ORÍ KẸSÀN-ÁN
“Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
1-3. (a) Kí ni àgbẹ̀ kan ṣe nígbà tó rí i pé irè oko òun ti pọ̀ ju ohun tí òun nìkan lè dá kó? (b) Ìṣòro wo ló dojú kọ Jésù ní ìgbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ọ̀nà wo ló sì gbé e gbà?
ÀGBẸ̀ kan wà tí ìṣòro ńlá kan dojú kọ. Ó dáko ní nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn, ó sì gbin nǹkan sí i. Ó ṣe sùúrù títí táwọn nǹkan tó gbìn fi bẹ̀rẹ̀ sí í hù, inú rẹ̀ sì dùn nígbà tí wọ́n dàgbà. Ní báyìí, gbogbo ìsapá rẹ̀ ò já sásán torí pé àkókò àtikórè ti tó. Àmọ́ ìṣòro kan tó wá dojú kọ ọ́ rèé o: Irè tá à ń sọ yìí ti pọ̀ jù fóun nìkan láti kó. Láti yanjú ìṣòro yìí, ó wá ọgbọ́n kan dá, ó pinnu láti gba àwọn òṣìṣẹ́ ó sì rán wọn lọ sínú oko rẹ̀. Ó ṣe tán, ó níye ọjọ́ tí irè náà gbọ́dọ̀ pẹ́ lóko dà.
2 Nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, irú ìṣòro àgbẹ̀ yìí ni Jésù kojú. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó gbin èso òtítọ́. Àkókò ti wá tó láti kórè, ìkòré náà sì pọ̀ gan-an ni. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti di ọmọ ẹ̀yìn. (Jòhánù 4:35-38) Báwo ni Jésù ṣe wá ojútùú sí ìṣòro yìí? Lórí òkè kan ní Gálílì, nígbà tó kù díẹ̀ kó gòkè re ọ̀run, ó gbé iṣẹ́ lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ pé kí wọ́n wá àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i, ó ní: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
3 Ẹni tó bá ń ṣe iṣẹ́ yẹn gan-an lẹni tó ń tọ Kristi lẹ́yìn ní tòótọ́. Ẹ wá jẹ́ ká gbé ìbéèrè mẹ́ta yìí yẹ̀ wò. Kí nìdí tí Jésù fi gbé iṣẹ́ lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti wá òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i? Ọ̀nà wo ló gbà kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti lè wá wọn rí? Báwo ni iṣẹ́ yìí ṣe kàn wá?
Ìdí Tá A Fi Nílò Àwọn Òṣìṣẹ́ Púpọ̀ Sí I
4, 5. Kí nìdí tí Jésù ò fi ní lè parí iṣẹ́ tó dáwọ́ lé, àwọn wo láá sì máa bá iṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn tó bá ti padà sọ́run?
4 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó mọ̀ pé òun nìkan ò ní lè parí iṣẹ́ tóun dáwọ́ lé yẹn. Ìwọ̀nba ni ibi tó lè wàásù dé láàárín àkókò tó lò láyé, ó sì níwọ̀nba iye àwọn èèyàn tó lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ wọn. Òótọ́ ni pé kìkì àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe, ìyẹn “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” nìkan ló wàásù fún. (Mátíù 15:24) Àmọ́ “àwọn àgùntàn” tí wọ́n “sọnù” wọ̀nyẹn ti fọ́n ká sí gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ilẹ̀ tó jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ni níbùú lóròó. Yàtọ̀ síyẹn, bó pẹ́ bó yá, kò sígbà tí kò ní pọn dandan láti wàásù ìhìn rere dé gbogbo ayé pátá.—Mátíù 13:38; 24:14.
5 Ó yé Jésù pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ṣì máa kù láti ṣe lẹ́yìn ikú òun. Ohun tó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ni pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 14:12) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọmọ ṣì máa padà sọ́run, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, títí kan gbogbo àwọn tó máa di ọmọlẹ́yìn lọ́jọ́ iwájú, ló máa ní láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni náà, kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì nìkan. (Jòhánù 17:20) Ìrẹ̀lẹ̀ mú kí Jésù gbà pé iṣẹ́ táwọn yẹn máa ṣe á “tóbi ju” èyí tóun ṣe lọ. Lọ́nà wo? Lọ́nà mẹ́ta ni.
6, 7. (a) Láwọn ọ̀nà wo ni iṣẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ṣe á fi tóbi ju ti Jésù lọ? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ìgbẹ́kẹ̀lé tí Jésù ní nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò já sí asán?
6 Lọ́nà kìíní, àwọn ọmọlẹ́yìn máa kárí ibi tó pọ̀ ju ibi tí Jésù kárí lọ. Lónìí, iṣẹ́ ìwàásù wọn ti dé ìkángun ayé, tó jìnnà réré sí ibi tí Jésù fúnra rẹ̀ wàásù dé. Lọ́nà kejì, wọ́n á wàásù fún èèyàn tó pọ̀ ju àwọn tí Jésù wàásù fún lọ. Kò pẹ́ rárá táwọn ọmọlẹ́yìn mélòó kan tí Jésù fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi di ẹgbẹẹgbẹ̀rún. (Ìṣe 2:41; 4:4) Lóde òní, wọ́n ti di àràádọ́ta ọ̀kẹ́. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹni tuntun sì ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. Lọ́nà kẹta, wọ́n á wàásù fún àkókò tó gùn ju èyí tí Jésù fi wàásù lọ, títí di àkókò wa yìí, èyí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún lẹ́yìn tí Jésù ti parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó fi ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ṣe lórí ilẹ̀ ayé.
7 Jésù fi hàn pé òun gbọ́kàn lé àwọn ọmọlẹ́yìn òun nígbà tó sọ pé wọ́n á ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” Iṣẹ́ tó ṣeyebíye gan-an lójú ẹ̀ ló gbé lé wọn lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Ó dá a lójú pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ náà tinútinú bóun ṣe rán wọn. Kí lèyí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Bá a bá fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí, tá a sì fi gbogbo ọkàn wa ṣe é, ńṣe là ń fi hàn pé ìgbẹ́kẹ̀lé tí Jésù ní nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò já sí asán. Ǹjẹ́ èyí kì í ṣe àǹfààní ńlá?—Lúùkù 13:24.
Ó Kọ́ Wọn Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Wàásù
8, 9. Nípa iṣẹ́ ìwàásù, àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa, báwo la sì ṣe lè máa wo àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ọ̀nà tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
8 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wọn. (Lúùkù 6:40) Ní Orí 8, a jíròrò nípa ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Tiẹ̀ dúró ná, ronú nípa àwọn ọmọlẹ́yìn tó wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó ń rìnrìn àjò kiri láti wàásù. Wọ́n ń kíyè sí bó ṣe jẹ́ pé ibikíbi tó bá ti lè rí àwọn èèyàn ló ti ń wàásù, létí adágún odò àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè, láàárín ìlú àti láàárín ọjà àti nínú ilé àwọn èèyàn. (Mátíù 5:1, 2; Lúùkù 5:1-3; 8:1; 19:5, 6) Wọ́n rí i pé òṣìṣẹ́kára ni, ó máa ń tètè jí, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ dalẹ́. Kò ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ tó kàn lè máa ṣe nígbà tọ́wọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀! (Lúùkù 21:37, 38; Jòhánù 5:17) Kò síyè méjì pé wọ́n á ti fojú ara wọn rí i pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní sáwọn èèyàn ló mú kó máa fẹ́ wàásù fún wọn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa rí i lójú rẹ̀ bí àánú àwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe é. (Máàkù 6:34) Ipa wo lo rò pé àpẹẹrẹ Jésù á ti ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ká sọ pé ìwọ náà wà ńbẹ̀, ṣe ì bá ní ipa rere lórí tìẹ náà?
9 Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, àpẹẹrẹ Jésù là ń wò tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Nípa báyìí, a kì í jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí kọjá láìjẹ́ pé a “jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Bíi ti Jésù, a máa ń wá àwọn èèyàn lọ sílé wọn. (Ìṣe 5:42) Bó bá pọn dandan, a máa ń yí ètò tá a ṣe padà sí àsìkò tá a mọ̀ pé ó ṣeé ṣe ká bá wọn nílé. A tún máa ń fọgbọ́n wo ibi táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí, bí òpópónà, inú ọgbà, ṣọ́ọ̀bù àti ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé wọn. Nítorí ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, à “ń ṣiṣẹ́ kára, . . . a sì ń tiraka.” (1 Tímótì 4:10) Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní fáwọn ẹlòmíì ló jẹ́ ká lè máa bá a lọ láti máa wá àǹfààní tá a lè fi wàásù níbikíbi àti nígbàkigbà tá a lè bá àwọn èèyàn nílé.—1 Tẹsalóníkà 2:8.
10-12. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kó tó rán wọn láti lọ wàásù?
10 Ọ̀nà mìíràn tí Jésù gbà kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni nípa fífún wọn ní ìtọ́ni tó kún rẹ́rẹ́. Kí Jésù tó rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jáde àti ṣáájú ìgbà tó rán àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn lọ láti lọ wàásù, ó ṣe ohun tá a lè pè ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ níbi tó ti fún wọn ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. (Mátíù 10:1-15; Lúùkù 10:1-12) Ìtọ́ni tó fún wọn náà sì sèso rere, nítorí Lúùkù 10:17 ròyìn pé: “Àwọn àádọ́rin náà padà dé pẹ̀lú ìdùnnú.” Ẹ jẹ́ ká wá gbé ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì tí Jésù kọ́ wọn yẹ̀ wò. Ká sì tó lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ náà, a ní láti fi àṣà àwọn Júù lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì sọ́kàn.
11 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe wá wúrà tàbí fàdákà tàbí bàbà sínú àpò ara àmùrè yín, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ fún ìrìnnà àjò náà, tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì, tàbí sálúbàtà tàbí ọ̀pá; nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀.” (Mátíù 10:9, 10) Ohun tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn ni pé kẹ́ni tó bá máa rìnrìn àjò de àmùrè tó ní àpò tí wọ́n máa fi owó sí, kó gbé àsùnwọ̀n oúnjẹ kó sì mú sálúbàtà míì yàtọ̀ sí èyí tó wọ̀ sí ẹsẹ̀ dání.a Nípa fífún wọn nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n má ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan yẹn, Jésù ń tipa báyẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé ẹkẹ̀ yín lé Jèhófà pátápátá, torí pé ó máa pèsè ohun tẹ́ ẹ bá nílò fún yín.” Jèhófà á pèsè fún wọn ní ti pé á mú kí àwọn tó bá gbọ́ ìhìn rere ṣe wọ́n lálejò, èyí tó jẹ́ àṣà wọn ní Ísírẹ́lì.—Lúùkù 22:35.
12 Jésù tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti yẹra fáwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wọn níyà. Ó ní: “Ẹ má sì gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà.” (Lúùkù 10:4) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ fún wọn ni pé kí wọ́n máa fajú ro tàbí kí wọ́n má ṣe túra ká? Kò rí bẹ́ẹ̀ o. Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ìkíni kì í ṣe ọ̀rọ̀ kéèyàn kàn ṣe “báwo ni o,” kéèyàn sì máa lọ. Nígbà yẹn, oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń kíra wọn, títí kan ọ̀rọ̀ àsọ-ọ̀-dákẹ́. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sọ pé: “Ìkíni àwọn ará Ìlà Oòrùn kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn tẹrí ba díẹ̀ tàbí kó bọ ẹlòmíì lọ́wọ́, bí èèyàn méjì bá ń kíra wọn, wọ́n á gbára wọn mọ́ra lọ́pọ̀ ìgbà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ láìmọye ìgbà kódà, wọ́n á máa dọ̀bálẹ̀ gbalaja sílẹ̀ẹ́lẹ̀. Gbogbo èyí sì ń gba àkókò tó pọ̀.” Nípa sísọ tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe kí ẹnikẹ́ni bí wọ́n ṣe sábàá máa ń kira níbẹ̀ yẹn, ohun tó ń sọ fún wọn ni pé: “Ìṣẹ́ òjíṣẹ́ yín ni kẹ́ ẹ lo àkókò yín fun o, torí iṣẹ́ tó gba kánjúkánjú ni.”b
13. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a fi àwọn ìtọ́ni tí Jésù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní sọ́kàn?
13 A máa ń fi ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní sílò. Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa, Jèhófà la máa ń fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé. (Òwe 3:5, 6) A mọ̀ pé a ò ní ṣaláìní àwọn kò-ṣeé-mánìí ìgbésí ayé bá a bá ń wá “ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Àwọn oníwàásù alákòókò kíkún tó wà káàkiri ayé lè jẹ́rìí sí i pé ọwọ́ Jèhófà ò kúrú, kódà lákòókò tí nǹkan bá nira. (Sáàmù 37:25) A tún mọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ gbà kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà. Bá a ò bá kíyè sára, ètò àwọn nǹkan yìí lè pín ọkàn wa níyà tìrọ̀rùntìrọ̀rùn. (Lúùkù 21:34-36) Kì í sì í ṣe irú àkókò yìí ló yẹ ká dẹni tí ọkàn rẹ̀ pínyà. Nítorí ẹ̀mí àwọn èèyàn tó wà nínú ewu, a ò gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ yìí falẹ̀. (Róòmù 10:13-15) Bá a bá ń fi sọ́kàn pé iṣẹ́ tó gba kánjúkánjú ló wà níkàáwọ́ wa, kò ní jẹ́ ká fàyè gba àwọn nǹkan tó ń pín ọkàn níyà nínú ayé yìí láti gba àkókò àti agbára tó yẹ ká fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ má gbàgbé pé àkókò tó kù ò pọ̀ mọ́ àti pé ìkórè pọ̀.—Mátíù 9:37, 38.
Bí Iṣẹ́ Náà Ṣe Kàn Wá
14. Báwo la ṣe mọ̀ pé gbogbo ọmọlẹ́yìn Kristi ni iṣẹ́ tó wà nínú Mátíù 28:18-20 kàn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
14 Iṣẹ́ ńlá ni Jésù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jí dìde gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” Kì í ṣe kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn lórí òkè ní Gálílì ló ní lọ́kàn.c Iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́ kan, wíwàásù fún “àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè,” iṣẹ́ náà sì ń bá a lọ “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Èyí mú kó ṣe kedere pé gbogbo ẹni tó bá ń tọ Kristi lẹ́yìn ni iṣẹ́ yìí kàn títí kan àwa tòde òní pẹ̀lú. Ẹ wá jẹ́ ká fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 28:18-20.
15. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu fún wa pé ká tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?
15 Kó tó gbé iṣẹ́ yẹn lé wọn lọ́wọ́, ó ní: “Gbogbo àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Ẹsẹ 18) Ṣé lóòótọ́ ni Jésù ní irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀? Kò purọ́, bó ṣe rí nìyẹn! Òun ni olú-áńgẹ́lì, tó ń darí àìmọye ọ̀kẹ́ àwọn áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16; Ìṣípayá 12:7) Gẹ́gẹ́ bí “orí ìjọ,” ó ní àṣẹ lórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Éfésù 5:23) Látọdún 1914 wá, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba ní ọ̀run. (Ìṣípayá 11:15) Kódà àṣẹ rẹ̀ dénú sàréè, nítorí pé ó ní agbára láti jí òkú dìde. (Jòhánù 5:26-28) Sísọ tó kọ́kọ́ sọ nípa bí àṣẹ tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e kì í ṣe àbá bí kò ṣe àṣẹ. Ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa ni pé ká ṣe ohun tó sọ pé ká ṣe nítorí pé òun kọ́ ló gbé àṣẹ yẹn léra rẹ̀ lọ́wọ́, Ọlọ́run ló gbé e lé e lọ́wọ́.—1 Kọ́ríńtì 15:27.
16. Kí ni Jésu ń pàṣẹ fún wa pé ká ṣe nígbà tó sọ fún wa pé ká “lọ”?
16 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í to iṣẹ́ náà lẹ́sẹẹsẹ, ohùn tó sì kọ́kọ́ sọ ni pé: “Ẹ lọ.” (Ẹsẹ 19) Ó tipa báyìí pa á láṣẹ fún wa pé ká fúnra wa lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe iṣẹ́ yìí láti mú àṣẹ yìí ṣẹ. Wíwàásù láti ilé dé ilé ni ọ̀nà tó dáa jù láti gbà rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. (Ìṣe 20:20) A tún máa ń lo àǹfààní tá a bá ní láti wàásù nígbà tí a ò bá sí lóde ẹ̀rí; a máa ń fẹ́ láti dá ìjíròrò nípa ìhìn rere sílẹ̀ níbi yòówù tó bá bójú mu nígbà tá a bá wà lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Onírúurú ọ̀nà ìwàásù la lè lò, ó sinmi lórí irú àwọn tó wà ládùúgbò wa àti bí àdúgbò náà ṣe rí. Ohun kan ni kì í yàtọ̀ nípa bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ náà, nǹkan ọ̀hún ni pé: A máa ń “lọ” láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn.—Mátíù 10:11.
17. Báwo la ṣe “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn”?
17 Lẹ́yìn náà, Jésù wá sọ ìdí tó fi gbé iṣẹ́ náà lé wa lọ́wọ́, ó ní ká “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Ẹsẹ̀ 19) Báwo la ṣe máa ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’? Ọmọ ẹ̀yìn lẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà, sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kì í ṣe ọ̀rọ̀ kíkó ìmọ̀ sí ẹnì kan lágbárí. Nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tá a tìtorí rẹ̀ ń kọ́ wọn ni pé kí wọ́n lè di ẹni tó ń tọ Kristi lẹ́yìn. Ní gbogbo ìgbà tó bá yẹ, a gbọ́dọ̀ tẹnu mọ́ àpẹẹrẹ Jésù kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa bàa lè rí Jésù bí Olùkọ́ wọn àti Ẹni tí wọ́n ní láti máa wo àwòṣe rẹ̀, kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó gbà gbé tiẹ̀ kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ tó ṣe.—Jòhánù 13:15.
18. Kí nìdí tí ìbatisí fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi?
18 Bí Jésù ṣe sọ apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú iṣẹ́ ọ̀hún rèé, ó ní: “Ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Ẹsẹ 19) Ìbatisí jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ọmọ ẹ̀yìn, torí òun gan-an lohun tó máa fi hàn pé ẹni náà ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tọkàntọkàn fún Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì fún ìgbàlà. (1 Pétérù 3:21) Nítorí náà, bí ọmọ ẹ̀yìn tó ṣèrìbọmi náà bá ń bá a lọ láti máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó máa retí ìbùkún jaburata nínú ayé tuntun tó ń bọ̀. Ṣó o ti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ṣe batisí rí? Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, kò sí nǹkan ayọ̀ tó jùyẹn lọ.—3 Jòhánù 4.
19. Kí la máa ń kọ́ àwọn ẹni tuntun, kí sì nìdí tá a fi lè máa kọ́ wọn nìṣó lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣèrìbọmi?
19 Jésù wá sọ èyí tó kàn nínu iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́, ó ní: “Ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Ẹsẹ 20) A máa ń kọ́ àwọn ẹni tuntun láti máa ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù títí kan èyí tó fi sọ fún wa pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò àti pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 22:37-39) A máa ń kọ́ wọn ní bí wọ́n á ṣe lè ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì àti bí wọ́n á ṣe máa fi ẹ̀rí gbe ìgbàgbọ́ wọn tó ń jinlẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Bí wọ́n bá ti yẹ lẹni tó lè jáde fún iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń bá wọn ṣiṣẹ́ ká lè kọ́ wọn nínú ọ̀rọ̀ àti nípasẹ̀ àpẹẹrẹ wa béèyàn ṣe lè ṣe iṣẹ́ náà tó fi máa yọrí sí rere. Kì í ṣe pé ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn gbọ́dọ̀ parí sórí ìrìbọmi wọn. Ó ṣeé ṣe káwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi nílò ìtọ́ni síwájú sí i láti lè kojú ohun tó lè jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti máa tọ Kristi lẹ́yìn.—Lúùkù 9:23, 24.
“Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”
20, 21. (a) Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́, kí ló dé tá ò fi gbọ́dọ̀ bẹ̀rù? (b) Kí nìdí tí a ò fi gbọ́dọ̀ dẹwọ́ lásìkò yìí, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ pinnu bẹ́ẹ̀?
20 Ọ̀rọ̀ tí Jésù fi parí iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni, ó ní: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Jésù mọ̀ pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lòun gbé lé wa lọ́wọ́. Ó sì tún mọ̀ pé àwọn kan ò ní ṣàì máa ta kò wá lẹnu iṣẹ́ náà. (Lúùkù 21:12) Àmọ́, ó dájú pé kò sídìí láti bẹ̀rù. Aṣíwájú wa kò dá wa dá iṣẹ́ náà. Ǹjẹ́ ọkàn wa ò balẹ̀ láti mọ̀ pé Ẹni tí “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” wà níkàáwọ́ rẹ̀ wà lẹ́yìn wa bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí?
21 Jésù fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé òun á wà lẹ́yìn wọn jálẹ̀ gbogbo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún títí “dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Títí dìgbà tí òpin á fi dé, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti máa ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ náà. Àkókò tá a wà yìí kì í ṣe àkókò láti dẹwọ́. Ìkórè tẹ̀mí rẹpẹtẹ ń bẹ! À ń kó ogunlọ́gọ̀ àwọn tó ń gba ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń tọ Kristi lẹ́yìn, ǹjẹ́ ká pinnu láti ṣe iṣẹ́ ńlá tó gbé lé wa lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti lo àkókò wa, agbára wa àti dúkìá wa lẹ́nu iṣẹ́ tí Kristi pa láṣẹ fún wa pé ká ṣe nígbà tó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.”
a Ó ṣeé ṣe kí àpò ara àmùrè jẹ́ oríṣi àpò kan tó máa ń wà lára ìgbànú tó wà fún kíkó owó ẹyọ sí. Àsùnwọ̀n oúnjẹ máa ń tóbi díẹ̀, awọ ni wọ́n sì sábà máa ń fi ṣe é, wọ́n máa ń gbé e kọ́ èjìká, inú rẹ̀ ni wọ́n máa ń kó oúnjẹ tàbí àwọn èlò mìíràn sí.
b Wòlíì Èlíṣà ti fún ìránṣẹ́ rẹ̀ nírú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ rí. Nígbà tó ń rán Géhásì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sílé obìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ kú, Èlíṣà sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o bá ẹnikẹ́ni pàdé, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kí i.” (2 Àwọn Ọba 4:29) Iṣẹ́ kánjúkánjú ni, kò sídìí láti fi àkókò ṣòfò.
c Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní Gálílì nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Mátíù 28:16-20 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni Jésù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde náà fara han àwọn “tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará” lọ. (1 Kọ́ríńtì 15:6) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìmọye ọmọlẹ́yìn ló wà ńbẹ̀ nígbà tí Jésù gbé iṣẹ́ sísọni-di-ọmọ-ẹ̀yìn lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́.