Orí Kọkànlélógún
Ọwọ́ Jèhófà Di Gíga
1. Kí ló jẹ́ kí Aísáyà máa gbé Jèhófà gẹ̀gẹ̀?
AÍSÁYÀ fẹ́ràn Jèhófà gidigidi, inú rẹ̀ sì máa ń dùn láti yìn ín lógo. Ó kígbe pé: “Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Mo gbé ọ ga, mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ.” Kí ló jẹ́ kí wòlíì yìí mọyì Ẹlẹ́dàá rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Níní tó ní ìmọ̀ Jèhófà àti ìmọ̀ nípa ìgbòkègbodò rẹ̀ lohun pàtàkì tó fà á. Ìmọ̀ tó ní yìí hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Nítorí pé o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu, àwọn ìpinnu láti àwọn àkókò ìjímìjí, nínú ìṣòtítọ́, nínú ìṣeégbẹ́kẹ̀lé.” (Aísáyà 25:1) Bí Jóṣúà tó gbé láyé ṣáájú Aísáyà ṣe mọ̀ náà ni Aísáyà mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, àti pé gbogbo “ìpinnu” rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tó bá pète láti ṣe, ló ń ṣẹ.—Jóṣúà 23:14.
2. Ìpinnu tí Jèhófà ṣe wo ni Aísáyà wá kéde nísinsìnyí, ìlú wo ló sì ṣeé ṣe kí ìpinnu yìí dá lé lórí?
2 Lára àwọn ìpinnu Jèhófà ni ìdájọ́ tó kéde sórí àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. Aísáyà kéde ọ̀kan lára wọn wàyí, ó ní: “Ìwọ ti sọ ìlú ńlá kan di ìtòjọpelemọ òkúta, o ti sọ ìlú olódi di ìrúnwómúwómú, o ti sọ ilé gogoro ibùgbé àwọn àjèjì di èyí tí kì í ṣe ìlú ńlá mọ́, tí a kì yóò tún kọ́, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 25:2) Ìlú wo ni ìlú tí wọn kò dárúkọ yìí? Bóyá Árì ti Móábù ni Aísáyà ń sọ, Móábù sì nìyí, ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run ni láti ìgbà pípẹ́ wá.a Ó sì lè jẹ́ ìlú mìíràn tó lágbára ju èyí lọ ló ń sọ nípa rẹ̀, ìyẹn Bábílónì.— Aísáyà 15:1; Sefanáyà 2:8, 9.
3. Ọ̀nà wo ni àwọn ọ̀tá Jèhófà gbà yìn ín lógo?
3 Kí làwọn ọ̀tá Jèhófà yóò ṣe nígbà tí ìpinnu rẹ̀ lórí ìlú wọn bá ṣẹ? “Àwọn alágbára ènìyàn yóò . . . yìn ọ́ lógo; ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, wọn yóò bẹ̀rù rẹ.” (Aísáyà 25:3) Kò yani lẹ́nu láti gbọ́ pé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run Olódùmarè yóò bẹ̀rù rẹ̀. Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe yìn ín lógo? Ṣé wọ́n máa kọ òrìṣà wọn sílẹ̀ ni, tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìsìn mímọ́ gaara? Bóyá ni! Dípò bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn wọn bí ọ̀ràn Fáráò àti Nebukadinésárì ni, ìgbà tọ́rọ̀ dójú ẹ̀ ni wọ́n tó gba Jèhófà lọ́gàá tí wọ́n sì yìn ín lógo.—Ẹ́kísódù 10:16, 17; 12:30-33; Dáníẹ́lì 4:37.
4. “Ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀” wo ló wà lóde òní, báwo sì lòun pàápàá ṣe fògo fún Jèhófà tipátipá?
4 Lóde òní, “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tó jẹ́ “ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé,” ni “ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀” yẹn. (Ìṣípayá 17:5, 18) Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú ilẹ̀ ọba yìí. Báwo làwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe wá fògo fún Jèhófà? Nípa pé wọ́n gbà tipátipá pé òótọ́ ni pé ó ṣe àwọn ohun àrà nítorí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ní pàtàkì, ‘jìnnìjìnnì bo’ àwọn aṣáájú wọ̀nyí “wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run” nígbà tí Jèhófà mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà sẹ́nu ìgbòkègbodò ní pẹrẹu lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ wọn kúrò ní ìgbèkùn tẹ̀mí, tí Bábílónì Ńlá kó wọn sí.—Ìṣípayá 11:13.b
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Jèhófà jẹ́ lójú àwọn ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n ibi ààbò ló jẹ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ tó bá fẹ́ láti sìn ín. Ní tòótọ́, àwọn òṣìkà nínú ẹ̀sìn àti nínú ìṣèlú lè sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn fọ́ ìgbàgbọ́ àwọn olùjọsìn tòótọ́, àmọ́ pàbó ló ń já sí nítorí pé ńṣe ni àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wẹ́rẹ́ ló máa ń pa àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu mọ́ bíi pé ó fi àwọsánmà bo oòrùn aṣálẹ̀ tó mú janjan mọ́lẹ̀, tàbí pé ó fi ògiri dènà ìjì òjò.—Ka Aísáyà 25:4, 5.
‘Àkànṣe Àsè fún Gbogbo Ènìyàn’
6, 7. (a) Irú àsè wo ni Jèhófà gbé kalẹ̀, àti fún ta ni? (b) Kí ni àkànṣe àsè tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ṣàpẹẹrẹ?
6 Gẹ́gẹ́ bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ti ń ṣe ni Jèhófà ṣe, yàtọ̀ sí pé ó dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀, ó tún ń bọ́ wọn pẹ̀lú, pàápàá nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tó ti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè tán lọ́dún 1919, ó gbé àkànṣe àsè ìṣẹ́gun kalẹ̀ fún wọn, ìyẹn ìpèsè rẹpẹtẹ nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni: “Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.”—Aísáyà 25:6.
7 Orí “òkè ńlá” Jèhófà ni wọ́n gbé àkànṣe àsè yẹn kalẹ̀ sí. Kí ni òkè ńlá yìí? “Òkè ńlá ilé Jèhófà” ni, èyí tí gbogbo orílẹ̀-èdè ń wọ́ sínú rẹ̀ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” “Òkè ńlá mímọ́” Jèhófà ni, níbi tí àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn rẹ̀ kì í ti í ṣe ìpalára èyíkéyìí, tí wọn kì í sì í fa ìparun kankan. (Aísáyà 2:2; 11:9) Ibi ìjọsìn gíga yìí ni Jèhófà gbé àkànṣe àsè rẹpẹtẹ kálẹ̀ sí fáwọn olóòótọ́. Àwọn ohun tẹ̀mí tó ń pèsè lọ́pọ̀ yanturu nísinsìnyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun ti ara tí yóò pèsè nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá di ìjọba kan ṣoṣo tó wà ní gbogbo ayé. Nígbà yẹn, ebi ò ní pani mọ́. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:8, 16.
8, 9. (a) Ọ̀tá ńláńlá méjì tí aráyé ní wo ni Ọlọ́run máa mú kúrò? Ṣàlàyé. (b) Kí ni Ọlọ́run yóò ṣe láti mú ẹ̀gàn àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò?
8 Àwọn tó bá ń jẹ nínú àsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run pèsè nísinsìnyí ní ìrètí ológo. Gbọ́ ọ̀rọ̀ Aísáyà tó tẹ̀ lé e. Ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wé “ohun híhun tí a hun pọ̀,” tàbí “ìràgàbò” tó lè pinni lẹ́mìí, ó ní: “Ní òkè ńlá yìí, dájúdájú, [Jèhófà] yóò gbé ojú ìràgàbò náà mì, èyí tí ó ràgà bo gbogbo ènìyàn, àti ohun híhun tí a hun pọ̀ sórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:7, 8a.
9 Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú mọ́! (Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ̀wẹ̀, ẹ̀gàn tí wọ́n fi irọ́ kó bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, èyí tí wọ́n ti ń fara dà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá, ni yóò mú kúrò pẹ̀lú. “Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.” (Aísáyà 25:8b) Báwo lèyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni Jèhófà máa mú orísun ẹ̀gàn yìí kúrò, ìyẹn Sátánì àti irú ọmọ rẹ̀. (Ìṣípayá 20:1-3) Abájọ tí ìyẹn yóò fi mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run polongo pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀, òun yóò sì gbà wá là. Jèhófà nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Aísáyà 25:9.
Ó Rẹ Onírera Wálẹ̀
10, 11. Ìyà wo ni Jèhófà fi pa mọ́ de Móábù?
10 Jèhófà gba àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lára àwọn èèyàn rẹ̀ là. Ṣùgbọ́n, agbéraga ni Móábù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì, Jèhófà sì kórìíra ìgbéraga. (Òwe 16:18) Nítorí náà, ẹ̀tẹ́ máa bá Móábù láìpẹ́. “Ọwọ́ Jèhófà yóò sọ̀ sórí òkè ńlá yìí, Móábù ni a ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní àyè rẹ̀ bí ìgbà tí a bá tẹ òkìtì ègé koríko mọ́lẹ̀ ní ibi ajílẹ̀. Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ní àárín rẹ̀ bí ìgbà tí òmùwẹ̀ bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́, òun yóò sì fi gbígbé tí òun ń gbé ọwọ́ lọ́nà àgálámàṣà rẹ ìrera rẹ̀ wálẹ̀. Ìlú ńlá olódi, pẹ̀lú àwọn ògiri gíga tí o fi ṣe ààbò, ni òun yóò wó palẹ̀; yóò rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀, yóò bá a kanlẹ̀, àní kan ekuru.”—Aísáyà 25:10-12.
11 Ọwọ́ Jèhófà yóò “sọ̀” sórí òkè Móábù. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀? Ṣe ni yóò gbá Móábù lábàrá, tí yóò sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí a bá tẹ ègé koríko mọ́lẹ̀ “ní ibi ajílẹ̀.” Nígbà ayé Aísáyà, wọn a máa fẹsẹ̀ tẹ ègé koríko wọnú ẹlẹ́bọ́tọ tí wọ́n rù jọ, láti lè sọ ọ́ di ajílẹ̀; nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Aísáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ pé Móábù á tẹ́, bó ti wù kí odi rẹ̀ ga kó sì lágbára tó.
12. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé Móábù nìkan ni Jèhófà kéde ìdájọ́ lé lórí?
12 Èé ṣe tó fi jẹ́ pé Móábù nìkan ni Jèhófà dojú irú ìbáwí lílekoko yìí kọ? Àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì, ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù, tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà, ni àwọn ọmọ Móábù jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú nìkan ni, ìbátan wọn ni wọ́n jẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, òrìṣà ni wọ́n yàn láti máa bọ, ọ̀tá paraku ni wọ́n sì ń bá Ísírẹ́lì ṣe. Ìyẹn ni àgbákò tó dé bá wọn fi tọ́ sí wọn gan-an. Ní ti èyí, irú ìwà tí Móábù hù náà làwọn ọ̀tá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń hù lónìí. Ní pàtàkì, òun gan-an ni Kirisẹ́ńdọ̀mù jọ, èyí tó sọ pé òun ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, tó sì jẹ́ pé òun gan-an ló kó apá pàtàkì jù lọ nínú Bábílónì Ńlá gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i níṣàájú.
Orin Ìgbàlà
13, 14. “Ìlú ńlá tí ó lágbára” wo làwọn èèyàn Ọlọ́run ní lónìí, àwọn wo ni wọ́n sì ń yọ̀ǹda fún láti wọ ibẹ̀?
13 Àwọn èèyàn Ọlọ́run wá ń kọ́ o? Nítorí pé ó jẹ́ ìwúrí fún wọn pé Jèhófà ṣojú rere sí wọn tó sì dáàbò bò wọ́n, ńṣe ni wọ́n bú sórin. Bẹ́ẹ̀ ni: “Ní ọjọ́ yẹn, orin yìí ni a ó kọ ní ilẹ̀ Júdà: ‘A ní ìlú ńlá tí ó lágbára. Ó mú ìgbàlà pàápàá wá fún àwọn ògiri àti ohun àfiṣe-odi. Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè, kí orílẹ̀-èdè òdodo tí ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ́ lè wọlé.’” (Aísáyà 26:1, 2) Lóòótọ́, kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ láyé àtijọ́, àmọ́ wọ́n tún ní ìmúṣẹ tó hàn kedere lónìí pẹ̀lú. Ètò àjọ alágbára, tó dà bí ìlú ńlá, ni wọ́n fi jíǹkí “orílẹ̀-èdè òdodo” ti Jèhófà, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Nǹkan ayọ̀ gbáà ni, ó tó ká torí ẹ̀ mórin kọ o jàre!
14 Irú àwọn èèyàn wo ló ń wọ “ìlú ńlá” yìí? Orin yẹn sọ ọ́, ó ní: “Ìtẹ̀sí tí a tì lẹ́yìn dáadáa ni ìwọ [Ọlọ́run] yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ nínú àlàáfíà tí ń bá a nìṣó, nítorí pé ìwọ ni a mú kí ẹnì kan gbẹ́kẹ̀ lé. Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin wà.” (Aísáyà 26:3, 4) “Ìtẹ̀sí” tí Jèhófà fara mọ́ náà ni ìfẹ́ tí ẹnì kan ní láti pa àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mọ́, àti láti gbẹ́kẹ̀ lé e, dípò gbígbẹ́kẹ̀ lé ètò ìṣòwò, ìṣèlú, àti ẹ̀sìn ayé tó ń ṣe mánamàna. “Jáà Jèhófà” nìkan ṣoṣo ni Àpáta ààbò tó ṣeé gbára lé. Ààbò Jèhófà máa ń wà lórí àwọn tó bá gbọ́kàn lé e pátápátá, “àlàáfíà tí ń bá a nìṣó” ni yóò sì wà fún wọn.—Òwe 3:5, 6; Fílípì 4:6, 7.
15. Báwo ni Jèhófà ṣe ti rẹ “ìlú gíga” yìí sílẹ̀ lónìí, ọ̀nà wo sì ni “ẹsẹ̀ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́” gbà ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀?
15 Èyí yàtọ̀ gbáà sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run! “Ó ti rẹ àwọn tí ń gbé ibi gíga sílẹ̀, ìlú gíga. Ó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀, ó rẹ̀ ẹ́ kanlẹ̀; ó mú un fara kan ekuru. Ẹsẹ̀ yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ẹsẹ̀ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ìṣísẹ̀ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.” (Aísáyà 26:5, 6) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ “ìlú gíga” kan ní Móábù ni Aísáyà ń bá wí, ó sì lè jẹ́ ìlú mìíràn ni, irú bíi Bábílónì tó dájú pé ìrera rẹ̀ ga gidigidi. Èyí ó wù kó jẹ́, Jèhófà ti mú kí nǹkan yí bìrí mọ́ “ìlú gíga” yìí lọ́wọ́, tí àwọn èèyàn tirẹ̀ ‘ẹni rírẹlẹ̀ àti ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́’ sí wá ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá Bábílónì Ńlá mu wẹ́kú, pàápàá Kirisẹ́ńdọ̀mù. Lọ́dún 1919, “ìlú gíga” yìí tú àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀ tipátipá, ìṣubú lọ́nà ẹ̀tẹ́ nìyẹn sì jẹ́ fún un, ni àwọn èèyàn Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ tẹ ẹni tó ti mú wọn lóǹdè rí mọ́lẹ̀. (Ìṣípayá 14:8) Lọ́nà wo? Nípa kíkéde ẹ̀san Jèhófà tí ń bọ̀ wá sórí rẹ̀ fáráyé gbọ́.—Ìṣípayá 8:7-12; 9:14-19.
Fífẹ́ Òdodo àti “Ìrántí” Jèhófà
16. Irú àpẹẹrẹ ìfọkànsìn wo ni Aísáyà fi lélẹ̀?
16 Lẹ́yìn orin ìṣẹ́gun yìí, Aísáyà wá fi bí ìfọkànsìn rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn, àti èrè tí ń bẹ nínú sísin Ọlọ́run òdodo. (Ka Aísáyà 26:7-9.) Wòlíì yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ní ti ‘níní ìrètí nínú Jèhófà’ àti ní ti fífẹ́ràn “orúkọ” Jèhófà àti “ìrántí” rẹ̀. Kí ni ìrántí Jèhófà? Ẹ́kísódù 3:15 sọ́ pé: “Jèhófà . . . ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” Gẹ̀gẹ̀ẹ̀gẹ̀ ni Aísáyà ń gbé orúkọ Jèhófà àti gbogbo ohun tó dúró fún, títí kan ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo àti àwọn ọ̀nà Rẹ̀. Ìbùkún Jèhófà dájú fún àwọn tó bá fẹ́ràn rẹ̀ lọ́nà kan náà.—Sáàmù 5:8; 25:4, 5; 135:13; Hóséà 12:5.
17. Àwọn àǹfààní wo ni wọn kì yóò fún àwọn ẹni burúkú?
17 Àmọ́ ṣá o, gbogbo èèyàn kọ́ ló fẹ́ràn Jèhófà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ tó ga. (Ka Aísáyà 26:10.) Àní bí wọ́n bá tilẹ̀ ké sí èèyàn burúkú wá, ńṣe ni yóò kọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ òdodo tó lè gbé e wọ “ilẹ̀ ìfòtítọ́-hùwà,” ìyẹn ilẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tí wọ́n jẹ́ afòtítọ́-hùwà nípa tí ara àti tẹ̀mí, ń gbé. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni burúkú “kì yóò . . . rí ọlá ògo Jèhófà.” Àwọn ìbùkún tí yóò máa ṣàn wá sọ́dọ̀ aráyé lẹ́yìn tí ìdáláre bá ti bá orúkọ Jèhófà kò ní ṣojú wọn rárá débi tí yòó kàn wọ́n. Àní nínú ayé tuntun pàápàá, nígbà tí gbogbo ayé yóò jẹ́ “ilẹ̀ ìfòtítọ́-hùwà,” àwọn kan lè kọ̀ láti kọbi ara sí inúrere onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà. Orúkọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sì ní wọ ìwé ìyè.—Aísáyà 65:20; Ìṣípayá 20:12, 15.
18. Ọ̀nà wo làwọn kan nígbà ayé Aísáyà fi mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti jẹ́ afọ́jú, ìgbà wo sì ni wọn yóò fi tipátipá “rí” Jèhófà?
18 “Jèhófà, ọwọ́ rẹ ti di gíga, ṣùgbọ́n wọn kò rí i. Wọn yóò wò, ojú yóò sì tì wọ́n nítorí ìtara fún àwọn ènìyàn rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, iná náà fún àwọn elénìní rẹ yóò jẹ wọ́n run.” (Aísáyà 26:11) Nígbà ayé Aísáyà, ọwọ́ Jèhófà fara hàn lọ́nà tó fi hàn pé ó ti di gíga nígbà tí Jèhófà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa kíkọlu àwọn ọ̀tá wọn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ ni kò mọ èyí bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, irú àwọn bẹ́ẹ̀, tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti jẹ́ afọ́jú nípa tẹ̀mí, yóò “rí” tàbí wọn yóò mọ Jèhófà tipátipá nígbà tí iná ìtara rẹ̀ bá jẹ wọ́n run. (Sefanáyà 1:18) Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì lẹ́yìn náà pé: “Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”—Ìsíkíẹ́lì 38:23.
“Ẹni Tí Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ni Ó Máa Ń Bá Wí”
19, 20. Èé ṣe tí Jèhófà fi jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ níyà, báwo ló ṣe jẹ wọ́n níyà, ta ló sì ti jàǹfààní látinú irú ìyà bẹ́ẹ̀?
19 Aísáyà mọ̀ pé ọlá ìbùkún Jèhófà làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè òun fi ń rí àlàáfíà àti aásìkí èyíkéyìí tí wọ́n bá ní. Ó ní: “Jèhófà, ìwọ yóò yan àlàáfíà fún wa, nítorí pé gbogbo iṣẹ́ wa ni o ti ṣe fún wa.” (Aísáyà 26:12) Síbẹ̀síbẹ̀, yàtọ̀ sí ti pé Jèhófà tún fún àwọn èèyàn rẹ̀ láǹfààní láti di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́,” báa bá yẹ ìtàn Júdà wò, ńṣe ni wọ́n ń fẹsẹ̀ kọ ṣáá. (Ẹ́kísódù 19:6) Ńṣe làwọn èèyàn ibẹ̀ ń bọ̀rìṣà léraléra. Nípa bẹ́ẹ̀, ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń jẹ wọ́n léraléra ni. Àmọ́, ìfẹ́ tí Jèhófà ní ló fi ń bá wọn wí bẹ́ẹ̀, nítorí “ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.”—Hébérù 12:6.
20 Lọ́pọ̀ ìgbà, ìbáwí tí Jèhófà máa ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ ni pé yóò yọ̀ǹda kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ìyẹn“àwọn ọ̀gá mìíràn,” jẹ gàba lé wọn lórí. (Ka Aísáyà 26:13.) Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó yọ̀ǹda kí àwọn ará Bábílónì kó wọn lọ sí ìgbèkùn. Ǹjẹ́ ìyẹn ṣe wọ́n láǹfààní kankan? Kò sí àǹfààní kankan nínú kí ìyà ó jẹni. Àmọ́, bí ẹni tí ìyà jẹ bá fi ìyẹn ṣàríkọ́gbọ́n, tó ronú pìwà dà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Jèhófà ní ìfọkànsìn àyàsọ́tọ̀ gédégbé, a jẹ́ pé ó ṣe é láǹfààní. (Diutarónómì 4:25-31) Ǹjẹ́ Júù kankan ronú pìwà dà lọ́nà tí Ọlọ́run ń fẹ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Aísáyà sọ ọ́ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ rẹ nìkan ni a óò mẹ́nu kan orúkọ rẹ.” Lẹ́yìn tí àwọn Júù ti dé láti ìgbèkùn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n lè jìyà nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn o, ṣùgbọ́n wọn kò tún jẹ́ tọrùn bọ ìjọsìn àwọn ọlọ́run òkúta rárá.
21. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó jẹ gàba lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí?
21 Àwọn tó wá mú Júdà lóǹdè ńkọ́? Ó ní: “Ní jíjẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú, wọn kì yóò dìde. Nítorí náà, ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ kí o lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú, kí o sì pa gbogbo mímẹ́nukàn wọ́n run.” (Aísáyà 26:14) Bábílónì yóò jìyà nítorí ìwà ìkà tó hù sí orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Jèhófà. Jèhófà yóò lo àwọn ará Mídíà àti Páṣíà láti fi dojú Bábílónì agbéraga dé, yóò sì tú àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn sílẹ̀. Wọn yóò sì sọ Bábílónì, ìlú ńlá nì, di aláìlè-ta-pútú, bí òkú ni yóò rí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, yóò pa rẹ́.
22. Lóde òní, báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ṣe rí ìbùkún gbà?
22 Nínú ìmúṣẹ tòde òní, ọdún 1919 ni wọ́n tú àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí táa ti yọ́ mọ́ sílẹ̀ kúrò nínú Bábílónì Ńlá, tí wọ́n sì dá wọn padà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bí okun àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sì ṣe sọjí padà, ni wọ́n bá tara bọ iṣẹ́ ìwàásù wọn ní pẹrẹu. (Mátíù 24:14) Jèhófà sì wá mú kí wọ́n bí sí i, débi pé ó tilẹ̀ mú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “àwọn àgùntàn mìíràn” wọlé wá kí wọ́n jùmọ̀ máa sìn. (Jòhánù 10:16) Ó ní: “Ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà; Jèhófà, ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà; ìwọ ti ṣe ara rẹ lógo. Ìwọ ti sún gbogbo ojú ààlà ilẹ̀ náà síwájú jìnnà-jìnnà. Jèhófà, nígbà wàhálà, wọ́n yí àfiyèsí wọn sọ́dọ̀ rẹ; wọ́n tú ọ̀rọ̀ àdúrà wúyẹ́wúyẹ́ jáde nígbà tí wọ́n rí ìbáwí rẹ.”—Aísáyà 26:15, 16.
“Wọn Yóò Dìde”
23. (a) Ọ̀nà ìyanu wo ni Jèhófà gbà lo agbára rẹ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Ọ̀nà tó jọ èyí wo ló tún gbà lò ó lọ́dún 1919 Sànmánì Tiwa?
23 Aísáyà wá padà sórí ipò tí Júdà wà nígbà tó ṣì jẹ́ òǹdè Bábílónì. Ó fi orílẹ̀-èdè yẹn wé obìnrin tó ń rọbí, tí kò sì lè dá ọmọ yẹn bí fúnra rẹ̀. (Ka Aísáyà 26:17, 18.) Ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ni ìrànlọ́wọ́ dé, àwọn èèyàn Jèhófà sì padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n ń hára gàgà láti tún tẹ́ńpìlì kọ́ kí wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé ṣe ló jí orílẹ̀-èdè yẹn dìde nínú òkú. Ó ní: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. Òkú tèmi—wọn yóò dìde. Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! Nítorí pé ìrì rẹ dà bí ìrì ewéko málò, ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” (Aísáyà 26:19) Áà, Jèhófà mà lo agbára rẹ̀ lọ́nà ìyanu o! Ẹ̀wẹ̀, ọ̀nà àrà gbáà ló sì tún ti lo agbára rẹ̀ lọ́dún 1919 nígbà tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ nípa tẹ̀mí! (Ìṣípayá 11:7-11) Áà, ọjọ́ lọjọ́ náà nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí yóò tún ṣẹ ní gidi nínú ayé tuntun, tí àwọn tí ikú sọ dí aláìlè-ta-pútú yóò ‘gbọ́ ohùn Jésù, tí wọn yóò sì jáde wá’ látinú ibojì ìrántí!—Jòhánù 5:28, 29.
24, 25. (a) Ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀nà wo ló jọ pé àwọn Júù gbà ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kí wọ́n lọ fi ara wọn pa mọ́? (b) Kí ni “yàrá inú lọ́hùn-ún” lè tọ́ka sí lásìkò òde òní, irú ẹ̀mí wo ló sì yẹ ká ní sí i?
24 Àmọ́, bí àwọn olóòótọ́ yóò bá gba àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà ṣèlérí, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà pa pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá. Nítorí pé, wò ó! Jèhófà ń jáde bọ̀ láti ipò rẹ̀, láti béèrè ìjíhìn fún ìṣìnà àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lòdì sí òun, dájúdájú, ilẹ̀ náà yóò sì fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ hàn síta, kì yóò sì tún bo àwọn tirẹ̀ tí a pa mọ́.” (Aísáyà 26:20, 21; fi wé Sefanáyà 1:14.) Ó ṣeé ṣe kí àyọkà yìí kọ́kọ́ ṣẹ nígbà tí Kírúsì Ọba kó àwọn ará Mídíà àti Páṣíà lọ ṣẹ́gun Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Sẹ́nófọ̀n, òpìtàn tó jẹ́ ará Gíríìkì wí, bí Kírúsì ṣe wọ Bábílónì, ńṣe ló pàṣẹ pé kónílé-ó-gbélé, nítorí pé òun ti sọ fún àwọn agẹṣinjagun òun pé “kí wọ́n ṣá ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí lóde balẹ̀.” Lónìí, a lè rí i pé “yàrá inú lọ́hùn-ún” tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ jẹ mọ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà tó wà káàkiri ayé. Ṣe ni àwọn ìjọ yẹn yóò máa bá a lọ láti kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa, kódà títí wọ ìgbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:14) Ó mà kúkú ṣe pàtàkì o, pé ká lẹ́mìí tó dáa sí ìjọ, kí a sì máa péjọ pọ̀ níbẹ̀ déédéé!—Hébérù 10:24, 25.
25 Láìpẹ́, òpin ayé Sátánì yóò dé. Ní báyìí, a ò tíì mọ ọ̀nà tí Jèhófà yóò gbà dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lákòókò ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ yẹn. (Sefanáyà 2:3) Ṣùgbọ́n, a mọ̀ dáadáa pé bí a óò bá là á já, ó kù sọ́wọ́ ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àti ìdúróṣinṣin wa àti gbígbọ́ tí a bá gbọ́ràn sí i lẹ́nu.
26. Kí ni “Léfíátánì” nígbà ayé Aísáyà àti nígbà tiwa, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí “ẹran ńlá abàmì inú òkun” yẹn?
26 Ọjọ́ iwájú yẹn ni Aísáyà ń wò tó fi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà, tòun ti idà rẹ̀ líle tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí Léfíátánì, ejò tí ń yọ́ bẹ̀rẹ́, àní sí Léfíátánì, ejò wíwọ́, dájúdájú, òun yóò pa ẹran ńlá abàmì inú òkun, èyí tí ń bẹ nínú òkun.” (Aísáyà 27:1) Àwọn orílẹ̀-èdè bíi Bábílónì, Íjíbítì, àti Ásíríà, tí Ísírẹ́lì fọ́n ká sí, ni “Léfíátánì” ń tọ́ka sí nígbà tó kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ. Orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ò ní lè dènà àwọn èèyàn Jèhófà kí wọ́n má padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn tó bá tó àsìkò rẹ̀. Àmọ́, ta ni Léfíátánì òde òní? Ó jọ pé Sátánì ni, ìyẹn “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” àti ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tó jẹ́ ohun èlò tó fi ń bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí jagun. (Ìṣípayá 12:9, 10; 13:14, 16, 17; 18:24) Ọdún 1919 ni apá “Léfíátánì” ò ti ká àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́, yóò sì di àfẹ́kù pátápátá nígbà tí Jèhófà bá “pa ẹran ńlá abàmì inú òkun” yẹn. Ní báyìí ná, kò sí ohun tí “Léfíátánì” bá ń gbìyànjú láti ṣe sí àwọn èèyàn Jèhófà tí yóò fi bẹ́ẹ̀ láṣeyọrí kankan.—Aísáyà 54:17.
“Ọgbà Àjàrà Wáìnì Tí Ń Yọ Ìfóófòó”
27, 28. (a) Kí ni ọgbà àjàrà Jèhófà ti fi kún gbogbo ayé? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo ọgbà àjàrà rẹ̀?
27 Aísáyà wá fi orin mìíràn ṣe àpèjúwe tó wúni lórí nípa bí àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n dá nídè ṣe méso jáde wọ̀ǹtìwọnti, ó ní: “Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin sí obìnrin náà pé: ‘Ọgbà àjàrà wáìnì tí ń yọ ìfóófòó! Èmi, Jèhófà, yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni èmi yóò máa bomi rin ín. Kí ẹnikẹ́ni má bàa yí àfiyèsí rẹ̀ lòdì sí i, èmi yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ ní òru àti ní ọ̀sán pàápàá.’” (Aísáyà 27:2, 3) Ní tòótọ́, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ń ṣiṣẹ́ kárakára ti fi èso nípa tẹ̀mí kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Èwo la ò wá ní yọ̀ sí, ká bú sórin o jàre! Jèhófà tó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ̀ ni gbogbo ọpẹ́ mà yẹ o.—Fi wé Jòhánù 15:1-8.
28 Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdùnnú ti dipò bíbínú tí Jèhófà bínú níṣàájú! “Èmi kò ní ìhónú kankan. Ta ni yóò fún mi ní àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò nínú ìjà ogun? Ṣe ni èmi yóò gbé ẹsẹ̀ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Èmi yóò dáná sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di ibi odi agbára mi mú, kí ó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi; àlàáfíà ni kí ó wá pẹ̀lú mi.” (Aísáyà 27:4, 5) Àtẹ̀rẹ́ ni Jèhófà ń tẹ ohunkóhun tó bá ti dà bí èpò tó lè nípa lórí ẹni, tó lè sọ ọgbà àjàrà rẹ̀ dìbàjẹ́, jíjẹ ló sì ń jẹ ẹ́ run bí iná, kí àjàrà rẹ̀ bàa lè máa “yọ ìfóófòó” lọ fùù. Nípa bẹ́ẹ̀, kẹ́nikẹ́ni má ṣe gbìdánwò àtidí àlàáfíà ìjọ Kristẹni lọ́wọ́ o! Dípò bẹ́ẹ̀, kí olúkúlùkù tètè ‘di ibi odi agbára Jèhófà mú’ ni o, kó sì máa wá ojú rere àti ààbò rẹ̀. Béèyàn bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ó ń wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí tó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Aísáyà fi mẹ́nu kàn án lẹ́ẹ̀mejì. Kí ni ìyẹn yóò yọrí sí? Ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, Jékọ́bù yóò ta gbòǹgbò, Ísírẹ́lì yóò mú ìtànná jáde, yóò sì rú jáde ní tòótọ́; ṣe ni wọn yóò wulẹ̀ fi èso kún ojú ilẹ̀ eléso.” (Aísáyà 27:6)c Ìmúṣẹ ẹsẹ yìí mà jẹ́rìí sí agbára Jèhófà lọ́nà ìyanu o! Láti ọdún 1919 ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ń fi “èso,” ìyẹn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, kún ilẹ̀ ayé. Ìyẹn ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn adúróṣinṣin fi lè dára pọ̀ mọ́ wọn, tí wọ́n sì jọ “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìṣípayá 7:15) Àwọn wọ̀nyí ló ń fi tayọ̀tayọ̀ bá a lọ láti máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga rẹ̀ nínú ayé tó díbàjẹ́ yìí. Jèhófà sì ń bá a lọ láti mú kí wọ́n bí sí i. Ǹjẹ́ ká má ṣe gbàgbé àǹfààní ńláǹlà tí a ní láti nípìn-ín nínú “èso” yìí kí a sì máa fi ìhó ìyìn tiwa pín in dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó jọ pé ohun tí Árì túmọ̀ sí ni “Ìlú.”
c A jíròrò Aísáyà 27:7-13 nínú àpótí tó wà lójú ewé 285.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 285]
“Ìwo Ńlá” Kéde Òmìnira
Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìrora Júdà pọ̀ sí i nígbà tí Jèhófà fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ní ti pé ó jẹ́ kí wọ́n kó wọn nígbèkùn, ìyẹn ni ọrẹ́ tó fi nà wọ́n. (Ka Aísáyà 27:7-11.) Ìṣìnà orílẹ̀-èdè yẹn ga gidigidi dépò pé ẹbọ ẹran ò lè ṣètùtù rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, bí ẹní ‘kígbe’ lé àgùntàn tàbí ewúrẹ́ láti tú wọn ká tàbí bí ẹní “fi ẹ̀fúùfù òjijì” gbá ìràwé dànù ni Jèhófà lé Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà wá dẹni tó jẹ́ pé ahẹrẹpẹ èèyàn pàápàá, tí a fi obìnrin ṣàpẹẹrẹ, lè máa jẹ gàba lé lórí.
Àmọ́, àsìkò tó tí Jèhófà fẹ́ tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbèkùn. Bí àgbẹ̀ ṣe ń tú àwọn èso ólífì tí igi gbé dè sílẹ̀, lédè àpèjúwe, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe tú wọn sílẹ̀. Ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò lu èso já bọ́, láti ibi ìṣàn Odò [Yúfírétì] títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ sì ni a ó ṣa ẹ̀yin fúnra yín ní ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì. Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé fífun ìwo ńlá yóò ṣẹlẹ̀, àwọn tí yóò sì ṣègbé ní ilẹ̀ Ásíríà àti àwọn tí a óò fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì yóò wá dájúdájú, wọn yóò sì tẹrí ba fún Jèhófà ní òkè ńlá mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.” (Aísáyà 27:12, 13) Lẹ́yìn tí Kírúsì ti ṣẹ́gun lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó pa àṣẹ kan pé kí gbogbo àwọn Júù di òmìnira ní ilẹ̀ ọba òun, ìyẹn sì kan àwọn tó wà ní Ásíríà àti Íjíbítì. (Ẹ́sírà 1:1-4) Àfi bí ẹní fun “ìwo ńlá” kan, tó ń mú kí ìró orin yẹn dún lọ rére pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ti dòmìnira.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 275]
“Àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 277]
Àwọn tó jẹ́ òǹdè tẹ́lẹ̀ rí ń fi ẹsẹ̀ tẹ Bábílónì mọ́lẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 278]
“Wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún”