-
2 Kíróníkà 28:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àwọn Filísínì+ náà tún wá kó ẹrù àwọn èèyàn ní àwọn ìlú Ṣẹ́fẹ́là+ àti Négébù ti Júdà, wọ́n sì gba Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ Áíjálónì,+ Gédérótì, Sókò àti àwọn àrọko rẹ̀,* Tímúnà+ àti àwọn àrọko rẹ̀ pẹ̀lú Gímúsò àti àwọn àrọko rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé níbẹ̀. 19 Jèhófà rẹ Júdà wálẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, torí ó ti jẹ́ kí ìwàkiwà gbilẹ̀ ní Júdà, èyí sì mú kí wọ́n máa hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà lọ́nà tó ga.
-