ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 16A
Ṣé Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ni Ìlú Jerúsálẹ́mù Ṣàpẹẹrẹ?
Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ìtẹ̀jáde wa ti máa ń sọ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà ṣàpẹẹrẹ. Ó dájú pé ìwà àìṣòótọ́ táwọn èèyàn hù nílùú Jerúsálẹ́mù, títí kan ìbọ̀rìṣà àti ìwà ìbàjẹ́ tó gbilẹ̀ níbẹ̀ rán wa létí àwọn ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe lóde òní. Àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ìtẹ̀jáde wa, títí kan èyí tí ẹ̀ ń kà lọ́wọ́ yìí, kì í ṣe irú ìfiwéra bẹ́ẹ̀, àfi tí Bíbélì bá fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ṣé Ìwé Mímọ́ sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù ṣàpẹẹrẹ? Rárá o.
Ẹ jẹ́ ká wò ó ná: Ìgbà kan wà tí Jerúsálẹ́mù jẹ́ ojúkò ìjọsìn mímọ́; nígbà tó yá, àwọn ará ìlú náà di apẹ̀yìndà. Àmọ́ ní ti ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì, kò fìgbà kankan jẹ́ ìjọsìn mímọ́ rí. Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti wà ló ti jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ni wọ́n fi ń kọ́ni.
Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn tí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, Jèhófà mú kí ìlú náà pa dà rí ojúure òun, ó sì pa dà di ojúkò ìjọsìn mímọ́. Àmọ́ inú Ọlọ́run ò fìgbà kankan dùn sí ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì, tó bá sì pa run nígbà ìpọ́njú ńlá, kò ní pa dà gbérí mọ́.
Kí la rí fà yọ nínú ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí? Tá a bá wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ṣẹ sórí ìlú Jerúsálẹ́mù táwọn èèyàn rẹ̀ ya aláìṣòótọ́, a lè sọ pé, ‘Ó rán wa létí àwọn ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe lóde òní.’ Àmọ́ a rí i pé Ìwé Mímọ́ ò sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù ṣàpẹẹrẹ.