37 Torí náà, Senakérúbù ọba Ásíríà kúrò níbẹ̀, ó pa dà sí Nínéfè,+ ó sì ń gbé ibẹ̀.+ 38 Bó ṣe ń forí balẹ̀ ní ilé Nísírọ́kì ọlọ́run rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, Adiramélékì àti Ṣárésà fi idà pa á,+ wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.