-
Ìsíkíẹ́lì 1:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ohun tó rí bí òkúta sàfáyà+ wà lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn, ó dà bí ìtẹ́.+ Ẹnì kan tó rí bí èèyàn sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 27 Mo sì rí ohun kan tó ń dán yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà,+ ó rí bí iná, ó jọ pé ó ń jó látibi ìbàdí rẹ̀ lọ sókè; mo rí ohun kan tó dà bí iná+ láti ìbàdí rẹ̀ lọ sísàlẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká
-