-
1 Àwọn Ọba 7:48-50Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
48 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, àwọn ni: pẹpẹ+ wúrà; tábìlì wúrà+ tí wọ́n á máa kó búrẹ́dì àfihàn sí; 49 àwọn ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, márùn-ún lápá ọ̀tún àti márùn-ún lápá òsì níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún; àwọn ìtànná òdòdó,+ àwọn fìtílà àti àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe;+ 50 àwọn bàsíà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà,+ àwọn abọ́, àwọn ife+ àti àwọn ìkóná+ tí á fi ògidì wúrà ṣe; ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé inú lọ́hùn-ún,+ ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì+ tí a fi wúrà ṣe.
-