-
Jẹ́nẹ́sísì 49:29-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Wọn ò ní pẹ́ kó mi jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn mi.*+ Torí náà, kí ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn bàbá mi sínú ihò tó wà lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Hétì,+ 30 ihò tó wà lórí ilẹ̀ Mákípẹ́là níwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú. 31 Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù àti Sérà+ ìyàwó rẹ̀ sí. Ibẹ̀ náà ni wọ́n sin Ísákì+ àti Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sí, ibẹ̀ sì ni mo sin Líà sí. 32 Ọwọ́ àwọn ọmọ Hétì+ ni Ábúráhámù ti ra ilẹ̀ náà àti ihò tó wà nínú rẹ̀.”
33 Nígbà tí Jékọ́bù fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìtọ́ni wọ̀nyí tán, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ sórí ibùsùn, ó mí èémí ìkẹyìn, wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.*+
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 50:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú ihò tó wà ní ilẹ̀ Mákípẹ́là, ilẹ̀ tó wà níwájú Mámúrè tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+ 14 Lẹ́yìn tó sin bàbá rẹ̀, Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e lọ sìnkú bàbá rẹ̀.
-