Àkọsílẹ̀ Jòhánù
13 Torí pé Jésù ti mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ Ìrékọjá pé wákàtí òun ti tó+ láti kúrò ní ayé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba,+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tó wà ní ayé, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.+ 2 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Èṣù sì ti fi sínú ọkàn Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ ọmọ Símónì, pé kó dà á.+ 3 Jésù mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ,+ 4 torí náà, ó dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ó wá mú aṣọ ìnura, ó sì so ó mọ́ ìbàdí.*+ 5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ń fi aṣọ ìnura tó so mọ́ ìbàdí* nù ún gbẹ. 6 Ó wá dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù. Ó bi í pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi ni?” 7 Jésù dá a lóhùn pé: “Ohun tí mò ń ṣe ò tíì yé ọ báyìí, àmọ́ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, ó máa yé ọ.” 8 Pétérù sọ fún un pé: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù dá a lóhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ,+ o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.” 9 Símónì Pétérù bá sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” 10 Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.” 11 Torí ó mọ ẹni tó máa da òun.+ Ìdí nìyí tó fi sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo yín lẹ mọ́.”
12 Lẹ́yìn tó fọ ẹsẹ̀ wọn tán, tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó pa dà jókòó* sídìí tábìlì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? 13 Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn.+ 14 Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín,+ ó yẹ* kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín.+ 15 Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.+ 16 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. 17 Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.+ 18 Gbogbo yín kọ́ ni mò ń bá wí; mo mọ àwọn tí mo ti yàn. Àmọ́ èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ+ pé: ‘Ẹni tí a jọ ń jẹun ti jìn mí lẹ́sẹ̀.’*+ 19 Láti ìsinsìnyí lọ, mò ń sọ fún yín kó tó ṣẹlẹ̀, kó lè jẹ́ pé tó bá ṣẹlẹ̀, ẹ máa lè gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà.+ 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹni yòówù tí mo rán gba èmi náà,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.”+
21 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara wọn, torí ọ̀rọ̀ náà rú wọn lójú, wọn ò mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 23 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́,+ jókòó* sí tòsí* Jésù. 24 Torí náà, Símónì Pétérù mi orí sí ẹni yìí, ó sì sọ fún un pé: “Sọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ fún wa.” 25 Ẹni yẹn wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”+ 26 Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.”+ Torí náà, lẹ́yìn tó ki búrẹ́dì bọ inú abọ́, ó mú un fún Júdásì, ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù. 27 Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì náà, Sátánì wọ inú Júdásì.+ Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” 28 Àmọ́ ìkankan nínú àwọn tó jókòó sídìí tábìlì ò mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ fún un. 29 Àwọn kan tiẹ̀ ń rò pé torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó wà,+ ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé, “Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà” tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan. 30 Torí náà, lẹ́yìn tó gba búrẹ́dì náà, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ilẹ̀ sì ti ṣú.+
31 Torí náà, lẹ́yìn tó jáde, Jésù sọ pé: “Ní báyìí, a ṣe Ọmọ èèyàn lógo,+ a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe Ọlọ́run lógo. 32 Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa ṣe é lógo,+ ó sì máa ṣe é lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ìgbà díẹ̀ sí i ni màá fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ máa wá mi; bí mo sì ṣe sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ,’+ mò ń sọ fún ẹ̀yin náà báyìí. 34 Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín,+ kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 35 Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”+
36 Símónì Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, ibo lò ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “O ò lè tẹ̀ lé mi lọ síbi tí mò ń lọ báyìí, àmọ́ o máa tẹ̀ lé mi tó bá yá.”+ 37 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló dé tí mi ò lè tẹ̀ lé ọ báyìí? Màá fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”+ 38 Jésù dáhùn pé: “Ṣé o máa fi ẹ̀mí* rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ó dájú pé àkùkọ ò ní kọ tí wàá fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+