo ni bí Jésù ṣe ṣe díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ tó tóbi jù lọ ní ọjọ́ Sábáàtì ṣe jẹ́ ká mọ́ irú ìtura tó máa mú bá aráyé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀? (Lúùkù 13:10-13; Sm. 46:9; Mát. 12:8; Kól. 2:16, 17; Ìṣí. 21:1-4)
Ka Mátíù 20:29-34.
Báwo ni ìtàn yìí ṣe fi hàn pé ọwọ́ Jésù kì í dí jù láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kí sì ni èyí kọ́ wa? (Diu. 15:7; Ják. 2:15, 16; 1 Jòh. 3:17)
Ìtàn 97
Jésù Dé Gẹ́gẹ́ bí Ọba
Nígbà tí Jésù dé abúlé kékeré kan tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù, kí ló sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn ṣe?
Nínú àwòrán yìí, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù sún mọ́ etí ìlú Jerúsálẹ́mù?
Kí làwọn ọmọdé ṣe nígbà tí wọ́n rí bí Jésù ṣe ń wo àwọn afọ́jú àti arọ sàn?
Kí ni Jésù sọ fún àwọn àlùfáà tí inú ń bí?
Báwo la ṣe lè dà bí àwọn ọmọdé tí wọ́n yin Jésù?
Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn fẹ́ mọ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 21:1-17.
Báwo ni wíwọ̀ tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe yàtọ̀ sí bí àwọn ọ̀gágun ṣe máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun lákòókò ilẹ̀ ọba Róòmù? (Mát. 21:4, 5; Sek. 9:9; Fílí. 2:5-8; Kól. 2:15)
Kí ni àwọn èwe òde òní lè rí kọ́ lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 118 nígbà tí Jésù wọ inú tẹ́ńpìlì? (Mát. 21:9, 15; Sm. 118:25, 26; 2 Tím. 3:15; 2 Pét. 3:18)
Ka Jòhánù 12:12-16.
Kí ni bí àwọn èèyàn tí wọ́n yin Jésù ṣe lo imọ̀ ọ̀pẹ dúró fún? (Jòh. 12:13; Fílí. 2:10; Ìṣí 7:9, 10)
Ìtàn 98
Lórí Òkè Ólífì
Tọ́ka sí Jésù nínú àwòrán yìí. Àwọn wo ló wà pẹ̀lú rẹ̀?
Kí ni àwọn àlùfáà gbìyànjú láti ṣe fún Jésù nínú tẹ́ńpìlì, kí sì ni Jésù sọ fún wọn?
Kí ni àwọn àpọ́sítélì Jésù bi í?
Kí nìdí tí Jésù fi sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà tó bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní ọ̀run fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
Kí ni Jésù sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ kí òun tó fòpin sí gbogbo ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 23:1-39.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ fi hàn pé kò burú tí èèyàn bá fi orúkọ oyè pe àwọn tó di ipò pàtàkì mú nínú ayé, kí ni ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 23:8-11 fi hàn nípa fífi orúkọ oyè pe àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni láti fi pọ́n wọn lé? (Ìṣe 26:25; Róòmù 13:7; 1 Pét. 2:13, 14)
Kí làwọn Farisí lò láti fi mú kí àwọn èèyàn má di Kristẹni, báwo sì ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣe ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó jọ ìyẹn lóde òní? (Mát. 23:13; Lúùkù 11:52; Jòh. 9:22; 12:42; 1 Tẹs. 2:16)
Ka Mátíù 24:1-14.
Nínú Mátíù 24:13, báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ní ìfaradà?
Kí ni ọ̀rọ̀ náà, “òpin” tó wà nínú Mátíù 2:13 túmọ̀ sí? (Mát. 16:27; Róòmù 14:10-12; 2 Kọ́r. 5:10)
Ka Máàkù 13:3-10.
Ọ̀rọ̀ wo nínú Máàkù 13:10 ló fi hàn pé a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere kíákíá, kí ló sì yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sún wa ṣe? (Róòmù 13:11, 12; 1 Kọ́r. 7:29-31; 2 Tím. 4:2)
Ìtàn 99
Nínú Yàrá Kan Lórí Òkè Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí ni Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá lọ ṣe nínú yàrá ńlá yìí lórí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì?
Ọkùnrin wo ló ń jáde kúrò nínú yàrá yẹn, kí ló sì ń lọ ṣe?
Oúnjẹ àkànṣe wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n parí oúnjẹ Ìrékọjá?
Ohun wo ni ayẹyẹ Ìrékọjá máa ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí rẹ̀, ohun wo sì ni àkànṣe oúnjẹ náà máa ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù létí rẹ̀?
Nígbà tí wọ́n parí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, kí ni Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì ni wọ́n ṣe?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 26:14-30.
Báwo ni Mátíù 26:15 ṣe fi hàn pé ńṣe ni Júdásì mọ̀ọ́mọ̀ da Jésù?
Àǹfààní méjì wo ni ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣe? (Mát. 26:27, 28; Jer. 31:31-33; Éfé. 1:7; Héb. 9:19, 20)
Ka Lúùkù 22:1-39.
Kí ló túmọ̀ sí pé Sátánì wọ inú Júdásì? (Lúùkù 22:3; Jòh. 13:2; Ìṣe 1:24, 25)
Ka Jòhánù 13:1-20.
Pẹ̀lú ohun tí Jòhánù 13:2 sọ, ǹjẹ́ a lè dá Júdásì lẹ́bi fún ohun tó ṣe, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run? (Jẹ́n. 4:7; 2 Kọ́r. 2:11; Gál. 6:1; Ják. 1:13, 14)
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù fi àpẹẹrẹ ara rẹ̀ kọ́ wa? (Jòh. 13:15; Mát. 23:11; 1 Pét. 2:21)
Ka Jòhánù 17:1-26.
Nígbà tí Jésù gbàdúrà pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “jẹ́ ọ̀kan,” ọ̀nà wo ni wọ́n á gbà jẹ́ ọ̀kan? (Jòh. 17:11, 21-23; Róòmù 13:8; 14:19; Kól. 3:14)
Ìtàn 100
Jésù Nínú Ọgbà
Ibo ni Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ nígbà tí wọ́n kúrò nínú yàrá orí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, kí ló sì sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe?
Kí ni Jésù rí i pé àwọn àpọ́sítélì òun ń ṣe nígbà tó padà wá sí ibi tí wọ́n wà, ẹ̀ẹ̀melòó ni wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀?
Àwọn wo ló wọ inú ọgbà náà, kí sì ni Júdásì Ísíkáríótù ṣe, bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí?
Kí nìdí tí Júdásì fi fẹnu ko Jésù lẹ́nu, kí sì ni Pétérù ṣe?
Kí ni Jésù sọ fún Pétérù, àmọ́ kí ni ìdí tí Jésù kò fi sọ pé kí Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì wá?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 26:36-56.
Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó yẹ káwọn alàgbà ìjọ máa tẹ̀ lé lónìí? (Mát. 20:25-28; 26:40, 41; Gál. 5:17; Éfé. 4:29, 31, 32)
Ojú wo ni Jésù fi wo fífi àdá tàbí àwọn ohun ìjà mìíràn àti ọ̀rọ̀ ẹnu bá ọmọnìkejì ẹni jà? (Mát. 26:52; Lúùkù 6:27, 28; Jòh. 18:36)
Ka Lúùkù 22:39-53.
Nígbà tí áńgẹ́lì kan fara han Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì tó sì fún un lókun, ǹjẹ́ ohun tí ìyẹn fi hàn ni pé ìgbàgbọ́ Jésù ti ń dín kù? Ṣàlàyé. (Lúùkù 22:41-43; Aísá. 49:8; Mát. 4:10, 11; Héb. 5:7)
Ka Jòhánù 18:1-12.
Báwo ni Jésù ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn alátakò rẹ̀, ẹ̀kọ́ wo ni a sì lè rí kọ́ nínú èyí? (Jòh. 10:11, 12; 18:1, 6-9; Héb. 13:6; Ják. 2:25)
Ìtàn 101
Wọ́n Pa Jésù
Ta lẹni tó mú káwọn èèyàn pa Jésù?
Kí làwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn mú Jésù?
Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ilé Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà?
Kí ni ìdí tí Pétérù fi jáde lọ sunkún?
Nígbà tí wọ́n dá Jésù padà sọ́dọ̀ Pílátù, igbe kí ni àwọn àlùfáà ń ké?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní ọ̀sán ọjọ́ Friday, ìlérí wo ló sì ṣe fún ọ̀daràn kan tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀?
Ibo ni Párádísè tí Jésù sọ yóò wà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 26:57-75.
Báwo ni àwọn tó máa ń gbọ́ ẹjọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù ṣe fi hàn pé ọkàn wọn burú? (Mát. 26:59, 67, 68)
Ka Mátíù 27:1-50.
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ojú ayé lásán ni bí Júdásì ṣe kábàámọ̀? (Mát. 27:3, 4; Máàkù 3:29; 14:21; 2 Kọ́r. 7:10, 11)
Ka Lúùkù 22:54-71.
Kí la lè rí kọ́ nínú bí Pétérù ṣe sẹ́ Jésù lọ́jọ́ tí Júdásì dà á tí wọ́n sì mú un? (Lúùkù 22:60-62; Mát. 26:31-35; 1 Kọ́r. 10:12)
Ka Lúùkù 23:1-49.
Kí ni Jésù ṣe nígbà tí wọ́n fìyà jẹ ẹ́ láìṣẹ̀ láìrò, ẹ̀kọ́ wo ni a sì lè rí kọ́ nínú ìyẹn? (Lúùkù 23:33, 34; Róòmù 12:17-19; 1 Pét. 2:23)
Ka Jòhánù 18:12-40.
Kí ni bí Pétérù ṣe tẹ̀ síwájú di ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àpọ́sítélì lẹ́yìn tí ìbẹ̀rù èèyàn borí rẹ̀ fúngbà díẹ̀ fi hàn? (Jòh. 18:25-27; 1 Kọ́r. 4:2; 1 Pét. 3:14, 15; 5:8, 9)
Ka Jòhánù 19:1-30.
Kí ni èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tí Jésù ní nípa ohun ìní tara? (Jòh. 2:1, 2, 9, 10; 19:23, 24; Mát. 6:31, 32; 8:20)
Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbẹ̀yìn tó fi kú ṣe jẹ́ ìkéde ìṣẹ́gun pé òun ti gbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ? (Jòh. 16:33; 19:30; 2 Pét. 3:14; 1 Jòh. 5:4)
Ìtàn 102
Jésù Jíǹde
Ta ni obìnrin tó wà nínú àwòrán yìí, àwọn wo ni ọkùnrin méjì tó wà níbẹ̀, ibo ni wọ́n sì wà?
Kí nìdí tí Pílátù fi sọ fún àwọn àlùfáà pé kí wọ́n rán àwọn ọmọ ogun láti lọ ṣọ́ ibojì Jésù?
Kí ni áńgẹ́lì kan ṣe ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, àmọ́ kí ni àwọn àlùfáà ṣe?
Kí nìdí tí ẹnu fi ya àwọn obìnrin kan nígbà tí wọ́n lọ síbi ibojì Jésù?
Kí nìdí tí Pétérù àti Jòhánù fi sáré lọ síbi ibojì Jésù, ṣé wọ́n sì rí nǹkan kan níbẹ̀?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ara Jésù, àmọ́ kí ló máa ń ṣe láti fi han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun ti jí dìde?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Mátíù 27:62-66 àti 28:1-15.
Nígbà tí Jésù jí dìde, báwo ni àwọn olórí àlùfáà, àwọn Farisí àti àwọn àgbà ọkùnrin ṣe dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́? (Mát. 12:24, 31, 32; 28:11-15)
Ka Lúùkù 24:1-12.
Báwo ni àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde Jésù ṣe fi hàn pé Jèhófà ka àwọn obìnrin sí ẹlẹ́rìí tó ṣeé fọkàn tẹ̀? (Lúùkù 24:4, 9, 10; Mát. 28:1-7)
Ka Jòhánù 20:1-12.
Báwo ni Jòhánù 20:8, 9 ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká ní sùúrù tá ò bá lóye àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Bíbélì sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́? (Òwe 4:18; Mát. 17:22, 23; Lúùkù 24:5-8; Jòh. 16:12)
Ìtàn 103
Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa
Ki ni Màríà sọ fún ọkùnrin kan tó kà sí olùṣọ́gbà, àmọ́ kí ló mú kó mọ̀ pé Jésù ni?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì kan tí wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn lọ sí abúlé Ẹ́máọ́sì?
Ohun ìyanu wo ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì náà sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé àwọn rí Jésù?
Ìgbà mélòó ni Jésù ti fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
Kí ni Tọ́másì sọ nígbà tó gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti rí Olúwa, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jòhánù 20:11-29.
Ṣé ohun tí Jésù ń sọ nínú Jòhánù 20:23 ni pé Ọlọ́run fún àwọn èèyàn láṣẹ láti máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini? Ṣàlàyé. (Sm. 49:2, 7; Aísá. 55:7; 1 Tím. 2:5, 6; 1 Jòh. 2:1, 2)
Ka Lúùkù 24:13-43.
Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ kó lè gba òtítọ́ Bíbélì? (Lúùkù 24:32, 33; Ẹ́sírà 7:10; Mát. 5:3; Ìṣe 16:14; Héb. 5:11-14)
Ìtàn 104
Jésù Padà Sọ́run
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn mélòó ló rí Jésù lẹ́ẹ̀kan náà, kí ló sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, báwo sì ni nǹkan yóò ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Jésù bá jọba fún ẹgbẹ̀rún ọdún?
Ọjọ́ mélòó rèé tí Jésù ti ń fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì ni àkókò ti tó fún un báyìí láti ṣe?
Kí Jésù tó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀, kí ló sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe?
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú àwòrán yìí, báwo sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò ṣe rí Jésù mọ́?
Àfikún ìbéèrè:
-
Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lè fi ìdánilójú bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Jésù, àwọn ohun wo ni àwa Kristẹni sì lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lónìí? (1 Kọ́r. 15:4, 7, 8; Aísá. 2:2, 3; Mát. 24:14; 2 Tím. 3:1-5)
Ka Ìṣe 1:1-11.
Ibo ni iṣẹ́ ìwàásù tàn káàkiri dé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣe 1:8? (Ìṣe 6:7; 9:31; 11:19-21; Kól. 1:23)
Ìtàn 105
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dúró sí Jerúsálẹ́mù
Bí àwòrán yìí ṣe fi hàn, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n dúró ní Jerúsálẹ́mù?
Ohun ìyanu wo ni àwọn tó wá sí Jerúsálẹ́mù rí?
Àlàyé wo ni Pétérù ṣe fáwọn èèyàn náà?
Lẹ́yìn táwọn èèyàn ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù, kí ni wọ́n káàánú nípa rẹ̀, kí sì ni Pétérù sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe?
Èèyàn mélòó la rì bọmi ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 2:1-47.
Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ nínú Ìṣe 2:23, 36 ṣe fi hàn pé gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló jẹ̀bi ikú Jésù? (1 Tẹs. 2:14, 15)
Báwo ni Pétérù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn fi Ìwé Mímọ́ ti àlàyé rẹ̀ lẹ́yìn? (Ìṣe 2:16, 17, 29, 31, 36, 39; Kól. 4:6)
Báwo ni Pétérù ṣe lo àkọ́kọ́ lára “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run” tí Jésù ṣèlérí pé òun á fún un? (Ìṣe 2:14, 22-24, 37, 38; Mát. 16:19)
Ìtàn 106
Ìdáǹdè Kúrò Nínú Túbú
Bí Pétérù àti Jòhánù ṣe ń lọ sínú tẹ́ńpìlì ní ọ̀sán ọjọ́ kan, kí ni wọ́n ṣe?
Kí ni Pétérù sọ fún ọkùnrin tó yarọ náà, ohun tó ju owó lọ wo ló sì fún un?
Kí nìdí tí inú fi bí àwọn aṣáájú ìsìn, kí ni wọ́n sì ṣe fún Pétérù àti Jòhánù?
Kí ni Pétérù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn náà, ìkìlọ̀ wo ni àwọn aṣáájú ìsìn sì ṣe fún àwọn àpọ́sítélì náà?
Kí nìdí tí àwọn aṣáájú ìsìn fi ń jowú, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n fi àwọn àpọ́sítélì sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì?
Báwo ni àwọn àpọ́sítélì ṣe fèsì nígbà tí wọ́n mú wọn wá sínú gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 3:1-10.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò fún wa ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ nínú Ìṣe 3:6 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń kéde? (Jòh. 17:3; 2 Kọ́r. 5:18-20; Fílí. 3:8)
Ka Ìṣe 4:1-31.
Tá a bá rí àtakò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, báwo ló ṣe yẹ ká fára wé àwọn Kristẹni arákùnrin wa ní ọ̀rúndún kìíní? (Ìṣe 4:29, 31; Éfé. 6:18-20; 1 Tẹs. 2:2)
Ka Ìṣe 5:17-42.
Báwo ni àwọn kan tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà àtijọ́ àti lóde òní ṣe fi ẹ̀tọ́ bá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù lò? (Ìṣe 5:34-39)
Ìtàn 107
Wọ́n Sọ Sítéfánù Lókùúta Pa
Tá ni Sítéfánù, kí ni Ọlọ́run sì ń ràn án lọ́wọ́ láti ṣe?
Kí ni Sítéfánù sọ tó mú kí inú bí àwọn aṣáájú ìsìn?
Lẹ́yìn tí àwọn ọkùnrin náà wọ́ Sítéfánù jáde kúrò nínú ìlú, kí ni wọ́n ṣe fún un?
Nínú àwòrán yìí, ta ni ọ̀dọ́kùnrin tó dúró ti àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè tó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ yẹn?
Kí Sítéfánù tó kú, àdúrà wo ló gbà sí Jèhófà?
Bíi ti Sítéfánù, kí ló yẹ ká ṣe tí ẹnì kan bá ṣe ohun búburú sí wa?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 6:8-15.
Àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn wo ni àwọn aṣáájú ìsìn ti lò láti dá iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró? (Ìṣe 6:9, 11, 13)
Ka Ìṣe 7:1-60.
Kí ló ran Sítéfánù lọ́wọ́ tó fi lè sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ìhìn rere níwájú Sànhẹ́dírìn, kí la sì lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀? (Ìṣe 7:51-53; Róòmù 15:4; 2 Tím. 3:14-17; 1 Pét. 3:15)
Èrò wo ló yẹ ká ní sí àwọn tó ń ta ko iṣẹ́ ìwàásù wa? (Ìṣe 7:58-60; Mát. 5:44; Lúùkù 23:33, 34)
Ìtàn 108
Lójú Ọ̀nà Damásíkù
Kí ni Sọ́ọ̀lù ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Sítéfánù
Bí Sọ́ọ̀lù ṣe wà lójú ọ̀nà Damásíkù, ohun ìyanu wo ló ṣẹlẹ̀?
Kí ni Jésù sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó ṣe?
Kí ni Jésù sọ fún Ananíà pé kó ṣe, báwo sì ni Sọ́ọ̀lù ṣe tún padà ríran?
Orúkọ wo ni wọ́n wá fi ń pe Sọ́ọ̀lù, báwo sì ni Jésù ṣe lo Sọ́ọ̀lù?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 8:1-4.
Báwo ni ọ̀pọ̀ inúnibíni tí wọ́n ṣe sí ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ṣe mú kí ẹ̀kọ́ Kristẹni tàn kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe ń ṣẹlẹ̀ lóde òní? (Ìṣe 8:4; Aísá. 54:17)
Ka Ìṣe 9:1-20.
Ọ̀nà mẹ́ta wo ni iṣẹ́ tí Jésù sọ pé òun fẹ́ rán Sọ́ọ̀lù pín sí? (Ìṣe 9:15; 13:5; 26:1; 27:24; Róòmù 11:13)
Ka Ìṣe 22:6-16.
Báwo la ṣe lè dà bí Ananíà, kí sì nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì gan-an? (Ìṣe 22:12; 1 Tím. 3:7; 1 Pét. 1:14-16; 2:12)
Ka Ìṣe 26:8-20.
Báwo ni dídi tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni ṣe jẹ́ ìṣírí fún àwọn tí ọkọ wọn tàbí aya wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ lónìí? (Ìṣe 26:11; 1 Tím. 1:14-16; 2 Tím. 4:2; 1 Pét. 3:1-3)
Ìtàn 109
Pétérù Lọ Sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù
Ta ni ọkùnrin tó wólẹ̀ nínú àwòrán yìí?
Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún Kọ̀nílíù?
Kí ni Ọlọ́run mú kí Pétérù rí nígbà tó wà lórí òrùlé ilé Símónì ní Jópà?
Kí nìdí tí Pétérù fi sọ fún Kọ̀nílíù pé kó má ṣe wólẹ̀ láti sin òun?
Kí nìdí tí ẹnu fi ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ Júù tí wọ́n tẹ̀ lé Pétérù?
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló yẹ ká kọ́ nínú ìtàn bí Pétérù ṣe lọ sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 10:1-48.
Kí ni ohun tí Pétérù sọ nínú Ìṣe 10:42 fi hàn nípa iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (Mát. 28:19; Máàkù 13:10; Ìṣe 1:8)
Ka Ìṣe 11:1-18.
Kí ni ìṣarasíhùwà Pétérù nígbà tí ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe fún àwọn Kèfèrí fara hàn kedere, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? (Ìṣe 11:17, 18; 2 Kọ́r. 10:5; Éfé. 5:17)
Ìtàn 110
Tímótì—Olùrànlọ́wọ́ Tuntun fún Pọ́ọ̀lù
Ta ni ọ̀dọ́mọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, ibo ló ń gbé, kí ni orúkọ ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀?
Kí ni Tímótì sọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù bi í pé ṣé á fẹ́ láti bá òun àti Sílà lọ láti wàásù fáwọn èèyàn ní ọ̀nà jíjìn réré?
Ibo ni wọ́n ti kọ́kọ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Kristẹni?
Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì kúrò ní Lísírà, kí ni orúkọ díẹ̀ lára àwọn ìlú tí wọ́n lọ?
Báwo ni Tímótì ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, ìbéèrè wo ló sì yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ òde òní bi ara wọn?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 9:19-30.
Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọgbọ́n nígbà tó rí àtakò látọ̀dọ̀ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere? (Ìṣe 9:22-25, 29, 30; Mát. 10:16)
Ka Ìṣe 11:19-26.
Báwo ni àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìṣe 11:19-21, 26 ṣe fi hàn pé ẹ̀mí Jèhófà ló ń tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ́nà tó sì ń darí wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Ka Ìṣe 13:13-16, 42-52.
Báwo ni Ìṣe 13:51, 52 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò jẹ́ kí àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wọn mú kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn? (Mát. 10:14; Ìṣe 18:6; 1 Pét. 4:14)
Ka Ìṣe 14:1-6, 19-28.
Báwo ni gbólóhùn náà, “wọ́n fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́” ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní máa ṣàníyàn tí kò yẹ nípa àwọn ẹni tuntun tá à ń ràn lọ́wọ́? (Ìṣe 14:21-23; 20:32; Jòh. 6:44)
Ka Ìṣe 16:1-5.
Báwo ni bí Tímótì ṣe gbà tinútinú láti jẹ́ kí wọ́n dá adọ̀dọ́ rẹ̀ ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe “ohun gbogbo nítorí ìhìn rere”? (Ìṣe 16:3; 1 Kọ́r. 9:23; 1 Tẹs. 2:8)
Ka Ìṣe 18:1-11, 18-22.
Kí ni Ìṣe 18:9, 10 fi hàn nípa bí Jésù alára ṣe ń lọ́wọ́ nínú dídarí iṣẹ́ ìwàásù, báwo lèyí sì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ lónìí? (Mát. 28:20)
Ìtàn 111
Ọmọkùnrin Kan Tó Sùn Lọ
Ta ni ọmọkùnrin tó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ nínú àwòrán yẹn, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i?
Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó rí i pé ọmọ náà ti kú?
Ibo ni Pọ́ọ̀lù, Tímótì àtàwọn tó ń bá wọn rìnrìn àjò ń lọ, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n dúró ní Mílétù?
Ìkìlọ̀ wo ni wòlíì Ágábù ṣe fún Pọ́ọ̀lù, báwo ni ohun tí wòlíì náà sọ sì ṣe ṣẹlẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 20:7-38.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Ìṣe 20:26, 27, báwo ni ọrùn wa ṣe lè “mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo”? (Ìsík. 33:8; Ìṣe 18:6, 7)
Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà ìjọ máa “di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin” nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ni? (Ìṣe 20:17, 29, 30; Títù 1:7-9; 2 Tím. 1:13)
Ka Ìṣe 26:24-32.
Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù fún àǹfààní iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́? (Ìṣe 9:15; 16:37, 38; 25:11, 12; 26:32; Lúùkù 21:12, 13)
Ìtàn 112
Ọkọ̀ Rì ní Erékùṣù Kan
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọkọ̀ ojú òkun tí Pọ́ọ̀lù wà nínú rẹ̀ bó ṣe ń gba ìtòsí erékùṣù Kírétè kọjá?
Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà?
Báwo ni ọkọ̀ náà ṣe fọ́ sí wẹ́wẹ́?
Kí ni ọ̀gágun tó wà nínú ọkọ̀ náà sọ pé káwọn èèyàn ṣe, àwọn mélòó ló sì dé èbúté ní àlàáfíà?
Kí ni orúkọ erékùṣù tí wọ́n gúnlẹ̀ sí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tí ojú ọjọ́ tún dára?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 27:1-44.
Báwo ló ṣe túbọ̀ dá wa lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì nígbà tá a kà nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Róòmù? (Ìṣe 27:16-19, 27-32; Lúùkù 1:3; 2 Tím. 3:16, 17)
Ka Ìṣe 28:1-14.
Bí àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé ní erékùṣù Málítà tí wọ́n jẹ́ Kèfèrí bá lè fi “àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn” hàn sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ tó rì, kí ló yẹ́ káwọn Kristẹni fi hàn; pàápàá jù lọ, ọ̀nà wo ló yẹ kí wọ́n gbà fi hàn? (Ìṣe 28:1, 2; Héb. 13:1, 2; 1 Pét. 4:9)
Ìtàn 113
Pọ́ọ̀lù ní Róòmù
Ta ni Pọ́ọ̀lù wàásù fún nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù?
Nínú àwòrán yẹn, ta ni àlejò tó jókòó nídìí tábìlì, kí ló sì ń bá Pọ́ọ̀lù ṣe?
Ta ni Ẹpafíródítù, kí ló sì mú dání nígbà tó padà sí Fílípì?
Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà sí Fílémónì ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́?
Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tí wọ́n dá a sílẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn náà?
Ta ni Jèhófà lò láti kọ àwọn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, kí sì ni ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣe 28:16-31 àti Fílípì 1:13.
Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń lo àkókò rẹ̀ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ipa wo sì ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí kò yẹ̀ ní lórí ìjọ Kristẹni? (Ìṣe 28:23, 30; Fílí. 1:14)
Ka Fílípì 2:19-30.
Àwọn ọ̀rọ̀ ìmoore wo ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì àti Ẹpafíródítù, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù? (Fílí. 2:20, 22, 25, 29, 30; 1 Kọ́r. 16:18; 1 Tẹs. 5:12, 13)
Ka Fílémónì 1-25.
Kí ni nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ pé kí Fílémónì tìtorí rẹ̀ ṣe ohun tó bẹ́tọ̀ọ́ mu, báwo ló sì ṣe yẹ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí lónìí? (Fílém. 9; 2 Kọ́r. 8:8; Gál. 5:13)
Báwo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Fílémónì 13, 14 ṣe fi hàn pé kò ṣaláì ka ohun tí ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ bá sọ fún wọn sí? (1 Kọ́r. 8:7, 13; 10:31-33)
Ka 2 Tímótì 4:7-9.
Bíi ti Pọ́ọ̀lù, báwo la ṣe lè ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà pé yóò fún wa ní èrè rere tá a bá jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin? (Mát. 24:13; Héb. 6:10)
Ìtàn 114
Òpin Gbogbo Ìwà Búburú
Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ nípa àwọn ẹṣin ní ọ̀run?
Kí ni orúkọ ogun tí Ọlọ́run yóò bá àwọn èèyàn búburú tó wà lórí ilẹ̀ ayé jà, kí sì ni ogun náà máa ṣe?
Nínú àwòrán yẹn, ta ni Ẹni tó ṣáájú nínú ogun náà, kí nìdí tó fi dé adé, kí sì ni idà rẹ̀ dúró fún?
Tá a bá wo Ìtàn 10, 15 àti 33 nínú ìwé yìí, kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run yóò pa àwọn èèyàn búburú run?
Báwo ni Ìtàn 36 àti 76 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run yóò pa àwọn èèyàn búburú run, wọn ì báà sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣípayá 19:11-16.
Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn kedere pé Jésù Kristi lẹni tó ń gun ẹṣin funfun? (Ìṣí. 1:5; 3:14; 19:11; Aísá. 11:4)
Báwo ni ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n wọ́n sára ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé, dájúdájú, ó máa ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run pátápátá? (Ìṣí. 14:18-20; 19:13)
Àwọn wo ló ṣeé ṣe kó wà lára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀ lé Jésù tó wà lórí ẹṣin funfun? (Ìṣí. 12:7; 19:14; Mát. 25:31, 32)
Ìtàn 115
Párádísè Tuntun Lórí Ilẹ̀ Ayé
Àwọn ohun wo ni Bíbélì sọ pé a óò gbádùn nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?
Kí ni Bíbélì ṣèlérí fún àwọn tó bá ń gbé nínú Párádísè?
Ìgbà wo ni Jésù máa rí i pé àwọn ìyípadà rere wọ̀nyí wáyé lórí ilẹ̀ ayé?
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, kí làwọn ohun tó ṣe láti jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó máa ṣe nígbà tó bá ń ṣàkóso bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run?
Kí ni Jésù àti àwọn tó máa bá a jọba lọ́run máa rí i dájú pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàkóso lé ayé lórí?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Ìṣípayá 5:9, 10.
Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé àwọn tó máa ṣàkóso lé ayé lórí gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún yóò jẹ́ olùgbatẹnirò àti aláàánú? (Éfé. 4:20-24; 1 Pét. 1:7; 3:8; 5:6-10)
Ka Ìṣípayá 14:1-3.
Kí ni bí orúkọ Baba àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣe wà níwájú orí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì fi hàn? (1 Kọ́r. 3:23; 2 Tím. 2:19; Ìṣí 3:12)
Ìtàn 116
Bá A Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé
Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ ká tó lè wà láàyè títí láé?
Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù, bí àwòrán ọmọbìnrin kékeré yìí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe fi hàn?
Ìwé mìíràn wo lo rí nínú àwòrán yẹn, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa kà á déédéé?
Yàtọ̀ sí pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù, ohun mìíràn wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú Ìtàn 69?
Kí ni àpẹẹrẹ rere tí Sámúẹ́lì ọ̀dọ́mọdé fi lélẹ̀ nínú Ìtàn 55 fi hàn?
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, kí la máa lè ṣe lọ́jọ́ iwájú?
Àfikún ìbéèrè:
Ka Jòhánù 17:3.
Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé gbígba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù sínú kọjá pé kéèyàn kàn mọ ohun tí Bíbélì sọ sórí? (Mát. 7:21; Ják. 2:18-20; 1 Jòh. 2:17)
Ka Sáàmù 145:1-21.
Kí ni díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà? (Sm. 145:8-11; Ìṣí 4:11)
Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “dára sí gbogbo ènìyàn,” báwo sì ni èyí ṣe lè mú ká túbọ̀ máa sún mọ́ ọn? (Sm. 145:9; Mát. 5:43-45)
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nínú ọkàn wa, kí nìyẹn máa mú ká ṣe? (Sm. 119:171, 172, 175; 145:11, 12, 21)