Àìsáyà
8 Jèhófà sọ fún mi pé: “Mú wàláà+ ńlá kan, kí o sì fi kálàmù lásán,* kọ ‘Maheri-ṣalali-háṣí-básì’* sára rẹ̀. 2 Mo fẹ́ rí i dájú pé àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fọwọ́ sí i,* ìyẹn àlùfáà Ùráyà+ àti Sekaráyà ọmọ Jeberekáyà.”
3 Lẹ́yìn náà, mo bá wòlíì obìnrin náà* ní àṣepọ̀,* ó sì lóyún, ó wá bí ọmọkùnrin kan.+ Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ ọmọ náà ni Maheri-ṣalali-háṣí-básì, 4 torí kí ọmọ náà tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe, ‘Bàbá mi!’ àti ‘Ìyá mi!’ wọ́n máa kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ẹrù ogun Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.”+
5 Jèhófà tún sọ fún mi pé:
6 “Torí pé àwọn èèyàn yìí ti pa omi Ṣílóà* tó rọra ń ṣàn tì,+
Tí wọ́n sì ń yọ̀ torí Résínì àti ọmọ Remaláyà,+
7 Torí náà, wò ó! Jèhófà máa mú kí
Ibú omi Odò ńlá* náà ya lù wọ́n,
Ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.
Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,
Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,
8 Ó sì máa rọ́ gba Júdà kọjá.
Ó máa kún bò ó, ó sì máa gbà á kọjá, ó máa kún dé ọrùn rẹ̀;+
Ìyẹ́ rẹ̀ tó nà jáde máa bo ìbú ilẹ̀ rẹ,
9 Ẹ ṣe wọ́n léṣe, ẹ̀yin èèyàn, àmọ́ a máa fọ́ ẹ̀yin náà sí wẹ́wẹ́.
Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wá láti apá ibi tó jìnnà ní ayé!
Ẹ múra ogun,* àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!+
Ẹ múra ogun, àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!
10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, àmọ́ a máa dà á rú!
11 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lára mi, ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, láti kìlọ̀ fún mi kí n má bàa tẹ̀ lé ọ̀nà àwọn èèyàn yìí:
12 “Tí àwọn èèyàn yìí bá ń pe nǹkan ní ọ̀tẹ̀, ẹ ò gbọ́dọ̀ pè é ní ọ̀tẹ̀!
Ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n bẹ̀rù;
Ẹ má ṣe jẹ́ kó kó jìnnìjìnnì bá yín.
13 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́,+
Òun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ bẹ̀rù,
Òun sì ni Ẹni tó yẹ kó mú kí ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì.”+
14 Ó máa dà bí ibi mímọ́,
Àmọ́ ó máa dà bí òkúta tí wọ́n á kọ lù
Àti àpáta tó ń múni kọsẹ̀+
Fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì,
Bíi pańpẹ́ àti ìdẹkùn,
Fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.
15 Ọ̀pọ̀ nínú wọn máa kọsẹ̀, wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì fọ́;
Wọ́n máa dẹkùn fún wọn, ọwọ́ á sì tẹ̀ wọ́n.
17 Màá máa dúró de* Jèhófà,+ ẹni tó ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù,+ màá sì ní ìrètí nínú rẹ̀.
18 Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi+ dà bí àmì+ àti iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tó ń gbé lórí Òkè Síónì.
19 Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò tàbí àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn tó ń ké ṣíoṣío, tí wọ́n sì ń jẹnu wúyẹ́wúyẹ́,” ṣebí ọwọ́ Ọlọ́run wọn ló yẹ kí àwọn èèyàn ti lọ wádìí? Ṣé ó yẹ kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú nítorí alààyè?+ 20 Kàkà bẹ́ẹ̀, inú òfin àti ẹ̀rí tó wà ní àkọsílẹ̀* ló yẹ kí wọ́n ti wádìí!
Tí wọn ò bá sọ ohun tó bá ọ̀rọ̀ yìí mu, wọn ò ní ìmọ́lẹ̀.*+ 21 Kálukú máa gba ilẹ̀ náà kọjá, ìyà á jẹ wọ́n, ebi á sì pa wọ́n;+ torí ebi tó ń pa á àti inú tó ń bí i, á máa gégùn-ún fún ọba rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń wòkè. 22 Ó máa wá wo ayé, ìdààmú àti òkùnkùn nìkan ló sì máa rí, ìríran bàìbàì àti àkókò tó le, ìṣúdùdù, láìsí ìmọ́lẹ̀.