Ìsíkíẹ́lì
27 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa Tírè,+ 3 kí o sì sọ fún Tírè pé,
‘Ìwọ tí ń gbé ní àwọn ẹnu ọ̀nà òkun,
Ò ń bá àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ erékùṣù dòwò pọ̀,
Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Ìwọ Tírè, o ti sọ pé, ‘Ẹwà mi ò lábùlà.’+
4 Àárín òkun ni àwọn ilẹ̀ rẹ wà,
Àwọn tó kọ́ ọ ti mú kí o rẹwà gan-an.
5 Igi júnípà ti Sénírì+ ni wọ́n fi ṣe gbogbo pákó rẹ,
Wọ́n sì fi igi kédárì láti Lẹ́bánónì ṣe òpó inú ọkọ̀ rẹ.
6 Àwọn igi ràgàjì* ti Báṣánì ni wọ́n fi ṣe àwọn àjẹ̀ rẹ,
Igi sípírẹ́sì tí wọ́n fi eyín erin tẹ́ inú rẹ̀ láti àwọn erékùṣù Kítímù+ ni wọ́n fi ṣe iwájú ọkọ̀ rẹ.
7 Aṣọ ọ̀gbọ̀* aláràbarà láti Íjíbítì ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹ,
Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù láti erékùṣù Élíṣáhì+ ni wọ́n fi ṣe ìbòrí ọkọ̀ rẹ.
8 Àwọn tó ń gbé Sídónì àti Áfádì+ ló ń bá ọ tukọ̀.
Ìwọ Tírè, àwọn èèyàn rẹ tó já fáfá ló ń bá ọ tukọ̀.+
9 Àwọn ará Gébálì+ tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́* tí wọ́n sì já fáfá ló dí àwọn àlàfo ara ọkọ̀ rẹ.+
Gbogbo ọkọ̀ òkun àti àwọn atukọ̀ wọn wá bá ọ dòwò pọ̀.
10 Àwọn ará Páṣíà, Lúdì àti Pútì+ wà lára àwọn jagunjagun rẹ, àwọn ọkùnrin ogun rẹ.
Inú rẹ ni wọ́n gbé apata àti akoto* wọn kọ́ sí, wọ́n sì ṣe ọ́ lógo.
11 Àwọn ará Áfádì tó wà lára àwọn ọmọ ogun rẹ wà lórí ògiri rẹ yí ká,
Àwọn ọkùnrin onígboyà sì wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ.
Wọ́n gbé àwọn apata* wọn kọ́ sára ògiri rẹ yí ká,
Wọ́n sì buyì kún ẹwà rẹ.
12 “‘“Táṣíṣì+ bá ọ dòwò pọ̀ torí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ.+ Fàdákà, irin, tánganran àti òjé ni wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+ 13 Jáfánì, Túbálì+ àti Méṣékì+ bá ọ dòwò pọ̀, wọ́n sì fi àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà ṣe àti àwọn ẹrú+ ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 14 Ilé Tógámà+ fi ẹṣin àti àwọn ẹṣin ogun àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 15 Àwọn ará Dédánì+ bá ọ dòwò pọ̀; o gba àwọn oníṣòwò síṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ erékùṣù; eyín erin+ àti igi ẹ́bónì ni wọ́n fi san ìṣákọ́lẹ̀* fún ọ. 16 Édómù bá ọ dòwò pọ̀ torí ọjà rẹ pọ̀ gan-an. Òkúta tọ́kọ́wásì, òwú aláwọ̀ pọ́pù, aṣọ tí wọ́n kóṣẹ́ aláràbarà sí, aṣọ àtàtà, iyùn àti òkúta rúbì ni wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.
17 “‘“Júdà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì bá ọ dòwò pọ̀, wọ́n ń fi àlìkámà* Mínítì,+ àwọn oúnjẹ tó dára jù, oyin,+ òróró àti básámù+ ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+
18 “‘“Damásíkù+ bá ọ dòwò pọ̀ torí ọjà rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ àti torí gbogbo ọrọ̀ rẹ, ó fi wáìnì Hélíbónì àti irun àgùntàn Séhárì* bá ọ ṣòwò. 19 Fédánì àti Jáfánì láti Úsálì fi àwọn ohun tí wọ́n fi irin ṣe, igi kaṣíà* àti pòròpórò* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 20 Dédánì + fi aṣọ tí wọ́n ń tẹ́ sẹ́yìn ẹran* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 21 O gba àwọn Árábù àti gbogbo ìjòyè Kídárì+ síṣẹ́, àwọn tó ń fi ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́ ṣòwò.+ 22 Àwọn oníṣòwò Ṣébà àti Ráámà+ bá ọ dòwò pọ̀; wọ́n fi onírúurú lọ́fínńdà tó dáa jù, àwọn òkúta iyebíye àti wúrà ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+ 23 Háránì,+ Kánè àti Édẹ́nì,+ àwọn oníṣòwò Ṣébà,+ Áṣúrì+ àti Kílímádì bá ọ dòwò pọ̀. 24 Ní àwọn ọjà rẹ, wọ́n ń ta àwọn aṣọ tó rẹwà, àwọn ìborùn búlúù tí wọ́n kóṣẹ́ aláràbarà sí àti àwọn kápẹ́ẹ̀tì aláràbarà. Wọ́n kó gbogbo wọn jọ, wọ́n sì fi okùn dè wọ́n.
25 Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lo fi kó àwọn ọjà rẹ,
Débi pé ọjà kún inú rẹ, o sì kún fọ́fọ́* láàárín òkun.
26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti wà ọ́ wá sínú agbami òkun;
Atẹ́gùn ìlà oòrùn ti mú kí o fọ́ sáàárín òkun.
27 Ọrọ̀ rẹ, àwọn ọjà rẹ, àwọn nǹkan tí ò ń tà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ rẹ àti àwọn atukọ̀ rẹ,
Àwọn tó ń dí àwọn àlàfo ara ọkọ̀ rẹ, àwọn tó ń bá ọ ṣòwò+ àti àwọn jagunjagun,+
Gbogbo àwọn* tó wà pẹ̀lú rẹ,
Gbogbo wọn ni yóò rì sínú òkun ní ọjọ́ tí o bá ṣubú.+
28 Gbogbo èbúté yóò mì tìtì nígbà tí àwọn atukọ̀ rẹ bá figbe ta.
29 Gbogbo àwọn tó ń fi àjẹ̀ tukọ̀, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ àti àwọn atukọ̀
Yóò kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọ́n á sì dúró sórí ilẹ̀.
30 Wọ́n á gbé ohùn wọn sókè, wọ́n á sì sunkún kíkan nítorí rẹ+
Bí wọ́n ṣe ń da eruku sórí ara wọn, tí wọ́n sì ń yíra nínú eérú.
31 Wọ́n á fá irun orí wọn, wọ́n á sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀;*
Wọ́n á sunkún kíkan* torí rẹ, wọ́n á sì pohùn réré ẹkún gidigidi.
32 Bí wọ́n bá ń dárò, wọn yóò máa kọrin arò nípa rẹ pé:
‘Ta ló dà bíi Tírè, tó ti dákẹ́ sínú òkun?+
33 Nígbà tí àwọn ọjà rẹ ti òkun dé, o tẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rùn.+
Ọrọ̀ rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn ọjà rẹ ti sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.+
34 O ti wá dákẹ́ sínú agbami òkun, sínú ibú omi,+
Ìwọ àti gbogbo ọjà rẹ àti àwọn èèyàn rẹ ti rì sínú òkun.+
35 Gbogbo àwọn tó ń gbé ní àwọn erékùṣù yóò wò ọ́ tìyanutìyanu,+
Ìbẹ̀rù yóò mú kí jìnnìjìnnì bá àwọn ọba wọn,+ ìdààmú yóò sì hàn lójú wọn.
36 Àwọn oníṣòwò tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yóò súfèé torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ.
Ìparun rẹ yóò dé lójijì, yóò sì burú jáì,
O ò sì ní sí mọ́ títí láé.’”’”+