Dáníẹ́lì
8 Ní ọdún kẹta àkóso Ọba Bẹliṣásárì,+ èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan, lẹ́yìn èyí tí mo kọ́kọ́ rí.+ 2 Mo rí ìran náà, bí mo sì ṣe ń wò ó, mo wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* tó wà ní ìpínlẹ̀* Élámù;+ mo rí ìran náà, mo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ipadò Úláì. 3 Nígbà tí mo gbé ojú mi sókè, wò ó! àgbò+ kan dúró níwájú ipadò náà, ó sì ní ìwo méjì.+ Ìwo méjèèjì ga, àmọ́ ọ̀kan ga ju ìkejì lọ, èyí tó ga jù sì jáde wá lẹ́yìn náà.+ 4 Mo rí i tí àgbò náà ń kàn ní ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù, kò sí ẹran inú igbó kankan tó lè dúró níwájú rẹ̀, kò sì sí ẹni tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.*+ Ohun tó wù ú ló ń ṣe, ó sì gbé ara rẹ̀ ga.
5 Bí mo ṣe ń wò, mo rí òbúkọ+ kan tó ń bọ̀ láti ìwọ̀ oòrùn,* ó ń kọjá lọ ní gbogbo ayé láìfi ẹsẹ̀ kanlẹ̀. Òbúkọ náà sì ní ìwo kan tó hàn kedere láàárín àwọn ojú rẹ̀.+ 6 Ó ń bọ̀ lọ́dọ̀ àgbò tó ní ìwo méjì náà, tí mo rí tó dúró níwájú ipadò; ó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú tó le gan-an.
7 Mo rí i tó ń sún mọ́ àgbò náà, ó sì kórìíra rẹ̀ gan-an. Ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì, àgbò náà ò sì lágbára láti dìde sí i. Ó la àgbò náà mọ́lẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sẹ́ni tó gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.*
8 Òbúkọ náà wá gbé ara rẹ̀ ga kọjá ààlà, àmọ́ gbàrà tó di alágbára, ìwo ńlá náà ṣẹ́; ìwo mẹ́rin tó hàn kedere sì jáde dípò ìwo kan ṣoṣo náà, wọ́n dojú kọ atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.+
9 Ìwo míì jáde látinú ọ̀kan lára wọn, ìwo kékeré ni, ó sì di ńlá gan-an, sí apá gúúsù, sí apá ìlà oòrùn* àti sí Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.*+ 10 Ó di ńlá débi pé ó dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó sì mú kí àwọn ọmọ ogun kan àti àwọn ìràwọ̀ kan já bọ́ sí ayé, ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 11 Ó gbéra ga sí Olórí àwọn ọmọ ogun pàápàá, a sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi tó fìdí múlẹ̀ ní ibi mímọ́ rẹ̀ lulẹ̀.+ 12 A fi àwọn ọmọ ogun kan léni lọ́wọ́, pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo,* torí ẹ̀ṣẹ̀; ó sì ń wó òtítọ́ lulẹ̀ ṣáá, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì ṣàṣeyọrí.
13 Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ kan ń sọ̀rọ̀, ẹni mímọ́ míì sì sọ fún ẹni tó ń sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* àti ti ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ìsọdahoro ṣe máa pẹ́ tó,+ láti sọ ibi mímọ́ náà àti àwọn ọmọ ogun náà di ohun tí wọ́n ń tẹ̀ mọ́lẹ̀?” 14 Ó wá sọ fún mi pé: “Títí di ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (2,300) alẹ́ àti àárọ̀; ó dájú pé ibi mímọ́ náà máa pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà.”
15 Bí èmi Dáníẹ́lì ṣe ń rí ìran náà, tí mo sì ń wá bó ṣe máa yé mi, ṣàdédé ni mo rí ẹnì kan tó rí bí èèyàn, tó dúró níwájú mi. 16 Mo wá gbọ́ ohùn èèyàn kan láàárín Úláì,+ ó sì ké jáde pé: “Gébúrẹ́lì,+ jẹ́ kí ẹni yẹn lóye ohun tó rí.”+ 17 Torí náà, ó sún mọ́ ibi tí mo dúró sí, àmọ́ nígbà tó dé, ẹ̀rù bà mí débi pé mo dojú bolẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ́ kó yé ọ pé àkókò òpin ni ìran náà wà fún.”+ 18 Àmọ́ bó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo sùn lọ fọnfọn níbi tí mo dojú bolẹ̀ sí. Ó wá fọwọ́ kàn mí, ó sì mú kí n dìde dúró níbi tí mo dúró sí.+ 19 Ó wá sọ pé: “Mo fẹ́ kí o mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìparí ìdálẹ́bi náà, torí àkókò òpin tí a yàn ló wà fún.+
20 “Àgbò oníwo méjì tí o rí dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.+ 21 Òbúkọ onírun náà dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì;+ ìwo ńlá tó wà láàárín àwọn ojú rẹ̀ sì dúró fún ọba àkọ́kọ́.+ 22 Ní ti ìwo tó ṣẹ́, tí mẹ́rin fi jáde dípò rẹ̀,+ ìjọba mẹ́rin máa dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.
23 “Ní apá ìparí ìjọba wọn, bí ìṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ṣe ń parí,* ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tó lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ púpọ̀,* máa dìde. 24 Ó máa lágbára gan-an, àmọ́ kì í ṣe nípa agbára òun fúnra rẹ̀. Ó máa mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀,* ó máa ṣàṣeyọrí, ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ó máa pa àwọn alágbára run àti àwọn tó jẹ́ ẹni mímọ́.+ 25 Nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ó máa fi ẹ̀tàn ṣàṣeyọrí; ó máa gbéra ga nínú ọkàn rẹ̀; ó sì máa pa ọ̀pọ̀ run ní àkókò ààbò.* Ó tiẹ̀ máa dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé, àmọ́ a máa ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́ èèyàn.
26 “Òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ nínú ìran náà nípa alẹ́ àti àárọ̀, àmọ́ kí o ṣe ìran náà ní àṣírí, torí ọ̀pọ̀ ọjọ́ sí àkókò yìí* ló ń tọ́ka sí.”+
27 Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, okun tán nínú mi, ara mi ò sì yá fún ọjọ́ mélòó kan.+ Mo wá dìde, mo sì ń bá iṣẹ́ ọba lọ;+ àmọ́ ohun tí mo rí jẹ́ kí ara mi kú tipiri, kò sì sẹ́ni tó yé.+