Ẹ́sírà
8 Àwọn olórí agbo ilé àti àkọsílẹ̀ orúkọ ìdílé àwọn tó tẹ̀ lé mi jáde kúrò ní Bábílónì nígbà ìjọba Ọba Atasásítà nìyí:+ 2 Gẹ́ṣómù, látinú àwọn ọmọ Fíníhásì;+ Dáníẹ́lì, látinú àwọn ọmọ Ítámárì;+ Hátúṣì, látinú àwọn ọmọ Dáfídì; 3 látinú àwọn ọmọ Ṣẹkanáyà àti látinú àwọn ọmọ Páróṣì, Sekaráyà, àádọ́jọ (150) ọkùnrin tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 4 látinú àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Elieho-énáì ọmọ Seraháyà, igba (200) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 5 látinú àwọn ọmọ Sátù,+ Ṣẹkanáyà ọmọ Jáhásíẹ́lì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 6 látinú àwọn ọmọ Ádínì,+ Ébédì ọmọ Jónátánì, àádọ́ta (50) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 7 látinú àwọn ọmọ Élámù,+ Jeṣáyà ọmọ Ataláyà, àádọ́rin (70) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 8 látinú àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà,+ Sebadáyà ọmọ Máíkẹ́lì, ọgọ́rin (80) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 9 látinú àwọn ọmọ Jóábù, Ọbadáyà ọmọ Jéhíélì, igba ó lé méjìdínlógún (218) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 10 látinú àwọn ọmọ Bánì, Ṣẹ́lómítì ọmọ Josifáyà, ọgọ́jọ (160) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 11 látinú àwọn ọmọ Bébáì,+ Sekaráyà ọmọ Bébáì, ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 12 látinú àwọn ọmọ Ásígádì,+ Jóhánánì ọmọ Hákátánì, àádọ́fà (110) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 13 látinú àwọn ọmọ Ádóníkámù,+ àwọn tó kẹ́yìn, orúkọ wọn nìyí: Élífélétì, Jéélì àti Ṣemáyà, ọgọ́ta (60) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú wọn 14 àti látinú àwọn ọmọ Bígífáì,+ Útáì àti Sábúdì, àádọ́rin (70) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú wọn.
15 Mo kó wọn jọ níbi odò tó ṣàn wá sí Áháfà,+ a sì pàgọ́ síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Àmọ́ nígbà tí mo yẹ àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà wò, mi ò rí ìkankan lára àwọn ọmọ Léfì níbẹ̀. 16 Torí náà, mo ránṣẹ́ pe Élíésérì, Áríélì, Ṣemáyà, Élínátánì, Járíbù, Élínátánì, Nátánì, Sekaráyà àti Méṣúlámù, wọ́n jẹ́ aṣáájú ọkùnrin, mo tún ránṣẹ́ pe Jóyáríbù àti Élínátánì tí wọ́n jẹ́ olùkọ́. 17 Mo wá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá Ídò tó jẹ́ olórí ní ibi tí wọ́n ń pè ní Kásífíà. Mo ní kí wọ́n sọ fún Ídò àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* tí wọ́n wà ní Kásífíà pé kí wọ́n bá wa mú àwọn òjíṣẹ́ wá fún ilé Ọlọ́run wa. 18 Nítorí pé ọwọ́ rere Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n mú ọlọ́gbọ́n ọkùnrin kan wá látinú àwọn ọmọ Máhílì+ ọmọ ọmọ Léfì ọmọ Ísírẹ́lì, orúkọ rẹ̀ ni Ṣerebáyà+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ méjìdínlógún (18); 19 wọ́n tún mú Haṣabáyà, Jeṣáyà látinú àwọn ọmọ Mérárì+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn, gbogbo wọn jẹ́ ogún (20) ọkùnrin. 20 Igba ó lé ogún (220) lára àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* wà, tí orúkọ gbogbo wọn wà lákọsílẹ̀. Dáfídì àti àwọn ìjòyè ló ní kí àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì máa ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́.
21 Lẹ́yìn náà, mo kéde ààwẹ̀ níbi odò Áháfà, láti rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run wa àti láti wá ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrìn àjò wa, fún àwa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ẹrù wa. 22 Ó tì mí lójú láti ní kí ọba fún wa ní àwọn ọmọ ogun àti àwọn agẹṣin láti dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá lójú ọ̀nà, torí a ti sọ fún ọba pé: “Ọwọ́ rere Ọlọ́run wa wà lára gbogbo àwọn tó ń wá a,+ àmọ́ agbára rẹ̀ àti ìbínú rẹ̀ wà lórí gbogbo àwọn tó fi í sílẹ̀.”+ 23 Torí náà, a gbààwẹ̀, a sì bẹ Ọlọ́run wa pé kó tọ́ wa sọ́nà nínú ìrìn àjò yìí, ó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.+
24 Mo wá ya àwọn méjìlá (12) sọ́tọ̀ lára àwọn olórí àlùfáà, àwọn ni, Ṣerebáyà àti Haṣabáyà+ pẹ̀lú mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn. 25 Lẹ́yìn náà, mo wọn fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò fún wọn, ọrẹ tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ mú wá fún ilé Ọlọ́run wa.+ 26 Nítorí náà, mo wọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé àádọ́ta (650) tálẹ́ńtì* fàdákà fún wọn àti ọgọ́rùn-ún (100) nǹkan èlò fàdákà tí ó tó tálẹ́ńtì méjì pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì wúrà 27 àti ogún (20) abọ́ kéékèèké tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó tó ẹgbẹ̀rún kan (1,000) owó dáríkì* àti nǹkan èlò méjì tí wọ́n fi bàbà dáradára ṣe, tó ń pọ́n yòò, tí ó sì ṣeyebíye bíi wúrà.
28 Mo wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà,+ àwọn nǹkan èlò náà sì jẹ́ mímọ́, fàdákà àti wúrà náà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín. 29 Ẹ tọ́jú wọn dáadáa títí ẹ ó fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù,+ nínú àwọn yàrá* tó wà ní ilé Jèhófà.” 30 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kó fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò tí mo wọ̀n fún wọn, kí wọ́n lè kó wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerúsálẹ́mù.
31 Níkẹyìn, a ṣí kúrò níbi odò Áháfà+ ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìíní+ láti lọ sí Jerúsálẹ́mù, ọwọ́ Ọlọ́run wa sì wà lára wa, ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá lójú ọ̀nà àti lọ́wọ́ àwọn dánàdánà. 32 Torí náà, a dé Jerúsálẹ́mù,+ a sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀. 33 Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò nínú ilé Ọlọ́run wa,+ a sì kó wọn fún Mérémótì+ ọmọ àlùfáà Úríjà, Élíásárì ọmọ Fíníhásì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì tó wà pẹ̀lú wọn ni Jósábádì+ ọmọ Jéṣúà àti Noadáyà ọmọ Bínúì.+ 34 Gbogbo nǹkan yìí ni wọ́n kà tí wọ́n sì wọ̀n, wọ́n sì kọ ìwọ̀n gbogbo wọn sílẹ̀. 35 Àwọn tó kúrò lóko ẹrú, ìyẹn àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀, rú àwọn ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì, akọ màlúù+ méjìlá (12) fún gbogbo Ísírẹ́lì àti àgbò+ mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77) àti òbúkọ+ méjìlá (12) tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Jèhófà.+
36 Lẹ́yìn náà, a fún àwọn baálẹ̀* ọba àti àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò*+ ní ìwé àṣẹ ọba,+ wọ́n sì ti àwọn èèyàn náà àti ilé Ọlọ́run tòótọ́ lẹ́yìn.+