Jẹ́nẹ́sísì
36 Èyí ni ìtàn Ísọ̀, ìyẹn Édómù.+
2 Ísọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì: Ádà+ ọmọ Élónì ọmọ Hétì;+ Oholibámà+ ọmọ Ánáhì, ọmọ ọmọ Síbéónì ọmọ Hífì; 3 àti Básémátì+ ọmọ Íṣímáẹ́lì, arábìnrin Nébáótì.+
4 Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Básémátì bí Réúẹ́lì,
5 Oholibámà sì bí Jéúṣì, Jálámù àti Kórà.+
Àwọn ni ọmọ Ísọ̀ tí wọ́n bí fún un ní ilẹ̀ Kénáánì. 6 Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ kó àwọn ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, gbogbo àwọn* tó wà ní agbo ilé rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹran rẹ̀ yòókù, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tó ti ní+ nílẹ̀ Kénáánì, ó sì lọ sí ilẹ̀ míì, níbi tó jìnnà sí Jékọ́bù àbúrò+ rẹ̀. 7 Torí ohun ìní wọn ti pọ̀ débi pé wọn ò lè máa gbé pa pọ̀, ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé* ò sì lè tó wọn mọ́ torí agbo ẹran wọn. 8 Ísọ̀ wá ń gbé ní agbègbè olókè Séírì.+ Ísọ̀ ni Édómù.+
9 Èyí ni ìtàn Ísọ̀, bàbá Édómù ní agbègbè olókè Séírì.+
10 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísọ̀ nìyí: Élífásì ọmọ Ádà ìyàwó Ísọ̀; Réúẹ́lì ọmọ Básémátì ìyàwó Ísọ̀.+
11 Àwọn ọmọ Élífásì ni Témánì,+ Ómárì, Séfò, Gátámù àti Kénásì.+ 12 Tímínà di wáhàrì* Élífásì ọmọ Ísọ̀. Nígbà tó yá, ó bí Ámálékì+ fún Élífásì. Àwọn ni ọmọ Ádà ìyàwó Ísọ̀.
13 Àwọn ọmọ Réúẹ́lì nìyí: Náhátì, Síírà, Ṣámà àti Mísà. Àwọn ni ọmọ Básémátì+ ìyàwó Ísọ̀.
14 Àwọn ọmọ tí Oholibámà ọmọ Ánáhì, ọmọ ọmọ Síbéónì, ìyàwó Ísọ̀ bí fún Ísọ̀ nìyí: Jéúṣì, Jálámù àti Kórà.
15 Àwọn tó jẹ́ séríkí* nínú àwọn ọmọ Ísọ̀+ nìyí: Àwọn ọmọkùnrin Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀ ni: Séríkí Témánì, Séríkí Ómárì, Séríkí Séfò, Séríkí Kénásì,+ 16 Séríkí Kórà, Séríkí Gátámù àti Séríkí Ámálékì. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Élífásì+ ní ilẹ̀ Édómù. Àwọn ọmọ Ádà nìyẹn.
17 Àwọn ọmọkùnrin Réúẹ́lì ọmọ Ísọ̀ nìyí: Séríkí Náhátì, Séríkí Síírà, Séríkí Ṣámà àti Séríkí Mísà. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Réúẹ́lì ní ilẹ̀ Édómù.+ Àwọn ni ọmọ Básémátì ìyàwó Ísọ̀.
18 Àwọn ọmọ Oholibámà ìyàwó Ísọ̀ sì nìyí: Séríkí Jéúṣì, Séríkí Jálámù àti Séríkí Kórà. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Oholibámà ọmọ Ánáhì, ìyàwó Ísọ̀.
19 Àwọn ọmọ Ísọ̀ nìyẹn, àwọn séríkí wọn sì nìyẹn. Òun ni Édómù.+
20 Àwọn ọmọ Séírì ọmọ Hórì tí wọ́n ń gbé ilẹ̀+ náà nìyí: Lótánì, Ṣóbálì, Síbéónì, Ánáhì,+ 21 Díṣónì, Ésérì àti Díṣánì.+ Àwọn ni séríkí àwọn Hórì, àwọn ọmọ Séírì, ní ilẹ̀ Édómù.
22 Àwọn ọmọ Lótánì ni Hórì àti Hémámù, arábìnrin Lótánì sì ni Tímínà.+
23 Àwọn ọmọ Ṣóbálì nìyí: Álífánì, Manáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Ónámù.
24 Àwọn ọmọ Síbéónì+ nìyí: Áyà àti Ánáhì. Òun ni Ánáhì tó rí àwọn ìsun omi gbígbóná nínú aginjù nígbà tó ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Síbéónì bàbá rẹ̀.
25 Àwọn ọmọ Ánáhì nìyí: Díṣónì àti Oholibámà ọmọbìnrin Ánáhì.
26 Àwọn ọmọ Díṣónì nìyí: Hémúdánì, Éṣíbánì, Ítíránì àti Kéránì.+
27 Àwọn ọmọ Ésérì nìyí: Bílíhánì, Sááfánì àti Ékánì.
28 Àwọn ọmọ Díṣánì nìyí: Úsì àti Áránì.+
29 Àwọn séríkí àwọn Hórì nìyí: Séríkí Lótánì, Séríkí Ṣóbálì, Séríkí Síbéónì, Séríkí Ánáhì, 30 Séríkí Díṣónì, Séríkí Ésérì àti Séríkí Díṣánì.+ Àwọn ni séríkí àwọn Hórì, wọ́n jẹ́ séríkí káàkiri ilẹ̀ Séírì.
31 Àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Édómù+ nìyí kí ọba kankan tó jẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.*+ 32 Bélà ọmọ Béórì jọba ní Édómù, orúkọ ìlú rẹ̀ sì ni Dínhábà. 33 Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Síírà láti Bósírà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 34 Nígbà tí Jóbábù kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 35 Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Mídíánì+ ní agbègbè* Móábù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀, orúkọ ìlú rẹ̀ sì ni Áfítì. 36 Nígbà tí Hádádì kú, Sámúlà láti Másírékà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 37 Nígbà tí Sámúlà kú, Ṣéọ́lù láti Réhóbótì tó wà lẹ́gbẹ́ẹ̀ Odò bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 38 Nígbà tí Ṣéọ́lù kú, Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 39 Nígbà tí Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì kú, Hádárì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, orúkọ ìyàwó rẹ̀ sì ni Méhétábélì ọmọ Mátírédì ọmọbìnrin Mésáhábù.
40 Orúkọ àwọn séríkí tó jẹ́ ọmọ Ísọ̀ nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ibi tí wọ́n ń gbé àti orúkọ wọn: Séríkí Tímínà, Séríkí Álíífà, Séríkí Jététì,+ 41 Séríkí Oholibámà, Séríkí Élà, Séríkí Pínónì, 42 Séríkí Kénásì, Séríkí Témánì, Séríkí Míbúsárì, 43 Séríkí Mágídíélì àti Séríkí Írámù. Àwọn ni séríkí Édómù gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ tó jẹ́ ohun ìní+ wọn. Èyí ni Ísọ̀, bàbá Édómù.+