Kíróníkà Kìíní
22 Nígbà náà, Dáfídì sọ pé: “Ilé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ nìyí, pẹpẹ ẹbọ sísun fún Ísírẹ́lì sì nìyí.”+
2 Dáfídì wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn àjèjì+ tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jọ, ó sì yàn wọ́n ṣe agbẹ́kùúta láti máa gé òkúta, kí wọ́n sì máa gbẹ́ òkúta tí wọ́n á fi kọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 3 Dáfídì tún pèsè irin tó pọ̀ gan-an láti fi ṣe ìṣó ilẹ̀kùn àwọn ẹnubodè àti àwọn ẹ̀mú,* bákan náà, ó pèsè bàbà tó pọ̀ débi pé kò ṣeé wọ̀n+ 4 àti ẹ̀là gẹdú kédárì+ tí kò níye, nítorí àwọn ọmọ Sídónì + àti àwọn ará Tírè+ kó ẹ̀là gẹdú kédárì tó pọ̀ gan-an wá fún Dáfídì. 5 Dáfídì sì sọ pé: “Sólómọ́nì ọmọ mi jẹ́ ọ̀dọ́, kò sì ní ìrírí,*+ ilé tí a máa kọ́ fún Jèhófà sì máa lẹ́wà yàtọ̀,+ kí wọ́n lè gbọ́ nípa òkìkí àti ẹwà rẹ̀+ ní gbogbo ilẹ̀.+ Nítorí náà, màá pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún un.” Dáfídì wá pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan ìkọ́lé sílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀.
6 Ó tún pe Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀, ó sì ní kó kọ́ ilé fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 7 Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Ní tèmi, ìfẹ́ ọkàn mi ni láti kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi.+ 8 Àmọ́ Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, ‘O ti ta ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an sílẹ̀, o sì ti ja àwọn ogun ńlá. O ò ní kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí o ti ta ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an sílẹ̀ níwájú mi. 9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+ 10 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.+ Á di ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ Màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.’+
11 “Wò ó, ọmọ mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o ṣe àṣeyọrí, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.+ 12 Kìkì pé kí Jèhófà fún ọ ní làákàyè àti òye+ nígbà tó bá fún ọ ní àṣẹ lórí Ísírẹ́lì, kí o lè máa pa òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́.+ 13 Wàá sì ṣàṣeyọrí tí o bá rí i pé o tẹ̀ lé àwọn ìlànà+ àti ìdájọ́ tí Jèhófà ní kí Mósè fún Ísírẹ́lì.+ Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má bẹ̀rù, má sì jáyà.+ 14 Wò ó, mo ti sapá gan-an láti pèsè ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) tálẹ́ńtì* wúrà sílẹ̀ fún ilé Jèhófà àti mílíọ̀nù kan (1,000,000) tálẹ́ńtì fàdákà pẹ̀lú bàbà àti irin+ tó pọ̀ gan-an débi pé kò ṣeé wọ̀n, mo sì ti pèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta+ sílẹ̀, àmọ́ wàá fi kún wọn. 15 Àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ wà pẹ̀lú rẹ, ìyẹn àwọn agbẹ́kùúta, àwọn oníṣẹ́ òkúta+ àti àwọn oníṣẹ́ igi pẹ̀lú onírúurú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.+ 16 Wúrà, fàdákà, bàbà àti irin náà pọ̀ débi pé kò ṣeé wọ̀n.+ Dìde kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”+
17 Dáfídì wá pàṣẹ fún gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ran Sólómọ́nì ọmọ òun lọ́wọ́, ó ní: 18 “Ṣebí Jèhófà Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú yín, ṣebí ó ti fún yín ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tó yí yín ká? Nítorí ó fi àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́, a sì ti ṣẹ́gun ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀. 19 Ní báyìí, ẹ pinnu pé ẹ máa fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ibi mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́,+ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti àwọn nǹkan èlò mímọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́+ wá sínú ilé tí a kọ́ fún orúkọ Jèhófà.”+