Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
2 Ní ọjọ́ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì,+ gbogbo wọn wà níbì kan náà, bí àjọyọ̀ náà ṣe ń lọ lọ́wọ́. 2 Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run, ó dà bíi ti atẹ́gùn líle tó ń rọ́ yìì, ó sì kún gbogbo inú ilé tí wọ́n jókòó sí.+ 3 Wọ́n rí àwọn ohun tó jọ iná tó rí bí ahọ́n, wọ́n tú ká, ìkọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, 4 gbogbo wọn wá kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè,* bí ẹ̀mí ṣe mú kí wọ́n máa sọ̀rọ̀.+
5 Nígbà yẹn, àwọn Júù olùfọkànsìn láti gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ọ̀run wà ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Nígbà tí ìró yìí dún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kóra jọ, wọ́n sì ń ṣe kàyéfì, torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ èdè rẹ̀. 7 Ní tòótọ́, ẹnu yà wọ́n gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wò ó, ará Gálílì+ ni gbogbo àwọn tó ń sọ̀rọ̀ yìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? 8 Báwo ló ṣe wá jẹ́ pé kálukú wa ń gbọ́ èdè ìbílẹ̀* rẹ̀? 9 Àwọn tó wà pẹ̀lú wa ni àwọn ará Pátíà, àwọn ará Mídíà+ àti àwọn ọmọ Élámù,+ àwọn tó ń gbé Mesopotámíà, Jùdíà àti Kapadókíà, Pọ́ńtù àti ìpínlẹ̀ Éṣíà,+ 10 Fíríjíà àti Panfílíà, Íjíbítì àti àwọn agbègbè Líbíà nítòsí Kírénè, àwọn àlejò láti Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe,*+ 11 àwọn ará Kírétè pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà, gbogbo wa gbọ́ tí wọ́n ń fi èdè wa sọ nípa àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.” 12 Àní, ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń ṣe kàyéfì, wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” 13 Síbẹ̀, àwọn kan ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé: “Wọ́n ti mu wáìnì dídùn* yó.”
14 Àmọ́, Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn Mọ́kànlá náà,+ ó gbóhùn sókè, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn Jùdíà àti gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé yín, kí ẹ sì fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 15 Ní ti tòótọ́, kì í ṣe pé àwọn èèyàn yìí mutí yó bí ẹ ṣe rò, nítorí wákàtí kẹta ọjọ́ ni.* 16 Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí a gbẹnu wòlíì Jóẹ́lì sọ ni pé: 17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn,* àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá,+ 18 kódà, èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní àwọn ọjọ́ náà, wọ́n á sì máa sọ tẹ́lẹ̀.+ 19 Èmi yóò fi àwọn ohun ìyanu* hàn ní ọ̀run lókè àti àwọn iṣẹ́ àmì ní ayé nísàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti iná pẹ̀lú èéfín tó ṣú bolẹ̀. 20 Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá yóò sì di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí Jèhófà* tó dé. 21 Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà* yóò sì rí ìgbàlà.”’+
22 “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: Jésù ará Násárẹ́tì ni ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn yín ní gbangba nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àwọn ohun ìyanu* pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín,+ bí ẹ̀yin fúnra yín ṣe mọ̀. 23 Ọkùnrin yìí, tí a fà lé yín lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìpinnu* àti ìmọ̀ Ọlọ́run,+ ni ẹ ti ọwọ́ àwọn arúfin kàn mọ́gi,* tí ẹ sì pa.+ 24 Àmọ́ Ọlọ́run jí i dìde,+ bó ṣe gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ oró* ikú, torí ikú ò lè dì í mú títí lọ.+ 25 Dáfídì sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Mo gbé Jèhófà* síwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, kí mìmì kan má bàa mì mí. 26 Nítorí èyí, ara mi yá gágá, ahọ́n mi sì ń yọ̀ gidigidi. Màá* sì máa fi ìrètí gbé ayé; 27 torí o ò ní fi mí* sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.+ 28 O ti jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè; wàá mú kí ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’+
29 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ ní fàlàlà fún yín nípa Dáfídì, olórí ìdílé, pé ó kú, wọ́n sin ín,+ ibojì rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30 Nítorí pé wòlíì ni, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti búra fún òun pé òun máa gbé ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀* gorí ìtẹ́ rẹ̀,+ 31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò fi í sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.*+ 32 Ọlọ́run jí Jésù yìí dìde, gbogbo wa sì jẹ́rìí sí i.+ 33 Tóò, nítorí pé a gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ tí ó sì gba ẹ̀mí mímọ́ tí Baba ṣèlérí,+ ó tú ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ jáde. 34 Nítorí Dáfídì kò lọ sí ọ̀run, àmọ́ òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi 35 títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”’+ 36 Nítorí náà, kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi*+ ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa+ àti Kristi.”
37 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn dé ọkàn, wọ́n sì sọ fún Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, kí ni ká ṣe?” 38 Pétérù sọ fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà,+ kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín+ ní orúkọ Jésù Kristi, kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín lè ní ìdáríjì,+ ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́. 39 Nítorí ìlérí náà+ wà fún ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn ọmọ yín àti fún gbogbo àwọn tó wà lọ́nà jíjìn, fún gbogbo àwọn tí Jèhófà* Ọlọ́run wa bá pè wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀.”+ 40 Ó tún bá wọn sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀, ó jẹ́rìí kúnnákúnná, ó sì ń gbà wọ́n níyànjú, pé: “Ẹ gba ara yín lọ́wọ́ ìran oníbékebèke yìí.”+ 41 Nítorí náà, àwọn tó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi,+ ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn* ló dara pọ̀ mọ́ wọn.+ 42 Wọ́n ń tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì, wọ́n ń wà pa pọ̀,* wọ́n ń jẹun,+ wọ́n sì ń gbàdúrà.+
43 Ní tòótọ́, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba gbogbo èèyàn,* ọ̀pọ̀ ohun ìyanu* àti iṣẹ́ àmì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn àpọ́sítélì.+ 44 Gbogbo àwọn tó di onígbàgbọ́ wà pa pọ̀, wọ́n sì jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní, 45 wọ́n ń ta àwọn ohun ìní+ àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó tí wọ́n rí níbẹ̀ fún gbogbo wọn, bí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò bá ṣe pọ̀ tó.+ 46 Láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọ́n ń pésẹ̀ déédéé sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan, wọ́n ń jẹun ní ilé ara wọn, wọ́n sì ń fi ayọ̀ púpọ̀ àti òótọ́ ọkàn pín oúnjẹ fún ara wọn, 47 wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà* ń mú kí àwọn tó ń rí ìgbàlà dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.+