Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
15 Mo rí àmì míì ní ọ̀run, ó kàmàmà, ó sì yani lẹ́nu, áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n ní ìyọnu méje. Àwọn yìí ló kẹ́yìn, torí a máa tipasẹ̀ wọn mú ìbínú Ọlọ́run wá sí òpin.+
2 Mo sì rí ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ tó dà pọ̀ mọ́ iná, àwọn tó ṣẹ́gun+ ẹranko náà àti ère rẹ̀+ àti nọ́ńbà orúkọ rẹ̀+ dúró níbi òkun tó ń dán bíi gíláàsì náà, wọ́n sì mú háàpù Ọlọ́run dání. 3 Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé:
“Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+ 4 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ Jèhófà,* tí kò ní yin orúkọ rẹ lógo, torí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?+ Torí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa wá jọ́sìn níwájú rẹ,+ torí a ti fi àwọn àṣẹ òdodo rẹ hàn kedere.”
5 Lẹ́yìn èyí, mo rí i, wọ́n ṣí ibi mímọ́ àgọ́ ẹ̀rí+ ní ọ̀run,+ 6 àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu méje + náà sì jáde látinú ibi mímọ́ náà, wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó mọ́, tó ń tàn yòò, wọ́n sì de ọ̀já wúrà mọ́ àyà wọn. 7 Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fún àwọn áńgẹ́lì méje náà ní abọ́ méje tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìbínú Ọlọ́run,+ ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé kún inú rẹ̀. 8 Èéfín sì kún ibi mímọ́ torí ògo Ọlọ́run+ àti agbára rẹ̀, ẹnì kankan ò sì lè wọnú ibi mímọ́ náà títí tí ìyọnu méje+ àwọn áńgẹ́lì méje náà fi parí.