-
2 Àwọn Ọba 21:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Mánásè ta ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé ó kún Jerúsálẹ́mù láti ìkángun kan dé ìkángun kejì,+ yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ èyí tí ó mú Júdà ṣẹ̀, tí wọ́n fi ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.
-
-
Àìsáyà 59:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;
Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+
-
-
Mátíù 23:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú, 35 kí ẹ lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ayé, látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ olódodo dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà ọmọ Barakáyà, ẹni tí ẹ pa láàárín ibi mímọ́ àti pẹpẹ.+
-