Kíróníkà Kejì
1 Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ń lágbára sí i nínú ìjọba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá tó ta yọ.+
2 Sólómọ́nì ránṣẹ́ pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé. 3 Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ náà lọ sí ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ torí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé Ọlọ́run tòótọ́ wà, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa ní aginjù. 4 Àmọ́, Dáfídì ti gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì ṣètò sílẹ̀ fún un; ó ti pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+ 5 Wọ́n ti gbé pẹpẹ bàbà+ tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì ṣe sí iwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ sì máa ń gbàdúrà níwájú rẹ̀.* 6 Sólómọ́nì wá rú àwọn ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹran ẹbọ sísun ló sì fi rúbọ lórí pẹpẹ bàbà+ tó wà ní àgọ́ ìpàdé.
7 Ní òru yẹn, Ọlọ́run fara han Sólómọ́nì, ó sì sọ fún un pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 8 Ni Sólómọ́nì bá sọ fún Ọlọ́run pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Dáfídì bàbá mi+ lọ́nà tó ga, o sì ti fi mí jọba ní ipò rẹ̀.+ 9 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ,+ nítorí o ti fi mí jọba lórí àwọn èèyàn tó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.+ 10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tí màá fi máa darí àwọn èèyàn yìí,* nítorí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ yìí?”+
11 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12 màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+
13 Nítorí náà, Sólómọ́nì dé láti ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ láti iwájú àgọ́ ìpàdé, sí Jerúsálẹ́mù; ó sì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. 14 Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ;* ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 15 Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 16 Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì,+ àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 17 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.