Àìsáyà
Wò ó! Jèhófà gun àwọsánmà tó ń yára kánkán, ó sì ń bọ̀ wá sí Íjíbítì.
Àwọn ọlọ́run Íjíbítì tí kò ní láárí máa gbọ̀n rìrì níwájú rẹ̀,+
Ọkàn Íjíbítì sì máa domi nínú rẹ̀.
2 “Màá mú kí àwọn ọmọ Íjíbítì dojú kọ ara wọn,
Wọ́n á sì bá ara wọn jà,
Kálukú máa bá arákùnrin rẹ̀ àti ọmọnìkejì rẹ̀ jà,
Ìlú máa bá ìlú jà, ìjọba sì máa bá ìjọba jà.
Wọ́n máa yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí,
Àwọn atujú, àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+
4 Màá fa Íjíbítì lé ọ̀gá tó le lọ́wọ́,
Ọba tó sì burú máa jẹ lé wọn lórí,”+ ni Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
5 Omi òkun máa gbẹ,
Kò ní sí omi nínú odò, ó sì máa gbẹ táútáú.+
6 Àwọn odò á máa rùn;
Àwọn ipa odò Náílì nílẹ̀ Íjíbítì máa fà, ó sì máa gbẹ táútáú.
Àwọn esùsú* àti koríko etídò máa jẹrà.+
7 Àwọn ewéko tó wà létí odò Náílì, ní bèbè Náílì,
Àti gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fúnrúgbìn sí létí odò Náílì+ máa gbẹ.+
Ó máa fẹ́ lọ, kò sì ní sí mọ́.
8 Àwọn apẹja máa ṣọ̀fọ̀,
Àwọn tó ń ju ìwọ̀ ẹja sínú odò Náílì máa dárò,
Àwọn tó sì ń na àwọ̀n ìpẹja wọn sí ojú omi máa dín kù.
9 Ojú máa ti àwọn tó ń ya ọ̀gbọ̀+
Àti àwọn tó ń hun aṣọ funfun.
10 Wọ́n máa tẹ àwọn ahunṣọ rẹ̀ rẹ́;
Gbogbo alágbàṣe rẹ̀ máa kẹ́dùn.*
11 Òmùgọ̀ ni àwọn olórí Sóánì.+
Ìmọ̀ràn tí kò bọ́gbọ́n mu làwọn tó gbọ́n jù nínú àwọn agbani-nímọ̀ràn Fáráò ń mú wá.+
Báwo lẹ ṣe máa sọ fún Fáráò pé:
“Àtọmọdọ́mọ àwọn ọlọ́gbọ́n ni mí,
Àtọmọdọ́mọ àwọn ọba àtijọ́”?
Jẹ́ kí wọ́n sọ fún ọ, tí wọ́n bá mọ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti pinnu nípa Íjíbítì.
13 Àwọn olórí Sóánì ti hùwà òpònú;
Wọ́n ti tan àwọn olórí Nófì*+ jẹ;
Àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀ya rẹ̀ ti kó Íjíbítì ṣìnà.
14 Jèhófà ti fi ẹ̀mí ìdàrúdàpọ̀ kọ lù ú;+
Wọ́n sì ti kó Íjíbítì ṣìnà nínú gbogbo ohun tó ń ṣe,
Bí ọ̀mùtí tó ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ nínú èébì rẹ̀.
16 Ní ọjọ́ yẹn, Íjíbítì máa dà bí obìnrin, ó máa gbọ̀n rìrì, ẹ̀rù á sì máa bà á torí ọwọ́ ìhàlẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gbé sókè sí i.+ 17 Ilẹ̀ Júdà sì máa di ohun ìbẹ̀rù fún Íjíbítì. Tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ rẹ̀, ẹ̀rù máa bà wọ́n torí ìpinnu tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti ṣe lòdì sí wọn.+
18 Ní ọjọ́ yẹn, ìlú márùn-ún máa wà nílẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n ń sọ èdè Kénáánì,+ tí wọ́n á sì búra pé àwọn máa dúró ti Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ìlú kan á máa jẹ́ Ìlú Ìyalulẹ̀.
19 Ní ọjọ́ yẹn, pẹpẹ kan máa wà fún Jèhófà ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì, òpó kan sì máa wà fún Jèhófà níbi ààlà rẹ̀. 20 Ó máa jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun nílẹ̀ Íjíbítì; torí wọ́n máa ké pe Jèhófà nítorí àwọn aninilára, ó sì máa rán olùgbàlà kan sí wọn, ẹni tó tóbi lọ́lá, tó máa gbà wọ́n là. 21 Jèhófà máa jẹ́ kí àwọn ọmọ Íjíbítì mọ òun, àwọn ọmọ Íjíbítì sì máa mọ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa rúbọ, wọ́n á mú ẹ̀bùn wá, wọ́n á jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì san án. 22 Jèhófà máa kọ lu Íjíbítì,+ á kọ lù ú, á sì wò ó sàn; wọ́n á pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, á gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn, á sì wò wọ́n sàn.
23 Ní ọjọ́ yẹn, ọ̀nà kan máa jáde+ láti Íjíbítì lọ sí Ásíríà. Ásíríà máa wá sí Íjíbítì, Íjíbítì sì máa lọ sí Ásíríà, Íjíbítì àti Ásíríà sì jọ máa sin Ọlọ́run. 24 Ní ọjọ́ yẹn, Ísírẹ́lì máa ṣe ìkẹta Íjíbítì àti Ásíríà,+ àwọn tí a bù kún ní àárín ayé, 25 torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti máa súre fún un pé: “Ìbùkún ni fún àwọn èèyàn mi, Íjíbítì, àti iṣẹ́ ọwọ́ mi, Ásíríà, àti ogún mi, Ísírẹ́lì.”+