Orí Kẹtàlélógún
“Orúkọ Tuntun” Kan
1. Ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ wo ló wà nínú Aísáyà orí kejìlélọ́gọ́ta?
Ọ̀RỌ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀, ìtùnú, àti ìrètí pé ìmúbọ̀sípò yóò wáyé ni àwọn Júù tó ti sọ̀rètí nù ní Bábílónì nílò. Ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló ti kọjá lọ lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ pa run. Ahoro ni Júdà wà lọ́hùn-ún, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà sí Bábílónì, àfi bíi pé Jèhófà tiẹ̀ ti gbàgbé àwọn Júù. Kí ló lè wá mú kí nǹkan sàn fún wọn? Àwọn ìlérí Jèhófà ni o, àwọn ìlérí tí ó ṣe pé òun yóò mú wọn padà lọ sí ìlú wọn, òun yóò sì yọ̀ǹda kí wọ́n tún padà máa ṣe ìsìn mímọ́ níbẹ̀. Ní ìgbà yẹn, àwọn orúkọ tó ń fi hàn pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run yóò rọ́pò àwọn àpèjúwe bí, obìnrin “tí a fi sílẹ̀ pátápátá” àti ilẹ̀ tó “wà ní ahoro.” (Aísáyà 62:4; Sekaráyà 2:12) Irú àwọn ìlérí bí èyí ló kún inú Aísáyà orí kejìlélọ́gọ́ta. Àmọ́, bíi tàwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò yòókù ni orí yìí ṣe rí, ó mẹ́nu kan àwọn ọ̀ràn mìíràn tó ré kọjá ìdáǹdè tí àwọn Júù yóò gbà kúrò nígbèkùn Bábílónì. Nígbà tí Aísáyà orí kejìlélọ́gọ́ta wá ní ìmúṣẹ pàtàkì, ó mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé ìgbàlà orílẹ̀-èdè Jèhófà nípa tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” dájú.—Gálátíà 6:16.
Jèhófà Kò Dúró Jẹ́ẹ́
2. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ṣojú rere sí Síónì lẹ́ẹ̀kan sí i?
2 Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, a ṣẹ́gun Bábílónì. Lẹ́yìn ìṣẹ́gun yẹn, Kírúsì ọba Páṣíà pa àṣẹ kan tó mú kí àwọn Júù tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè padà sí Jerúsálẹ́mù láti tún lọ bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn Jèhófà padà níbẹ̀. (Ẹ́sírà 1:2-4) Ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ni àwọn Júù tó kọ́kọ́ gbéra láti padà sílé dé ìlú ìbílẹ̀ wọn. Báyìí ni Jèhófà tún ṣojú rere sí Jerúsálẹ́mù lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí sì hàn nínú ọ̀nà tó tuni lára tó gbà fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí pé: “Nítorí ti Síónì, èmi kì yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, àti nítorí ti Jerúsálẹ́mù, èmi kì yóò dúró jẹ́ẹ́ títí òdodo rẹ̀ yóò fi jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ìtànyòò, àti ìgbàlà rẹ̀ bí ògùṣọ̀ tí ń jó.”—Aísáyà 62:1.
3. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ Síónì orí ilẹ̀ ayé sílẹ̀ níkẹyìn, ta ló sì rọ́pò rẹ̀? (b) Ìyapa wo ló wáyé, ìgbà wo ló wáyé, àkókò kí ni a sì wà lóde òní?
3 Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà mú ìlérí tó ṣe pé òun yóò mú Síónì tàbí Jerúsálẹ́mù bọ̀ sípò ṣẹ. Ó gba àwọn aráàlú yẹn là, òdodo wọn sì tàn yòò. Àmọ́, nígbà tó yá, wọ́n tún yà kúró nínú ìsìn mímọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n kọ Jésù sílẹ̀ pé kì í ṣe Mèsáyà, ni Jèhófà bá kúkú kọ̀ wọ́n pátápátá pé wọn kì í ṣe àyànfẹ́ orílẹ̀-èdè òun mọ́. (Mátíù 21:43; 23:38; Jòhánù 1:9-13) Jèhófà wá mú kí orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wáyé. Orílẹ̀-èdè tuntun yìí di àkànṣe èèyàn rẹ̀, àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè yìí ní ọ̀rúndún kìíní ń fi ìtara wàásù ìhìn rere jákèjádò ibi tí àwọn èèyàn mọ̀ ní ayé ìgbà yẹn. (Gálátíà 6:16; Kólósè 1:23) Ó wá bani nínú jẹ́ pé, bí àwọn àpọ́sítélì ṣe kú tán, làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí yapa kúró nínú ìsìn tòótọ́. Ìyẹn ni ìsìn Kristẹni tàwọn apẹ̀yìndà fi bẹ̀rẹ̀, àwọn la sì ń rí káàkiri inú Kirisẹ́ńdọ̀mù lóde òní. (Mátíù 13:24-30, 36-43; Ìṣe 20:29, 30) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni Jèhófà fi fi Kirisẹ́ńdọ̀mù sílẹ̀ kí wọ́n máa kó ẹ̀gàn ńlá bá orúkọ òun. Àmọ́, níkẹyìn, lọ́dún 1914, “ọdún ìtẹ́wọ́gbà” Jèhófà bẹ̀rẹ̀, ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí sì wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ pàtàkì.—Aísáyà 61:2.
4, 5. (a) Ta ní dúró fún Síónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ lóde òní? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo Síónì tí “ìgbàlà” Síónì fi wá dà bí iná “ògùṣọ̀ tí ń jó”?
4 Lóde òní, ìlérí tí Jèhófà ṣe láti mú Síónì padà bọ̀ sípò ti ṣẹ sórí ètò àjọ rẹ̀ ní ọ̀run, èyíinì ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ní ti pé ó ṣẹ sórí àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn Kristẹni táa fẹ̀mí yàn. (Gálátíà 4:26) Ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run jẹ́ olùrànlọ́wọ́ àtàtà, ìyẹn ni pé ó wà lójúfò, ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti òṣìṣẹ́ aláápọn. Nígbà tó wá bí Ìjọba Mèsáyà lọ́dún 1914, ayọ̀ yẹn pọ̀ jọjọ! (Ìṣípayá 12:1-5) Láti ọdún 1919 ní pàtàkì ni àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ti ń wàásù fún àwọn orílẹ̀-èdè ayé nípa jíjẹ́ tó jẹ́ olódodo àti nípa ìgbàlà rẹ̀. Ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ni àwọn ọmọ yìí ṣe, wọ́n tàn rokoṣo bí iná ògùṣọ̀ láàárín òkùnkùn, wọ́n ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn.—Mátíù 5:15, 16; Fílípì 2:15.
5 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ gidigidi, kò sì ní sinmi tàbí kó dúró jẹ́ẹ́, títí tí yóò fi mú àwọn ìlérí tó ṣe fún Síónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ pátápátá. Àwọn àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò jẹ́ panu mọ́ bákan náà. (Jòhánù 10:16) Ìró ohùn wọn gbalẹ̀ kan ni, bí wọ́n ṣe ń tọ́ka ọ̀nà ìgbàlà kan ṣoṣo tó wà fún àwọn èèyàn.—Róòmù 10:10.
Jèhófà Sọ Ọ́ Ní “Orúkọ Tuntun”
6. Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe fún Síónì?
6 Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe fún Síónì, “obìnrin” rẹ̀ ti ọ̀run, èyí tí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ ṣàpẹẹrẹ? Ó ní: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì rí òdodo rẹ, ìwọ obìnrin, gbogbo àwọn ọba yóò sì rí ògo rẹ. Ní ti tòótọ́, a ó sì máa fi orúkọ tuntun pè ọ́, èyí tí ẹnu Jèhófà gan-an yóò dárúkọ.” (Aísáyà 62:2) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń hùwà òdodo, ó di dandan fún àwọn orílẹ̀-èdè láti yí àfiyèsí sí wọn. Kódà, àwọn ọba gbà tipátipá pé Jèhófà ló ń lo Jerúsálẹ́mù àti pé èyíkéyìí nínú ìṣàkóso tí àwọn ń ṣe kò já mọ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ìjọba Jèhófà.—Aísáyà 49:23.
7. Kí ni orúkọ tuntun tí Síónì gbà dúró fún?
7 Jèhófà wá fìdí àyípadà tó bá Síónì múlẹ̀ nípa sísọ ọ́ lórúkọ tuntun. Orúkọ tuntun yẹn dúró fún ipò aásìkí àti iyì tí àwọn ọmọ Síónì lórí ilẹ̀ ayé bọ́ sí láti ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa.a Ó fi hàn pé Jèhófà gbà pé Síónì jẹ́ tòun. Lóde òní, ìwúrí ló jẹ́ fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run pé àwọn jẹ́ ẹni tí inú Jèhófà dùn sí lọ́nà báyìí, àwọn àgùntàn mìíràn sì ń bá wọn yọ̀ pẹ̀lú.
8. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà bọlá fún Síónì?
8 Bí Jèhófà ṣe sọ Síónì lórúkọ tuntun tán, ó wá ṣèlérí pé: “Ìwọ yóò sì di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà, àti láwàní ọba ní àtẹ́lẹwọ́ Ọlọ́run rẹ.” (Aísáyà 62:3) Jèhófà gbé aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn Síónì ti ọ̀run ga kí a lè máa fojú iyì wò ó. (Sáàmù 48:2; 50:2) Adé ẹwà àti “láwàní ọba” tí ibí yìí wí ń fi hàn pé Jèhófà bọlá fún un, ó sì fún un ní ọ̀pá àṣẹ. (Sekaráyà 9:16) Iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run fọwọ́ ara rẹ̀ ṣe, ohun tó fi agbára rẹ̀ ṣe, ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run, tó dúró fún Síónì ti ọ̀run, tàbí “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” (Gálátíà 4:26) Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, ìwà títọ́ àti ìfọkànsìn tó bùáyà ni orílẹ̀-èdè nípa tẹ̀mí yìí ti ń bá bọ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, ì báà jẹ́ àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, sì rí okun gbà, èyí tó mú kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó tayọ lọ́lá. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, àwọn ẹni àmì òróró, tí yóò ti gba èrè wọn ológo ní ọ̀run, ni ohun èlò tí Jèhófà yóò lo láti fi mú kí ìṣẹ̀dá tó ń kérora di èyí tó gba ìyè ayérayé.—Róòmù 8:21, 22; Ìṣípayá 22:2.
‘Jèhófà Ní Inú Dídùn sí Ọ’
9. Ṣàpèjúwe àyípadà tó bá Síónì.
9 Orúkọ tuntun tí Síónì ti ọ̀run wá ń jẹ́ ni ara àyípadà dídùnmọ́ni tó dé bá a, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. A kà á pé: “A kì yóò sọ mọ́ pé ìwọ jẹ́ obìnrin tí a fi sílẹ̀ pátápátá; a kì yóò sì sọ mọ́ pé ilẹ̀ rẹ wà ní ahoro; ṣùgbọ́n a óò máa pe ìwọ alára ní Inú Dídùn Mi Wà Nínú Rẹ̀, a ó sì máa pe ilẹ̀ rẹ ní Èyí Tí A Mú Ṣe Aya. Nítorí pé Jèhófà yóò ti ní inú dídùn sí ọ, ilẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ èyí tí a mú ṣe aya.” (Aísáyà 62:4) Láti ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Síónì orí ilẹ̀ ayé ti wà láhoro. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí fi í lọ́kàn balẹ̀ pé yóò padà bọ̀ sípò àti pé àwọn èèyàn yóò padà máa wá gbé inú ilẹ̀ rẹ̀. Síónì tó ti fìgbà kan wà láhoro kò ní jẹ́ obìnrin tí a fi sílẹ̀ pátápátá mọ́, ilẹ̀ rẹ̀ kò sì ní wà láhoro mọ́. Ipò tuntun ni pípadà tí Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa jẹ́ fún un, ó yàtọ̀ pátápátá sí ahoro tó ti wà látẹ̀yìnwá. Jèhófà kéde pé, a óò máa pe Síónì ní “Inú Dídùn Mi Wà Nínú Rẹ,” àti ilẹ̀ rẹ̀ ní “Èyí Tí A Mú Ṣe Aya.”—Aísáyà 54:1, 5, 6; 66:8; Jeremáyà 23:5-8; 30:17; Gálátíà 4:27-31.
10. (a) Báwo ni àyípadà ṣe bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run? (b) Kí ni “ilẹ̀” Ísírẹ́lì Ọlọ́run?
10 Ọdún 1919 ni irú àyípadà bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run kọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀. Àmọ́ lọ́dún 1919, wọ́n tún padà sí ipò ojú rere tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn sì di èyí táa yọ́ mọ́. Èyí kan àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, ó kan ètò àjọ wọn, ó sì kan ìgbòkègbodò wọn. Ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run wá dẹni tó wá sí “ilẹ̀” rẹ̀, ìyẹn ipò rẹ̀ tàbí àgbègbè ìgbòkègbodò rẹ̀ nípa tẹ̀mí.—Aísáyà 66:7, 8, 20-22.
11. Báwo ni àwọn Júù ṣe fi ìyá wọn ṣe aya?
11 Jèhófà wá túbọ̀ ṣàlàyé sí i nípa ipò ojú rere tí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sí, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin ti ń mú wúńdíá ṣe aya, àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò mú ọ ṣe aya. Àti pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà tí ọkọ ìyàwó máa ń ní nítorí ìyàwó, Ọlọ́run rẹ yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà àní nítorí rẹ.” (Aísáyà 62:5) Báwo ni àwọn Júù, “àwọn ọmọ” Síónì, ṣe lè fi ìyá wọn ṣe aya? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní ti pé àwọn ọmọ Síónì táa dá nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì padà wá gba olú ìlú wọn àtijọ́, wọ́n sì tún padà ń gbé ibẹ̀. Nígbà tí ìyẹn sì ti ṣẹlẹ̀, Síónì kò wà láhoro mọ́, ńṣe ni àwọn ọmọ rẹ̀ kún ibẹ̀ bámúbámú.—Jeremáyà 3:14.
12. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ ara ètò àjọ tí òun fi ṣe aya? (b) Báwo ni ìwà tí Jèhófà hù sí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe jẹ́ àwòkọ́ṣe àtàtà fún àwọn tó wà nínú ìdè ìgbéyàwó lóde òní? (Wo àpótí ojú ewé 342.)
12 Ní ọ̀nà kan náà, láti ọdún 1919 ni àwọn ọmọ Síónì ti ọ̀run ti gba ilẹ̀ wọn, ìyẹn ipò wọn nípa tẹ̀mí, tí ó ń jẹ́ orúkọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, “Èyí Tí A Mú Ṣe Aya.” Ìgbòkègbodò Kristẹni tí wọ́n ń ṣe nínú ilẹ̀ yẹn jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ” Jèhófà. (Ìṣe 15:14) Èso Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń mú jáde, tí wọ́n sì ń kéde orúkọ Jèhófà, jẹ́ kó hàn kedere pé inú Jèhófà dùn sí àwọn Kristẹni yìí. Jèhófà kúkú ti sọ ọ́ gbangba pé wọ́n jẹ́ ara ètò àjọ tó ní àjọṣe pẹ̀lú òun nínú ìṣọ̀kan tí kò lè fọ́. Bí Jèhófà ṣe fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni yìí, tó dá wọn nídè kúrò nínú ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, tó sì ń lò wọ́n láti máa wàásù ìrètí Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo aráyé, ṣe ló ń fi hàn pé òun ń yọ̀ nítorí wọn bí ọkọ ìyàwó ṣe máa ń yọ̀ nítorí ìyàwó rẹ̀.—Jeremáyà 32:41.
“Kí Ìdákẹ́jẹ́ẹ́ Má Ṣe Sí Níhà Ọ̀dọ̀ Yín”
13, 14. (a) Láyé àtijọ́, báwo ni Jerúsálẹ́mù ṣe di ìlú tó jẹ́ ibi ààbò? (b) Lóde òní, báwo ni Síónì ṣe di “ìyìn ní ilẹ̀ ayé”?
13 Orúkọ ìṣàpẹẹrẹ tuntun tí Jèhófà sọ àwọn èèyàn rẹ̀ yìí ń mú kí wọ́n ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn, àti pé tirẹ̀ ni àwọn ń ṣe. Wàyí o, Jèhófà lo àpèjúwe mìíràn, ó bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ bíi pé wọ́n jẹ́ ìlú olódi, ó ní: “Èmi ti fàṣẹ yan àwọn olùṣọ́ sórí àwọn ògiri rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ àti láti òru mọ́jú, nígbà gbogbo, kí wọ́n má ṣe dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ̀yin tí ń mẹ́nu kan Jèhófà, kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ má ṣe sí níhà ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ má sì fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ títí yóò fi fìdí Jerúsálẹ́mù sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, bẹ́ẹ̀ ni, títí yóò fi gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyìn ní ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 62:6, 7) Nígbà tó tákòókò lójú Jèhófà, lẹ́yìn tí àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ padà dé láti Bábílónì, Jerúsálẹ́mù di “ìyìn ní ilẹ̀ ayé” lóòótọ́, àní ìlú olódi tó jẹ́ ibi ààbò fún àwọn olùgbé ibẹ̀. Tọ̀sán tòru làwọn olùṣọ́ tó wà lórí àwọn ògiri rẹ̀ wà lójúfò láti rí i dájú pé ààbò wà fún ìlú yẹn àti láti lè ta àwọn aráàlú lólobó.—Nehemáyà 6:15; 7:3; Aísáyà 52:8.
14 Lóde òní, Jèhófà ti lo àwọn olùṣọ́ rẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró, láti fi tọ́ka ọ̀nà òmìnira kúrò nínú ìsìn èké fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Wọ́n sì ti ké sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n wá sínú ètò àjọ Jèhófà, níbi tí wọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ohun tó ń sọni di àìmọ́ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àkóràn àwọn àṣà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, tí ìbínú Jèhófà kò sì sí lórí wọn. (Jeremáyà 33:9; Sefanáyà 3:19) Ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó ń pèsè “oúnjẹ” nípa tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ń kó ipa tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn ààbò yìí. (Mátíù 24:45-47) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń bá ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí ṣiṣẹ́ pọ̀ ń kó ipa pàtàkì pẹ̀lú ní mímú kí Síónì jẹ́ “ìyìn ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 7:9.
15. Ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn gbà ń sin Jèhófà láìdáwọ́dúró?
15 Iṣẹ́ ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò dáwọ́ dúró rárá o! Ẹ̀rí pé wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ wọn hàn látinú ìgbòkègbodò onítara tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń ṣe pẹ̀lú ìtìlẹyìn àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn aya wọn; àwọn òṣìṣẹ́ ní onírúurú ilé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ohun èlò ìtẹ̀wé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò; àwọn míṣọ́nnárì; àtàwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, aṣáájú ọ̀nà déédéé, àti olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà. Láfikún sí i, wọ́n tún ń ṣiṣẹ́ kárakára lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, bíbẹ àwọn aláìsàn wò, ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tó bá dojú kọ ìpèníjà nípa gbígba ìtọ́jú ìṣègùn, àti pípèsè ohun àfiṣèrànwọ́ ní kánmọ́ fún àwọn tí àjálù bá tàbí àwọn tí jàǹbá ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, “tọ̀sán-tòru” kúkú ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó fi ara wọn rúbọ lọ́nà báyìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn lójú méjèèjì!—Ìṣípayá 7:14, 15.
16. Ọ̀nà wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò fi “fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́”?
16 A rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n máa gbàdúrà láìdabọ̀, kí wọ́n máa bẹ Ọlọ́run pé kí ‘ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ (Mátíù 6:9, 10; 1 Tẹsalóníkà 5:17) A gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n: ‘Má ṣe fún Jèhófà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́’ títí tí yóò fi ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ àti ìrètí wọn, ìyẹn ni pé kí ìsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Jésù tẹnu mọ́ yíyẹ tó yẹ ká máa gbàdúrà lemọ́lemọ́, ó sì rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí “wọ́n ké jáde sí [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.”—Lúùkù 18:1-8.
Èrè Ń Bẹ fún Iṣẹ́ Ìsìn Táa Bá Ṣe fún Ọlọ́run
17, 18. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn ará Síónì fi lè retí pé àwọn yóò rí èrè iṣẹ́ àwọn jẹ? (b) Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà lónìí ṣe ń rí èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ?
17 Orúkọ tuntun tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ mú kí ọkàn wọn balẹ̀ pé ìsapá wọn kò ní já sí asán rárá. Ó ní: “Jèhófà ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá rẹ̀ lílágbára búra pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọkà rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kì yóò mu wáìnì rẹ tuntun mọ́, èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá lé lórí. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń kó o jọ gan-an ni yóò jẹ ẹ́, ó sì dájú pé wọn yóò yin Jèhófà; àní àwọn tí ń gbá a jọ ni yóò mu ún ní àwọn àgbàlá mímọ́ mi.’” (Aísáyà 62:8, 9) Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà àti apá rẹ̀ alágbára ṣàpẹẹrẹ agbára àti okun rẹ̀. (Diutarónómì 32:40; Ìsíkíẹ́lì 20:5) Fífi tó fi ìwọ̀nyí búra ń fi hàn pé ó ti pinnu láti ṣe àyípadà sí ipò tí Síónì wà. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà gba àwọn ọ̀tá Síónì láyè láti já wọ ibẹ̀ kí wọ́n sì kó o lẹ́rù lọ. (Diutarónómì 28:33, 51) Ṣùgbọ́n ní báyìí, kìkì ọwọ́ àwọn tó bá lẹ́tọ̀ọ́ sí ohun ìní Síónì nìkan ni yóò tẹ̀ ẹ́.—Diutarónómì 14:22-27.
18 Nígbà tí ìlérí yìí ṣẹ lóde òní, ńṣe ni àwọn èèyàn Jèhófà tó ti padà bọ̀ sípò ní ọ̀pọ̀ yanturu aásìkí tẹ̀mí. Wọ́n rí èrè tó pọ̀ gidigidi jẹ látinú iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ìyẹn ni pé, iye àwọn tó di Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn pọ̀ sí i, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ nípa tẹ̀mí gbà. (Aísáyà 55:1, 2; 65:14) Nítorí pé àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà kò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ṣèdíwọ́ fún aásìkí wọn nípa tẹ̀mí, tàbí pé kí wọ́n dènà èrè iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣe. Kò sí èyíkéyìí nínú ohun téèyàn bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tí yóò já sí asán.—Málákì 3:10-12; Hébérù 6:10.
19, 20. (a) Báwo ni a ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn Júù láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù? (b) Lóde òní, báwo ni a ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù kí wọ́n lè wá sínú ètò àjọ Jèhófà?
19 Orúkọ tuntun yìí sì tún mú kí ètò àjọ Jèhófà fa àwọn olóòótọ́ èèyàn mọ́ra. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn ló ń rọ́ wá síbẹ̀, ọ̀nà sì wà ní ṣíṣísílẹ̀ fún wọn láti wọlé. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Ẹ kọjá síta, ẹ gba àwọn ẹnubodè kọjá síta. Ẹ tún ọ̀nà àwọn ènìyàn ṣe. Ẹ kọ bèbè, ẹ kọ bèbè òpópó. Ẹ ṣa àwọn òkúta rẹ̀ kúrò. Ẹ gbé àmì àfiyèsí sókè fún àwọn ènìyàn.” (Aísáyà 62:10) Ó jọ pé ìpè pé kí wọ́n gba àwọn ẹnubodè àwọn ìlú ńlá Bábílónì jáde láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù ni ibí yìí ń tọ́ka sí nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹ. Àwọn tó ń padà lọ sílé yìí yóò ní láti ṣa àwọn òkúta kúrò lọ́nà láti mú kí ìrìn àjò wọn rọrùn, wọn yóò sì gbé àmì àfiyèsí sókè láti fi tọ́ka ọ̀nà fáwọn èèyàn.—Aísáyà 11:12.
20 Láti ọdún 1919 ni a ti ya àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” (Aísáyà 35:8) Àwọn ló kọ́kọ́ gba òpópónà nípa tẹ̀mí jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá. (Aísáyà 40:3; 48:20) Ọlọ́run sì wá fún wọn ní àǹfààní pé kí wọ́n mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ pípolongo àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ̀, àti láti fọ̀nà bí àwọn yòókù yóò ṣe de òpópó yẹn hàn wọ́n. Ṣíṣa àwọn òkúta kúrò níbẹ̀, ìyẹn kíkó àwọn ohun ìdìgbòlù ibẹ̀ kúrò, jẹ́ fún àǹfààní tiwọn fúnra wọn. (Aísáyà 57:14) Ó gba pé kí ète àti àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run yé wọn kedere. Lóòótọ́, àwọn ìgbàgbọ́ èké jẹ́ òkúta ìdìgbòlù lójú ọ̀nà ìyè, àmọ́, ṣe ni Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà “bí ọmọ owú tí ń fọ́ àpáta gàǹgà túútúú.” Òun ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lò láti fi fọ́ àwọn òkúta ìdìgbòlù tó lè gbé àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà ṣubú.—Jeremáyà 23:29.
21, 22. Àmì àfiyèsí wo ni Jèhófà gbé kálẹ̀ fún àwọn tó fi ìsìn èké sílẹ̀, báwo lá sì ṣe mọ̀?
21 Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù di àmì àfiyèsí tó ń pe àfiyèsí àṣẹ́kù àwọn Júù pé kí wọ́n padà wálé láti wá tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Aísáyà 49:22) Lọ́dún 1919, nígbà tí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn ìsìn èké, wọn kò rìn gbéregbère kiri. Wọ́n mọ ibi tí wọ́n ń lọ, nítorí Jèhófà gbé àmì àfiyèsí sókè fún wọn. Àmì àfiyèsí wo nìyẹn? Àmì àfiyèsí kan náà tí Aísáyà 11:10 sọ ni, èyí tó kà báyìí pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé gbòǹgbò Jésè yóò wà tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ sí Jésù lára. (Róòmù 15:8, 12) Dájúdájú, Kristi Jésù, Ọba tí ń ṣàkóso lórí Òkè Síónì ti ọ̀run, ni àmì àfiyèsí náà!—Hébérù 12:22; Ìṣípayá 14:1.
22 Ọ̀dọ̀ Jésù Kristi làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn para pọ̀ sí láti fi ìṣọ̀kan jọ́sìn Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo. Ìṣàkóso rẹ̀ wà fún dídá ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà láre, àti láti bù kún àwọn olóòótọ́ ọkàn tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Ǹjẹ́ èyí kò fún olúkúlùkù wa nídìí tó fi yẹ kí a dara pọ̀ nínú yíyìn ín àti nínú gbígbé e ga?
“Ìgbàlà Rẹ Ń Bọ̀”!
23, 24. Báwo ni àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ ṣe ń dẹni tó rí ìgbàlà?
23 Orúkọ tuntun tí Jèhófà fi ta ètò àjọ rẹ̀ tó dà bí aya lọ́rẹ wé mọ́ ìgbàlà ayérayé ti àwọn ọmọ rẹ̀. Aísáyà kọ̀wé pé: “Wò ó! Jèhófà tìkára rẹ̀ ti mú kí a gbọ́ ọ títí dé ibi jíjìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé pé: ‘Ẹ wí fún ọmọbìnrin Síónì pé, “Wò ó! Ìgbàlà rẹ ń bọ̀. Wò ó! Ẹ̀san tí ó ń san ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, owó ọ̀yà tí ó ń san sì wà níwájú rẹ̀.”’” (Aísáyà 62:11) Ìgbàlà dé fún àwọn Júù nígbà tí Bábílónì ṣubú, tí wọ́n sì padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Àmọ́ ohun tó tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ làwọn ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí. Ìkéde Jèhófà múni rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Sekaráyà sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé: “Kún fún ìdùnnú gidigidi, ìwọ ọmọbìnrin Síónì. Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”—Sekaráyà 9:9.
24 Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, tí Ọlọ́run sì fi ẹ̀mí yàn án, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì fọ tẹ́ńpìlì ibẹ̀ mọ́. (Mátíù 21:1-5; Jòhánù 12:14-16) Lóde òní, Jésù Kristi ni ẹni tó ń mú ìgbàlà látọ̀dọ̀ Jèhófà wá fún gbogbo àwọn tó bá gba Ọlọ́run gbọ́. Bí Jésù ṣe gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914, Jèhófà tún yàn án ṣe Onídàájọ́ àti Amúdàájọ́ṣẹ. Lọ́dún 1918, ìyẹn ọdún mẹ́ta ààbọ̀ lẹ́yìn tó gorí ìtẹ́, ó fọ tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí mọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé ṣe fi hàn. (Málákì 3:1-5) Gbígbé tí Jèhófà gbé e sókè gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí, jẹ́ àmì pé iṣẹ́ ìkórè ńlá ti kíkórè àwọn èèyàn láti ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé ní ìtìlẹyìn Ìjọba Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀. Bíi ti ayé àtijọ́, “ìgbàlà” dé fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run nígbà tí wọ́n gba ìdáǹdè kúrò nínú Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919. “Ẹ̀san” tàbí “owó ọ̀yà” tó wà fún àwọn olùkórè tó lẹ́mìí ìfara-ẹni rúbọ yóò jẹ́ ìyè àìleèkú ní ọ̀run tàbí kó jẹ́ ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé. Kí gbogbo àwọn tó bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ fọkàn balẹ̀ pé “òpò” àwọn “kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
25. Ìdánilójú wo làwọn èèyàn Jèhófà rí gbà?
25 Gbangba gbàǹgbà ló hàn pé nǹkan ń bọ̀ wá dùn yùngbà fún ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti fún olúkúlùkù èèyàn aláápọn tó bá dara pọ̀ mọ́ wọn! (Diutarónómì 26:19) Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ṣe ni àwọn ènìyàn yóò sì máa pè wọ́n ní ẹni mímọ́, àwọn tí Jèhófà tún rà; a ó sì máa pe ìwọ alára ní Ẹni Tí A Wá Kiri, Ìlú Ńlá Tí A Kò Fi Sílẹ̀ Pátápátá.” (Aísáyà 62:12) Lásìkò kan, “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” èyí tí Ísírẹ́lì Ọlọ́run ń ṣojú fún, rò pé Ọlọ́run ti pa òun tì. Àmọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tún ní wá sí i lọ́kàn mọ́ rárá. Títí láé ni Jèhófà yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, tí wọn yóò máa rí ìdùnnú rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì “orúkọ tuntun” lè dúró fún ipò tàbí àǹfààní tuntun kan.—Ìṣípayá 2:17; 3:12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 342]
Àwòkọ́ṣe Tó Ga Lọ́lá fún Tọkọtaya
Nígbà tí àwọn èèyàn bá di tọkọtaya, ó máa ń ní ohun tí olúkúlùkù wọn ti fọkàn sí pé ìgbéyàwó yẹn yóò ṣe fún òun. Ṣùgbọ́n kí ni ohun tí Ọlọ́run fọkàn sí ní tirẹ̀? Òun ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. Kí ni ète rẹ̀ nípa rẹ̀?
Ohun kan tó fi irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn yìí hàn ṣe kedere látinú àjọṣe tí ń bẹ láàárín òun àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Aísáyà pe àjọṣe yìí ní ìgbéyàwó. (Aísáyà 62:1-5) Ṣàkíyèsí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “ọkọ” ṣe fún “ìyàwó” rẹ̀. Ó dáàbò bò ó, ó sì yà á sí mímọ́. (Aísáyà 62:6, 7, 12) Ó bọlá fún un, ó sì yẹ́ ẹ sí. (Aísáyà 62:3, 8, 9) Ó sì ní inú dídùn sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn látinú orúkọ tuntun tó sọ ọ́.—Aísáyà 62:4, 5, 12.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àpèjúwe kan náà tí Aísáyà lò fún àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Ísírẹ́lì ni Pọ́ọ̀lù tún lo nígbà tó ń fi àjọṣe tó wà láàárín ọkọ àti aya wé àjọṣe ti Kristi àti ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.—Éfésù 5:21-27.
Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n fi àjọṣe tó wà láàárín Jésù àti ìjọ ṣe àwòṣe nínú ìgbéyàwó tiwọn. Kò tún sí ìfẹ́ tó lè ga tó èyí tí Jèhófà ní sí Ísírẹ́lì àti èyí tí Kristi ní sí ìjọ. Àwọn àjọṣe ìṣàpẹẹrẹ yìí jẹ́ àwòkọ́ṣe tó ga lọ́lá fún àwọn Kristẹni tó bá ń fẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn tòrò kí ó sì dùn.—Éfésù 5:28-33.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 339]
Jèhófà yóò sọ Síónì ti ọ̀run ní orúkọ tuntun kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 347]
Lóde òní, ẹgbẹ́ olùṣọ́ ti Jèhófà kò panu mọ́