Àìsáyà
26 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa kọ orin yìí+ ní ilẹ̀ Júdà:+
“A ní ìlú tó lágbára.+
Ó fi ìgbàlà ṣe àwọn ògiri rẹ̀, ó sì fi mọ òkìtì yí i ká.+
3 O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá;*
O máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin, +
Torí pé ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.+
5 Torí ó ti rẹ àwọn tó ń gbé ibi gíga sílẹ̀, ìlú tó ga.
Ó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀,
Ó mú un wá sílẹ̀ pátápátá;
Ó mú un wá sínú iyẹ̀pẹ̀.
6 Ẹsẹ̀ máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,
Ẹsẹ̀ àwọn tí ìyà ń jẹ, ìṣísẹ̀ àwọn tó rẹlẹ̀.”
Torí pé o jẹ́ olóòótọ́,
O máa mú kí ọ̀nà àwọn olódodo dán mọ́rán.
8 Bí a ṣe ń tọ ọ̀nà àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà,
Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
Orúkọ rẹ àti ìrántí rẹ ń wù wá* gan-an.*
9 Ní òru, gbogbo ọkàn* mi wà lọ́dọ̀ rẹ,
Àní, ẹ̀mí mi ń wá ọ ṣáá;+
Torí tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ wá sí ayé,
Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà máa kọ́ òdodo.+
10 Tí a bá tiẹ̀ ṣojúure sí ẹni burúkú,
Kò ní kọ́ òdodo.+
11 Jèhófà, ọwọ́ rẹ wà lókè, ṣùgbọ́n wọn ò rí i.+
Wọ́n máa rí ìtara tí o ní fún àwọn èèyàn rẹ, ojú á sì tì wọ́n.
Àní, iná tó wà fún àwọn ọ̀tá rẹ máa jó wọn run.
14 Òkú ni wọ́n; wọn ò ní wà láàyè.
Ikú ti pa wọ́n,* wọn ò ní dìde.+
Torí o ti yíjú sí wọn,
Kí o lè pa wọ́n rẹ́, kí ẹnikẹ́ni má sì dárúkọ wọn mọ́.
15 O ti mú kí orílẹ̀-èdè náà tóbi sí i, Jèhófà,
O ti mú kí orílẹ̀-èdè náà tóbi sí i;
O ti ṣe ara rẹ lógo.+
O ti sún gbogbo ààlà ilẹ̀ náà síwájú gan-an.+
16 Jèhófà, wọ́n yíjú sí ọ nígbà wàhálà;
Wọ́n gbàdúrà sí ọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látọkàn wá nígbà tí o bá wọn wí.+
17 Bí aláboyún tó fẹ́ bímọ,
Tó ń rọbí, tó sì ń ké torí ó ń jẹ̀rora,
Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe rí nítorí rẹ, Jèhófà.
18 A lóyún, a sì ní ìrora ìrọbí,
Àmọ́ ṣe ló dà bíi pé afẹ́fẹ́ la bí.
A ò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ náà,
A ò sì bí ẹnì kankan tó máa gbé ilẹ̀ náà.
19 “Àwọn òkú rẹ máa wà láàyè.
Ẹ jí, ẹ sì kígbe ayọ̀,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú iyẹ̀pẹ̀!+
21 Torí pé, wò ó! Jèhófà ń bọ̀ láti àyè rẹ̀,
Láti pe àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà pé kí wọ́n wá jẹ́jọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
Ilẹ̀ náà sì máa tú ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ síta,
Kò ní lè bo àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n pa, bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.”