Àìsáyà
Mi ò sì ní dúró jẹ́ẹ́ nítorí Jerúsálẹ́mù,
Títí òdodo rẹ̀ fi máa tàn bí iná tó mọ́lẹ̀ yòò,+
Tí ìgbàlà rẹ̀ sì máa jó bí iná ògùṣọ̀.+
A sì máa fi orúkọ tuntun pè ọ́,+
Èyí tí Jèhófà máa fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.
3 O máa di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà,
Láwàní ọba ní àtẹ́lẹwọ́ Ọlọ́run rẹ.
Àmọ́ wọ́n máa pè ọ́ ní Inú Mi Dùn sí I,+
Wọ́n sì máa pe ilẹ̀ rẹ ní Èyí Tí A Gbé Níyàwó.
Torí inú Jèhófà máa dùn sí ọ,
Ilẹ̀ rẹ sì máa dà bí èyí tí a gbé níyàwó.
5 Torí bí ọ̀dọ́kùnrin ṣe ń gbé wúńdíá níyàwó,
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ máa gbé ọ níyàwó.
Bí ọkọ ìyàwó ṣe máa ń yọ̀ nítorí ìyàwó,
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ máa yọ̀ nítorí rẹ.+
6 Mo ti yan àwọn olùṣọ́ sórí àwọn ògiri rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.
Nígbà gbogbo, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ àti ní gbogbo òru mọ́jú, wọn ò gbọ́dọ̀ dákẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ Jèhófà,
Ẹ má sinmi,
7 Ẹ má ṣe jẹ́ kó sinmi rárá, títí ó fi máa fìdí Jerúsálẹ́mù múlẹ̀ gbọn-in,
Àní, títí ó fi máa fi í ṣe ìyìn ayé.”+
8 Jèhófà ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, apá rẹ̀ tó lágbára, búra pé:
“Mi ò ní fi ọkà rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́,
Àwọn àjèjì ò sì ní mu wáìnì tuntun rẹ mọ́, èyí tí o ṣiṣẹ́ kára fún.+
9 Àmọ́ àwọn tó ń kó o jọ máa jẹ ẹ́, wọ́n sì máa yin Jèhófà;
Àwọn tó ń gbà á sì máa mu ún ní àwọn àgbàlá mímọ́ mi.”+
10 Ẹ kọjá, ẹ gba àwọn ẹnubodè kọjá.
Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn èèyàn.+
Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe òpópó.
Ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.+
Ẹ gbé àmì* sókè fún àwọn èèyàn.+
11 Ẹ wò ó! Jèhófà ti kéde títí dé àwọn ìkángun ayé pé:
“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé,
‘Wò ó! Ìgbàlà rẹ ń bọ̀.+
Wò ó! Èrè rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,
Ẹ̀san rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.’”+