Àìsáyà
21 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí aginjù òkun:*+
Ó ń bọ̀ bí ìjì tó fẹ́ kọjá ní gúúsù,
Láti aginjù, láti ilẹ̀ tó ń dẹ́rù bani.+
2 A ti sọ ìran kan tó le fún mi:
Ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,
Apanirun sì ń pani run.
Gòkè lọ, ìwọ Élámù! Gbógun tini, ìwọ Mídíà!+
Màá fòpin sí gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tó mú kó bá àwọn èèyàn.+
3 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń jẹ̀rora gidigidi.*+
Àwọn iṣan mi ń sún kì,
Bíi ti obìnrin tó ń bímọ.
Ìdààmú tó bá mi ò jẹ́ kí n gbọ́ràn;
Ìyọlẹ́nu tó bá mi ò jẹ́ kí n ríran.
4 Ọkàn mi dà rú; jìnnìjìnnì bò mí.
Ìrọ̀lẹ́ tí mò ń retí ń dẹ́rù bà mí.
5 Ẹ tẹ́ tábìlì, kí ẹ sì to àwọn ìjókòó!
Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu!+
Ẹ dìde, ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fi òróró yan* apata!
6 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:
“Lọ, yan aṣọ́nà, kí o sì ní kó ròyìn ohun tó bá rí.”
Ó fara balẹ̀ wò ó, ó sì kíyè sí i dáadáa.
8 Ó wá ké jáde bíi kìnnìún, ó ní:
“Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mò ń dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán,
Mi ò sì kúrò níbi tí a fi mí ṣọ́ ní gbogbo òru.+
9 Wo ohun tó ń bọ̀:
Àwọn ọkùnrin wà nínú kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n so àwọn ẹṣin mọ́!”+
Ó wá sọ pé:
“Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú!+
Gbogbo ère gbígbẹ́ àwọn ọlọ́run rẹ̀ ló ti fọ́ sílẹ̀ túútúú!”+
10 Ẹ̀yin èèyàn mi tí wọ́n ti pa bí ọkà,
Ohun tó tinú ibi ìpakà mi jáde,*+
Mo ti sọ ohun tí mo gbọ́ fún ọ látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
Ẹnì kan ń ké pè mí láti Séírì+ pé:
“Olùṣọ́, báwo ni òru ṣe rí?
Olùṣọ́, báwo ni òru ṣe rí?”
12 Olùṣọ́ sọ pé:
“Òwúrọ̀ ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òru.
Tí ẹ bá fẹ́ wádìí, ẹ wádìí.
Ẹ tún pa dà wá!”
13 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú:
Inú igbó, nínú aṣálẹ̀ tó tẹ́jú lẹ máa sùn mọ́jú,
Ẹ̀yin ará Dédánì+ tó ń rìnrìn àjò.
14 Ẹ gbé omi wá pàdé ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Témà,+
Kí ẹ sì gbé oúnjẹ wá fún ẹni tó ń sá lọ.
15 Torí wọ́n ti sá fún àwọn idà, idà tí wọ́n fà yọ,
Fún ọrun tí wọ́n fà àti ogun tó gbóná janjan.
16 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Láàárín ọdún kan, bíi ti ọdún alágbàṣe,* gbogbo ògo Kídárì+ máa wá sí òpin. 17 Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú àwọn jagunjagun Kídárì tí wọ́n ń ta ọfà máa kéré, torí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ ọ́.”