-
Éfésù 1:9-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 bó ṣe jẹ́ ká mọ àṣírí mímọ́+ nípa ìfẹ́ rẹ̀. Èyí bá ohun tó ń wù ú mu, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò 10 iṣẹ́ àbójútó kan* láti kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi nígbà tí àwọn àkókò tí a yàn bá tó, àwọn ohun tó wà ní ọ̀run àti àwọn ohun tó wà ní ayé.+ Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ẹni 11 tí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí a sì yàn wá láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú rẹ̀,+ ní ti pé a ti yàn wá ṣáájú nítorí ohun tí ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo fẹ́, bí ó ṣe ń pinnu ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, 12 kí iṣẹ́ ìsìn àwa tí a kọ́kọ́ nírètí nínú Kristi lè yìn ín lógo.
-
-
Kólósè 1:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 àṣírí mímọ́+ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ti kọjá+ àti láti àwọn ìran tó ti kọjá. Àmọ́ ní báyìí, a ti fi han àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 27 ìyẹn àwọn tó wu Ọlọ́run pé kí wọ́n mọ ọrọ̀ ológo nípa àṣírí mímọ́ yìí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ àṣírí yìí ni Kristi tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín, ìyẹn ìrètí ògo rẹ̀.+
-