Àìsáyà
61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+
Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+
Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,
Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,
Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+
2 Láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà* Jèhófà
Àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa,+
Láti tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú,+
3 Láti pèsè fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ torí Síónì,
Láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú,
Òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
Aṣọ ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.
4 Wọ́n máa tún àwọn ibi tó ti pa run nígbà àtijọ́ kọ́;
Wọ́n máa kọ́ àwọn ibi tó ti dahoro nígbà àtijọ́,+
Wọ́n sì máa mú kí àwọn ìlú tó ti pa run pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀,+
Àwọn ibi tó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran.+
5 “Àwọn àjèjì máa dúró, wọ́n sì máa tọ́jú àwọn agbo ẹran yín,
Àwọn àlejò + máa jẹ́ àgbẹ̀ yín, wọ́n á sì máa bá yín rẹ́wọ́ àjàrà.+
7 Dípò ìtìjú, ẹ máa ní ìpín ìlọ́po méjì,
Dípò ìdójútì, wọ́n máa kígbe ayọ̀ nítorí ìpín wọn.
Àní, ìpín ìlọ́po méjì ni wọ́n máa gbà ní ilẹ̀ wọn.+
Wọ́n á máa yọ̀ títí ayérayé.+
Màá fi òótọ́ san èrè iṣẹ́ wọn fún wọn,
Màá sì bá wọn dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé.+
10 Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà.