ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9Ẹ
‘Àkókò Ìmúbọ̀sípò Ohun Gbogbo’
ÌṢE 3:21
Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo,’ ṣe ló ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò gígùn kan tó máa bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí Kristi bá di Ọba títí dé ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
1914—Jésù Kristi di Ọba ní ọ̀run. Àwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí lọ́dún 1919
Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
AMÁGẸ́DỌ́NÌ—Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bẹ̀rẹ̀, ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ sì tún máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé gbádùn àwọn ìbùkún tara
Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso
ẸGBẸ̀RÚN ỌDÚN ÌṢÀKÓSO KRISTI PARÍ—Jésù parí iṣẹ́ rẹ̀ láti mú kí gbogbo nǹkan pa dà bọ̀ sípò, ó sì dá Ìjọba náà pa dà fún Bàbá rẹ̀
Párádísè Títí Ayé
ÌṢÀKÓSO JÉSÙ MÁA MÚ KÍ . . .
orúkọ Ọlọ́run pa dà di ológo
ara àwọn aláìsàn yá
àwọn arúgbó pa dà di ọ̀dọ́
àwọn òkú jíǹde
àwọn olóòótọ́ èèyàn pa dà di ẹni pípé
ayé pa dà di Párádísè