ORÍ KARÙN-ÚN
Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni
Kí ni ìràpadà?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe pèsè rẹ̀?
Àǹfààní wo ló lè ṣe fún ọ́?
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì rẹ̀?
1, 2. (a) Kí la fi ń díwọ̀n bí ẹ̀bùn kan ṣe ṣeyebíye tó? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé nínú gbogbo ẹ̀bùn tó ṣeé ṣe kó o rí gbà, ìràpadà ló ṣeyebíye jù lọ?
NÍNÚ gbogbo ẹ̀bùn tó o ti gbà rí, èwo ló ṣeyebíye jù lọ lójú rẹ? Kò dìgbà tí ẹ̀bùn kan bá jẹ́ olówó ńlá kó tó lè ṣe pàtàkì sẹ́ni tá a fún. Ó ṣe tán, kì í ṣe bí owó ẹ̀bùn kan bá ṣe tó la fi ń díwọ̀n bí ẹ̀bùn náà ṣe ṣe pàtàkì tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí ẹ̀bùn kan bá fi lè mú inú rẹ dùn tàbí tó bọ́ sí àkókò tó o nílò rẹ̀, a jẹ́ pé ó ṣeyebíye fún ọ nìyẹn.
2 Ẹ̀bùn kan wà tó ta yọ gbogbo ẹ̀bùn. Ọlọ́run ló fún aráyé lẹ́bùn ọ̀hún. Ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ni Jèhófà fún wa, àmọ́, èyí tó ṣeyebíye jù lọ nínú gbogbo wọn ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi tí í ṣe Ọmọ rẹ̀. (Ka Mátíù 20:28) Bí a ó ti rí i nínú orí tá à ń kà yìí, nínú gbogbo ẹ̀bùn tó ṣeé ṣe kó o rí gbà, ìràpadà ló ṣeyebíye jù lọ nítorí pé, ó lè fún ọ ní ayọ̀ tó ga, ó sì lè jẹ́ kó o ní ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o nílò. Ní tòdodo, ìràpadà ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fìfẹ́ rẹ̀ hàn.
KÍ NI ÌRÀPADÀ?
3. Kí ni ìràpadà, kí sì ni ohun tá a gbọ́dọ̀ mọ̀ ká tó lè mọ ìdí tí ìràpadà fi jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye fún wa?
3 Ní ṣókí, ìràpadà lohun tí Jèhófà lò láti dá aráyé nídè tàbí láti gbà aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Éfésù 1:7) Ká tó lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí, a ní láti ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Tá a bá mọ ohun tí Ádámù pàdánù nígbà tó dẹ́sẹ̀ nìkan la fi lè mọ ìdí tí ìràpadà fi jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye fún wa.
4. Àǹfààní wo ni Ádámù rí látinú jíjẹ́ tó jẹ ẹ̀dá èèyàn pípé?
4 Nígbà tí Jèhófà dá Ádámù, ó fún un ní ohun kan tó ṣeyebíye gidigidi, ìyẹn ni, ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé. Gbé àǹfààní tí ìyẹn jẹ́ kí Ádámù ní yẹ̀ wò. Nítorí pé ara pípé àti ọpọlọ pípé ni Ọlọ́run fún un, kò ní ṣàìsàn, kò ní darúgbó, kò sì ní kú. Nítorí pé ó jẹ́ èèyàn pípé, ó ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Bíbélì sọ pé Ádámù jẹ́ “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Nípa bẹ́ẹ̀, Ádámù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, bí àjọṣe tó máa ń wà láàárín bàbá onífẹ̀ẹ́ àti ọmọ rẹ̀. Jèhófà máa ń bá ọmọ rẹ̀ yìí tó wà lórí ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, ó fún un ní iṣẹ́ aláyọ̀ ó sì jẹ́ kó mọ ohun tó fẹ́ kó ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-30; 2:16, 17.
5. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé a dá Ádámù “ní àwòrán Ọlọ́run”?
5 A dá Ádámù “ní àwòrán Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé bí ìrísí Ọlọ́run ṣe rí gẹ́lẹ́ ni ìrísí Ádámù ṣe rí o. A kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kìíní ìwé yìí pé ẹni ẹ̀mí téèyàn ò lè rí ni Jèhófà. (Jòhánù 4:24) Nítorí náà, Jèhófà kì í ṣe ẹlẹ́ran ara òun ẹ̀jẹ̀ bíi tiwa. Ohun tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá Ádámù ní àwòrán ara rẹ̀ ni pé, ó dá àwọn ànímọ́ kan tó ní mọ́ Ádámù, àwọn bí ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára. Ọ̀nà pàtàkì mìíràn tí Ádámù gbà dà bí bàbá rẹ̀ ni pé, ó ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú. Ìyẹn ni Ádámù ò fi dà bí irin iṣẹ́ tó jẹ́ pé iṣẹ́ kan ṣoṣo tí wọ́n tìtorí rẹ̀ ṣe é ló lè ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lè fúnra rẹ̀ ṣe ìpinnu ó sì lè yan èyí tó wù ú láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ká ní Ádámù pinnu láti ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ni, ì bá wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
6. Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, kí ló pàdánù, báwo lèyí si ṣe kan àwa ọmọ rẹ̀?
6 Nípa báyìí, ó ṣe kedere pé nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí Ọlọ́run sì dájọ́ ikú fún un, àdánù ńláǹlà ni èyí mú bá a. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mú kó pàdánù ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé àti gbogbo ìbùkún tó jẹ mọ́ ọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ó bani nínú jẹ́ pé, ara rẹ̀ nìkan kọ́ ni Ádámù gbé ìwàláàyè iyebíye yìí sọ nù fún, ó gbé e sọ nù fáwọn ọmọ rẹ̀ ẹ̀yìnwá ọ̀la pẹ̀lú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [ìyẹn Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo wa ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé ó “ta” ara rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 7:14) Kò sí ìrètí kankan fún Ádámù àti Éfà, nítorí pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé kò sí ìrètí kankan fún àwa tá a jẹ́ ọmọ wọn ni?
7, 8. Nǹkan méjì wo ni ìràpadà jẹ́?
7 Ìràpadà ni Jèhófà lò láti fi gba aráyé sílẹ̀. Kí ni ìràpadà jẹ́? Nǹkan méjì ni ìràpadà jẹ́. Àkọ́kọ́, ìràpadà jẹ́ iyekíye téèyàn san kí wọ́n lè dá ẹnì kan sílẹ̀ tàbí iyekíye téèyàn san láti fi gba nǹkan kan padà. Àpẹẹrẹ èyí ni iye owó táwọn gbọ́mọgbọ́mọ bá béèrè kí wọ́n lè fi ẹnì kan tí wọ́n gbé sílẹ̀. Ìkejì, ìràpadà jẹ́ iye kan tí ó kájú ohun tẹ́nì kan bà jẹ́ tàbí ohun tó yá. Ìyẹn ni wọ́n fi máa ń sọ pé, ‘igbá tá a bá fi yá ọkà la fi ń san án.’ Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá fi agolo mílíìkì yá ìrẹsì, ìwọ̀n tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ẹ̀kún agolo mílíìkì náà ló gbọ́dọ̀ fi san án padà.
8 Báwo la ṣe lè san iye tó lè kájú ohun bàǹtà-banta tí Ádámù gbé sọ nù fún gbogbo wa ká sì bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? Jẹ́ ká gbé ìràpadà tí Jèhófà pèsè yẹ̀ wò àti àǹfààní tó lè ṣe fún ọ.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE PÈSÈ ÌRÀPADÀ NÁÀ
9. Irú ìràpadà wo lá nílò?
9 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé la pàdánù, kò sí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn aláìpé kankan tó lè rà á padà. (Sáàmù 49:7, 8) Ìràpadà tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìwàláàyè pípé tá a pàdánù la nílò. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìdájọ́ òdodo pípé tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sọ pé: “Ọkàn fún ọkàn.” (Diutarónómì 19:21) Nítorí náà, kí ló máa ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọkàn ẹ̀dá èèyàn pípé, tàbí ìwàláàyè pípé tí Ádámù gbé sọ nù? Ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé mìíràn ló máa jẹ́ “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” tá a nílò.—1 Tímótì 2:6.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà?
10 Báwo wá ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà náà? Ó pèsè rẹ̀ nípa rírán ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí wá sórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n Jèhófà ò kàn rán ẹ̀dá ẹ̀mí èyíkéyìí. Ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣeyebíye sí i jù lọ ló rán, ìyẹn Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. (Ka 1 Jòhánù 4:9, 10) Ńṣe ni Ọmọ yìí fínnúfíndọ̀ fi ọ̀run tí í ṣe ilé rẹ̀ sílẹ̀. (Fílípì 2:7) A kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹrin ìwé yìí pé ṣe ni Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu nígbà tó mú Ọmọ yìí kúrò lọ́run tó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, Màríà bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé. Nítorí náà, Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀.—Lúùkù 1:35.
11. Báwo ni ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè san ìràpadà fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ aráyé?
11 Báwo lẹnì kan ṣoṣo ṣe lè san ìràpadà fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ aráyé? Ó dára, báwo ni ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ aráyé ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀? Rántí pé ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ló fi gbé ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé sọ nù. Nípa bẹ́ẹ̀, kò lè fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ogún ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nìkan ló fi sílẹ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún. Ṣùgbọ́n Jésù, tí Bíbélì pè ní “Ádámù ìkẹyìn,” ní ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé ní tiẹ̀, kò sì dẹ́ṣẹ̀ rí. (1 Kọ́ríńtì 15:45) A lè sọ pé ńṣe ni Jésù rọ́pò Ádámù kó bàa lè gbà wá là. Nípa fífi ìwàláàyè pípé rẹ̀ rúbọ tàbí nípa fífi lélẹ̀ pẹ̀lú ìgbọràn tí kò yingin sí Ọlọ́run, Jésù san ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù náni. Bí Jésù ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ádámù nírètí nìyẹn.—Róòmù 5:19; 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.
12. Ẹ̀rí wo ni ìyà tí Jésù jẹ fi hàn?
12 Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìyà tí Jésù fara dà kó tó kú. Àwọn èèyàn nà án lọ́nà rírorò, wọ́n kàn án mọ́gi níkàn ìkà, ó sì kú ikú oró lórí igi. (Jòhánù 19:1, 16-18, 30; Àfikún, “Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn”.) Kí ló dé tó fi pọn dandan kí Jésù jìyà tó bẹ́ẹ̀? Tó bá yá, a óò rí i ní orí kan nínú ìwé yìí pé Sátánì sọ fún Jèhófà pé bóyá ni ẹ̀dá èèyàn kankan tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ á lè jẹ́ olóòótọ́ sí i lábẹ́ àdánwò. Jésù fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa nípa fífi ìṣòtítọ́ fara da ìyà tó pọ̀ gan-an. Jésù fi hàn pé ohunkóhun tó wù kí Èṣù ṣe, èèyàn pípé tó ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìkù síbì kan. O ò rí i pé inú Jèhófà á dùn gan-an nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i!—Òwe 27:11.
13. Báwo la ṣe san ìràpadà?
13 Báwo la ṣe san ìràpadà náà? Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni lórí kàlẹ́ńdà àwọn Júù, Jèhófà fàyè gba àwọn èèyàn kí wọ́n pa Ọmọ rẹ̀ tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé rẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Hébérù 10:10) Jèhófà jí Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọjọ́ kẹta tó kú. Nígbà tí Jésù padà dé ọ̀run, ó fún Jèhófà ní ìtóye ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé rẹ̀ tó fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ádámù. (Hébérù 9:24) Jèhófà gba ìtóye ẹbọ Jésù pé kó jẹ́ ìràpadà tá a nílò láti lè dá aráyé nídè kúrò nínú ṣíṣe ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Ka Róòmù 3:23, 24.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O LÈ RÍ LÁTINÚ ÌRÀPADÀ
14, 15. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa” gbà?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, a lè rí àwọn ìbùkún iyebíye gbà nítorí ìràpadà náà. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún wa yìí lè ṣe fún wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
15 Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí àìpé tá a jogún, ńṣe la máa ń tiraka láti ṣe ohun tó tọ́. Gbogbo wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa tàbí nínú ìwà tá à ń hù. Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù, a lè rí “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa” gbà. (Kólósè 1:13, 14) Àmọ́ ṣá o, ká tó lè rí ìdáríjì gbà, a gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn. A tún gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́ kó dárí jì wá lórí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 1:8, 9.
16. Kí ló jẹ́ ká lè máa fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Ọlọ́run, kí sì ni àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní irú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ bẹ́ẹ̀?
16 Fífi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Ọlọ́run. Tí ẹ̀rí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi, ó lè mú ká wà láìnírètí tàbí kó máa ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìdáríjì tí ìràpadà mú kó ṣeé ṣe, Jèhófà jẹ́ ká lè fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin òun láìka ti pé a jẹ́ aláìpé sí. (Hébérù 9:13, 14) Èyí jẹ́ ká lómìnira láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ìdí nìyẹn tá a fi lè máa bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà. (Hébérù 4:14-16) Tá a bá ń bá a lọ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a óò ní àlàáfíà ọkàn, a ò ní máa rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan, a óò sì láyọ̀.
17. Àwọn ìbùkún wo ló ṣeé ṣe nítorí pé Jésù kú fún wa?
17 Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Róòmù 6:23 sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Ẹsẹ yìí kan náà fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” Ní Orí Kẹta ìwé yìí, a jíròrò àwọn ìbùkún tí a óò gbádùn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀. (Ìṣípayá 21:3, 4) Nítorí pé Jésù kú fún wa ni gbogbo ìbùkún ọjọ́ ọ̀la yẹn fi ṣeé ṣe, títí kan ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìlera pípé. Tá a bá fẹ́ rí àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn gbà, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn ìràpadà.
BÁWO LO ṢE LÈ FI ÌMỌRÍRÌ HÀN?
18. Kí nìdí tá a fi ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún pípèsè tó pèsè ìràpadà?
18 Kí nìdí tó fi yẹ ká dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìràpadà tó pèsè? Ó dára, bí ẹnì kan bá yọ̀ọ̀da àkókò rẹ̀ tó sì náwó nára kó bàa lè fún wa lẹ́bùn kan, ǹjẹ́ ẹ̀bùn náà kò ní túbọ̀ ṣe iyebíye lójú wa? Tí ẹ̀bùn tẹ́nì kan fún wa bá fi hàn pé ojúlówó ìfẹ́ lẹni náà ní sí wa, ẹ̀bùn náà á jọ wá lójú. Ìràpadà ni ẹ̀bùn tó ta yọ gbogbo ẹ̀bùn, ìdí sì ni pé, ohun tó ga jù lọ ló ná Ọlọ́run láti pèsè rẹ̀. Jòhánù 3:16 sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.” Ìràpadà ni ẹ̀rí tó ga jù lọ tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Ó tún fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, nítorí pé ńṣe ló fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí tiwa. (Ka Jòhánù 15:13) Nítorí náà, ó yẹ kí ẹ̀bùn ìràpadà náà mú kó dá wa lójú hán-únhán-ún pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́ràn.—Gálátíà 2:20.
19, 20. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa?
19 Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa? Ohun àkọ́kọ́ tí wàá ṣe rèé: Sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i nípa Jèhófà, ẹni tó fún wa ní ìràpadà náà. (Jòhánù 17:3) Fífi ìwé yìí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ìmọ̀ tó o ní nípa Jèhófà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún un yóò máa jinlẹ̀ sí i. Ìfẹ́ yẹn, ẹ̀wẹ̀, yóò mú kó o fẹ́ láti ṣe ohun tí yòó mú inú rẹ̀ dùn.—1 Jòhánù 5:3.
20 Lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:36) Báwo la ṣe lè lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù? Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ la fi ń fi hàn pé a ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ o. Jákọ́bù 2:26 sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” Bó ṣe rí nìyẹn o, “àwọn iṣẹ́” tàbí ohun tá a bá ń ṣe ló máa fi hàn pé a ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan tá a lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni pé ká máa sa gbogbo ipá wa láti fara wé e, èyí ò sì ní jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa nìkan, àmọ́ nínú àwọn ohun tá à ń ṣe pẹ̀lú.—Jòhánù 13:15.
21, 22. (a) Kí nìdí tá a fi ní láti máa lọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó ń wáyé lọ́dọọdún? (b) Kí ni Orí Kẹfà àti Ìkeje ìwé yìí máa ṣàlàyé?
21 Máa lọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó ń wáyé lọ́dọọdún. Ní alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù dá àkànṣe ètò kan sílẹ̀ tí Bíbélì pè ní “oúnjẹ alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:20; Mátíù 26:26-28) A tún ń pè é ní Ìrántí Ikú Kristi. Jésù dá ṣíṣe ìrántí ikú rẹ̀ yìí sílẹ̀ kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó bá di Kristẹni tòótọ́ lẹ́yìn wọn lè máa fi sọ́kàn pé, nígbà tóun kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, òun fi ọkàn òun tàbí ẹ̀mí òun lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. Ohun tí Jésù pa láṣẹ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ṣíṣe Ìrántí Ikú Jésù á máa rán wa létí ìfẹ́ títóbi jù lọ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa nípa pípèsè tí wọ́n pèsè ìràpadà. A lè fi hàn pé a mọrírì ìràpadà náà nípa lílọ síbi Ìrántí Ikú Jésù tá à ń ṣe lọ́dọọdún.a
22 Ní tòdodo, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni ìràpadà tí Jèhófà pèsè fún wa. (2 Kọ́ríńtì 9:14, 15) Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yìí lè ṣàǹfààní fáwọn tó ti ku pàápàá. Orí Kẹfà àti Ìkeje ìwé yìí yóò ṣàlàyé bó ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní.
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìtumọ̀ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, wo Àfikún, “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run.”