Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
14 Lẹ́yìn náà, wò ó! mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ tó dúró lórí Òkè Síónì,+ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000) wà pẹ̀lú rẹ̀, a kọ orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba+ rẹ̀ sí iwájú orí wọn. 2 Mo gbọ́ ìró kan tó dún láti ọ̀run bí ìró omi púpọ̀ àti bí ìró ààrá tó rinlẹ̀ gan-an; ìró tí mo gbọ́ náà sì dà bíi ti àwọn akọrin tí wọ́n ń ta háàpù sí orin tí wọ́n ń kọ. 3 Wọ́n sì ń kọ orin kan tó dà bí orin tuntun+ níwájú ìtẹ́ àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ àti àwọn àgbààgbà náà,+ kò sì sí ẹnì kankan tó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000) tí a ti rà látinú ayé. 4 Àwọn yìí kò fi obìnrin sọ ara wọn di aláìmọ́; kódà, wúńdíá ni wọ́n.+ Àwọn ló ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lọ síbikíbi tó bá ń lọ.+ A rà wọ́n+ látinú aráyé, wọ́n sì jẹ́ àkọ́so+ fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, 5 kò sí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu wọn; wọn ò sì ní àbààwọ́n.+
6 Mo rí áńgẹ́lì míì tó ń fò lójú ọ̀run,* ó ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti kéde fún àwọn tó ń gbé ayé, fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn.+ 7 Ó ń sọ̀rọ̀ tó dún ketekete pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, torí wákàtí tó máa ṣèdájọ́ ti dé,+ torí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun+ àti àwọn ìsun* omi.”
8 Áńgẹ́lì kejì tẹ̀ lé e, ó ń sọ pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá+ ti ṣubú,+ ẹni tó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀!”+
9 Áńgẹ́lì kẹta tẹ̀ lé wọn, ó sì ń fi ohùn tó dún ketekete sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko náà+ àti ère rẹ̀, tó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀,+ 10 òun náà máa mu nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tó tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìbínú Rẹ̀,+ a sì máa fi iná àti imí ọjọ́+ dá a lóró níwájú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 11 Àwọn tó ń jọ́sìn ẹranko náà àti ère rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tó bá gba àmì orúkọ rẹ̀,+ èéfín oró* wọn á máa gòkè lọ títí láé àti láéláé,+ wọn ò sì ní sinmi tọ̀sántòru. 12 Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́ ní ìfaradà nìyí,+ àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́+ Jésù.”
13 Mo gbọ́ tí ohùn kan dún láti ọ̀run pé, “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn òkú tó kú ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Olúwa+ láti ìsinsìnyí lọ. Àní, ohun tí ẹ̀mí sọ nìyẹn, kí wọ́n sinmi kúrò nínú wàhálà wọn, torí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”*
14 Lẹ́yìn náà, wò ó! mo rí ìkùukùu* funfun kan, ẹnì kan tó rí bí ọmọ èèyàn jókòó sórí ìkùukùu* náà,+ ó dé adé wúrà, dòjé tí ẹnu rẹ̀ mú sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Áńgẹ́lì míì jáde látinú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, ohùn rẹ̀ dún ketekete bó ṣe ń sọ fún ẹni tó jókòó sórí ìkùukùu pé: “Ti dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kórè, torí wákàtí ìkórè ti tó, ayé ti gbó dáadáa, ó sì ti tó kórè.”+ 16 Ẹni tó jókòó sórí ìkùukùu ti dòjé rẹ̀ bọ ayé, ó sì kórè ayé.
17 Síbẹ̀, áńgẹ́lì míì jáde látinú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní ọ̀run, dòjé tó mú wà lọ́wọ́ òun náà.
18 Áńgẹ́lì míì tún jáde láti ibi pẹpẹ, ó ní àṣẹ lórí iná. Ó sì fi ohùn tó dún ketekete sọ fún ẹni tí dòjé tó mú wà lọ́wọ́ rẹ̀, pé: “Ti dòjé rẹ tó mú bọ̀ ọ́, kí o sì kó àwọn òṣùṣù èso àjàrà ayé jọ, torí èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.”+ 19 Áńgẹ́lì náà ti dòjé rẹ̀ bọ ayé, ó kó àjàrà ayé jọ, ó sì jù ú síbi tí ó tóbi tí a ti ń fún wáìnì ti ìbínú Ọlọ́run.+ 20 A sì tẹ àjàrà náà ní òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì tú jáde láti ibi tí a ti ń fún wáìnì náà, ó ga dé ìjánu àwọn ẹṣin, ó sì lọ jìnnà dé ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ìwọ̀n Sítédíọ̀mù.*